ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 53:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Àmọ́ ó wu Jèhófà* láti tẹ̀ ẹ́ rẹ́, ó sì jẹ́ kó ṣàìsàn.

      Tí o bá máa fi ẹ̀mí* rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀bi,+

      Ó máa rí ọmọ* rẹ̀, ó máa mú kí àwọn ọjọ́ rẹ̀ gùn,+

      Ohun tí inú Jèhófà dùn sí* sì máa yọrí sí rere nípasẹ̀ rẹ̀.+

  • Dáníẹ́lì 9:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 “A ti pinnu àádọ́rin (70) ọ̀sẹ̀* fún àwọn èèyàn rẹ àti ìlú mímọ́ rẹ,+ láti fòpin sí àṣìṣe, láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́,+ láti ṣe ètùtù torí ìṣìnà,+ láti mú òdodo tó máa wà títí láé wá,+ láti gbé èdìdì lé ìran náà àti àsọtẹ́lẹ̀*+ àti láti fòróró yan Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́.*

  • Mátíù 20:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ èèyàn ò ṣe wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kó sì fi ẹ̀mí* rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”+

  • Gálátíà 3:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Kristi rà wá,+ ó tú wa sílẹ̀+ lábẹ́ ègún Òfin bó ṣe di ẹni ègún dípò wa, nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹni ègún ni ẹni tí a gbé kọ́ sórí òpó igi.”+

  • Títù 2:13, 14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 bí a ti ń dúró de àwọn ohun aláyọ̀ tí à ń retí+ àti bí Ọlọ́run Olódùmarè ṣe máa fara hàn nínú ògo pẹ̀lú Olùgbàlà wa, Jésù Kristi, 14 ẹni tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ nítorí wa+ kó lè tú wa sílẹ̀*+ kúrò nínú gbogbo onírúurú ìwà tí kò bófin mu, kó sì wẹ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́, àwọn ohun ìní rẹ̀ pàtàkì, tí wọ́n ní ìtara fún iṣẹ́ rere.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́