May
Wednesday, May 1
Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.—Òwe 4:13.
Òótọ́ ni pé ìbáwí máa ń dunni, àmọ́ téèyàn ò bá gba ìbáwí, ohun tó máa ń yọrí sí máa ń burú jùyẹn lọ. (Héb. 12:11) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Kéènì. Nígbà tí Kéènì kórìíra Ébẹ́lì débi pé ó ń ronú bó ṣe máa pa á, Ọlọ́run gbà á níyànjú pé: “Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?” (Jẹ́n. 4:6, 7) Kéènì ò tẹ́tí sí Jèhófà, ó kó sínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ló sì fi jìyà ohun tó ṣe yẹn. (Jẹ́n. 4:11, 12) Ká sọ pé ó gba ìbáwí tí Jèhófà fun un ni, kò bá má jìyà tóyẹn. Ẹ ò rí bí Jèhófà ṣe ń kọ́ wa ká má bàa kàgbákò bíi tàwọn tá a sọ tán yìí! (Aísá. 48:17, 18) Torí náà, ẹ jẹ́ ká “fetí sí ìbáwí ká lè di ọlọ́gbọ́n.”—Òwe 8:33. w18.03 32 ¶18-20
Thursday, May 2
Èmi fúnra mi, Dáníẹ́lì, fi òye mọ̀ láti inú ìwé, iye ọdún.—Dán. 9:2.
Ó ṣe kedere pé àwọn òbí Dáníẹ́lì kọ́ ọ pé kó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí Dáníẹ́lì sì ṣe ń dàgbà, kò gbàgbé ohun tí wọ́n kọ́ ọ, jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ló fi sin Jèhófà. Kódà nígbà tó darúgbó, ó ṣì ń fara balẹ̀ ka Ìwé Mímọ́. Ohun tí Dáníẹ́lì mọ̀ nípa Jèhófà àti bí Jèhófà ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò ṣe kedere nínú àdúrà tó gbà nínú Dáníẹ́lì 9:3-19. O ò ṣe wáyè ka àdúrà yẹn, kó o sì ṣàṣàrò lé e. Kò rọrùn fáwọn Júù olóòótọ́ tó ń gbé nílùú Bábílónì láti sin Ọlọ́run láàárín àwọn abọ̀rìṣà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fáwọn Júù pé: “Ẹ wá àlàáfíà ìlú ńlá tí mo mú kí a kó yín lọ ní ìgbèkùn.” (Jer. 29:7) Ìyẹn ò wá ní kí wọ́n máa jọ́sìn àwọn òrìṣà wọn torí Jèhófà sọ pé òun nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ jọ́sìn. (Ẹ́kís. 34:14) Kí ló ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti pa àṣẹ méjèèjì yìí mọ́? Ọgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ kó mọ̀ pé ó níbi téèyàn lè bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ mọ. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká fìyàtọ̀ sóhun tá à ń fún Ọlọ́run àtohun tó tọ́ sáwọn aláṣẹ.—Lúùkù 20:25. w18.02 10 ¶11-12
Friday, May 3
Sàmì sí iwájú orí àwọn ènìyàn.—Ìsík. 9:4.
Àwọn ìṣòro wo lò ń kojú? Ṣé àìlera ni, àìlówó lọ́wọ́ tàbí inúnibíni? Nígbà míì, ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o kò láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà mọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Aláìpé ni wọ́n, irú àwọn ìṣòro tá à ń kojú làwọn náà kojú, kódà wọ́n kojú àwọn ìṣòro tó lè gbẹ̀mí wọn. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà ò yingin, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. (Ìsík. 14:12-14) Ìlú Bábílónì ni Ìsíkíẹ́lì ti kọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà lọ́dún 612 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Ìsík. 1:1; 8:1) Ìyẹn ọdún díẹ̀ ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù tó wáyé lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn díẹ̀ ló jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù, àwọn olóòótọ́ yìí nìkan ló sì là á já. (Ìsík. 9:1-5) Bíi ti ìgbà yẹn, àwọn tí Jèhófà bá kà sí olódodo bíi Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù nìkan ló máa la ayé búburú yìí já.—Ìṣí. 7:9, 14. w18.02 3-4 ¶1-3
Saturday, May 4
Rántí . . . Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.—Oníw. 12:1.
Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé torí àwọn òbí mi ni mo ṣe ń lọ́wọ́ sáwọn nǹkan tẹ̀mí, àbí ó tọkàn mi wá? Ṣé mò ń sapá láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?’ Kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló yẹ kí wọ́n ní àfojúsùn tẹ̀mí, ó kan àwọn àgbàlagbà náà. Tá a bá láwọn àfojúsùn tẹ̀mí, gbogbo wa máa fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa, àá sì dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. (Oníw. 12:13) Tá a bá ti mọ àwọn ibi tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe, ó yẹ ká tètè ṣe bẹ́ẹ̀ ká lè tẹ̀ síwájú. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká dẹni tẹ̀mí, tá ò bá dẹni tẹ̀mí, ìyè àìnípẹ̀kun lè bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. (Róòmù 8:6-8) Kò dìgbà tá a bá di ẹni pípé ká tó lè dẹni tẹ̀mí. Jèhófà lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ láti tẹ̀ síwájú. Síbẹ̀, àwa náà ní láti sapá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń gbádùn mọ́ni, kò yẹ ká máa kà á bí ìwé ìtàn àròsọ tá a fi ń dá ara wa lára yá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa wá àwọn ìṣúra tẹ̀mí tó máa ràn wá lọ́wọ́. w18.02 25 ¶10-11
Sunday, May 5
Èé ti ṣe tí ìwọ fi ń jáfara? Dìde, kí a batisí rẹ.—Ìṣe 22:16.
Kò dìgbà téèyàn bá mọ gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì kó tó lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ kó sì ṣèrìbọmi. Ìdí ni pé gbogbo Kristẹni ló yẹ kó máa gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣèrìbọmi. (Kól. 1:9, 10) Torí náà, báwo ni ìmọ̀ tẹ́nì kan ní ṣe gbọ́dọ̀ tó kó tó lè ṣèrìbọmi? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìdílé kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa jẹ́ káwọn òbí mọ bí ẹnì kan ṣe gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó kó tó lè ṣẹ̀rìbọmi. (Ìṣe 16:25-33) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹ̀ẹ̀kejì, ó lọ sílùú Fílípì lọ́dún 50 Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó débẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn èké kan òun àti Sílà tí wọ́n jọ ń rìnrìn-àjò, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Nígbà tó di òru, ìmìtìtì ilẹ̀ kan wáyé, ó sì mi ọgbà ẹ̀wọ̀n náà débi pé gbogbo ilẹ̀kùn ló ṣí sílẹ̀ gbayawu. Nígbà tí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó rò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ti sá lọ, ló bá fẹ́ pa ara rẹ̀, àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù àti Sílà wàásù fún ọkùnrin náà àti ìdílé rẹ̀, ohun tí wọ́n gbọ́ sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Àmọ́, kí lohun tí wọ́n gbọ́ yẹn mú kí wọ́n ṣe? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n ṣèrìbọmi. w18.03 10 ¶7-8
Monday, May 6
Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!—Sm. 144:15.
Ọlọ́run aláyọ̀ ni Jèhófà, báwọn èèyàn rẹ̀ sì ṣe rí nìyẹn. Wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn onímọtara-ẹni-nìkan tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa gba tọwọ́ àwọn míì ni wọ́n ń wá, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni torí pé wọ́n máa ń lo ara wọn fáwọn míì. (Ìṣe 20:35; 2 Tím. 3:2) Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ ara wa ju Ọlọ́run lọ? Ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 2:3, 4. Ẹsẹ yìí ní ká má ṣe ‘ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí a máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ, kí a má ṣe máa mójú tó ire ara wa nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò ní ìgbésí ayé mi? Ṣé mo máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́ yálà nínú ìjọ tàbí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?’ Kò rọrùn láti lo ara ẹni fáwọn míì, ó máa ń gba kéèyàn sapá gan-an, kó sì yááfì àwọn nǹkan kan. Àmọ́, kò sóhun tó lè múnú wa dùn tó mímọ̀ tá a mọ̀ pé inú Jèhófà Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ń dùn sí wa. w18.01 23 ¶6-7
Tuesday, May 7
Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́.—2 Kọ́r. 13:5.
Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo gbà lóòótọ́ pé inú ètò kan ṣoṣo tí Ọlọ́run fọwọ́ sí tó sì ń lò ni mo wà yìí? Ṣé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí mo sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? Ǹjẹ́ ìwà mi ń fi hàn pé mo gbà lóòótọ́ pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí àti pé òpin ètò Sátánì ti sún mọ́lé? Ṣé mo ṣì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà àti Jésù bí mo ṣe ní in nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara mi sí mímọ́?’ (Mát. 24:14; 2 Tím. 3:1; Héb. 3:14) Tá a bá ń ronú lórí irú àwọn ìbéèrè yìí, á ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run tó sọ̀rọ̀ nípa bí Ìrántí Ikú Kristi ti ṣe pàtàkì tó, kó o sì ṣàṣàrò lé wọn lórí. (Jòh. 3:16; 17:3) Ohun kan ṣoṣo tó lè mú ká jogún ìyè àìnípẹ̀kun ni pé ká ‘gba ìmọ̀’ Jèhófà ká sì máa “lo ìgbàgbọ́” nínú Jésù, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. Tó o bá fẹ́ múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi, á dáa kó o dìídì ṣètò láti ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa lọ́nà táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Jésù. w18.01 13 ¶5-6
Wednesday, May 8
Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.—Jòh. 6:44.
Tó o bá ń ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, tó o sì ń lọ sípàdé, á túbọ̀ ṣe kedere sí ẹ pé Jèhófà máa ń ti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́yìn kí wọ́n lè jólóòótọ́. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tíwọ náà sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó yẹ kó o rí ọwọ́ Jèhófà láyé tìẹ náà. Ǹjẹ́ o lè rántí àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún ọ? Ọ̀nà kan wà tí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà tọ́ Jèhófà wò tá a sì rí i pé ẹni rere ni, ìyẹn sì ni bó ṣe mú wa wá sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ̀. Ọ̀dọ́ kan lè ronú pé, ‘Ṣebí Jèhófà ti fa àwọn òbí mi, èmi náà sì tẹ̀ lé wọn, wọ́n ṣáà sọ pé bí ìgbín bá fà, ìkarahun á tẹ̀ lé e.’ Àmọ́ rántí pé nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèrìbọmi, ṣe lo wọnú àdéhùn pẹ̀lú Jèhófà, tó o sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, o kì í ṣe àjèjì sí Jèhófà, ó mọ̀ ẹ́ dáadáa. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni ó mọ̀.” (1 Kọ́r. 8:3) Torí náà, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn pé o wà nínú ètò Jèhófà, kó máa dán gbinrin lọ́kàn rẹ. w17.12 26 ¶12-13
Thursday, May 9
Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.—Héb. 12:6.
Ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí” lè mú kọ́kàn ẹ lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ fìyà jẹ, àmọ́ ká fìyà jẹni nìkan kọ́ ni ìbáwí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà ìbáwí pẹ̀lú àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì, irú bí ìmọ̀, ọgbọ́n, ìfẹ́ àti ìwàláàyè. (Òwe 1:2-7; 4:11-13) Ìdí sì ni pé Ọlọ́run máa ń bá wa wí torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó fẹ́ ká wà láàyè títí láé. (Héb. 12:6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbáwí lè ní ìyà díẹ̀ nínú, síbẹ̀ Jèhófà kì í le koko jù tàbí kó fìyà jẹ wá ju bó ṣe yẹ lọ tó bá ń bá wa wí. Ká sòótọ́, ohun tí ìbáwí túmọ̀ sí ni pé ká kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn irú ẹ̀kọ́ tí òbí kan máa ń kọ́ ọmọ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́. Lónìí, bá a ṣe wà nínú ìjọ Kristẹni ti mú ká di ara ìdílé Ọlọ́run. (1 Tím. 3:15) Torí náà, a gbà pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa ní ìtọ́ni àti pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fìfẹ́ bá wa wí tá a bá ṣàìgbọràn. Bákan náà, tá a bá hùwà tí kò dáa, tá a sì jìyà ẹ̀, á jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ṣègbọràn sí Baba wa ọ̀run.—Gál. 6:7. w18.03 23 ¶1; 24 ¶3
Friday, May 10
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.—Òwe 17:27.
Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí rẹ kò mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ tàbí pé wọ́n ti le koko jù, kí ni wàá ṣe? Inú lè bẹ̀rẹ̀ sí í bí ẹ, kó o sì máa ṣiyèméjì bóyá kó o sin Jèhófà tàbí kó o má sìn ín. Àmọ́ tó o bá bínú fi Jèhófà sílẹ̀, bópẹ́bóyá wàá rí i pé kò sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ rẹ tó àwọn òbí rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà. Tó bá jẹ́ pé àwọn òbí rẹ kì í bá ẹ wí rárá, ǹjẹ́ o ò ní bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ? (Héb. 12:8) Ó lè jẹ́ pé ọ̀nà tí àwọn òbí rẹ ń gbà bá ẹ wí ló máa ń bí ẹ nínú. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, dípò kó o máa bínú torí ọ̀nà tí wọ́n gbà bá ẹ wí, á dáa kó o ronú nípa ìdí tí wọ́n fi bá ẹ wí. Torí náà, ṣe sùúrù, má ṣe máa fapá jánú tí wọ́n bá ń bá ẹ wí. Torí náà, sapá kó o lè máa hùwà àgbà, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ bó o ṣe lè fi sùúrù gba ìbáwí àti bó o ṣe lè jàǹfààní nínú ìbáwí náà.—Òwe 1:8. w17.11 29 ¶16-17
Saturday, May 11
Ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.—Ìṣí. 2:4.
Ó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ṣèrìbọmi àmọ́ tí wọ́n ń ronú pé àwọn ò rídìí tó fi yẹ káwọn máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Torí náà, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ pé bóyá ìfẹ́ tí ọmọ rẹ ní níbẹ̀rẹ̀ lè di tútù lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi. Kí lo lè ṣe tí irú ẹ̀ ò fi ní ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ, tí wàá sì ràn án lọ́wọ́ kó lè “dàgbà dé ìgbàlà”? (1 Pét. 2:2) Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Tímótì yẹ̀ wò. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì, ó sọ pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn àti pé láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́ [ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù], èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (2 Tím. 3:14, 15) Kíyè sí ohun mẹ́ta tí Pọ́ọ̀lù sọ pé Tímótì ṣe (1) ó mọ ìwé mímọ́, (2) a yí i lérò pa dà láti gba àwọn ohun tó kọ́ gbọ́, àti (3) ó di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tó ní nínú Kristi Jésù. w17.12 18-19 ¶2-3
Sunday, May 12
Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe ẹkún nítorí ìrora ọkàn-àyà.—Aísá. 65:14.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ní ti pé wọ́n ń ti àwọn olóṣèlú lẹ́yìn, wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá, wọ́n sì máa ń kọ́ni pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ máa jóná nínú ọ̀run àpáàdì. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé àwọn á láyọ̀ láìṣe ẹ̀sìn kankan. Òótọ́ ni pé èèyàn á láyọ̀ tí kò bá ṣe ẹ̀sìn èké, àmọ́ téèyàn bá máa ní ojúlówó ayọ̀, ó ṣe pàtàkì kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà tí Bíbélì pè ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tím. 1:11) Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń ṣe ló ń ṣe wá láǹfààní. Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń láyọ̀ torí pé à ń ran àwọn míì lọ́wọ́. (Ìṣe 20:35) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe ń mú kéèyàn láyọ̀. Ó ń jẹ́ káwọn tọkọtaya mọ bí wọ́n ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, bó ṣe yẹ kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́, kí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ síra wọn. Bákan náà, ó ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè tọ́ ọmọ yanjú kí wọ́n sì máa fìfẹ́ bá ara wọn gbé. Nípa bẹ́ẹ̀, ìjọsìn tòótọ́ ń mú kí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ àti láàárín ẹgbẹ́ ará kárí ayé. w17.11 21 ¶6-7
Monday, May 13
Èmi abòṣì ènìyàn!—Róòmù 7:24.
Bó ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù náà ló rí lára ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí. Torí pé gbogbo wa la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, ó máa ń ká wa lára gan-an tá a bá ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Jèhófà. Àwọn Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tiẹ̀ máa ń ronú pé Jèhófà ò lè dárí ji àwọn láéláé torí ohun táwọn ṣe. Bó ti wù kó rí, Ìwé Mímọ́ fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tá a bá sá di Jèhófà, a ò tún ní máa dá ara wa lẹ́bi mọ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti dárí jì wá. (Sm. 34:22) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ bó ṣe dun òun tó pé òun ò lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ délẹ̀délẹ̀, ó sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣì ń sapá láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, tó sì ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó dá sẹ́yìn, ó dá a lójú pé Ọlọ́run ti dárí ji òun lọ́lá ìràpadà Jésù. Torí pé Jésù ti rà wá pa dà, a ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ọkàn wa sì balẹ̀. (Héb. 9:13, 14) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé òun ni Àlùfáà Àgbà, “ó lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.”—Héb. 7:24, 25. w17.11 8 ¶1-2; 12 ¶15
Tuesday, May 14
Ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, kí ẹ sì san án fún Jèhófà Ọlọ́run yín.—Sm. 76:11.
