Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 25. Fùn àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde náà, “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Àwọn àwọ̀ wo ni a lò jù fún àwọn ohun èèlò tí a fi ṣe tẹ́ńpìlì lọ́ṣọ̀ọ́ àti nínú àwọn aṣọ tí olórí àlùfáà ń wọ̀? (Ẹ́kísódù 36:35)
2. Àwọn ọmọ aládé Páṣíà mélòó ni wọ́n ṣiṣẹ́ sìn bí olùdámọ̀ràn Ọba Ahasuwérúsì tí wọ́n sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, tí wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìdájọ́ tí a ṣe fún Ayaba Fáṣítì? (Ẹ́sítà 1:13-15)
3. Ní ìlú ńlá ìgbàanì wo ni Melikisédékì ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà? (Jẹ́nẹ́sísì 14:18)
4. Irú ọ̀rọ̀ wo ni a lò láti tọ́ka sí òpó tí wọ́n fi Jésù kọ́ sórí rẹ̀ nínú Bíbélì ti ẹ̀dà èdè Látìn? (Wo Mátíù 10:38, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW)
5. Ta ni bàbá ìyàwó Mósè? (Númérì 10:29)
6. Jésù sọ pé, kò sí Júù kankan tí ó lè sọ pé òun ṣe kí ni nípa Òfin Mósè? (Jòhánù 7:19)
7. Ní èdè àfiwé, kí ni ènìyàn jẹ́ lọ́wọ́ Amọ̀kòkò Ńlá náà? (Aísáyà 64:8)
8. Báwo ni olórí àlùfáà Ísírẹ́lì ṣe máa ń wọ inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ lemọ́lemọ́ tó? (Hébérù 9:7)
9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn lè máa gbìn, kí wọ́n sì máa bomi rin, kí ni a ń fi ìyìn rẹ̀ fún Ọlọ́run? (Kọ́ríńtì Kíní 3:7)
10. Kí ni Jésù sọ pé ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá òun jẹ́ fún òun? (Jòhánù 4:32, 34)
11. Ní ríronú pé ó ní ìyìn ní ti ìjọsìn, ibo ni àwọn Farisí máa ń fọ ọwọ́ wọn dé kí wọ́n tó jẹun? (Máàkù 7:3)
12. Jésù sọ pé, ẹnì kan “gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú gbogbo yín” láti wà ní ipò wo? (Máàkù 10:44)
13. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé kì í ṣe ojúlówó tí a bá rí i? (Róòmù 8:24)
14. Kí ni a ń pe ọ̀wọ́ àwọn ẹran tí ń jẹ̀ pọ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 32:16)
15. Ọmọlẹ́yìn wo ló bi Jésù léèrè pé: “Ìwọ ha ń dá gbé gẹ́gẹ́ bí àtìpó ní Jerúsálẹ́mù?” (Lúùkù 24:18)
16. Inú kí ni Pọ́ọ̀lù ṣí wa létí láti “dàgbà di géńdé” nígbà tí a sì jẹ́ “ìkókó ní ti ìwà búburú”? (Kọ́ríńtì Kíní 14:20)
17. Inú oṣù àwọn Júù wo ni Nehemáyà parí àtúnkọ́ ògiri Jerúsálẹ́mù? (Nehemáyà 6:15)
18. Ìlú ńlá wo ló jẹ́ olú ìlú ìjọba ìhà àríwá Ísírẹ́lì fún nǹkan bí 200 ọdún? (Àwọn Ọba Kejì 3:1)
19. Ta ni bàbá wòlíì Jóẹ́lì? (Jóẹ́lì 1:1)
20. Irú igi wo ni Aísáyà sọ pé ẹnì kan yóò gbìn, tí yóò tún wá fi se oúnjẹ rẹ̀, tí yóò fi yáná, tí yóò sì fi ṣe ọlọ́run kan? (Aísáyà 44:14-17)
21. Àkọsílẹ̀ wo ló tẹ̀ lé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ilé ìṣọ́ Bábélì? (Jẹ́nẹ́sísì 11:10)
22. Àkókò sáà tí a sọ tẹ́lẹ̀ wo ni yóò dé kété ṣáájú ìfarahàn Mèsáyà? (Dáníẹ́lì 9:25)
23. Ta ni ìyá Hesekáyà Ọba rere náà? (Àwọn Ọba Kejì 18:2; Kíróníkà Kejì 29:1)
24. Bí ẹnì kan bá fi “ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn hàn sí àwọn òrìṣà,” kí ni a kò ní retí kí ó ṣe sí àwọn tẹ́ńpìlì? (Róòmù 2:22)
25. Orí ìpìlẹ̀ wo ni a óò fi dá ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òkú tí a jí dìde lẹ́jọ́? (Ìṣípayá 20:12, 13)
26. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ti sọ, gbígba ti àwọn wo rò ló jẹ́ àmì ìdánimọ̀ àwọn olùjọsìn tòótọ́? (Jákọ́bù 1:27)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀ dòdò ti kòkòrò kókọ́sì (NW)
2. Méje
3. Sálẹ́mù
4. Crux
5. Réúẹ́lì (NW)
6. Pé òun ṣègbọràn sí i
7. Amọ̀
8. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún
9. Mímú kí ó dàgbà
10. Oúnjẹ
11. Ìgúnpá
12. Ẹni àkọ́kọ́ láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù
13. Ìrètí
14. Agbo
15. Kíléópà
16. “Agbára òye”
17. Élúlì
18. Samáríà
19. Pétúélì
20. Lọ̀rẹ́ẹ̀lì (NW)
21. “Ọ̀rọ̀ ìtàn nípa Ṣémù” (NW)
22. “Ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta” náà
23. Ábí tàbí Ábíjà
24. Jà wọ́n lólè
25. Àwọn iṣẹ́ wọn
26. Àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó