Wíwo Ayé
Àrùn Ọpọlọ Ń Peléke Sí I
Ìwé ìròyìn First Call for Children sọ pé àwùjọ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìlera kárí ayé kan ti kìlọ̀ nípa “ìwọ̀n àrùn ọpọlọ tí ń dáni níjì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.” Àwọn olùwádìí náà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Harvard ṣàkọsílẹ̀ àwọn àrùn ọpọlọ mélòó kan tí ń ṣẹlẹ̀ ní ìwọ̀n gíga gẹ́gẹ́ bí àbájáde “ogun, àwọn ìjábá àdánidá, ìlòkulò àti ìṣekúpa àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àwọn ìyípadà tí ń ṣẹlẹ̀ nínú iye ènìyàn, ọ̀ràn ìṣèlú àti ètò ọrọ̀ ajé.” Ní àfikún sí i, ìwọ̀n ìkù-díẹ̀-káà-tó ọpọlọ àti wárápá jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta sí márùn-ún ní àwọn àwùjọ tí owó tí ń wọlé fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ti kéré jọjọ, ìṣekúpara-ẹni sì jẹ́ okùnfà títayọ kan nínú ikú àwọn ọ̀dọ́. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Arthur Kleinman, tí ó darí àwùjọ náà, ṣe sọ, a gbọ́dọ̀ pàfiyèsí sí ìlera ọpọlọ kárí ayé. Ó wí pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣàìní àti àwọn tí ó lọ́rọ̀ bákan náà ti kùnà láti náwónára bí ó ti yẹ lórí ìmúbọ̀sípò àti ìdáàbò bo ìlera ọpọlọ.”
Kókó Ìfohùnṣọ̀kan
Ìwé ìròyìn Christianity Today fi hàn pé: “Àwọn aṣíwájú ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Rọ́ṣíà àti àwọn ti Mùsùlùmí láti orílẹ̀-èdè olómìnira mẹ́rin tí àwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí jù ní Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí—Kazakhstan, Tajikistan, Turkmenistan, àti Uzbekistan—ti ṣe àdéhùn àjọṣe onísìn kan tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, láti ṣẹ́pá àwọn ẹ̀ka ìsìn àti ẹgbẹ́ àwùjọ ìsìn tí kò bẹ́gbẹ́ mu, tí ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní àárín gbùngbùn Asia.” Àwọn aṣíwájú ìsìn náà tí wọ́n pàdé ní Tashkent, olú ìlú ilẹ̀ Uzbekistan, “jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pawọ́ pọ̀ dá ìgbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ àwọn Kristian ajíhìnrere, ìjọ Onítẹ̀bọmi, ìsìn Mormon, àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofah dúró.”
Àìlọ́wọ̀ fún Ìdáàbò Bo Ohun Alààyè
A rí adárípọ́n phalarope, ẹyẹ ṣíṣọ̀wọ́n kan, ní igbó ọba kan ní Leicestershire, England, àwọn olùwòran ẹyẹ jákèjádò ilẹ̀ Britain sì rìnrìn àjò wá wò ó. Ṣùgbọ́n ẹ̀rú bà wọ́n bí wọ́n ti rí àgbáàràgbá ẹja pike kan tí ó gùn ní ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin tí ó gbé ẹyẹ tí ń ṣí kiri náà mì káló. Olùwòran ẹyẹ kan sọ pé: “Ńṣe ni ó dà bí ìran kan nínú sinimá Jaws. Ní ìṣẹ́jú kan, ẹyẹ náà ń lúwẹ̀ẹ́—ní ìṣẹ́jú tó tẹ̀ lé e, nǹkan kan hán an, ó lumi, ó sì pò ó rá.” Ìròyìn Reuters kan sọ pé: “Kìkì ìyẹ́ mélòó kan ló kù láti fẹ̀rí hàn pé àrà ọ̀tọ̀ ẹyẹ omi náà ti ṣèbẹ̀wò sí igbó ọba Leicestershire rí.”
