Àwọn Obìnrin Ń pẹ́ Jù Láyé Kò Túmọ̀ Sí Pé Wọ́n Ń gbádùn Jù
JÁKÈJÁDÒ ayé, àwọn obìnrin ń pẹ́ kí wọ́n tó lọ sílé ọkọ, wọ́n sì ń bí ọmọ tí kò pọ̀, wọ́n sì ń pẹ́ láyé. Ìwé ìròyìn UNESCO Sources sọ pé: “Ìgbésí ayé àwọn obìnrin ti ń yí pa dà.” Láàárín 1970 sí 1990, nígbà tí a bá bímọ obìnrin, iye ọdún tí a retí pé yóò lò láyé fi ọdún mẹ́rin pọ̀ sí i ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà, ó sì fi ohun tí ó tó ọdún mẹ́sàn-án pọ̀ sí i ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. “Èyí já sí pé, ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti gòkè àgbà lónìí, àwọn obìnrin ń fi ìpíndọ́gba ọdún 6.5 pẹ́ láyé ju àwọn ọkùnrin lọ. Ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ọdún márùn-ún ni ìyàtọ̀ àárín wọn ní Latin America àti ní Caribbean, ó jẹ́ ọdún 3.5 ní Áfíríkà, ó sì jẹ́ ọdún mẹ́ta ní Éṣíà àti Pacific.”
Bí ó ti wù kí ó rí, fún ọ̀pọ̀ obìnrin, pípẹ́ láyé kò túmọ̀ sí gbígbádùn ayé wọn. Our Planet, ìwé ìròyìn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ pé, ní ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrin ayé, àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí kò ṣeé máà ní ṣì “jẹ́ ohun tí wọ́n fọkàn fẹ́ gidigidi àmọ́, tí ọwọ́ wọn kò tí ì tẹ̀. Wọ́n ṣì ń wá láti ní búrẹ́dì lásán tí a kò dárà sí àti omi.” Àjọ UN sọ pé, síbẹ̀, ọwọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn obìnrin kò tilẹ̀ lè tẹ àwọn ohun kòṣeémánìí nítorí pé àwọn ṣì ni wọ́n pọ̀ jù lọ lára gbogbo àwọn púrúǹtù, àwọn olùwá-ibi-ìsádi, àti àwọn aláìní lágbàáyé. Ìwé ìròyìn UNESCO Sources parí ọ̀rọ̀ sí pé, “gbogbo ìfojúsọ́nà ọjọ́ ọ̀la fún àwọn obìnrin . . . kò ṣíni lórí.”