ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/22 ojú ìwé 19-24
  • Ọmọ Àkèré

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọmọ Àkèré
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Mo Ń Ṣe Gẹ́gẹ́ Bí Afọ̀jọ̀jọ̀-Àlejò-Ṣiṣẹ́ṣe
  • Ta Ni Ìyá Mi?
  • Ọmọkùnrin Kan ní Àkókò Ogun
  • Ojúṣe Mi Nínú Ìdílé
  • Pípèsè fún Ọmọbìnrin Mi
  • Ìsìn Di Iṣu Ata-yán-an-yàn-an
  • Ìyípadà Nínú Ìgbésí Ayé Mi
  • Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ Mi
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Ìgbàṣọmọ—Ojú Wo Ni Ó Yẹ Kí N Fi Wò Ó?
    Jí!—1996
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 2/22 ojú ìwé 19-24

Ọmọ Àkèré

“Àkèré lọmọ àkèré.”

Òwe àwọn ará Japan yìí túmọ̀ sí pé ọmọ máa ń dàgbà, tí yóò sì rí gẹ́lẹ́ bí àwọn òbí rẹ̀ ni.

Afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe ni ìyá mi.

MO GBỌ́NJÚ sí ilé iṣẹ́ àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe kan tí ìyá mi ń darí. Nítorí bẹ́ẹ̀, láti ìgbà tí mo ti wà ní kékeré ni àwọn òrékelẹ́wà tí wọ́n máa ń wọ aṣọ gbàgẹ̀rẹ̀ ilẹ̀ Japan tí ó gbówó lórí jù lọ ti wà láyìíká mi. Mo mọ̀ pé bí mo bá dàgbà, èmi náà yóò dara pọ̀ mọ́ wọn nínú iṣẹ́ yìí. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ mi bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1928, ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹfà ọdún tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́fà. Wọ́n gbà gbọ́ pé nọ́ḿbà 666 máa ń mú kí ènìyàn ṣàṣeyọrí.

Mo kọ́ àwọn iṣẹ́ ọnà àtayébáyé ilẹ̀ Japan—ijó jíjó, orin kíkọ, lílo àwọn ohun èèlò orin, ṣíṣe ayẹyẹ iṣenilalejo lọ́nà ìṣẹ̀ǹbáyé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lójoojúmọ́, lẹ́yìn tí mo bá ti jáde ilé ẹ̀kọ́, n óò sáré lọ sílé, n óò pààrọ̀ ẹ̀wù mi, n óò sì lọ sí ibi tí wọ́n ti ń kọ́ mi. Nígbà tí mo bá débẹ̀, n óò dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi ní ilé ẹ̀kọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé gbogbo wa ni a jẹ́ ọmọ afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe. Ọwọ́ wa máa ń dí gan-an nígbà náà, mo sì gbádùn rẹ̀.

Ní ìgbà náà lọ́hùn-ún, ṣaájú Ogun Àgbáyé Kejì, ẹ̀kọ́ ìwé tí a kàn nípá dópin ní ọmọ ọdún 12, nítorí náà, ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nìyẹn. Níwọ̀n bí mo sì ti jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀dé afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe síbẹ̀, mo máa ń wọ àwọn aṣọ gbàgẹ̀rẹ̀ ilẹ̀ Japan tí ó gbayì, tí ọwọ́ rẹ̀ yóò sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máa wọ́lẹ̀. Inú mi dùn dẹ́yìn nígbà tí mo ń lọ síbi iṣẹ́ mi àkọ́kọ́.

Ohun Tí Mo Ń Ṣe Gẹ́gẹ́ Bí Afọ̀jọ̀jọ̀-Àlejò-Ṣiṣẹ́ṣe

Lájorí ohun tí iṣẹ́ mi jẹ mọ́ ni dídá àwọn ènìyàn lárayá àti ṣíṣe bí agbàlejò. Nígbà tí àwọn ọlọ́lá bá wéwèé àríyá ní àwọn ilé àrójẹ kàǹkà-kàǹkà, wọn yóò ké sí ilé iṣẹ́ àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe, wọn yóò sì sọ pé kí àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe bíi mélòó kan wá ṣiṣẹ́ fún àwọn. A retí pé kí àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe náà mú kí alẹ́ náà rọ̀ ṣọ̀mù, kí wọ́n sì rí i dájú pé gbogbo àwọn àlejò ni wọ́n darí sílé pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, nípa níní ìmọ̀lára pé àwọ́n ti lọ yọ̀tọ̀mì.

