Ìwé Kan Tí A Fẹ́ràn Jù Lọ
Ìtẹ̀jáde Àwọn Ìwé Tí A Fẹ́ràn Jù Lọ (Gẹ̀ẹ́sì), tí a tẹ̀ jáde ní nǹkan bí ọdún márùn-ún sẹ́yìn ní California, U.S.A., jẹ́ àkójọ ohun tí àwọn ọ̀dọ́ sọ nípa àwọn ìwé tí wọ́n fẹ́ràn jù lọ. Èwe kan yan ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó fẹ́ràn jù lọ. Ọ̀dọ́ òǹkọ̀wé náà ṣàlàyé ìdí rẹ̀ pé:
‘Ìwé àgbàyanu yìí jẹ́ nípa àwọn ìbéèrè àti ìdáhùn tí àwọn ọ̀dọ́ ń bi ara wọn lónìí bí, “Èé ṣe tí àwọn òbí mi kò fi lóye mi?” “Mo ha gbọ́dọ̀ lo oògùn àti ọtí líle wò bí?” “Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ìfẹ́ gidi ni?” “Kí ni ọjọ́ ọ̀la ní nípamọ́ fún mi?” “Kí ni nípa ti ìbálòpọ̀ takọtabo ṣáájú ìgbéyàwó?” Ìwọ̀nyẹn jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àkòrí orí ìwé inú ìwé yìí. Mo fẹ́ràn ìwé yìí, kì í ṣe kìkì nítorí pé ó ní àwọn ìbéèrè ọ̀ràn ara ẹni nínú, ṣùgbọ́n, nítorí pé ó pèsè àwọn ìdáhùn rírọrùn, tí ń tẹ́ni lọ́rùn. Àwọn ọmọdé yóò fẹ́ràn rẹ̀.’
A lo ọtí líle àti oògùn bí àpẹẹrẹ àwọn ìdẹwò tí àwọn ọ̀dọ́ ń dojú kọ lónìí. Èwe náà ṣàlàyé pé: ‘Àwọn ìwé ìròyìn àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n ń fi àwọn ohun mímu àti ọtí líle tí ń mú kí o fẹ́ láti lò wọ́n hàn. Àwọn èwe àti àwọn ọ̀dọ́langba mìíràn ń tàn ọ́ láti lò wọ́n. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, ó jọ pé àwọn ọmọdé kò mọ ohun tí ó yẹ kí wọn ṣe. Ìwé yìí dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ẹ ti mọ ìdí tí mo fi fẹ́ràn ìwé yìí báyìí. Èmi àti ìyá mi sábà jọ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ọjọọjọ́ Thursday. A ti bá ìwé náà dé nǹkan bí ìdajì báyìí.’
Láìsí iyè méjì, ìwọ pẹ̀lú yóò jàǹfààní gidigidi láti inú ìwé aláwòrán mèremère, olójú ìwé 320 yìí. Bí o bá fẹ́ láti mọ bí o ṣe lè gba ẹ̀dà rẹ̀ kan, tàbí tí o bá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú ní ojú ìwé 5.