Orin 148
O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Kan Ṣoṣo
Bíi Ti Orí Ìwé
	- Jèhófà, Baba wa, - Nígbà tá ò nírètí. - O pèsè ’ràpadà - Ká lè nírètí! - A ó fayé wa sìn ọ́, - Gbogbo ohun tá a jẹ́. - A ó wàásù fáráyé, - Kí ìfẹ́ rẹ lè ṣẹ. - (ÈGBÈ) - O fún wa l’Ọ́mọ rẹ, - A sì ń kọrin yìn ọ́, - A ó máa yìn ọ́ títí láé, - fún bó o ṣe fún wa l’Ọ́mọ rẹ. 
- Àánú rẹ, oore rẹ, - Ló ń jẹ́ ká sún mọ́ ọ. - Oókọ rẹ, ìfẹ́ rẹ, - Sí wa dùn mọ́ wa. - Ẹ̀bùn tó dára jù - Ni ọmọ rẹ ọ̀wọ́n. - Ó kú ká lè níyè. - Ìwọ lo rán an wá. - (ÈGBÈ) - O fún wa l’Ọ́mọ rẹ, - A sì ń kọrin yìn ọ́, - A ó máa yìn ọ́ títí láé, - fún bó o ṣe fún wa l’Ọ́mọ rẹ. - (ÌPARÍ) - Jèhófà, Baba wa, ọkàn wa kún f’ọ́pẹ́. - A dúpẹ́ tó o fún wa ní Ọmọ rẹ kan ṣoṣo. 
(Tún wo Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:9.)