Láti ṣe èyí, a ní láti ronú ohun tí àlejò kọ̀ọ̀kan fẹ́, kí a sì pèsè rẹ̀—àní kí àlejò náà tilẹ̀ tóó mọ̀ pé òún fẹ́ nǹkan pàápàá. Mo rò pé èyí tí ó le jù lọ níbẹ̀ ni ṣíṣe ohunkóhun tí wọ́n bá bèèrè lọ́wọ́ wa lójú ẹsẹ̀ tí wọ́n bá bèèrè. Bí àwọn àlejò bá fẹ́ láti wòran ijó jíjó, a óò jó. Bí wọ́n bá fẹ́ orin, a óò gbé àwọn ohun èèlò orin wa, a óò sì fi àwọn ohun èèlò náà kọrin tí wọ́n bá ń bèèrè fún, tàbí kí a kọ irú orin yòówù tí wọ́n bá fẹ́ kí a kọ.

Èrò tí kò tọ̀nà tí ó wọ́pọ̀ tí àwọn ènìyàn ní ni pé gbogbo àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe ló jẹ́ àgbà aṣẹ́wó, tí tiwọn ti kúrò ní ti gbáàtúẹ̀yọ̀. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe kan wà tí ń wá àtijẹ àtimu nípa títa ara wọn, kò sí ìdí kankan tí afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe fi gbọ́dọ̀ fi ara rẹ̀ wọ́lẹ̀ débẹ̀ yẹn. Mo mọ̀ nítorí pé èmi fúnra mi kò ṣe bẹ́ẹ̀ rí. Adánilárayá ni afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe kan jẹ́, bí ó bá sì mọwọ́ rẹ̀, òye iṣẹ́ tí ó ní yóò mú iṣẹ́, àwọn ẹ̀bùn gbígbówó lórí, àti ẹ̀bùn owó wọlé fún un láti ọ̀dọ̀ àwọn oníbàárà.

Òtítọ́ ni pé, ìwọ̀nba díẹ̀ ló máa ń rọ́wọ́ mú. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe máa ń mọ ọ̀kan ṣoṣo nínú àwọn iṣẹ́ ọnà àtayébáyé ilẹ̀ Japan dunjú. Ṣùgbọ́n mo gba oyè nínú iṣẹ́ ọnà méje, èyí tí ó ní nínú ijó Japan, títo òdòdó, ṣíṣe ayẹyẹ ìṣenilálejò lọ́nà ìṣẹ̀ǹbáyé, lílu ìlù ilẹ̀ Japan tí à ń pè ní taiko, àti àwọn ọ̀nà ìgbàkọrin mẹ́ta pẹ̀lú ohun èèlò orin olókùn mẹ́ta tí à ń pè ní shamisen. Láìsí àwọn ìdáńgájíá òye iṣẹ́ wọ̀nyí, bóyá èmi náà ì bá ti rí i bí ohun tí ó pọn dandan láti ṣe ohunkohun tí àwọn oníbàárà bá sọ pé kí n ṣe láti fi lè gbọ́ bùkáátà.

Nígbà tí ipò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Japan kò fara rọ, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọbìnrin máa ń yàn láti di afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe kí wọ́n baà lè ti ìdílé wọn lẹ́yìn. Wọ́n máa ń yáwó láti lè sanwó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti aṣọ gbàgẹ̀rẹ̀ ilẹ̀ Japan wọn. Ìdílé àwọn mìíràn tà wọ́n sí ilé iṣẹ́ afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe. Nítorí pé àwọn olówó wọn ti san owó bàǹtà-banta, wọ́n máa ń bèèrè àsanpadà láti ọwọ́ àwọn ọmọbìnrin yìí. Nǹkan kì í sàn fún àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe tí wọ́n bá wà nínú irú ipò yìí, nítorí pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọ́n máa ń pẹ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀, wọn sì máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn pẹ̀lú gbèsè lọ́rùn. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe máa ń yíjú sí ìwà pálapàla kí wọ́n baà lè gbọ́ bùkáátà wọn, tàbí kí ó jẹ́ pé ipò nǹkan tì wọ́n wọ̀ ọ́.