Báwo la ṣe lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ? Onírúurú àdánwò là ń kojú, àwọn kan máa ń le àwọn míì kò sì fi bẹ́ẹ̀ le. Torí náà, ohun tá a bá ṣe lójú àdánwò ló máa fi hàn bóyá a fọwọ́ gidi mú ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Jèhófà pé ìfẹ́ rẹ̀ la ó máa ṣe lójoojúmọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Sm. 61:8) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan níbiṣẹ́ wa tàbí níléèwé wa ń bá wa tage, ṣé a máa yẹra fún onítọ̀hún, ká sì fi hàn pé lóòótọ́ la “ní ìdùnnú sí àwọn ọ̀nà” Jèhófà? (Òwe 23:26) Tó bá jẹ́ pé àwa nìkan ni Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé wa, ṣé a máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa hùwà tó yẹ Kristẹni kódà báwọn míì kò bá tiẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé a máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́, tá a sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìfẹ́ tó fi hàn sí wa àti bó ṣe mú wa wá sínú ètò rẹ̀? Ǹjẹ́ a máa ń wáyè ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ó ṣe tan, àwọn nǹkan yìí wà lára ohun tá a ṣèlérí fún Jèhófà nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Torí náà, ó yẹ ká mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. Tá a bá ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà, tá a sì ń ṣègbọràn sí i, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé lóòótọ́ la ya ara wa sí mímọ́ fún un. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé gbogbo apá ìgbésí ayé wa la ti ń fi hàn pé à ń jọ́sìn Jèhófà, kì í ṣe ìgbà tá a bá wà nípàdé tàbí òde ẹ̀rí nìkan. w17.10 23 ¶11-12
Wednesday, May 15
Ó dára láti máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run wa.—Sm. 147:1.
Gbajúmọ̀ olórin kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn ronú. Orin sì máa ń jẹ́ kéèyàn fi ìmọ̀lára hàn.” Àwọn orin wa máa ń jẹ́ ká yin Jèhófà Baba wa ọ̀run, ó sì máa ń jẹ́ ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé apá pàtàkì ni orin jẹ́ nínú ìjọsìn tòótọ́, yálà à ń dá kọrin tàbí à ń kọrin pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. Ṣé ó máa ń wù ẹ́ láti kọrin sókè nípàdé, àbí ojú máa ń tì ẹ́? Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn ọkùnrin kì í fẹ́ kọrin níṣojú àwọn míì. Irú èrò yìí lè ní ipa tí kò dáa lórí àwọn ará ìjọ, pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn tó ń múpò iwájú kì í kọrin tàbí tí wọ́n ń ṣe nǹkan míì nígbà táwọn ará ń kọrin lọ́wọ́. (Sm. 30:12) Tá a bá gbà lóòótọ́ pé apá pàtàkì lorin jẹ́ nínú ìjọsìn wa, àá sapá láti wà níbẹ̀ kí orin tó bẹ̀rẹ̀, a ò sì ní máa rìn lọ rìn bọ̀ tí orin bá ń lọ lọ́wọ́. w17.11 3 ¶1-3
Thursday, May 16
Ẹ má rò pé mo wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé; èmi kò wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀, bí kò ṣe idà.—Mát. 10:34.
