ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọmọdé Jagunjagun Abẹ́lẹ̀
  • Dídáàbò Bó Irúgbìn Cycad
  • Àwọn Ìdérí Ihò Abẹ́lẹ̀ Tí Ń Pòórá
  • Àwọn Ìtumọ̀ Bibeli Tuntun
  • Àwọn Ìṣòro Orúkọ
  • A Fẹ̀sùn Kan Àwọn Obìnrin Ilẹ̀ Rwanda
  • Àwọn Aṣojú Ìpalẹ̀ẹ̀dọ̀tímọ́ Àdánidá
  • Lílo Orí Wọn
  • “Àrùn Jerusalemu”
  • Kí Ló Wà Níwájú fún Àwọn Obìnrin?
    Jí!—1998
  • Mímọyì Àwọn Obìnrin àti Iṣẹ́ Wọn
    Jí!—1998
  • Ipa Wo Ni Àwọn Obìnrin Ń Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • “Awọn Obinrin Ti Wọn Nṣiṣẹ Kára Ninu Oluwa”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ọmọdé Jagunjagun Abẹ́lẹ̀

Àwọn ọmọdé ti di púpọ̀ láàárín àwọn jagunjagun abẹ́lẹ̀ káàkiri àgbáyé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ti sọ, àwọn ọmọdé tètè máa ń kọ́ bí a ṣe ń pànìyàn, òye wọn nípa ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú kò sì fi bẹ́ẹ̀ lágbára bíi ti ìfẹ́ ọkàn tí wọ́n ní láti di ẹni tí ẹgbẹ́ jagunjagun tí ó gbà wọ́n síṣẹ́ tẹ́wọ́ gbà. Agbẹnusọ kan fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Ní Rwanda àti àwọn ibòmíràn, àwọn ọmọdé ni wọ́n máa ń hu àwọn ìwà ibi tí ó burú jù lọ. Wọ́n fẹ́ kí a tẹ́wọ́ gba àwọn, kí a sì máa kan sáárá sí àwọn, kìkì ọ̀nà kan ṣoṣo tí àwọn ọ̀dọ́ ojúgbà wọn sì lè gbà tẹ́wọ́ gbà wọ́n ni nípa jíjẹ́ ẹni tí ó túbọ̀ gbóyà tàbí ẹni tí ó ya òǹrorò ju àwọn àgbàlagbà lọ.” Nínú ìforígbárí kan ní Áfíríkà, àwọn ọmọdékùnrin tí wọn kò ju ọmọ ọdún mẹ́jọ péré lọ ni a ń dá lẹ́kọ̀ọ́, tí a sì ń fipá mú láti hu àwọn ìwà ìkà, bíi yíyìnbọn fún àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì gé ọ̀fun wọn. Wọ́n fipá mú àwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n jí gbé láti gbọ́únjẹ, tún ilé ṣe, kí wọ́n sì pèsè ìgbádùn ìbálòpọ̀ fún àwọn ọkùnrin àgbàlagbà. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Ìfojúdíwọ̀n iye àwọn ọmọdé tí wọ́n wà lójú ogun ní báyìí wà láàárín 50,000 sí 200,000 nínú ìforígbárí 24.”

Dídáàbò Bó Irúgbìn Cycad

Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ nípa ewéko ka irúgbìn cycad, Encephalartos woodii, sí irúgbìn tí ó ṣọ̀wọ́n jù lọ lágbàáyé. Nítorí náà, nígbà tí Gúúsù Áfíríkà pinnu láti fi ẹ̀yà irúgbìn ilẹ̀ olóoru tí ó jọ ọ̀pẹ yìí ránṣẹ́ síbi Àfihàn Òdòdó Chelsea ní London ní èṣí, wọ́n lo ìṣọ́ra láti ki ègé pẹlẹbẹ, tí ń dènà jíjí i gbé, tí wọ́n fi òróró agbógunti bakiteria pa bọ inú igi rẹ̀. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, gbogbo irúgbìn cycad tí a ń gbé kiri ní Gúúsù Áfíríkà ni a ti dáàbò bò lọ́nà yìí. Láti gbógun ti àwọn olè, àwọn olùdáàbòbo igbó ní Gúúsù Áfíríkà ti ń dáàbò bo àwọn irúgbìn cycad ẹgàn bákan náà, pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ fífi sátẹ́láìtì tọpa rẹ̀.

