Wíwá Párádísè Tí Kò Ti Sí Wàhálà Kiri
TỌKỌTAYA ará Britain kan ṣàlàyé pé: “Gbogbo ohun tí a fẹ́ ṣe ni kí a ṣẹ̀dá ọ̀nà ìgbésí ayé aláàbò kan, bóyá tí ó jẹ́ ti àtijọ́, níbi tí àwọn ènìyàn ti ń bìkítà fún ara wọn lẹ́nì kíní kejì.” Wọ́n pinnu láti ṣàwárí párádísè erékùṣù ilẹ̀ olóoru kan, kí wọ́n sì dá ẹgbẹ́ àwùjọ kan tí yóò máa gbé pọ̀ lálàáfíà sílẹ̀ níbẹ̀. Láìsí iyè méjì, o lè lóye ìmọ̀lára wọn. Ta ni kì yóò yára tẹ́wọ́ gba àǹfààní láti gbé inú párádísè kan tí kò ti sí wàhálà?
Yíya Àṣo Ni Ojútùú Náà Bí?
Èròǹgbà wíwà ní erékùṣù kan máa ń fa ọ̀pọ̀ olùwá-párádísè mọ́ra, nítorí ìnìkanwà náà ń pèsè ààbò dé ìwọ̀n kan. Àwọn kan yan àwọn erékùṣù òdì kejì Etíkun Pacific ti Panama, tàbí àwọn erékùṣù ilẹ̀ Caribbean, bí àwọn ti òdì kejì Belize. Àwọn mìíràn darí àfiyèsí wọn sí àwọn ibi àrímáleèlọ nínú Òkun Íńdíà—bí àpẹẹrẹ, Seychelles.
Àwọn ohun tí ó rọ̀ mọ́ ìdásílẹ̀ àwùjọ àdádó kan kọjá agbára àfinúrò. Ká tilẹ̀ sọ pé owó tó pọ̀ tó wà, àwọn òfin ìjọba lè pààlà sí ríra ilẹ̀ kíákíá. Ṣùgbọ́n, ká sọ pé erékùṣù ilẹ̀ olóoru pípé náà ṣeé rí, ìwọ yóò ha láyọ̀ níbẹ̀ bí? Kì yóò ha sí wàhálà ní párádísè rẹ bí?
Àwọn erékùṣù jíjìnnà tó wà ní àyíká etíkun Britain ń ní ènìyàn púpọ̀ sí i nísinsìnyí. Ní gbogbogbòò, àwọn olùgbé tuntun náà jẹ́ àwọn ènìyàn tí ń wá ìnìkangbé àti àlàáfíà. Ọkùnrin kan tí ń dá gbé erékùṣù Eorsa tí ó fẹ̀ ní 100 hẹ́kítà, ní òdì kejì ìhà ìwọ̀ oòrùn etíkun Scotland, sọ pé òun kò fìgbà kankan nímọ̀lára ìnìkanwà nítorí tí òun ní ohun púpọ̀ láti ṣe, láti bójú tó agbo ẹran òun tí ó ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn nínú. Kì í pẹ́ tí àwọn mìíràn tí ó ti wá àyè láti dá wà ní erékùṣù fi ń bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára ìnìkanwà. A ti gbọ́ pé àwọn kan gbìyànjú láti pa ara wọn, tí wọ́n sì nílò ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ewu.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé erékùṣù àrímáleèlọ kékeré kan ní ilẹ̀ olóoru yóò jẹ́ párádísè. Gbígbé lábẹ́ ipò ojú ọjọ́ tó tura, tí ó ní àwọn àkókò tí ipò ojú ọjọ́ ń le jù mélòó kan, fà wọ́n mọ́ra. Ṣùgbọ́n ìdàníyàn nípa ṣíṣeéṣe tí ó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ ayé móoru, àti ìlọsókè ìpele ojú òkun tí ìyẹn lè fà, ti ń fa ìdààmú fún ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé erékùṣù. Àwọn olùgbé àwọn erékùṣù olómi-láàárín tí kò ga sókè, tó para pọ̀ di ẹkùn ilẹ̀ Tokelau ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn òkun Pacific, àti àwọn ti àwọn erékùṣù Maldive tó wà káàkiri Òkun Íńdíà, àwọn erékùṣù tí kò ga ju mítà méjì lọ sókè ìtẹ́jú òkun nígbà tí omi bá kún rẹ́rẹ́, nímọ̀lára ewu bákan náà pẹ̀lú.