Iṣẹ́ mi di ohun tí àwọn ènìyàn gbígbajúmọ̀ ní agbo eré ìdárayá, eré ìnàjú, ìṣòwò, àti ìṣèlú ń bèèrè fún. Àwọn aṣòfin àti àwọn mínísítà àgbà orílẹ̀-èdè wà lára àwọn oníbàárà mi. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí máa ń fi ọ̀wọ̀ fún mi, wọ́n sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún iṣẹ́ tí mo ń ṣe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í dá sí ọ̀rọ̀ tí gbogbo wọ́n bá ń sọ, tí kì í bá ṣe pé wọ́n pè mí sí i, nígbà míràn wọ́n máa ń sọ pé kí ń sọ ohun tí mo bá rò nípa ọ̀rọ̀ kan. Nítorí èyí, mo máa ń ka àwọn ìwé agbéròyìnjáde, mo sì máa ń tẹ́tí sí rédíò lójoojúmọ́, kí n baà lè mọ ohun tí ń lọ lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ibi àwọn àríyá tí wọ́n ti ń ṣe ìdúnàádúrà ni mo ti máa ń ṣiṣẹ́, nítorí èyí, mo gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó gbọ́n, kí n sì máà sọ ohun tí mo bá gbọ́ jáde.

Ta Ni Ìyá Mi?

Ní ọjọ́ kan ní ọdún 1941, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún 19, wọ́n sọ pé kí n wá ní ilé àrójẹ kan, mo sì bá àwọn obìnrin méjì tí wọ́n ń dúró dè mí níbẹ̀. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé òun ni ìyá tí ó bí mi lọ́mọ, àti pé òún wá mú mi ni. Obìnrin kejì gba àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe, ó sì gbé iṣẹ́ fún mi. O ronú pé mo ní láti máa ṣiṣẹ́ kí n lè ti ìyá tí ó bí mi lọ́mọ lẹ́yìn, dípò ìyá tí ó gbà mí tọ́. Kò tilẹ̀ wá sọ́kàn mi rí pé ìyá tí ó tọ́ mi dàgbà kì í ṣe ìyá mi gan-an.

Níwọ̀n bí gbogbo rẹ̀ ti dojú rú mọ́ mi lọ́wọ́, mo sáré lọ sílé, mo sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ìyá tí ó gbà mí tọ́. Nǹkan kì í sábà wọ̀ ọ́ lára tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n omi ń bọ́ lójú rẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí. Ó sọ pé òun ti fẹ́ kí ó jẹ́ pé òún ni òun sọ fún mi pé nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún kan ni wọ́n ti jù mí sí ilé iṣẹ́ àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe. Nígbà tí mo gbọ́ òtítọ́ yìí, gbogbo ìgbọ́kànlé tí mo ní nínú ènìyàn ló pòórá, mo sì di ẹni tí ń ṣe túú, tí ó sì ń ṣe jẹ́ẹ́.

Mo kọ̀ láti gba ìyà tí ó bí mi lọ́mọ. Fún ọwọ́ ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ tí a fi pàdé, ó ṣe kedere pé, ó mọ̀ nípa àṣeyọrí tí mo ti ní, ó sì fẹ́ kí n máa ṣiṣẹ́ láti fi ti òun lẹ́yìn. Nítorí apá ibi tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́, mo mọ̀ pé iṣẹ́ rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìwà pálapàla. Mo fẹ́ láti wá àtijẹ-àtimu nípa lílo ẹ̀bùn iṣẹ́ ọnà, kì í ṣe nípa títa ara mi. Mo lérò pé mò ń ṣe ìpinnu tí ó tọ̀nà nígbà náà, bẹ́ẹ̀ náà ni mo sì ṣe rò nísinsìnyí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú bí mi sí ìyá tí ó gbà mí tọ́, kí á sọ tòótọ́, ó ti dá mi lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí mo fi lè gbọ́ bùkátà ara mi. Bí mo bá ṣe ronú nípa rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe máa ń kún fún ọpẹ́ sí i tó. Ó sábà máa ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yan ibi tí n óò ti ṣiṣẹ́ fún mi, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bò mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń wá kí afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe wá ṣiṣẹ́ fún àwọn kìkì nítorí àtiṣe ìṣekúṣe. Títí di òní olónìí ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìyẹn.