“A Kò Gbọdọ̀ Tọwọ́ Bọ Bibeli Lójú”
Lábẹ́ àkọlé yìí, ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Weekend Australian bẹnu àtẹ́ lu “ìgbìdánwò láti tún Bibeli ṣàlàyé àti láti ṣàtúnṣe àwọn apá kan nínú rẹ̀ kí wọ́n lè bá àìní ìgbàlódé mu.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtumọ̀ tuntun “ti jẹ́ iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́, tí ń kófa àwọn àwárí tuntun ti àwọn ìwé ìjímìjí àti ìwádìí onítàn,” ọ̀rọ̀ olóòtú náà kìlọ̀ lòdì sí “ṣíṣí iṣẹ́ ìṣètumọ̀ mú fún ṣíṣàlàyé.” Àwọn kókó ọ̀ràn àríyànjiyàn kan àwọn ìlànà fún àwùjọ àlùfáà àti àwọn olùkọ́ tí Ìgbìmọ̀ Àwọn Kristian àti Júù tẹ̀ jáde láti yẹra fún ìmọ̀lára ìkorò lòdì sí àwọn Júù gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ìsìn tàbí ẹ̀yà ìran kan. Àwọn ọ̀rọ̀ bí “àwọn Júù,” tí a lò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àdánwò àti ikú Jesu, yóò yí padà sí “díẹ̀ lára àwọn olùgbé Jerusalemu”; “àwọn Farisi,” yóò sì di “àwọn aṣáájú ìsìn kan.” Ọ̀rọ̀ olóòtú náà fi kún un pé: “Àkọsílẹ̀ Májẹ̀mú Tuntun kì í ṣe ọ̀rọ̀ èrò inú. . . . Títọwọ́ bọ àwọn ọ̀rọ̀ náà lójú àti yíyí ẹsẹ ìwé padà lè yára di ohun tí apá kò ká, kí ó sì ṣamọ̀nà sí àfihàn alábòsí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbé ayé Kristi. Àwọn àyíká ọ̀rọ̀ ìgbé ayé àwùjọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ wà bí ó ti rí gan-an ní ìgbà ìwàláàyè rẹ̀.”
Yíyẹ Ìjábá Ojú Ọjọ́ Sílẹ̀
Ìgbìmọ̀ Ìdámọ̀ràn Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ ní Germany ti kìlọ̀ pé, ojú ọjọ́ ilẹ̀ ayé yóò dojú kọ ìjábá láàárín ọdún 25 sí 30 tí ń bọ̀ yìí bí a kò bá yára ṣe nǹkan sí i. Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung ròyìn pé: “Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ń béèrè fún dídín afẹ́fẹ́ carbon dioxide (CO2) tí ń ba afẹ́fẹ́ àyíká jẹ́ kù, ní ìwọ̀n ìpín 1 nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún. A kò gbọdọ̀ fàyè gba ìlọsókè ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ju ìwọ̀n 0.2 lórí òṣùwọ̀n Celsius láàárín ẹ̀wádún kọ̀ọ̀kan.” Àwọn olórí kọ̀lọ̀rànsí tí ń fa ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún ìbàjẹ́ afẹ́fẹ́ àyíká ayé ni àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ ìbílẹ̀ Germany kan ń pèsè ìlọ́po 20 ìwọ̀n afẹ́fẹ́ carbon dioxide tí ọmọ ìbílẹ̀ India kan ń pèsè, ní ìpíndọ́gba. Àwọn lájorí ìṣòro àyíká mìíràn tí a sọ pé ènìyàn ń fà ni ìgbádànù ilẹ̀, ọ̀wọ́n omi mímọ́ gaara, àti ìmújoro iye onírúurú ohun alààyè.