Nǹkan bí 40 ìjọba ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti pawọ́ pọ̀ nínú àjọṣe Àwọn Orílẹ̀-Èdè Erékùṣù Kéékèèké Tí Ń Gòkè Àgbà láti wá ìtìlẹ́yìn fún yíyanjú ìṣòro wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùgbé àwọn erékùṣù kéékèèké ní gbogbogbòò ní ìfojúsọ́nà pípẹ́ láyé, tí iye ọmọdé wọn tí ń kú sì kéré gidigidi, wọ́n ń bá a nìṣó ní kíkojú àwọn ìṣòro àyíká lílekoko. Epo ojú omi àti àwọn òkun tí ó ti deléèérí ń dojú ètò ọrọ̀ ajé àwọn erékùṣù kan bolẹ̀. Àwọn mìíràn ti di àkìtàn èròjà onímájèlé tí àwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá fẹ́ láti kó dà nù.
Kódà, àwọn erékùṣù tí àwọn olùwá-párádísè fọkàn fẹ́ bí ibùdó ń wuni léwu. Báwo? Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tí ń ya lọ sí àwọn etíkun olóòrùn àwọn erékùṣù náà ń fa àpọ̀jù ènìyàn àti ìdínkù àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí kò tó nǹkan tẹ́lẹ̀ lọ́nà bíburú jù. Àwọn olùbẹ̀wò wọ̀nyí tún ń mú kí ìṣòro ìsọdèérí pọ̀ sí i. Ní Caribbean, bí àpẹẹrẹ, ìdá mẹ́wàá péré nínú ìyàgbẹ́ àwọn 20 mílíọ̀nù olùbẹ̀wò rẹ̀ lọ́dọọdún ni a ń da kẹ́míkà sí kí wọ́n tó dà á nù.
Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ibi àrà ọ̀tọ̀ míràn jọra. Fi ọ̀ràn Goa ní etíkun ìwọ̀ oòrùn Íńdíà ṣàpẹẹrẹ. Ìwé agbéròyìnjáde The Independent on Sunday ti London polongo pé: “Ìrìn àjò afẹ́ ọlọ́pọ̀ èrò ‘ń ba párádísè kan jẹ́.’” Àwọn ìfojúdíwọ̀n tí ìjọba gbé jáde fi hàn pé iye àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ lọ sókè láti 10,000 ní 1972 sí iye tí ó lé ní mílíọ̀nù kan ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990. Àwùjọ kan kìlọ̀ pé àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ Goa wà nínú ewu láti ọwọ́ àwọn oníwọra tí ń kọ́ hòtẹ́ẹ̀lì, tí wọ́n ń hára gàgà láti kófà lára àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tí ń ya wọ etíkun náà. Ìròyìn kan tí ìjọba ilẹ̀ Íńdíà ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti kọ́ àwọn hòtẹ́ẹ̀lì kan sí etíkun náà láìbófinmu. Wọ́n ti wa iyanrìn, wọ́n ti hú igi, wọ́n sì ti sọ àwọn òkè oníyanrìn tí afẹ́fẹ́ gbá jọ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń da ìyàgbẹ́ sí etíkun náà tàbí sínú àwọn ilẹ̀ àbàtà tó wà nítòsí, tí ń tipa bẹ́ẹ̀ tan ìsọdèérí kálẹ̀.
Ṣé Wọ́n Bọ́ Lọ́wọ́ Ìwà Ọ̀daràn?
Bí ìwà ọ̀daràn ṣe ń wọlé ń ba orúkọ rere tí àwọn àgbègbè tó lálàáfíà jù lọ pàápàá ní jẹ́. Ìròyìn kan tí ó wá láti erékùṣù kóńkóló Barbuda ti Caribbean ní àkọlé náà, “Ìpakúpa ní Párádísè.” Èyí ṣàlàyé ìṣìkàpànìyàn bíbanilẹ́rù ti àwọn ẹni mẹ́rin tí wọ́n pa nínú ọkọ ojú omi ẹlẹ́ńjìnnì kan, tí wọ́n fi ń gba fàájì, tí wọ́n fi gúnlẹ̀ sí etíkun erékùṣù náà. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí ìyẹn mú kí àníyàn pọ̀ sí i lórí bí ìwà ọ̀daràn ṣe ń gbilẹ̀ jákèjádò ẹkùn ilẹ̀ náà.
Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London gbé ìròyìn kan tí ó ní àkọlé, “Oògùn Líle Tanná Ran Ogun Àjọ Ìpàǹpá ní ‘Párádísè,’” jáde nípa Orílẹ̀-Èdè Àárín Gbùngbùn America kan. Olùyẹ̀wò-ṣàtúnṣe-ládùúgbò kan kédàárò lórí òtítọ́ náà pé àlàáfíà ti kásẹ̀ nílẹ̀, ni sísọ pé: “Ó wọ́pọ̀ pé kí a jí ní òwúrọ̀ nísinsìnyí, kí a sì rí ọmọ ọdún 16 kan nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ lójú títì.”
Àwọn tí ń lépa gbígbé nínú ẹgbẹ́ àwùjọ párádísè ń retí láti fa àwọn ènìyàn tí yóò gbà láti gbé lálàáfíà mọ́ra. Àmọ́ kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní gidi? Kò pẹ́ tí àìfohùnṣọ̀kan fi ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn àwọn tọkọtaya ará Britain tí a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀. Ó ṣe kedere pé àwọn kan lára àwọn tí wọ́n fẹ́ dara pọ̀ nínú ìdáwọ́lé wọn ń fẹ́ láti fi ìwéwèé náà pawó ni. Onígbọ̀wọ́ ìwéwèé náà polongo pé: “A kò fẹ́ àwọn aṣíwájú. Èròǹgbà náà jẹ́ láti ṣàkópọ̀ gbogbo ẹ̀bùn àdánidá wa, kí ohun gbogbo sì máa tẹ̀ síwájú. Mo pè é ní ẹgbẹ́ àwùjọ Utopia.” Lọ́nàkọnà, èyí kì í ṣe àkọ́kọ́ irú ìdáwọ́lé bẹ́ẹ̀.—Wo àpótí náà, “Àwọn Àfidánrawò Ẹgbẹ́ Àwùjọ Párádísè.”
Àwọn mìíràn tí ń wá párádísè gbà gbọ́ pé ọwọ́ àwọn yóò tẹ ohun tí àwọn ń lépa nípa jíjẹ tẹ́tẹ́ lọ́tìrì. Àmọ́ èrè owó tí a jẹ lọ́nà yí kì í fìgbà gbogbo mú ayọ̀ wá. Ní February 1995, ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ròyìn pé ìdílé ẹni tí ó jẹ tẹ́tẹ́ lọ́tìrì jù lọ ní Britain títí di báyìí ń ní èdè àìyédè ọlọ́jọ́ pípẹ́ láàárín ara wọn; jíjẹ tẹ́tẹ́ kò fún wọn ní ohunkóhun tó yàtọ̀ sí “ìkórìíra, ìṣọ̀tá ọlọ́jọ́ gbọọrọ àti àìnírètí.” Èyí wọ́pọ̀ nínú irú ipò bẹ́ẹ̀.
Nínú ìwádìí kan lórí bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń wá Utopia kiri, akọ̀ròyìn Bernard Levin sọ̀rọ̀ nípa “àlá ọlà ojú ẹsẹ̀,” ó sì wí pé: “Bí ó ti rí pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àlá, kò jìnnà sí ohun tí ń dẹ́rù bani. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtàn tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ló wà nípa ọlà ojú ẹsẹ̀ tó yọrí sí ìjábá pátápátá (títí kan pípa ara ẹni) tó bẹ́ẹ̀ tí a kò lè pa wọ́n tì gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ kòńgẹ́ lásán.”
Àwọn Ẹ̀ya Ìsìn Ọjọ́ Ìdájọ́ Ń Kọ́?