Ó kọ́ mi ní ìlànà ìwà rere. Ọ̀kan tí ó tẹnu mọ́ jù ni pé kí bẹ́ẹ̀ ni mi jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí bẹ́ẹ̀ kọ́ mi sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó tún kọ́ mi láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́, kí n sì máa bá ara mi wí. Nítorí pé mo tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere tí ó kọ́ mi, mo ní àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ mi. Kò dájú pé ǹ bá ti rí irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ gbà lọ́wọ́ ìyá tí ó bí mi lọ́mọ. Gbígbà tí ó gbà mí tọ́ kò jẹ́ kí n gbé ìgbésí ayé àlùsì, mo sì dé orí èrò pé, ó dùn mọ́ mi pé ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Ọmọkùnrin Kan ní Àkókò Ogun

Mo bí ọmọkùnrin kan ní ọdún 1943. Ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Japan, tí kò mọ ohun tí ń jẹ́ “ẹ̀ṣẹ̀,” n kò rò pé mo ti ṣe ohun kan tí kò dára tàbí tí ń tini lójú. Ọmọ mi dùn mí nínú. Òun ni ohun tí ó ṣeyebíye jù lọ tí mo ní—ẹnì kan tí n óò máa torí rẹ̀ gbé ayé, tí n óò sì máa torí rẹ̀ ṣiṣẹ́.

Ní ọdún 1945, bọ́m̀bù fa Tokyo ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì di dandan kí n sá kúrò ní ìlú náà pẹ̀lú ọmọkùnrin mi. Oúnjẹ kò tó, ó sì ń ṣàìsàn gidigidi. Àwọn ènìyàn lọ́lùpọ̀ tíọtìọ ní ibùdókọ̀ ojú irin, àmọ́, a tiraka wọ ọkọ̀ ojú irin tí ń lọ sí ìhà àríwá ní Fukushima. A dúró níbẹ̀ ní ilé àlejò kan ní alẹ́ yẹn, àmọ́ kí n tó lè gbé ọmọkùnrin mi lọ sí ilé ìwòsàn, àìjẹunrekánú àti àìlómilára pa á. Ọmọ ọdún méjì péré ni nígbà náà. Ìbànújẹ́ bò mí. Ọkùnrin tí ń bá wọn se omi ní ilé àlejò náà sun ọmọ mi nínú iná tí ó fi ń se omi ìwẹ̀.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí ogún parí, mo sì padà sí Tokyo. Bọ́m̀bù ti sọ ìlú náà di ìdàkudà. Ilé mi àti gbogbo ohun tí mo ní ti lọ. Mo lọ sílé ọ̀rẹ́ kan. Ó yá mi ní asọ gbàgẹ̀rẹ̀ ilẹ̀ Japan rẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ padà. Ìyá tí ó gbà mi tọ́, tí ó ti kó kúrò lọ sí ibì kan lẹ́yìn òde Tokyo, sọ pé kí n fi owó ránṣẹ́, kí n sì kọ́ ilé kan fún òun ní Tokyo. Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ mú kí n nímọ̀lára bí ẹni tí ó dá nìkan wà ju bí mo tí ì ṣe rí lọ. Mo ṣì ń kẹ́dùn ọmọ mi, mo ṣì ń wá ìtùnú síbẹ̀, kò tilẹ̀ sọ pé òun yóò mẹ́nu ba ti ọmọ mi. Gbogbo ohun tí ó mú un lára ni ti ara rẹ̀.

Ojúṣe Mi Nínú Ìdílé

Àṣà kọ́ wa pé gbogbo ohun tí a bá ní jẹ́ ti àwọn òbí àti àwọn baba ńlá wa, àti pé ó jẹ́ ojúṣe àwọn ọmọ láti san oore fún àwọn òbí wọn nípa ṣíṣègbọràn sí wọn láìjanpata, kí wọ́n sì máa tọ́jú wọn títí tí wọn yóò fi kú. Nítorí èyí, mo ṣe ojúṣe mi, ṣùgbọ́n ohun tí ìyá tí ó gbà mi tọ́ ń bèèrè ti pọ̀ jù. Ó tún retí kí n ti àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ méjì tí ó gbà tọ́ lẹ́yìn. N kò mọ̀ títí tí mo fi pé ọmọ ọdún 19 pé wọn kì í ṣe ọmọ ìyá mi.

