26 Nígbà tí olùrànlọ́wọ́ tí màá rán sí yín látọ̀dọ̀ Baba bá dé, ẹ̀mí òtítọ́,+ tó wá látọ̀dọ̀ Baba, ó máa jẹ́rìí nípa mi;+27 kí ẹ̀yin náà sì jẹ́rìí,+ torí pé ẹ ti wà pẹ̀lú mi láti ìbẹ̀rẹ̀.
8 Àmọ́, ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín,+ ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí+ mi ní Jerúsálẹ́mù,+ ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà+ àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”*+