Àwọn ìwéwèé mìíràn nípa párádísè ti ní ìtumọ̀ ibi jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde kan ń ròyìn nípa ìsàgatì àwọn ẹ̀ka agbófinró ìjọba lórí ilẹ̀ àwọn Branch Davidians ní Waco, Texas, ní 1993, ó sọ nípa “ìdàrúdàpọ̀ ìbọn, ìfẹ̀tàndani-lọ́pọlọ-rú àti wòlíì ọjọ́ ìdájọ́ kan” tó ṣamọ̀nà sí ìjàǹbá náà. Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ló wà.
Àwọn ọmọlẹ́yìn olóògbé Bhagwan Shree Rajneesh, aṣáájú ọ̀ràn tẹ̀mí kan ní Íńdíà, gbé àwùjọ kan kalẹ̀ ní Oregon, ṣùgbọ́n wọ́n ṣẹ̀ sí èròǹgbà ìwà rere àwọn aládùúgbò wọn. Ìkọ́rọ̀jọ àwọn aṣáájú wọn àti àfidánrawò ìbálòpọ̀ tí wọ́n ń ṣe ba ìpolongo wọn pé àwọn ti ṣàgbékalẹ̀ “ibi ààbò rírẹwà kan” jẹ́.
Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ awo tí àwọn ènìyàn tí ń retí párádísè jẹ́ aṣáájú fún ń béèrè pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn wọn máa ṣe àwọn ààtò ṣíṣàjèjì, tí ń yọrí sí ìgbéjàkoni nígbà púpọ̀. Akọ̀ròyìn fún ìwé ìròyìn kan, Ian Brodie, ṣàlàyé pé: “Àwọn ẹgbẹ́ awo ń pèsè ibi ààbò àti ẹgbẹ́ àwùjọ tí a ṣètò fún àwọn tí wọ́n rò pé àwọn ń dá gbé tàbí tí wọn kò lè kojú àwọn hílàhílo ayé ní gidi.” Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́rìí sí òtítọ́ náà pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò fẹ́ láti gbé nínú párádísè kan.
Párádísè Kan Tí Kò Ti Sí Wàhálà
Ó jọ pé àkọsílẹ̀ àwọn wàhálà kò lópin: ìsọdèérí, ìwà ọ̀daràn, ìjoògùnyó, àpọ̀jù ènìyàn, ìforígbárí ìran, rúkèrúdò ìṣèlú—ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ tí àwọn wàhálà tó kan gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, àrùn àti ikú. Ìparí èrò náà gbọ́dọ̀ jẹ́ pé kò sí ibikíbi lórí pílánẹ́ẹ̀tì yí, tí párádísè kan tí kò ti sí wàhálà rárá wà. Gẹ́gẹ́ bí Bernard Levin ṣe sọ: “Àkọsílẹ̀ ìran ènìyàn ní àbààwọ́n kan, ó sì jọ pé ó ti wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìran ènìyàn. Ó ní ìrísí àìlèjọgbé tayọ̀tayọ̀ ní ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn míràn tó pọ̀ ju iye mélòó kan lọ.”
Bí ó ti wù kí ó rí, párádísè kan tí ó kárí ayé, tí yóò sì wà láìsí wàhálà ní tòótọ́ yóò dé. Agbára kan tó ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ ló fún wa ni ìdánilójú bí yóò ti wà pẹ́ tó. Ní tòótọ́, àwọn ènìyàn tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ń ṣiṣẹ́ síhà ìlépa yẹn nísinsìnyí, wọ́n sì ń gbádùn ìṣọ̀kan oníyebíye àti àyíká kan tí kò ti sí wàhálà dé ìwọ̀n àyè kan láàárín ara wọn. Ibo lo ti lè rí wọn? Báwo ni o ṣe lè ṣàjọpín ìrètí àti àǹfààní kan náà tí wọ́n ń gbádùn nísinsìnyí? Báwo ni Párádísè tí ń bọ̀ yẹn yóò sì ti wà pẹ́ tó?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Àfidánrawò Ẹgbẹ́ Àwùjọ Párádísè
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ọmọ ilẹ̀ Faransé tó ní èrò ẹgbẹ́ àjùmọ̀ní náà, Étienne Cabet (1788 sí 1856), àti 280 àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dá ibùdó àjùmọ̀ní kan, tí ó gbé karí àwọn èròǹgbà rẹ̀, sílẹ̀ ní Nauvoo, Illinois. Ṣùgbọ́n, láàárín ọdún mẹ́jọ, ìyapa ńlá yọjú ní àwùjọ náà tí ó fi tú ká láìpẹ́, bí àwọn àwùjọ tó jọ ọ́ ní Iowa àti California ti ṣe.
