Àwọn Olùtànmọ́lẹ̀ Tíntìntín ní New Zealand
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NEW ZEALAND
ÒKÙNKÙN ṣú biribiri ní alẹ́—òṣùpá kò yọ, ojú ọ̀run sì mọ́ fee. Nígbà tí iná àgọ́ kú, ó jọ pé àgbáálá ayé kan tí ó kún fún àwọn ìràwọ̀ mímọ́lẹ̀ rekete ni a wà. A jáde gba ọ̀nà ìsàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kan lọ sí ibi adágún omi ṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná kan ní ìsàlẹ̀ ibi àbájáde tóóró kan. Ewéko ń hù ní ìhà méjèèjì omi tí ń yọ oruku náà. A kó wọnú omi náà, a sì sinmi díẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fi gbogbo ọjọ́ rìn. Adágún yìí, tí ó ní omi gbígbóná tí ń tú kọ̀ọ́kọ̀ọ́ jáde láti inú ilẹ̀, lọ́nà àdánidá, wà ní àgọ́ àwọn arìnrìn-àjò tí a wọ̀ sí mọ́jú.
Mo ń wo bí ìràwọ̀ kan ṣe yára la òfuurufú já. Mo yí pa dà láti wí fún aya mi nípa rẹ̀, bí mo sì ti ń yí, mo fẹsẹ̀ kọ, mo sì nalẹ̀ pọ̀ọ̀. Sí ìyàlẹ́nu mi, àwọn ìràwọ̀ bíi mélòó kan sì paná lójijì—wọ́n pòórá! Nígbà tí mo sọ̀rọ̀ tìyanutìyanu, odindi ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan sì pòórá. Ó jọ pé mo ti dá ihò kan sí ojú àgbáálá ayé!
Bí mo ti ń gbìyànjú láti ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, àwọn ìràwọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í yọ pa dà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo wá rí i pé ìṣùpọ̀ kan sún mọ́ mi ju àwùjọ ńlá àwọn ìràwọ̀ gidi lọ. Ní gidi, àwọn kan súnmọ́tòsí tó láti fi ọwọ́ kàn. A bá ìmú-ùnmúná ti New Zealand pàdé fún ìgbà àkọ́kọ́. Wọ́n wà ní òfegè lókè orí wa lára àwọn irúgbìn tí a kò lè rí nínú òkùnkùn, àwọn iná wọn fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ bá ìrísí ọwọ́ ẹ̀yìn wọn tí ó kún fún ìràwọ̀ mu.
Kòkòrò ni ìmú-ùnmúná ti New Zealand kì í ṣe ìdin. Ó yàtọ̀ sí àwọn ìmú-ùnmúná àti kòkòrò tannátanná ti àwọn apá ibòmíràn lágbàáyé. Orúkọ rẹ̀ Arachnocampa luminosa lè mú kí o lérò pé ó jẹ́ irú aláǹtakùn adányinrin kan. Àmọ́, ìyẹn pẹ̀lú kò rí bẹ́ẹ̀.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìbápàdé wa àkọ́kọ́ náà ni a tún bá àwọn ìmú-ùnmúná pàdé, ní Hòrò Waitomo ní Erékùṣù Àríwá New Zealand. Ẹ jẹ́ kí ń ṣàlàyé ìrìn àjò wa lọ sí hòrò àtọwọ́dá ti ìmú-ùnmúná, níbi tí ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ kan gbé wa lọ láti wo àwọn ìṣẹ̀dá tíntìntín wọ̀nyí.
Hòrò Waitomo
Àgbàyanu gbáà ni Hòrò Ìmú-ùnmúná, tí ìmọ́lẹ̀ tàn sí lọ́nà rírẹwà, láti fi iṣẹ́ ọnà kíkàmàmà àwọn ẹfun sísorọ̀ àti ẹfun gígan mọ́lẹ̀, tí ó ti ń dà jọ láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá hàn. Afinimọ̀nà wa ń tan iná bí a bá ti ń sún mọ́ àgbègbè kọ̀ọ̀kan, àwọn ọnà àti ọ̀nà abẹ́lẹ̀ fífanilọ́kàn-mọ́ra náà sì yà wá lẹ́nu—àgbègbè àgbàyanu ṣíṣàjèjì, tí a kò retí láti rí lábẹ́ ilẹ̀. Ìró ẹsẹ̀ wa ń dún àdúntúndún nígbà tí a kóra jọ sókè àkàsọ̀ tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ sínú òkùnkùn. Bí ojú wa ti mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn ìdányinrin tíntìntín iná aláwọ̀ ewé lókè fíofío. Àwọn ìmú-ùnmúná!
A dé èbúté kan, a sì wọ ọkọ̀ kan. Bí a ti kúrò ní èbúté náà, a tukọ̀ wọnú òkùnkùn. Lẹ́yìn náà, bí a ti dé igun kan, ohun tí mo wulẹ̀ lè ṣàpèjúwe bí abala ìkìpọ̀ odindi Milky Way fara hàn gẹ́rẹ́ lókè orí wa—gbogbo òkè hòrò náà kún fún àwọn ìmú-ùnmúná. Òǹkọ̀wé George Bernard Shaw pe ibí yìí ní “ìyanu kẹjọ lágbàáyé.”
