“Ìwé Gidi Mà Lèyí O!”
Báwo layé àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lójú, kí wọ́n lóye ara wọn, kí wọ́n sì kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn? Láìpẹ́ yìí, ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Sípéènì rí lẹ́tà kan gbà, díẹ̀ lára ohun tó wà nínú rẹ̀ nìyí:
“Ìdí tí mo fi kọ̀wé yìí jẹ́ láti kí yín fún iṣẹ́ rere tí ẹ ń ṣe nípa ṣíṣe àwọn ìwé àgbàyanu jáde, bí èyí tí ẹ pè ní Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Ìwé gidi mà lèyí o! Mo kí àwọn tó kọ ìwé náà àti àwọn tó ṣe é jáde, tí wọ́n mú kí àlá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ ṣẹ.
“Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ni mí, mo fàyè sílẹ̀, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà kan rí. . . . Lọ́nà kan ṣáá, ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ ti ọwọ́ ọ̀rẹ́ mi kan dé ọwọ́ mi.
“Mo kọ́kọ́ rò pé kò lè ṣe mí láǹfààní kankan, ṣùgbọ́n kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ láti kà á. Ó jẹ́ kí n máa ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan, bí ọ̀nà tó yẹ kí n gbà lo ayé mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn àwọn ìbéèrè mi díẹ̀díẹ̀. Níwọ̀n bí ohun iyebíye yẹn ti wà lọ́wọ́ mi, mo kọ́ bí mo ṣe lè máa lóye àwọn òbí mi, bí mo ṣe lè máa dárí jini, àti bí mo ṣe lè jẹ́ obìnrin kí n sì máa hùwà bí obìnrin.”
Bí o bá fẹ́ jàǹfààní nínú ìsọfúnni tó wà nínú ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, o lè rí ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà rẹ̀ gbà nípa kíkọ̀wé kún fọ́ọ̀mù ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó wà lára fọ́ọ̀mù náà tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sí ojú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé náà, Àwọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, gbà.
Kọ èdè tí o fẹ́.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.