29 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ ti ṣàṣìṣe, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run;+30 torí nígbà àjíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+
24 Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣebí ìdí tí ẹ fi ṣàṣìṣe nìyẹn, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run?+25 Torí tí wọ́n bá jíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+