Àrànṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Kan fún Ìgbésí Ayé
Olùkọ́ kan ní Zimbabwe, Áfíríkà, sọ pé ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Nyatsime, níbi tí òun ti ń kọ́ni, wọ́n ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan tí ń jẹ́ “Ẹ̀kọ́ fún Ìgbésí Ayé.” Ó ṣàpèjúwe àwọn ìṣòro ìdílé tí òun ti ní, ó sì gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́ láti yanjú wọn.
Nígbà tí ó ń ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí òun gbéyàwó, ó sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ kété lẹ́yìn náà ni àwọn ìṣòro ti bẹ̀rẹ̀, tí ó sì mú kí á pinnu láti pínyà ní November 1989.” Àwọn ìṣòro mìíràn tún wà. Ó kọ̀wé pé: “Èmi ni ọmọkùnrin tí ó dàgbà jù nínú àwọn ọmọ ìyá mi, tí ó jẹ́ ìyáálé bàbá mi. Nígbà tí mo wà ní ọdún kejì nílé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́, bàbá mi kú, ó fi àbúrò 16 lọ́kùnrin àti lóbìnrin sílẹ̀ fún mi láti bójú tó.”
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran olùkọ́ yìí lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro ìdílé tí ó ní. Òun àti ìyàwó rẹ̀ ti pa dà wà ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì láyọ̀. Ó kọ̀wé pé: “Nípa ìrírí onírora tí àwa fúnra wa ní, èmi àti ìyàwó mi ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, òmúlẹ̀mófo ni àwọn ìsapá ènìyàn láti yanjú àwọn ìṣòro rẹ̀ láìgbáralé Ọlọ́run.” Bí ó ti wù kí ó rí, kí ni ó ṣe láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro tiwọn?
Ó kọ̀wé pé: “Mo fi ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ han ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ wa àti àwọn olùkọ́ mìíràn pé ó dára fún ìlò gẹ́gẹ́ bí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo wọn gbà, ilé ẹ̀kọ́ sì béèrè fún ìwé 56, tí mo ti kó fún ilé ẹ̀kọ́ náà láti ìgbà náà.”
A gbà gbọ́ pé ìwọ pẹ̀lú yóò jàǹfààní gidigidi láti inú àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ olójú-ìwé 320, tí ó ní àwòrán mèremère yìí. Bí o bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà rẹ̀ kan gbà tàbí tí o bá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.