Ọ̀pọ̀ àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe ni kì í lọ́kọ, wọ́n kì í sì í fẹ́ẹ́ ní ọmọ tiwọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń gba àwọn ọmọbìnrin jòjòló láti àwọn ìdílé tí ó tòṣì wò, wọn yóò sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe, kìkì fún ète rírí ìtìlẹ́yìn owónàá gbà, kí wọ́n baà lè gbádùn ìgbésí ayé tí ó rọ̀ ṣọ̀mù nígbà tí wọ́n bá darúgbó. Ó bani nínú jẹ́ pé mo bẹ̀rẹ̀ síí lóye ìdí tí wọ́n fi fún mi ni gbogbo ìtọ́jú àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fún mi. Orí ibi ti gbogbo rẹ̀ dá lé ni ààbò owónàá fún ọjọ́ ọ̀la.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ń ṣe kàyéfì ìdí tí ó fi jẹ́ pé mo ní láti ti àwọn “arákùnrin” àti “arábìnrin,” tí gbogbo wọ́n lera, tí wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ lẹ́yìn, síbẹ̀ mo tẹ́wọ́ gba gbogbo rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ti àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lẹ́yìn, nípa ṣíṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá bèèrè fún. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìyá mi kúnlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀, ó tẹrí ba, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní ọjọ́ tí ó ṣaájú ikú rẹ̀ ní ọdún 1954. Ó sọ pé mo ti ṣe gudugudu méje, yàyà mẹ́fà. Ọ̀rọ̀ ìmoore àti ìdúpẹ́ kan ṣoṣo yìí dí gbogbo ọdún tí mo fi ṣiṣẹ́. Ìtẹ́lọ́rùn mímọ̀ pé mo ti gbé gbogbo ẹrù iṣẹ́ mi sì máa ń mú kí n sunkún síbẹ̀.

Pípèsè fún Ọmọbìnrin Mi

Ní ọdún 1947, mo di ìyá ọmọbìnrin kékeré kan, mo sì pinnu láti ṣiṣẹ́ kára láti kó ọrọ̀ jọ fún un. Alaalẹ́ ni mò ń jáde lọ ṣiṣẹ́. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré lórí ìtàgé ní àwọn ilé eré orí ìtàgé pàtàkì-pàtàkì ilẹ̀ Japan, irú bíi Kabukiza tí ó wà ní Ginza. Èyí náà máa ń mú owó wọlé gan-an.

Yálà níbi ijó jíjó ní o, tàbí níbi lílu ohun èèlò orin shamisen, ipò aṣíwájú ni wọ́n ṣáà máa ń fi mí sí. Síbẹ̀, láìka níní àṣeyọrí tí àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe mìíràn ń lálàá rẹ̀ sí, inú mi kò dùn. Bóyá n kì bá tí nímọ̀lára ìdánìkanwà tó bẹ́ẹ̀, ká ni mo ti lọ́kọ ni, ṣùgbọ́n, ìgbésí ayé afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe àti ìgbéyàwó kò bára dọ́gba. Kìkì ìtùnú tí mo ni ní Aiko, ọmọbìnrin mi kékeré, orí rẹ̀ ni mo sì kó gbogbo ìgbésí ayé mi lé.

Àwọn afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe sábà máa ń tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà, ì báà jẹ́ èyí tí àwọn fúnra wọn bí tàbí èyí tí wọ́n gbà tọ́, láti ṣe irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Mo tẹ̀ lé àṣà yẹn, àmọ́ nígbà tí ó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìgbésí ayé tí mò ń múra rẹ̀ sílẹ̀ fún. Bí ó bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, yóò túmọ̀ sí pé ìrandíran wa kò ní mọ ohun tí ìdílé gidi túmọ̀ sí. Mo fẹ́ já àṣà tí ó ń ta mọ́ra yẹn. Mo fẹ́ kí Aiko, àti àwọn ọmọ tí yóò bí gbádùn ìgbeyàwó àti ìgbésí ayé ìdílé tí gbogbo ènìyàn ń ní. N kò fẹ́ kí ọmọ àkèré yìí di àkèré!