Àwọn Ìdérí Ihò Abẹ́lẹ̀ Tí Ń Pòórá

Ìwé agbéròyìnjáde Economic Daily sọ pé, ní 1994, ó lé ní 200 àwọn olùgbé Beijing tí wọ́n ṣubú sínú ihò abẹ́lẹ̀ tí ó wà ní ṣíṣí sílẹ̀. Kí ló fà á? Àwọn olè ti jí ohun tí ó lé ní 2,000 ìdérí ihò abẹ́lẹ̀ ní àwọn òpópónà olù ìlú China láàárín ọdún náà. Wọ́n sọ pé àwọn tí ń ṣí kiri, tí a ń pè ní àwọn alárìnká ilẹ̀ China, ni wọ́n jí ọ̀pọ̀ lára wọn. Jíjí tí àwọn ènìyàn ń jí àwọn ìdérí wọ̀nyí túbọ̀ ń pọ̀ sí i láàárín ẹ̀wádún tí ó kọjá pa pọ̀ pẹ̀lú iye àwọn aṣíkiri ìlú ńlá náà tí ń pọ̀ sí i. Wọ́n lè ta ìdérí tí ó jẹ́ 60 kìlógíráàmù náà ní iye tí ó lé ní 100 owó yuan (dọ́là 12 ti U.S.). Àwọn olùgbé ibẹ̀ tí wọ́n fara pa ní àwọn tí ń fẹsẹ̀ rìn àti àwọn agunkẹ̀kẹ́ nínú.

Àwọn Ìtumọ̀ Bibeli Tuntun

Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ìtẹ̀jáde Bibeli ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a mú sunwọ̀n sí i ti ń dé àwọn ilé ìtajà.” A ti ń ṣe Bibeli jáde fún àwọn ọmọdé, àwọn eléré ìdárayá, àwọn arúgbó, àwọn ìyá tí kì í kúrò nílé, àwọn bàbá, àti ẹgbẹ́ àwọn mìíràn. Ọ̀kan tí ń jẹ́ Black Bible Chronicles, “lo àkúfọ́ ọ̀rọ̀ àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ láti mú kí àwọn àpèjúwe Bibeli túbọ̀ gbádùn mọ́ni fún àwọn ọ̀dọ́langba adúláwọ̀ ará Amẹ́ríkà.” Òmíràn tí ń jẹ́ The New Testament and Psalms: An Inclusive Version, lo ède kò-ṣakọ-kò-ṣabo. Ó pe Ọlọrun ní “Bàbá Òun Ìyá,” Ọmọkùnrin ènìyàn sì di “ẹ̀dá ènìyàn náà.” Láti yẹra fún ṣíṣẹ àwọn alòsì, àwọn olùtúmọ̀ rẹ̀ pé ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun ní “ọwọ́ agbára” rẹ̀, àti nítorí ọ̀ràn ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ohun dúdú ni a kò tún fi wéra pẹ̀lú ibi mọ́. Ẹ̀kẹta tí ń jẹ́ New International Reader’s Version New Testament, ni àwọn tí wọ́n ṣe é ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “Bibeli àkọ́kọ́ tí a tí ì kọ ní ìpele ìkàwé 2.9, èyí tí ó rọrùn jù lọ ní ọjà.” Àpilẹ̀kọ náà parí ọ̀rọ̀ pé: “Lápapọ̀, ó lé ní 450 ìtẹ̀jáde Bibeli tí ó wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan. Pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀dá tuntun tí ń dé orí àtẹ àwọn ilé ìtàwé, ó ṣeé ṣe kí Bibeli náà má tètè kúrò lára àwọn tí ó tà jù lọ.”