“Ẹ Tún Ìdílé Tò”
Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Brazil náà, O Estado de S. Paulo, ròyìn pé àìka àwọn ọmọdé sí àti híhu ìwà ipá sí wọn ń pọ̀ sí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà lè jẹ́ kókó abájọ kan, àìtọ́ nínú ìbálò pẹ̀lú àwọn ọmọdé kò mọ sí agbègbè àwọn tálákà. Gẹ́gẹ́ bí Lia Junqueira, olùdarí Ibùdó Ìtọ́kasí fún Àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́langba, ṣe wí, ‘kò sí ìyàtọ̀ láàárín ọlọ́rọ̀ àti tálákà lọ́nàkọnà—yàtọ̀ sí pé nínú àwọn ilé onípákó tàbí ilé ibùwọ̀ alábọ́dé, gbogbo ayé ń gbóhùn ẹkún àwọn ọmọdé; nígbà tí àwọn ògiri ilé ńlá àwọn olówó kò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀.’ Paulo Victor Sapienza, olùdarí Ẹ̀ka Ìdáàbò Bo Àwọn Ọmọdé, rò pé fífún ìdè ìdílé lókun ni ọ̀nà dídára jù lọ láti gbógun ti ìṣòro náà. Ó sọ pé: “Fífi ọmọ kan sínú ìgbékalẹ̀ kan tí kì yóò fún un ní ìfẹ́ àti ìfẹ́ni kò wúlò. Ó pọn dandan láti ṣèrànwọ́ síhà títún ìdílé tò, kí àwọn ọmọdé lè ní ìfẹ́ni àti ìfẹ́ nínú agbo ilé.”
Àwọn Ọmọdé Oníkaféènì
Ìwé Tufts University Diet & Nutrition Letter sọ pé àwọn ọmọ tí kì í payè pọ̀, tí ara kì í rọ̀, tí ọkàn wọ́n tètè ń pínyà, tí wọ́n sì ń hùwà láìronú wò lè máa jìyà lọ́wọ́ àlòjù kaféènì. Fún ọmọ kan tí ó wọn kílógíráàmù 18, “àdàlú agolo kólà kan àti ìdajì ife tíì oníyìnyín kan dọ́gba pẹ̀lú ife kọfí mẹ́ta” fún àgbàlagbà kan. Àpilẹ̀kọ náà tọ́ka sí ìwádìí tí Mitchell Schare, ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ ìfìṣemọ̀rònú ní Yunifásítì Hofstra ṣe, tí ó fi hàn pé “ọ̀pọ̀ àmì àfimọ̀ àlòjù kaféènì nínú àwọn ọmọdé fara jọ àwọn àmì àfimọ̀ ìṣiṣẹ́gbòdì ìhùwàsí bí agbára ìfiyèsílẹ̀ tí ó lábùkù tàbí àrùn araàbalẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Kí o tó pinnu pé ọ̀dọ́langba rẹ tí ara rẹ̀ kò balẹ̀ tàbí tí ń bẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀, o lè rí i pé ojútùú àìrọra náà wà nínú wíwulẹ̀ dín ìwọ̀n kólà àti tíì tí ń mu kù.”
Ìránnilétí fún Àwọn Olùfẹ́ Ẹranko
Ṣé olùfẹ́ ẹranko ni ọ́? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ó ṣeé ṣe kí ajá kan tí ń bá ọ ṣiré ti pọ́n ojú tàbí ọwọ́ rẹ lá. Ìyówù ó jẹ́, gẹ́gẹ́ bí Lane Graham, onímọ̀ nípa àwọn kòkòrò àfòmọ́ ní Yunifásítì Manitoba, ṣe sọ, ó ṣeé ṣe kí o ti kó irú kòkòrò bẹ́ẹ̀ tàbí aràn. Ìwé agbéròyìnjáde Winnipeg Free Press ròyìn pé: “Ó dára jù lọ láti má ṣe jẹ́ kí ẹnu ajá rẹ sún mọ́ tìrẹ jù.” Àwọn ajá máa ń fi ahọ́n wọn nura; níwọ̀n bí ahọ́n wọ́n sì ti dà bí kànrìnkàn, onírúurú nǹkan ni wọ́n ń fi kó, títí kan ìyàgbẹ́. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé àwọn ọmọ ajá “gbajúmọ̀ fún níní irun tí ó kún fún kòkòrò àrùn lára.” Bí o tilẹ̀ lè má ṣàìsàn, ìmọ̀ràn náà ni pé kí o “wẹ ọwọ́ àti ojú rẹ, àti ti àwọn ọmọ kéékèèké, lẹ́yìn àkókò ifẹnupọ́nnilá gígùn èyíkéyìí pẹ̀lú ajá, kìkì láti dènà láabi èyíkéyìí.”
