Ìbápàdé Àràmàǹdà
“OHUN gbígbádùn mọ́ni jù lọ tí mo tí ì ṣe rí nínú ìgbésí ayé mi!” Bẹ́ẹ̀ ni Kristie ṣe ṣàpèjúwe àràmàǹdà ìbápàdé rẹ̀. Ṣé irú ìmọ̀lára yìí ni ìwọ náà ì bá ní, ká ní ó ṣeé ṣe fún ọ láti bá àwọn ẹja òbéjé lúwẹ̀ẹ́ nínú Ìyawọlẹ̀ Omi Mexico?
Rírí ẹja òbéjé tí ń lúwẹ̀ẹ́ tàbí tí ń ṣeré nínú omi, irú bíi fífẹ̀yìn rìn lórí ìrù wọn, fífò jáde sókè fíofío lọ́nà yíyani lẹ́nu láti inú omi, tàbí fífàyè gba àwọn ènìyàn láti gùn wọ́n, máa ń dùn mọ́ gbogbo ènìyàn lọ́kàn. Wíwulẹ̀ wo àwọn àṣehàn wọ̀nyí lè mú kí ẹnì kan fẹ́ẹ́ kó sómi, kí ó sì bá àwọn òbéjé wọ̀nyẹn ṣeré.
Kristie ti máa ń ní irú ìmọ̀lára yìí. Ó wáá ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ kan, bí ó ṣe ń wa ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ, tí ó sì ń lúwẹ̀ẹ́ nínú Ìyawọlẹ̀ Omi Mexico, orí kan yọ jáde lójijì níwájú rẹ̀. Láìpẹ́, ó jọ pé àwọn ẹja òbéjé onífẹ̀ẹ́ ìtọpinpin mẹ́ta náà rò pé àwọn ti rí alábàáṣiré kan. Ẹ̀rù kọ́kọ́ ba Kristie díẹ̀, ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù náà wáá yí padà di ìdùnnú bí ó ṣe ń bá àwọn òbéjé náà ṣeré. Ní fífi àyè sílẹ̀ fún wọn láti pinnu ọ̀ràn náà, ó fara balẹ̀ láti rí ohun tí ó kàn tí wọn yóò ṣe.
Kristie wí pé: “Ẹja òbéjé kan yóò wulẹ̀ yọrí jáde níwájú mi—a óò sì máa wo ara wa. Mo rí ara mi tí mo ń fọwọ́ pa á lára, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ sí i—bí mo ti máa ń ṣe fún ajá mi gan-an.”
Nítorí làákàyè tí àwọn ẹja òbéjé ní, gbajúmọ̀ adánilárayá ni wọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ sì sọ pé nítorí ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn ènìyàn, kò di ìgbà tí o bá fún àwọn ẹja òbéjé ní oúnjẹ kí wọ́n tóó dá ọ lára yá.
Nígbà tí a béèrè ohun tí a lè gbádùn jù lọ bí a bá wà pẹ̀lú àwọn ẹja òbéjé, Liz Morris, onímọ̀ ìhùwàsí àwọn ẹranko tí a kò fi dọ́sìn ní Sea World ní Florida, U.S.A., sọ pé: “Mo rò pé irú ìwà àdánidá wọn ni. Nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹ̀dá tí ń báni ṣeré, tí wọ́n sì ní ìfẹ́ ìtọpinpin, o lè bá wọn ní àjọṣepọ̀ gidi . . . Wọ́n máa ń hùwà padà dáradára sí ìfọwọ́bà àti ìfẹ́ni.” Nínú ètò ìgbékalẹ̀ tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, gbogbo wa yóò lè ní ọ̀pọ̀ ìbápàdé àràmàǹdà bíi ti Kristie.