Ọmọ ilẹ̀ Faransé mìíràn, Charles Fourier (1772 sí 1837), mú èròǹgbà àwùjọ oníṣẹ́ àgbẹ̀ aláfọwọ́-sowọ́pọ̀ kan dàgbà pẹ̀lú ìyípadà nínú ipa tí gbogbo àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ń kó. Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò máa gba iye owó tí a gbé karí bí àwùjọ náà lápapọ̀ bá ṣe ń ṣàṣeyọrí tó. Àmọ́, àwọn àwùjọ tí a ń gbé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ wọ̀nyí ní ilẹ̀ Faransé àti ní United States kì í tọ́jọ́.
Ní nǹkan bí àkókò kan náà, alátùn-únṣe ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ará Wales náà, Robert Owen (1771 sí 1858), wéwèé àwọn abúlé aláfọwọ́-sowọ́pọ̀, níbi tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn yóò ti máa gbé pọ̀ ní lílo ibi ìgbọ́únjẹ àti ibi ìjẹun àjùmọ̀ní. Ìdílé kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé ní ilé tiwọn, wọn yóò sì máa bójú tó àwọn ọmọ wọn, títí wọn yóò fi pé ọmọ ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà, àwùjọ náà lápapọ̀ yóò tẹ́wọ́ gba ẹrù àbójútó àwọn ọmọ. Àmọ́ àfidánrawò tí Owen ṣe forí ṣánpọ́n, ó sì pàdánù ọ̀pọ̀ lára ohun ìní tirẹ̀ fúnra rẹ̀.
John Noyes (1811 sí 1886) di olùdásílẹ̀ ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica pè ní “àwùjọ àjùmọ̀ní utopia tó kẹ́sẹ járí jù lọ ní United States.” Nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kọ ìgbéyàwó ọkọ kan aya kan sílẹ̀, tí wọ́n sì fàyè gba ìbálòpọ̀ lórí ìfohùnṣọ̀kan láàárín gbogbogbòò, wọ́n fàṣẹ mú Noyes lórí ẹ̀sùn panṣágà.
Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London ròyìn pé, Laissez Faire City, oríṣi “Utopia olówò bòńbàtà” kan ní Àárín Gbùngbùn America, jẹ́ ìgbìdánwò lọ́ọ́lọ́ọ́ kan láti ṣẹ̀dá irú àwùjọ Utopia bẹ́ẹ̀ kan. A wá àwọn tí yóò gbówó kalẹ̀ fún ìdáwọ́lé náà. Bí ìfojúsọ́nà gbígbé láàárín “ìlú àgbàyanu ti ọ̀rúndún kọkànlélógún” ti fẹ̀tàn fà wọ́n mọ́ra, a ké sí àwọn tí ń wá párádísè láti fi 5,000 dọ́là ránṣẹ́, kí wọ́n sì dara pọ̀ nínú oríṣi ìtajà ìfibébàṣírò èrè tí a fojú sọ́nà fún kan, kí wọ́n sì máa wá àwọn ènìyàn tó ní èrò kan náà, tí àwọn náà yóò tún fi owó wọn dókòwò lẹ́yìn náà. Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́, ìwé ìròyìn náà ṣàlàyé pé, gbogbo ohun tí owó yìí wà fún ni láti gba tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ òfuurufú kan láti lọ wo bí ìdáwọ́lé náà yóò ṣe rí, “ká ní a tilẹ̀ lè rọ orílẹ̀-èdè kan láti yọ̀ǹda ilẹ̀ tí a lè kọ́ ọ sí, kí a sì kọ́ hòtẹ́ẹ̀lì kékeré kan síbẹ̀.” Kò sí ìrètí gidi kankan nípa dídá “párádísè” kan sílẹ̀ níbẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Erékùṣù kan máa ń fa ọ̀pọ̀ olùwá-párádísè lọ́kàn mọ́ra. Ṣùgbọ́n lónìí, ìwà ọ̀daràn ń ba àgbègbè alálàáfíà jù lọ pàápàá jẹ́