ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 20:29-34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 Bí wọ́n ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, èrò rẹpẹtẹ tẹ̀ lé e. 30 Wò ó! àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tí wọ́n jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!”+ 31 Àmọ́ àwọn èrò náà bá wọn wí, wọ́n ní kí wọ́n dákẹ́; àmọ́ ṣe ni wọ́n tún ń kígbe sókè pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!” 32 Torí náà, Jésù dúró, ó pè wọ́n, ó sì sọ pé: “Kí lẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?” 33 Wọ́n sọ fún un pé: “Olúwa, jẹ́ kí ojú wa là.” 34 Àánú wọn ṣe Jésù, ó sì fọwọ́ kan ojú wọn,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n pa dà ríran, wọ́n sì tẹ̀ lé e.

  • Máàkù 10:46-52
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 46 Wọ́n wá dé Jẹ́ríkò. Àmọ́ bí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, Báátíméù (ọmọ Tíméù), afọ́jú tó ń ṣe agbe, jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà.+ 47 Nígbà tó gbọ́ pé Jésù ará Násárẹ́tì ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, ó sì ń sọ pé: “Ọmọ Dáfídì,+ Jésù, ṣàánú mi!”+ 48 Ni ọ̀pọ̀ èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, wọ́n ní kó dákẹ́, àmọ́ ṣe ló túbọ̀ ń kígbe pé: “Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 49 Torí náà, Jésù dúró, ó sì sọ pé: “Ẹ pè é wá sọ́dọ̀ mi.” Wọ́n wá pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n sọ fún un pé: “Mọ́kàn le! Dìde; ó ń pè ọ́.” 50 Ló bá bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ dà nù, ó fò dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Jésù. 51 Jésù wá sọ fún un pé: “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ọkùnrin afọ́jú náà sọ fún un pé: “Rábónì,* jẹ́ kí n pa dà ríran.” 52 Jésù sì sọ fún un pé: “Máa lọ. Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pa dà ríran,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e lójú ọ̀nà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́