JÓNÀ
1 Jèhófà bá Jónà*+ ọmọ Ámítáì sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Gbéra, lọ sí Nínéfè+ ìlú ńlá náà, kí o sì kéde ìdájọ́ mi fún wọn, torí mo ti rí gbogbo ìwà burúkú wọn.”
3 Àmọ́ Jónà fẹ́ lọ sí Táṣíṣì, kó lè sá fún Jèhófà. Torí náà, ó gbéra, ó lọ sí Jópà, ó sì rí ọkọ̀ òkun kan tó ń lọ sí Táṣíṣì. Ó san owó ọkọ̀, ó sì wọlé láti bá wọn lọ sí Táṣíṣì, kó lè sá fún Jèhófà.
4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí ìjì kan tó lágbára jà lórí òkun, ìjì náà sì le débi pé ọkọ̀ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ ya. 5 Ẹ̀rù ba àwọn atukọ̀ òkun náà gan-an, kálukú wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe ọlọ́run rẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́. Ni wọ́n bá ń ju àwọn nǹkan tó wà nínú ọkọ̀ náà sínú òkun, kó lè fúyẹ́.+ Àmọ́ Jónà ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀* náà, ó sì ti sùn lọ fọnfọn. 6 Lẹ́yìn náà, ọ̀gá àwọn atukọ̀ lọ bá a, ó sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ò ń sùn? Dìde, ké pe ọlọ́run rẹ! Bóyá Ọlọ́run tòótọ́ á tiẹ̀ ṣàánú wa, ká má bàa ṣègbé.”+
7 Wọ́n wá sọ fún ara wọn pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká ṣẹ́ kèké,+ ká lè mọ ẹni tó fa àjálù yìí.” Ni wọ́n bá ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jónà.+ 8 Torí náà, wọ́n bi í pé: “Jọ̀ọ́ sọ fún wa, ta ló fa àjálù yìí? Iṣẹ́ wo lò ń ṣe, ibo lo ti wá? Ọmọ orílẹ̀-èdè wo ni ọ́, ẹ̀yà wo lo sì ti wá?”
9 Jónà fèsì pé: “Hébérù ni mí. Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run, Ẹni tó dá òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ ni mò ń sìn.”*
10 Èyí dẹ́rù ba àwọn ọkùnrin náà gan-an, wọ́n sì bí i pé: “Kí lo ṣe?” (Àwọn ọkùnrin náà ti mọ̀ pé ó ń sá fún Jèhófà, torí ó ti sọ fún wọn.) 11 Wọ́n wá bi í pé: “Kí ni ká ṣe sí ọ, kí òkun bàa lè pa rọ́rọ́ fún wa?” Torí ìjì náà túbọ̀ ń le sí i. 12 Ó fèsì pé: “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì jù mí sínú òkun, òkun yóò sì pa rọ́rọ́ fún yín; torí mo mọ̀ pé èmi ni mo fa ìjì líle tó dé bá yín.” 13 Àmọ́ àwọn ọkùnrin náà fi gbogbo okun wọn tukọ̀ náà* kí wọ́n lè ṣẹ́rí rẹ̀ pa dà sí etíkun, ṣùgbọ́n wọn ò rí i ṣe, torí ìjì náà ń le sí i níbi tí wọ́n wà.
14 Ni wọ́n bá ké pe Jèhófà, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ ká ṣègbé nítorí ọkùnrin yìí!* Jèhófà, jọ̀ọ́ má ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa lọ́rùn, torí o ti ṣe ohun tí o fẹ́.” 15 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé Jónà, wọ́n sì jù ú sínú òkun; bí òkun náà ṣe pa rọ́rọ́ nìyẹn. 16 Èyí mú kí àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Jèhófà gan-an,+ torí náà, wọ́n rúbọ sí Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.
17 Jèhófà wá mú kí ẹja ńlá kan gbé Jónà mì, ọjọ́ mẹ́ta* sì ni Jónà fi wà nínú ikùn ẹja náà.+
2 Ìgbà yẹn ni Jónà gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ikùn ẹja náà,+ 2 ó sì sọ pé:
“Mo ké pe Jèhófà nígbà tí mo wà nínú ìṣòro, ó sì dá mi lóhùn.+
Láti inú* Isà Òkú* ni mo ti kígbe pé kí o ràn mí lọ́wọ́.+
O sì gbọ́ ohùn mi.
3 Nígbà tí o jù mí sínú ibú omi, sínú agbami òkun,
Omi òkun bò mí mọ́lẹ̀.+
Gbogbo ìgbì òkun àti omi rẹ tó ń ru gùdù sì kọjá lórí mi.+
4 Mo sì sọ pé, ‘O ti lé mi kúrò níwájú rẹ!
Ṣé màá tún lè pa dà rí tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ báyìí?’
Koríko inú omi wé mọ́ mi lórí.
6 Mo rì wọnú ibú omi lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè.
Ní ti ilẹ̀ ayé, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ wà lórí mi títí láé.
Àmọ́, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi gbé mi dìde láàyè látinú kòtò.+
7 Jèhófà, ìwọ ni Ẹni tí mo rántí nígbà tí ẹ̀mí* mi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́.+
Ìgbà yẹn ni mo gbàdúrà sí ọ, àdúrà mi sì wọnú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ.+
8 Àwọn tó ń sin òrìṣà lásánlàsàn ti kọ ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí wọn.*
9 Àmọ́ ní tèmi, màá fi ohùn mi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ bí mo ṣe ń rúbọ sí ọ.