Nígbà tí Aiko ń di ọ̀dọ́langba lọ, ó di ewèlè. Láti ìgbà tí ìyá tí ó gbà mi tọ́ ti kú ní nǹkan bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ tí mo gbà ni wọ́n ti jẹ́ kìkì alábàáṣeré kan ṣoṣo tí ó kù fún Aiko nílé. Ó nílò àkókò àti àfiyèsí mi lójú méjèèjì. Nítorí èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ ní ọmọ 30 ọdún ni, tí ọwọ́ iná iṣẹ́ mi sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í jó, mo pinnu láti fi iṣẹ́ afọ̀jọ̀jọ̀-àlejò-ṣiṣẹ́ṣe sílẹ̀, kí n sì máa gba iṣẹ́ ijó jíjó àti fífi ohun èèlò shamisen ṣeré nìkan. Mo paṣẹ́ tì nítorí ti Aiko. A bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun alẹ́ pa pọ̀, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lójú ẹsẹ̀ ló ti yíwà padà. Fífún un ní àkókò mi ṣiṣẹ́ ribiribi lára rẹ̀.

Nígbà tí ó yá, a ṣí lọ sí agbègbè ilé gbígbé kan tí ó parọ́rọ́, níbi tí mo ti ṣí ìsọ̀ kọfí. Aiko dàgbà, inú mi sì dùn láti rí i tí ó fẹ́ Kimihiro, ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ kan tí ó fí òye hàn sí irú ìgbésí ayé tí mo ti gbé.

Ìsìn Di Iṣu Ata-yán-an-yàn-an

Ní ọdún 1968, Aiko bí ọmọ ọmọ mi àkọ́kọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí ó fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Èyí yà mí lẹ́nu, nítorí pé a ti ní ìsìn kan tẹ́lẹ̀. Mo ti kọ́ pẹpẹ ìjọsìn Buddha ńlá kan sínú ilé wa lẹ́yìn tí Ìyá—ìyá tí ó gbà mí tọ́—kú, gbogbo ìgbà ni mo sì máa ń wólẹ̀ síwájú rẹ̀ láti jọ́sìn rẹ̀. Bákan náà, mo máa ń ṣèbẹ̀wò sí ibojì ìdílé lóṣooṣù láti sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un.

Ìjọsìn àwọn baba ńlá tẹ́ mi lọ́rùn. Mo rò pé mò ń ṣe ohun tí ó yẹ kí n ṣe láti tọ́jú àwọn baba ńlá mi àti láti fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí wọn, mo sì tọ́ Aiko dàgbà láti ṣe ohun kan náà. Nítorí náà, ìpayà bá mi nígbà tí ó sọ fún mi pé òun kò ní lọ́wọ́ nínú ìjọsìn àwọn baba ńlá mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òun kò ní jọ́sìn mi bí mo bá kú. Mo bi ara mi pé, ‘Níbo ni irú ọmọ bẹ́ẹ̀ ti wá, báwo ni ó sì ṣe lè dara pọ̀ mọ́ ìsìn tí ń kọ́ àwọn ènìyàn láti jẹ́ aláìmoore sí àwọn baba ńlá wọn?’ Ní ọdún mẹ́ta tí ó tẹ̀ lé e, ńṣe ló dà bí ẹni pé ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ mí.

