-
1 Kíróníkà 24:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Bí a ṣe ṣètò iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn+ nígbà tí wọ́n bá wá sínú ilé Jèhófà nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí Áárónì baba ńlá wọn ṣe là á kalẹ̀ àti bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣe pa á láṣẹ fún un.
-
-
2 Kíróníkà 8:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Síwájú sí i, ó yan àwùjọ àwọn àlùfáà+ sí àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dáfídì bàbá rẹ̀ fi lélẹ̀, ó yan àwọn ọmọ Léfì sẹ́nu iṣẹ́ wọn, láti máa yin+ Ọlọ́run àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú àwọn àlùfáà bí wọ́n ti ń ṣe lójoojúmọ́, ó tún yan àwùjọ àwọn aṣọ́bodè sí ẹnubodè kọ̀ọ̀kan,+ nítorí ohun tí Dáfídì, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ nìyẹn.
-
-
2 Kíróníkà 31:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Nígbà náà, Hẹsikáyà yan àwọn àlùfáà sí àwùjọ wọn,+ ó sì yan àwọn ọmọ Léfì sí àwùjọ wọn,+ ó yan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn,+ láti máa rú ẹbọ sísun, kí wọ́n sì máa rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́, kí wọ́n máa dúpẹ́, kí wọ́n sì máa yin Ọlọ́run ní àwọn ẹnubodè tó wà ní àwọn àgbàlá* Jèhófà.+
-