Màá san ẹ̀jẹ́ mi.+
Jèhófà ló ń gbani là.”+
10 Nígbà tó yá, Jèhófà pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jónà sórí ilẹ̀.
3 Jèhófà tún bá Jónà sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì pé:+ 2 “Gbéra, lọ sí Nínéfè + ìlú ńlá náà, kí o sì lọ jíṣẹ́ tí mo rán ọ.”
3 Torí náà, Jónà gbéra, ó sì lọ sí Nínéfè,+ bí Jèhófà ṣe sọ fún un.+ Ìlú Nínéfè tóbi gan-an,* ọjọ́ mẹ́ta ló máa ń gbà láti rìn yí i ká. 4 Jónà bá wọnú ìlú náà, ó rin ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde pé: “Ogójì (40) ọjọ́ péré ló kù kí Nínéfè pa run.”
5 Àwọn ará ìlú Nínéfè wá gba Ọlọ́run gbọ́,+ wọ́n kéde pé kí gbogbo ìlú gbààwẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* látorí ẹni tó tóbi jù dórí ẹni tó kéré jù. 6 Nígbà tí ọba Nínéfè gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ aṣọ oyè rẹ̀, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì jókòó sínú eérú. 7 Yàtọ̀ síyẹn, ó ní kí wọ́n kéde ní gbogbo ìlú Nínéfè pé:
“Ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ti pàṣẹ pé: Èèyàn tàbí ẹran èyíkéyìí, títí kan agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, kò gbọ́dọ̀ fi ẹnu kan ohunkóhun. Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹun, wọn ò sì gbọ́dọ̀ mu omi. 8 Kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, èèyàn àti ẹran; kí wọ́n ké pe Ọlọ́run tọkàntọkàn, kí wọ́n yí ìwà burúkú wọn pa dà, kí wọ́n sì jáwọ́ nínú ìwà ipá. 9 Ta ló mọ̀ bóyá Ọlọ́run tòótọ́ máa pèrò dà* nípa ohun tó ní lọ́kàn, kó sì yí ìbínú rẹ̀ pa dà, ká má bàa ṣègbé?”
10 Nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ rí ohun tí wọ́n ṣe, bí wọ́n ṣe yí ìwà burúkú wọn pa dà,+ ó pèrò dà* nípa àjálù tó sọ pé òun máa mú kó dé bá wọn, kò sì jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí wọn.+
4 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú sì bí i gan-an. 2 Torí náà, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jèhófà, ṣebí ohun tí mo rò nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi ló wá ṣẹlẹ̀ yìí? Torí ẹ̀ ni mo ṣe kọ́kọ́ sá lọ sí Táṣíṣì.+ Mo ti mọ̀ pé Ọlọ́run tó máa ń gba tẹni rò* ni ọ́, o jẹ́ aláàánú, o kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi, inú rẹ kì í sì í dùn sí àjálù. 3 Jèhófà, jọ̀ọ́ gbẹ̀mí* mi, torí ó sàn kí n kú ju kí n wà láàyè.”+
4 Jèhófà bi í pé: “Ṣé ó yẹ kí inú bí ẹ tó báyìí?”
5 Jónà wá jáde kúrò nínú ìlú náà, ó sì lọ jókòó sí apá ìlà oòrùn ìlú náà. Ó ṣe àtíbàbà kan síbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó sábẹ́ rẹ̀ kó lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.+ 6 Lẹ́yìn náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí ewéko akèrègbè* kan hù bo àtíbàbà tí Jónà ṣe, kó lè ṣíji bo orí rẹ̀, kí ara sì tù ú. Inú Jónà dùn gan-an sí ewéko tó hù yìí.
7 Àmọ́ bí ilẹ̀ ọjọ́ kejì ṣe ń mọ́ bọ̀, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí kòkòrò mùkúlú kan jẹ ewéko akèrègbè náà, ó sì rọ. 8 Nígbà tí oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí í ràn, Ọlọ́run tún mú kí afẹ́fẹ́ tó gbóná fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, oòrùn sì pa Jónà lórí débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dá kú. Ó ń sọ ṣáá pé kí òun kú,* ó sì ń sọ pé: “Ó sàn kí n kú ju kí n wà láàyè.”+
9 Ọlọ́run wá bi Jónà pé: “Ṣé ó yẹ kí inú bí ẹ tó báyìí torí ewéko akèrègbè yìí?”+
Ó fèsì pé: “Ó tọ́ kí n bínú, kódà inú ń bí mi débi pé mi ò kọ̀ kí n kú.” 10 Àmọ́ Jèhófà sọ fún un pé: “O káàánú ewéko akèrègbè tí o kò ṣiṣẹ́ fún, tí kì í ṣe ìwọ lo mú kó hù; ó hù ní alẹ́, ó sì kú lọ́jọ́ kejì. 11 Ṣé kò wá yẹ kí n ṣàánú Nínéfè tó jẹ́ ìlú ńlá,+ tí àwọn èèyàn ibẹ̀ lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000), tí wọn ò sì mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí èyí tí kò tọ́,* títí kan ọ̀pọ̀ ẹran tó wà níbẹ̀?”+
Ó túmọ̀ sí “Àdàbà.”
Tàbí “ọkọ̀ òkun alájà òkè.”
Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Tàbí “wá bí wọ́n ṣe máa kọjá.”
Tàbí “nítorí ọkàn ọkùnrin yìí!”
Ní Héb., “ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.”
Ní Héb., “ikùn.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “Omi yí mi ká títí dé ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí kó jẹ́, “ti di aláìṣòótọ́.”
Ní Héb., “tóbi lójú Ọlọ́run.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”
Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Tàbí “gba ọkàn.”
Tàbí kó jẹ́, “ewéko láà.”
Tàbí “kí ọkàn òun kú.”
Tàbí “mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì wọn.”