Àwọn Ìṣòro Orúkọ

China, tí ó ní àwọn ènìyàn tí iye wọn lé ní 1.2 bílíọ̀nù, ń dojú kọ ọ̀ràn orúkọ ìdílé púpọ̀ tí ó jẹ́ nǹkan kan náà. Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣèwádìí ti sọ, 3,100 péré ni orúkọ ìdílé tí wọ́n ń lò níbẹ̀ ní báyìí, tí a bá fi wé nǹkan bí 12,000 ní ìgbà kan rí. Nǹkan bí 350 mílíọ̀nù ènìyàn—tí ó dọ́gba pẹ̀lú àpapọ̀ gbogbo àwọn olùgbé United States àti Japan—ni wọ́n jùmọ̀ ń lo àwọn orúkọ ìdílé márùn-ún tí ó wọ́pọ̀ jù lọ náà: Li, Wang, Zhang, Liu, àti Chen. Ní àfikún sí i, ó tún wọ́pọ̀ kí àwọn ènìyàn máa lo orúkọ àpèjẹ́ tí ó jẹ́ nǹkan kan náà. Fún àpẹẹrẹ, ní Tianjin, ó lé ní 2,300 ènìyàn tí wọ́n jùmọ̀ ń jẹ́ orúkọ náà, Zhang Li, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ lọ́nà kan náà, nígbà tí àwọn púpọ̀ sí i sì ń lo ọ̀nà pípè kan náà ṣùgbọ́n tí wọ́n ń kọ ọ́ lọ́nà tí ó yàtọ̀. Nítorí ìdàrúdàpọ̀ náà, wọ́n ti fàṣẹ mú àwọn ènìyàn tí kò ṣẹ̀, wọ́n ti fi àṣìṣe gbọ́n àkáǹtì àwọn ènìyàn gbẹ́, wọ́n sì ti fi àṣìṣe ṣiṣẹ́ abẹ fún àwọn tí kò yẹ ní àwọn ilé ìwòsàn. Orílẹ̀-èdè Olómìnira Korea ní irú ìṣòro kan náà. Ìwádìí kan tí a ṣe ní 1987 fi hàn pé ìdá 1 nínú 5 lára àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni orúkọ ìdílé wọn ń jẹ́ Kim. A ti ka ìgbéyàwó láàárín àwọn ẹni tí orúkọ ìdílé wọn pa pọ̀ léèwọ̀ kí a baà lè yẹra fún ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan. Èyí ló fà á tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tọkọtaya fi máa ń gbé pa pọ̀ láìní forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, tí wọ́n kò sì tipa bẹ́ẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ sí ètò ìbánigbófò àti àwọn àǹfààní mìíràn. Bí ó ti wù kí ó rí, ilé ẹjọ́ gíga jù lọ orílẹ̀-èdè náà ti pàṣẹ pé a óò ka ìgbéyàwó láàárín àwọn tí orúkọ ìdílé wọn pa pọ̀ bẹ́ẹ̀ sí èyí tí ó bófin mu bí àwọn tọkọtaya náà bá kọ́kọ́ ṣègbéyàwó ní orílẹ̀-èdè míràn.

A Fẹ̀sùn Kan Àwọn Obìnrin Ilẹ̀ Rwanda

Àjọ Ẹ̀tọ́ Áfíríkà tí ó fìdí kalẹ̀ sí London sọ pé, àtọkùnrin àtobìnrin ni wọ́n gbọ́dọ̀ dáhùn fún ẹ̀bi pípa, ó kéré tán, 500,000 ènìyàn ní ilẹ̀ Rwanda ní 1994. Ìròyìn wọn sọ pé: “Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn obìnrin ni àwọn obìnrin mìíràn pa. Ìwọ̀n tí àwọn obìnrin fi kópa gidi nínú ìpànìyàn náà kò tí ì láfiwé. Èyí kò ṣèèṣì ṣẹlẹ̀. Àwọn ọ̀dádá tí ó dá ìpakúpa rẹpẹtẹ náà sílẹ̀ wá ọ̀nà láti fa iye àwọn ènìyàn bí ó bá ti lè pọ̀ tó sínú ọ̀ràn náà—àwọn ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé tí wọn kò ju ọmọ ọdún mẹ́jọ lọ pàápàá. Wọ́n pète láti ṣẹ̀dá orílẹ̀-èdè kan ti àwọn òṣèlú aláṣerégèé tí ìdè ẹ̀jẹ̀ ìpalápalù ẹ̀yà so pọ̀.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn obìnrin tí ọ̀ràn kàn wà ní ipò pàtàkì—mínísítà ìṣàkóso ìjọba, àwọn alábòójútó ẹlẹ́kùnjẹkùn, àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé, àwọn olùkọ́, àti àwọn nọ́ọ̀sì. Àwọn kan kópa gidi nínú ìpànìyàn náà, nípa lílo àdá àti ìbọn, nígbà tí àwọn mìíràn ṣètìlẹ́yìn nípa gbígbóṣùbà fún àwọn ọkùnrin tí ń pànìyàn, nípa jíjẹ́ kí wọ́n wọ àwọn ilé àti ilé ìwòsàn, àti nípa pípiyẹ́ àwọn ilé àti yíyọ nǹkan ìní ara àwọn òkú.

Àwọn Aṣojú Ìpalẹ̀ẹ̀dọ̀tímọ́ Àdánidá

Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London ròyìn pé, àwọn irúgbìn òdòdó kan ń fi agbára kíkàmàmà ti ìwẹ̀nùmọ́ àti ìṣàtúnṣe erùpẹ̀ ẹgàn tí epo ti sọ dìbàjẹ́ hàn. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ṣàwárí pé níbi tí epo náà kò bá ti fi ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún wúwo ju erùpẹ̀ náà lọ, àwọn irúgbìn náà lè gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, gbòǹgbò wọn sì máa ń wà ní mímọ́ délẹ̀délẹ̀. Kí ló fà èyí? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn bakitéríà tí ń gbé ní àyíká gbòǹgbò àwọn irúgbìn náà ń fa òróró, wọ́n sì ń mú ohun tí kò lè pani lára jáde láti inú àgbára rẹ̀ tí kò lè ṣèpalára. Àwọn irúgbìn yìí wá láti inú ọ̀kan lára ìdílé àwọn irúgbìn títóbi jù lọ, Compositae, tí ó ní daisy, aster, àti ọ̀pọ̀ àwọn èpò nínú. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ dámọ̀ràn pé kí a gbìn wọ́n láti lè mú ìwẹ̀nùmọ́ ẹgàn yára ní Kuwait. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ogun tí wọ́n bá Iraq jà, ẹgàn tí ó jẹ́ nǹkan bí 50 kìlómítà níbùú lóròó ṣì wà ní bíbà jẹ́.