Ìmú-ùnmúná Fífanilọ́kàn-Mọ́ra Náà
Nígbà tí ìfinimọlẹ̀ náà parí, ìyàlẹ́nu wa nípa ìmú-ùnmúná náà fún wa níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa rẹ̀. Ohun tí a sì kọ́ ń fani lọ́kàn mọ́ra gan-an bí ohun tí a rí. Bí ó ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìwàláàyè gẹ́gẹ́ bí ìdin tín-ńtín kan, tí ó ní ìrù oníná tí ó ti ń tanná, ìmú-ùnmúná ti New Zealand fi ikun àti ṣẹ́dà láti inú ẹṣẹ́ yíyàtọ̀ kan nínú ẹnu rẹ̀ ṣe ibùsùn àsorọ̀ kan, ó sì so ó mọ́ òkè hòrò àtọwọ́dá kan. Ní gidi, ibùsùn àsorọ̀ náà jẹ́ ihò kan tí ìdin náà lè máa rìn lọ, rìn bọ̀ nínú rẹ̀.
Ìmú-ùnmúná náà nílò oúnjẹ láti máa wà láàyè, nítorí náà, ó máa ń dọdẹ ṣa ìjẹ fún oṣù mẹ́fà sí mẹ́sàn-án. Àmọ́, àwọn ẹran ìjẹ rẹ̀ máa ń wà lójú òfuurufú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń ti inú omi wá. Odò pàtàkì náà máa ń mú ìpèsè àwọn kòtóǹkan, yànmùyánmú, stonefly, àti mayfly tí iná máa ń fà mọ́ra wá. Láti mú wọn, ìmú-ùnmúná náà máa ń dẹ ọ̀wọ́ àwọn okùn ṣẹ́dà (tí wọ́n máa ń pọ̀ tó 70 nígbà míràn) wálẹ̀ láti inú ibùsùn àsorọ̀ rẹ̀. Àwọn àlàfo tí ó wà láàárín ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn okùn náà ní ọ̀wọ́ àwọn ẹ̀kán ikun tí ń fà mọ̀dẹ̀mọ̀dẹ̀, tí a nà dọ́gbandọ́gba, nítorí náà, àwọn okùn náà jọ ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tíntìntín tí wọ́n dà wálẹ̀ gbọọrọ.
Apá fífanilọ́kàn-mọ́ra jù lọ lára àwọn ìmú-ùnmúná náà ni iná tí ó fi ń tànmọ́lẹ̀ sára àwọn okùn ìdọdẹ náà. Ìmú-ùnmúná ti New Zealand jẹ́ ọ̀kan lára àwùjọ àwọn kòkòrò tí ìtànyinrinyinrin wọn kò wá láti inú agbára ètò ìgbékalẹ̀ ọpọlọ. Síbẹ̀, ó lè pa iná náà nígbàkigbà tó bá fẹ́. Àwọn ẹ̀yà ara tí ń tanná náà wà ní ìkangun àwọn ihò tí ó ń gbà da ìdọ̀tí inú ara nù, apá kan ètò ìgbékalẹ̀ tí ìdin náà fi ń mí sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi dígí, tí ń tan ìmọ́lẹ̀ pa dà sí ìsàlẹ̀. Ó ń pa iná náà nípa dídí afẹ́fẹ́ oxygen tàbí àwọn kẹ́míkà tí ó nílò láti ṣèmújáde iná lọ́wọ́.
Bí ó ti wù kí ó rí, iná tí ó wà ní ìkangun ihò ìmú-ùnmúná náà kì í ṣe àmì tí ń fúnni nírètí tí kòkòrò ìjẹ kan ń retí. Ó fò lu ọ̀wọ́ àwọn okùn ìkélé ikú náà, níbi tí kẹ́míkà kan ti lè máa pa ìmọ̀lára rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ. Tí ó bá ti nímọ̀lára ìjàpìtìpìtì ẹran ìjẹ náà, ìdin náà yóò yọ jáde nínú ibùsùn àsorọ̀ náà lọ́nà tí ó léwu, yóò sì fi ẹnu rẹ̀ fa okùn náà mọ́ra, ní lílo ìsúnkì ara rẹ̀.
Lẹ́yìn tí ìdin náà bá ti ń dọdẹ mú ìjẹ, tí ó sì ń bọ́ ara rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà sí mẹ́sàn-án, yóò wá di mùkúlú, lẹ́yìn náà, yóò máa gbádùn ìwàláàyè bí àgbà kòkòrò. Bóyá àgbà kòkòrò náà ń gbádùn ìwàláàyè gan-an ń ṣeni níyè méjì. Yóò wà fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta péré, nítorí pé àgbà kòkòrò náà kò ní ẹnu, nítorí náà, kò lè jẹun. Àkókò rẹ̀ tó kù wà fún ìmúrújáde. Àwọn àgbà akọ kòkòrò ń da àtọ̀ sára àwọn abo ní gbàrà tí wọ́n bá ti jáde láti inú àwọn ekùkù wọn. Abo náà lè lo odindi ọjọ kan láti yé ẹyin rẹ̀, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, tí yóò sì kú lẹ́yìn náà. Lẹ́yìn tí ó ti ṣàlékún ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ dídán yinrin tí ń fún ẹ̀dá ènìyàn ní ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn kíkàmàmà, àyípoyípo ìwàláàyè olóṣù 10 sí 11 ti olùtànmọ́lẹ̀ tín-ńtín ti New Zealand náà ti dópin.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Lódì kejì: Wíwọnú hòrò àtọwọ́dá ti ìmú-ùnmúná náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Lókè: Òkè hòrò àtọwọ́dá tí ìmú-ùnmúná náà tanná sínú rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Lápá ọ̀tún: Àwọn okùn ìdọdẹ ìmú-ùnmúná
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn àwòrán ojú ìwé 16 àti 17: Waitomo Caves Museum Society Inc.