Àwọn Ìlérí Tí A Kò Mú Ṣẹ
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Time ti sọ: “Bíi ti gbogbo àwọn ìyípadà tegbòtigaga nínú ìṣègùn tí ó ṣáájú rẹ̀, ọ̀nà ìṣètọ́jú apilẹ̀ àbùdá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ọjọ́ iwájú dídán yanran sí i. Àwọn olùwádìí lérí láti wo àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì tí a ń jogún bá, irú bí ìṣùpọ̀ iṣan ara níbi àpò ìtọ̀, ìjẹrà iṣu ẹran ara, àìtó sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa, sàn, láìlo egbòogi bí àṣà, ṣùgbọ́n nípa yíyí apilẹ̀ àbùdá padà lọ́nà àrà, fífi àwọn apilẹ̀ àbùdá tí ara wọ́n dá rọ́pò àwọn tí wọ́n lábùkù.” Ṣùgbọ́n ní báyìí, tí ó ti lé lọ́dún márùn-ún lẹ́yìn tí a fọwọ́ sí ìdánrawò lára ènìyàn kíní, tí a sì ti lo 600 ènìyàn nínú 100 ìgbìdánwò ìṣègùn, kò tí ì sí àṣeyọrí kankan. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Lẹ́yìn gbogbo àyẹ̀wò àti ìpolongo olówó gọbọi náà, kò tí ì sí ẹ̀rí dídájú kankan pé ìṣègùn apilẹ̀ àbùdá tí ṣèwòsàn—tàbí kí ó tilẹ̀ ṣèrànwọ́—fún agbàtọ́jú kan ṣoṣo.” Ní ti gidi, àwọn olùwádìí kò ì mọ ọ̀nà dídára jù lọ láti fi àwọn apilẹ̀ àbùdá náà sí inú sẹ́ẹ̀lì tí ó lábùkù náà tàbí bí a ti lè ṣe é kí ètò ìgbógunti àrùn inú ara má ta wọ́n nù. Onímọ̀ apilẹ̀ àbùdá ní Yunifásítì Arizona, Robert Erickson, sọ pé: “Nígbà tí kò bá sí ẹ̀rí pé ohun kan múná dóko, kò yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ asán.”
Kíkápá Ẹranko Elk
Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé: “Ìdajì gbogbo ìjàm̀bá ojú pópó tí a ròyìn fún àwọn ọlọ́pàá ní Sweden, jẹ́ ìkọlura pẹ̀lú àwọn ẹranko.” Ọmọ ilẹ̀ Sweden 12 sí 15 ń kú lọ́dọọdún nítorí irú ìkọlura bẹ́ẹ̀. Èyí tí ó gbàfiyèsí jù lọ ni ti ẹranko elk ilẹ̀ Europe, tí ó lè tóbi tó 800 kìlógíráàmù, tí kì í sì í bẹ̀rù ọkọ̀. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, ní Finland tí ó múlé gbè é, ẹranko elk ‘ni ó tẹ̀ lé ọtí líle nínú okùnfà ìjàm̀bá ojú pópó.’ Láti kojú ìṣòro náà, ilé iṣẹ́ Saab tí ń ṣe ọkọ̀ ní Sweden, ń ṣe àfidánrawò ìkọlù pẹ̀lú àdàmọ̀dì ẹranko elk, láti fi mọ bí ọkọ̀ wọn ṣe láàbò tó. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní Finland sì ti ya mílíọ̀nù 22 dọ́là sọ́tọ̀ fún líla ọ̀nà abẹ́lẹ̀ fún àwọn ẹranko elk níbi àwọn ọ̀nà tí ọkọ̀ ń gbà lọ gbà bọ̀ nígbà gbogbo. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, ‘àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà yóò fún àwọn ẹranko elk láǹfààní láti rí òdì kejì, a óò sì gbin àwọn ewéko tí wọ́n fẹ́ràn jù síbẹ̀. Ní sáà tí wọ́n máa ń gùn, àwọn ẹranko elk kì í wọ̀tún wòsì kí wọ́n tó ré títì kọjá.’