ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 26:47-51
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 47 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! Júdásì, ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà dé pẹ̀lú èrò rẹpẹtẹ tí wọ́n kó idà àti kùmọ̀ dání, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà ló rán wọn wá.+

      48 Ẹni tó fẹ́ dà á ti fún wọn ní àmì kan, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un.” 49 Ó wá lọ tààràtà sọ́dọ̀ Jésù, ó sọ pé: “Mo kí ọ o, Rábì!” ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 50 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Ọ̀gbẹ́ni, kí lo wá ṣe níbí?”+ Ni wọ́n bá wá síwájú, wọ́n gbá Jésù mú, wọ́n sì mú un sọ́dọ̀. 51 Àmọ́ wò ó! ọ̀kan lára àwọn tó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ dà nù.+

  • Lúùkù 22:47-51
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 47 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! àwọn èrò dé, ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní Júdásì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà, ló ṣáájú wọn, ó sì sún mọ́ Jésù kó lè fẹnu kò ó lẹ́nu.+ 48 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Júdásì, ṣé o fẹ́ fi ẹnu ko Ọmọ èèyàn lẹ́nu kí o lè dalẹ̀ rẹ̀ ni?” 49 Nígbà tí àwọn tó yí i ká rí ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, wọ́n sọ pé: “Olúwa, ṣé ká fi idà bá wọn jà?” 50 Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù.+ 51 Àmọ́ Jésù fèsì pé: “Ó tó.” Ló bá fọwọ́ kan etí ọkùnrin náà, ó sì wò ó sàn.

  • Jòhánù 18:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Torí náà, Júdásì kó àwùjọ àwọn ọmọ ogun àti àwọn òṣìṣẹ́ ti àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí, wọ́n sì wá síbẹ̀, tàwọn ti ògùṣọ̀, fìtílà àti ohun ìjà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́