Ohun tí ó wá yí gbogbo rẹ̀ padà ni ìgbà tí Aiko ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nítorí pé ó ya ọ̀rẹ́ Aiko kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lẹ́nu pé n kò sí níbẹ̀ nígbà tí ọmọ mi ṣe ìrìbọmi, ó sọ fún Aiko pé òun yóò ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ mi. Inú bí mi, àmọ́ nígbà tí ó dé, kìkì nítorí pé ìwà ọ̀wọ̀ ti di ara mi pátápátá ni mo fi yára mọ́ ọn. Fún ìdí kan náà, n kò lè sọ pé rárá nígbà tí ó sọ pé ó di ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e kí òún tóó padà. Ìbẹ̀wò yìí ń bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, ó ń mú inú bí mi débi pé n kò tilẹ̀ rí ohunkóhun kọ́ nínú ohun tí ó ń sọ lákọ̀ọ́kọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìjíròrò náà bẹ̀rẹ̀ sí í mú mi ronú.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rántí àwọn nǹkan tí ìyá mi sọ fún mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ kí n máa jọ́sìn òun lẹ́yìn tí òun bá kú, ìwàláàyè lẹ́yìn ikú kò dá a lójú. Ó máa ń sọ pé ohun tí àwọn òbí ń fẹ́ jù ni kí wọn ọmọ wọn jẹ́ aláàánú sí àwọn, kí wọ́n sì fi gbogbo ara bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n wà láyé. Nígbà tí mo ka ìwé mímọ́ bí Oniwasu 9:5, 10, àti Efesu 6:1, 2, tí mo sì rí i pé Bibeli fún ohun kan náà ní ìṣírí, ńṣe ló dà bí ẹni pé ìbòjú kan ṣí kúrò lójú mi. Gbogbo nǹkan mìíràn tí ìyá mi ti kọ́ mi ló wà nínú Bibeli, irú bíi pé bẹ́ẹ̀ ni mi gbọ́dọ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, àti pé bẹ́ẹ̀ kọ́ mi gbọ́dọ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́. (Matteu 5:37) Nítorí pé mò ń ṣe kàyéfì nípa kí ni àwọn ohun mìíràn tí Bibeli tún fi kọ́ni, mo gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé.

Gbogbo ìbànújẹ́ àti ìjákulẹ̀ tí mo ti ní fún èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo ìgbésí ayé mi fò lọ bí mo ti ń tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Bibeli. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó mà wú mi lórí o. Ayé kan tí ó yàtọ̀ ló wà níhìn-ín. Àwọn ènìyàn jẹ́ olótìítọ́ inú, onínú rere, àti oníwà bí ọ̀rẹ́, èyí sì ta ọkàn mi kìjí. Ohun tí ó tilẹ̀ ṣí mi lórí jù lọ ni ìgbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àánú Jehofa. Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó bá ronú pìwà dà. Bẹ́ẹ̀ ni, yóò dárí gbogbo àwọn ìkùnà mi ìgbà tí ó ti kọjá jì mí, yóò sì ràn mí lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé tuntun!

Ìyípadà Nínú Ìgbésí Ayé Mi

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́ láti jọ́sìn Jehofa, mo ti ní ìsokọ́ra típẹ́típẹ́ pẹ̀lú agbo eré ìnàjú. Mo ti lé ní ọmọ 50 ọdún nígbà náà lọ́hùn-ún, àmọ́, mo ṣì ń ṣeré orí ìtàgé síbẹ̀. Mo tún jẹ́ aṣíwájú àti ọ̀kan nínú àwọn olùṣètò àwọn akọrin shamisen nígbà tí Danjuro Ichikawa ṣeré Sukeroku ní Kabukiza. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn òṣèré shamisen tí ó lè fúnni ní ohùn orin lọ́nà ti katoubushi tí a nílò fún eré Sukeroku kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, kò sí ẹni tí yóò dípò mi bí mo bá sọ pé n kò ṣe mọ́. Nítorí èyí, ó dà bí ẹni pé mo ti há.

Bí ó ti wù kí ó rí, Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ arúgbó, tí òun náà ń lọ́wọ́ nínú irú eré ìnàjú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Japan kan bèèrè ìdí tí mo fi rò pé ó pọn dandan pé kí n pa iṣẹ́ tì. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n baà lè gbọ́ bùkátà ara wọn.” Ó ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé kì í ṣe ohun kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ni mò ń ṣe, àti pé mo lè jọ́sìn Jehofa, kí n sì máa bá iṣẹ́ eré mi lọ.

Fún ìgbà díẹ̀, mò ń bá a lọ ní Kabukiza, ògúnná gbòǹgbò ilé eré ìtàgé ní Japan. Nígbà tí ó yá, eré bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ sí àkókò tí à ń ṣe ìpàdé lálẹ́, nítorí èyí, mo sọ pé kí wọ́n máa fi ẹlòmíràn dípò mi ní àwọn alẹ́ wọ̀nyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́, àkókò ìpàdé wa yí padà, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti lè lọ sí ibi iṣẹ́ àti ìpàdé lọ́gbọọgba. Síbẹ̀, láti dé sí àwọn ìpàdé lásìkò, lọ́pọ̀ ìgbà ó di dandan pé kí n sáré fò sínú takisí kan tí ń dúró lójú ẹsẹ̀ lẹ́yìn tí eré bá ti parí, kàkà tí n óò fi máa gba fàájì pẹ̀lú àwọn òṣèré yòókù gẹ́gẹ́ bí a ti máa ń ṣe. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo pinnu láti paṣẹ́ tì.

