Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
Lóde òní, àwọn èèyàn kì í sábà pọ́nni lé mọ́. Torí náà, ó máa ń jọ wọ́n lójú gan-an tí wọ́n bá rí i tẹ́nì kan ń pọ́n ẹlòmíì lé.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ kì í bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn, àwọn èèyàn kì í bẹ̀rù ẹni tó jù wọ́n lọ, wọn kì í sì í bọ̀wọ̀ fáwọn ọlọ́pàá, àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ àtàwọn olùkọ́. Ti orí ìkànnì àjọlò ló wá burú jù, ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń rí ara wọn fín níbẹ̀, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ burúkú síra wọn! Kódà, ìwé ìròyìn Harvard Business Review sọ pé, ‘ojoojúmọ́ làwọn èèyàn túbọ̀ ń ṣe ohun tó fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fúnni.’ Ìwé ìròyìn yẹn wá fi kún un pé “àwọn èèyàn ti túbọ̀ ń kíyè sí ìwà yìí, ńṣe ló sì ń burú sí i.”