Ǹjẹ́ Ìfàjẹ̀sínilára Tiẹ̀ Pọndandan?
ÀPILẸ̀KỌ inú ìwé ìròyìn kan ló gbé ìbéèrè tó wà lókè yìí jáde ní November ọdún tó kọjá, tí Dókítà Ciril Godec, alága ìmọ̀ ìṣègùn nípa àwọn ẹ̀yà inú ara tí ń gbé ìtọ̀ jáde lára ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn Long Island, ní Brooklyn, New York gbé jáde. Ó kọ̀wé pé: “Ó ṣeé ṣe kí a má fọwọ́ sí lílo ẹ̀jẹ̀ bí egbòogi lóde òní, nítorí pé kò kúnjú ọ̀pá ìdíwọ̀n pípèsè ààbò tí Àjọ Abójútó Oúnjẹ àti Oògùn là sílẹ̀. Ọ̀kan lára ẹ̀yà ara ni ẹ̀jẹ̀, fífàjẹ̀sínilára kò sì yàtọ̀ sí iṣẹ́ abẹ pípààrọ̀ ẹ̀yà ara.”
Dókítà Godec sọ pé: “Pípààrọ̀ ẹ̀yà ara ni oríṣi ìtọ́jú tí a máa ń wéwèé kẹ́yìn fún aláìsàn. Nítorí àwọn ìṣòro ńláńlá tó ṣeé ṣe kó tìdí ẹ̀ yọ, ńṣe ni a máa ń ṣàlàyé dáadáa nípa gbogbo ohun mìíràn tí a lè ṣe dípò pípààrọ̀ ẹ̀yà ara fún aláìsàn ká tó ṣe é.” Ní ti ìfàjẹ̀sínilára, ó sọ pé: “Àǹfààní tó wà níbẹ̀ kò dáni lójú rárá débi pé ọ̀pọ̀ àwọn oníṣẹ́ abẹ ti sọ ‘yíyẹra fún ìfàjẹ̀sínilára’ dàṣà, kì í ṣe kìkì nítorí ọ̀ràn ìṣègùn nìkan ṣùgbọ́n nítorí ọ̀ràn òfin pẹ̀lú.”
Ìṣòro pàtàkì kan tí ń tìdí ìfàjẹ̀sínilára wá ni pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ló ti kó àrùn aṣekúpani, tí àrùn éèdì jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tí a ń gbà yẹ ẹ̀jẹ̀ wò ti sunwọ̀n sí i níbi púpọ̀, Dókítà Godec sọ pé: “Ewu kan wà nínú ẹ̀jẹ̀ tí àwọn ènìyàn fi ń tọrẹ, ìyẹn àwọn tí wọ́n ti kó àrùn ṣùgbọ́n tí kò tíì sí àwọn agbógunti àrùn tí a lè rí lára wọn nígbà tí a bá ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ wọn.”
Nígbà tí Dókítà Godec ń parí àpilẹ̀kọ rẹ̀, ó dáhùn ìbéèrè tí a béèrè lókè yìí pé: “Bí àwọn oníṣègùn àti àwọn oníṣẹ́ abẹ ṣe túbọ̀ ń lóye ìmọ̀ nípa bí afẹ́fẹ́ ṣe ń lọ káàkiri ara tí wọ́n sì ń mọ̀ pé ìwọ̀n èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀ kò ní láti pọ̀ tó bí àwọn ṣe rò tẹ́lẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbà gbogbo ló máa ń ṣeé ṣe fún wọn láti wá ojútùú mìíràn dípò ìfàjẹ̀sínilára. Láìpẹ́, ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn, ẹ̀jẹ̀ máa ń dà nù gan-an lára àwọn tí a ń ṣe iṣẹ́ abẹ tó ṣòro gan-an fún, ìyẹn iṣẹ́ abẹ́ pípààrọ̀ ọkàn-àyà àti ẹ̀dọ̀ki, débi pé a máa ń rò pé wọ́n nílò ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ gan-an láti rọ́pò èyí tó dà nù. Ní báyìí, wọ́n ti gbìyànjú ìlànà iṣẹ́ abẹ méjèèjì láìfàjẹ̀ síni lára.
“Ó ṣeé ṣe pé kí a fagi lé ìfàjẹ̀sínilára láìpẹ́. . . . Kì í ṣe pé ìfàjẹ̀sínilára gbówólórí, pé ó sì léwu nìkan ni; ó wulẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ojúlówó ìtọ́jú tó tọ́ sí aláìsàn.”