Párádísè kan Láìsí Wàhálà—Àlá Lásán Ni Bí?
“Ó LÁLÀÁFÍÀ gidigidi!” Ìran náà láti ibi igbó àwọn igi ahóyaya tí ó wà lápá òkè Adágún Redfish ní ìpínlẹ̀ Idaho, U.S.A., pa rọ́rọ́ ní tòótọ́. Arìnrìn-àjò náà sọ pé: “Ó rí bí mo ṣe finú wòye pé kí párádísè rí.”
Oòrùn mú dáradára ní etíkun ìhà gúúsù erékùṣù òkun Mediterranean ti Cyprus. Ìgbì omi rọra ń ya lu etíkun náà. Àlejò náà tí ó jókòó nílé àrójẹ tó wà lórí òkè kan ní àdojúkọ ìran náà fìmọ̀lára sọ pé: “Párádísè nìyí!”
Ọ̀pọ̀ nínú wa ń ṣìkẹ́ àwọn ìrántí bí ìwọ̀nyí. Ṣùgbọ́n àwọn olùgbé mọ̀ pé àwọn àyíká tó ní ìrísí párádísè sábà máa ń tanni jẹ ní ti ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ìṣòro ìgbésí ayé ojoojúmọ́: iná tí ń jó igbó nínú àwọn igi ẹsẹ̀ Òkè Ńlá Rocky, sísọ òkun dìbàjẹ́ tí ń nípa lórí àwọn ẹja àti ènìyàn níkẹyìn—ká má wulẹ̀ mẹ́nu ba àwọn ìforígbárí tí ń wu ìwàláàyè léwu láàárín àwọn orílẹ̀-èdè àti láàárín àwọn aládùúgbò.
Párádísè—Kí Ló Jẹ́?
Báwo ni ìwọ ṣe ń finú yàwòrán párádísè? Ìtumọ̀ àkọ́kọ́ nínú ìwé atúmọ̀ èdè The New Shorter Oxford English Dictionary pè é ni: “Ọgbà Édẹ́nì tí a ṣàpèjúwe nínú Jẹ́n[ẹ́sísì] 2, 3.” Èyí tọ́ka sí àpèjúwe tí ìwé kìíní nínú Bíbélì ṣe nípa ẹkùn ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi ọkùnrin kìíní, Ádámù, sí. Nínú Párádísè ìpilẹ̀ṣẹ̀ yẹn, àwọn igi “tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ” hù lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 2:9.
Ìtumọ̀ kejì nínú ìwé atúmọ̀ èdè yẹn so “párádísè” pọ̀ mọ́ “Ọ̀run, nínú ẹ̀kọ́ ìsìn ti àwọn Kristẹni àti Mùsùlùmí” ṣùgbọ́n ó ṣàfikún pé: “Ó jẹ́ [ti] ọ̀rọ̀ àròfọ̀ nísinsìnyí.” Bí ó ti wù kí ó rí, ní ti arìnrìn-àjò tó tún jẹ́ àlejò wa, párádísè jẹ́ ìtumọ̀ kẹta tí ìwé atúmọ̀ èdè náà fún un, “ẹkùn ilẹ̀ ẹlẹ́wà tàbí ìdùnnú kíkàmàmà.”
Alàgbà Thomas More tó jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèlú ilẹ̀ Britain ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún kọ ìwé kan tó pè ní Utopia, tó fi ṣàpèjúwe orílẹ̀-èdè àfinúrò kan, níbi tí àwọn òfin, ìṣàkóso, àti àwọn ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ti jẹ́ pípé. Lónìí, ó jọ ohun tí kò lè jóòótọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s New Collegiate Dictionary fi túmọ̀ “Utopia” sí “ìwéwèé tí kò lè gbéṣẹ́ nípa ìmúsunwọ̀n ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.”
Ní ti àwọn tí ń tẹ̀ lé aṣáájú ẹ̀ya ìsìn People’s Temple náà, Jim Jones, Utopia jẹ́ ibi gbalasa kan nínú igbó Guyana. Ó bani nínú jẹ́ pé, ní 1978, ibi tí a retí pé yóò jẹ́ párádísè yí di ibi ìran ikú fún iye tó lé ní 900 lára wọn—ohun tí ń dẹ́rù bani ní gidi! Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, nígbà míràn, àwọn ènìyàn máa ń so èròǹgbà nípa párádísè mọ́ àwọn ẹ̀ya ìsìn àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn ìṣe wọn ń múni gbọ̀n rìrì, tí ó sì ń dani lórí rú.
Nínú ayé kan tí ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá ti ń wuni léwu, tí àrùn ń wu tàgbàtèwe léwu lọ́nà kan náà, tí ìkórìíra òun ìyàtọ̀ nínú ẹ̀sìn sì ń pín àwọn àwùjọ níyà, àwọn àyíká rírẹwà sábà máa ń jẹ́ ìrísí ẹ̀tàn tí ń ṣeni lójú yòyò lásán. Abájọ tí àwọn ènìyàn fi ń rò pé párádísè wulẹ̀ jẹ́ àlá kan lásán! Àmọ́ èyí kò tí ì dá àwọn kan lọ́wọ́ kọ́ nínú gbígbìyànjú láti rí párádísè tàbí kí wọ́n tilẹ̀ ṣe ọ̀kan fúnra wọn. Báwo ni wọ́n ti kẹ́sẹ járí tó?