Lílo Orí Wọn

Ìwé ìròyìn Discover sọ pé: “Àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà máa ń rin ọ̀pọ̀ máìlì pẹ̀lú garawa omi ńlá tàbí apẹ oúnjẹ lórí, bíi pé wọn kò ru nǹkankan. Àwọn olùṣèwádìí ti ṣàwárí pé àwọn obìnrin náà lè gbé ẹrù títóbi ràpàtà láìlo àfikún agbára kankan.” Àwọn obìnrin ilẹ̀ Kenya kan lè gbé ohun tí ó tóbi tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún ìtẹ̀wọ̀n ara wọn láìsí àfikún ìsapá rárá. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Ìwé ìròyìn New Scientist dáhùn pé, nípa gbígbé “ẹrù wọn lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ ju ti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ẹ̀yìn gbé ẹrù wíwúwo tàbí àwọn tí a kò tí ì dá lẹ́kọ̀ọ́ láti fi orí rú ẹrù. Àwọn olùṣèwádìí náà gba gbọ́ pé àṣírí rẹ̀ wà nínú rírìn tí àwọn obìnrin náà máa ń rìn, tí wọn yóò sì máa fì bí ẹpọ̀n agogo.” Bí a bá ń rìn, ń ṣe ni a máa ń dà bí ẹpọ̀n agogo tí ń fì, tí ń gbé díẹ̀ lára agbára rẹ̀ lọ síbi ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Ní ti àwọn ará Europe, ìgbéṣẹ́ ìtàtaré agbára yìí máa ń dín kù bí ẹrù bá ṣe ń wúwo sí i. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn obìnrin Áfíríkà tí ń fi orí ru ẹrù, ìgbéṣẹ́ náà máa ń pọ̀ sí i ní ti gidi ni, tí ó fi jẹ́ pé àwọn iṣan ara wọn kò ní láti ṣe àṣekún iṣẹ́ kankan. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ń gba ọ̀pọ̀ ọdún kí a tó lè di ògbógi nínú ìlànà ìṣe náà.

“Àrùn Jerusalemu”

Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ó jẹ́ àrùn tí àwọn arìnrìn àjò, tí èrò ìmọ̀lára lílágbára ti pé àwọn wà ní ìlú ńlá náà ṣẹ̀dá rẹ̀, tí wọ́n ti gbà pé àwọn ni Olùgbàlà, tàbí àwọn sàràkísàràkí mìíràn nínú Bibeli, tàbí pé àwọn ní ìhìn iṣẹ́ pàtàkì kan tàbí àṣẹ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọ́n ní àkọsílẹ̀ àrùn ọpọlọ.” Ará Itali kan tí ó ní irùngbọ̀n yẹ̀wùkẹ̀, tí wọ́n rí tí ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri ní àárín àwọn òkè tí ó wà nítòsí Betlehemu, tí ó wọ aṣọ gbàgẹ̀rẹ̀, sọ pé òun ni Jesu. Ọkùnrin kan tí ó wà níhòhò, tí ń fi idà, ń sáré kiri Ìlú Ńlá Àtọjọ́mọ́jọ́ náà, ó ń sọ pé òún ní iṣẹ́ ìjíhìn ti wíwo àwọn afọ́jú sàn. Ará Kánádà títaagun kan sọ pé òun ni Samsoni, ó sì “fi ẹ̀rí” èyí hàn nípa fífa irin ojú fèrèsé ilé ìwòsàn tí ó wà yọ, tí ó sì sá lọ. Àwọn tí àrùn Jerusalem náà mú ni wọ́n sábà máa ń mú lọ sí Ilé Ìwòsàn Àrùn Ọpọlọ Kfar Shaul ní Jerusalemu—kì í ṣe láti lọ wò wọ́n sàn, ṣùgbọ́n láti lè mú kí ara wọ́n ṣe wọ̀ọ̀, kí wọ́n lè padà sí ilé láti gba ìtọ́jú. Ilé ìwòsàn náà máa ń ní nǹkan bí 50 irú àwọn alárùn bẹ́ẹ̀ lọ́dún, ní pàtàkì láti Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Europe àti láti United States.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́