Nígbà yẹn, ó ti pẹ́ tí a ti ń bá àṣedánrawò ọ̀wọ́ eré olóṣù mẹ́fà kan tí a óò ṣe ní àwọn ìlú pàtàkì-pàtàkì Japan bọ̀. Tí mo bá lọ sọ̀rọ̀ fífi iṣẹ́ sílẹ̀, yóò fa ọ̀pọ̀ wàhálà. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í dá ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ láti gbapò mi, láìsọ ìdí tí mo fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ìrìn àjò eré náà parí, mo ṣàlàyé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn pé mo ti ṣe ẹrù iṣẹ́ mi àti pé mo fẹ́ fi iṣẹ́ sílẹ̀. Inú bí àwọn kan. Àwọn kan fi ẹ̀sùn jíjẹ́ onígbèéraga àti ẹni tí ń mọ̀ọ́mọ̀ fa wàhálà fún wọn kàn mí. Kì í ṣe àkókò tí ó rọrùn fún mi, àmọ́, mo rọ̀ mọ́ ìpinnu mi, mo sì fi iṣẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn 40 ọdún tí mo ti fi ń ṣeré. Láti ìgbà yẹn ni mo ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní shamisen, èyí ni ó sì ń mú owó díẹ̀-díẹ̀ wọlé wá.

Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ Mi

Ní ọdún bíi mélòó kan ṣaájú, mo ti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ sí Jehofa Ọlọrun. Mo ṣe ìrìbọmi ní August 16, 1980. Ìmọ̀lára tí ó bò mí ṣíbáṣíbá nísinsìnyí ni tí ìmoore sí Jehofa. Mo ka ara mi sí ẹni tí ó ti dà bí obìnrin ará Samaria tí a mẹ́nu kàn nínú Bibeli ní Johannu 4:7-42, lọ́nà kan. Jesu bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lú inú rere, ó sì ronú pìwà dà. Bákan náà, Jehofa, ẹni tí ń “wo ọkàn,” fi pẹ̀lú inú rere fi ọ̀nà hàn mí, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun, nítorí àánú rẹ̀.—1 Samueli 16:7.

Ní March ọdún 1990, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí n pé ọmọ ọdún 68, mo di aṣaájú ọ̀nà, bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Aiko náà jẹ́ aṣaájú ọ̀nà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Wọ́n dàgbà sókè láti dà bí ìyá wọn, ní ìbámu pẹ̀lú òwe àwọn ará Japan tí ó sọ pé: “Àkèré lọmọ àkèré.” Kristian alàgbà ni ọkọ Aiko nínú ìjọ. Ẹ wo bí a ti bù kún mi tó pé ìdílé mi yí mi ká, gbogbo wọ́n sì ń rìn nínú òtítọ́, àti láti ní àwọn arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ!

Bí mo ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn baba ńlá mi tó, ọpẹ́ mi tí ó ga jù lọ sọ́dọ̀ Jehofa, ẹni tí ó ti ṣe púpọ̀ fún mi, ju ohun tí ènìyàn lè ṣe lọ. Ní pàtàkì jù lọ, ìmoore tí mo ní fún ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ àti ìtùnú tí ó fún mi ni ó sún mi láti fẹ́ láti yìn ín títí ayérayé.—Gẹ́gẹ́ bí Sawako Takahashi ṣe sọ ọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ṣíṣèdánrawò, lọ́mọ́ ọdún mẹ́jọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Èmi àti ìyá tí ó gbà mi tọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ọmọ mi ni ògo ìgbésí ayé mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Mo jọ́sìn ìyá mi níwájú pẹpẹ ìdílé yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Èmi àti ọmọ mi, ọkọ rẹ̀, àti àwọn ọmọ ọmọ mi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́