Òpópónà Emmy Zehden—Bí Orúkọ náà Ṣe Wáyé
NÍ May 1992, wọ́n sọ òpópó kan ní ìlú ńlá Berlin, Germany, ní orúkọ Emmy Zehden, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Wọ́n bí Emmy ní ọdún 1900. Júù oníṣòwò kan, Richard Zehden, tí ó kú sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Auschwitz lákòókò ìṣàkóso ìjọba Nazi, ni ọkọ rẹ̀. Richard àti Emmy ní ọmọkùnrin kan tí wọ́n gbà ṣọmọ, Horst Schmidt. Ó di ọ̀ràn-anyàn fún Horst àti àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì míràn láti sá pa mọ́ nígbà tí a pè wọ́n fún iṣẹ́ ológun.
Emmy fi Horst àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ méjèèjì pa mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, bí àkókò ti ń lọ, àṣírí tú. Wọ́n dájọ́ ikú fún àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin—ti àwọn ọmọdékùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà jẹ́ nítorí pé wọn kò tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ológun, ti Emmy sì jẹ́ nítorí pé ó fi wọ́n pa mọ́. Wọ́n bẹ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ Horst méjèèjì lórí. Emmy béèrè fún ìdáríjì, àmọ́ wọn kò dárí jì í. Wọ́n bẹ́ ẹ lórí ní Plötzensee, ní Berlin, ní June 9, 1944.a Horst Schmidt la ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Nazi já, nígbà tí ó sì ṣe, ó gbé Ẹlẹ́rìí kan tí ó la àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ já níyàwó.
Ní May 7, 1992, wọ́n sọ òpópónà kan ní Berlin ní orúkọ Emmy Zehden. Nínú ọ̀rọ̀ kan tí òṣìṣẹ́ kan ní Germany sọ, wọ́n yìn ín fún ìgboyà rẹ̀, wọ́n sì tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ‘àwọn òjìyà’ ogun náà ‘tí a ti gbàgbé.’
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ tí a fàṣẹ sí tí ó wà ní Ibi Ìrántí Berlin-Plötzensee, June 9, 1944 ni wọ́n pa Emmy Zehden.