Gbogbo wa la fẹ́ àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn. A sì dúpẹ́ pé Jèhófà ń fún wa lóhun tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run.” Àlàáfíà yìí ni kì í jẹ́ ká kọ́kàn sókè nígbà ìṣòro. (Fílí. 4:6, 7) Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a tún ń gbádùn “àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run,” ìyẹn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Róòmù 5:1) Àmọ́, kò tíì tó àsìkò tí Ọlọ́run máa mú kí àlàáfíà jọba níbi gbogbo láyé. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń kó wa lọ́kàn sókè láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn ń bá ara wọn jagun, wọn ò sì lẹ́mìí àlàáfíà. (2 Tím. 3:1-4) Yàtọ̀ síyẹn, àwa Kristẹni náà ń ja ogun tẹ̀mí, à ń bá Sátánì jagun, a sì ń túdìí àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké tó fi ń kọ́ni. (2 Kọ́r. 10:4, 5) Ṣùgbọ́n ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè jù, tó sì ń mú kó nira fún wa láti sin Jèhófà ni àtakò látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kò sí nínú òtítọ́. Àwọn kan lára wọn máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àwọn míì sì máa ń sọ pé à ń tú ìdílé ká, kódà wọ́n lè halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn á kọ̀ wá tá ò bá fi ẹ̀sìn wa sílẹ̀. w17.10 12 ¶1-2
Friday, May 17
Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.—Sm. 119:97.
Bí ìyípadà ṣe ń bá àwọn èdè yòókù náà ló ń bá àwọn èdè tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí. Bíbélì táwọn èèyàn ti ń kà ní àkàgbádùn lè wá dèyí tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lóye mọ́. Àpẹẹrẹ kan ni Bíbélì King James Version tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì nígbà àkọ́kọ́ lọ́dún 1611. Ó wà lára Bíbélì Gẹ̀ẹ́sì táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, kódà díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ti di ara èdè táwọn èèyàn ń lò lójoojúmọ́. Bó ti wù kó rí, èyí tó pọ̀ jù lára ọ̀rọ̀ tí Bíbélì King James Version lò ni kò bóde mu mọ́. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sáwọn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè míì nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa dúpẹ́ pé a ní Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí èdè rẹ̀ bóde mu? Bíbélì yìí ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó ju àádọ́jọ [150] lọ, èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa ka Bíbélì náà lédè wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn lóye tí wọ́n lò mú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọni lọ́kàn. w17.09 19 ¶5-6
Saturday, May 18
Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.—Òwe 27:11.
Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ń kojú tó máa gba pé kí wọ́n lo ìgboyà kí wọ́n sì fi hàn pé Jèhófà làwọn ń sìn. Wọ́n nílò ìgboyà kí wọ́n lè pinnu àwọn tí wọ́n máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́ àti irú eré ìnàjú tí wọ́n máa ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n nílò ìgboyà kí wọ́n má bàa lọ́wọ́ nínú ìwàkiwà, kí wọ́n sì pinnu ìgbà tí wọ́n máa ṣèrìbọmi. Kì í ṣe ohun tí Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run fẹ́ làwọn ọ̀dọ́ yìí ń ṣe, torí náà wọ́n nílò ìgboyà gan-an. Ó ṣe pàtàkì káwọn ọ̀dọ́ pinnu bí wọn ṣe máa lo ìgbésí ayé wọn. Láwọn ilẹ̀ kan, ṣe ni wọ́n máa ń fúngun mọ́ àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, kí wọ́n sì wá iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé. Láwọn ilẹ̀ míì, ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ ti mú káwọn ọ̀dọ́ máa ronú àtiforí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè pèsè jíjẹ mímu fún ìdílé wọn. Jèhófà máa bù kún àwọn ọ̀dọ́ tó bá ń fi Ìjọba Ọlọ́run síwájú nígbèésí ayé wọn, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nínú ètò rẹ̀. Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò. Àpẹẹrẹ gidi ni Tímótì tó gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní jẹ́ fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ tó bá di pé kẹ́ ẹ gbájú mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín.—Fílí. 2:19-22. w17.09 29-30 ¶10-12
Sunday, May 19
Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, . . . Kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.—Jóṣ. 1:8.
Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè mú kó o ní ìkóra-ẹni-níjàánu? Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń kó ara wa níjàánu àti ohun tó lè yọrí sí tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ó nídìí tí Jèhófà fi jẹ́ káwọn ìtàn yìí wà lákọọ́lẹ̀. (Róòmù 15:4) Ẹ ò rí i pé ó máa ṣe wá láǹfààní gan-an tá a bá ń kà wọ́n, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ wọn, tá a sì ń ṣàṣàrò nípa wọn! Máa ronú nípa ẹ̀kọ́ tí ìwọ àti ìdílé rẹ lè rí kọ́. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi ohun tó wà nínú Bíbélì sílò. Tó o bá rí i pé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti kó ara ẹ níjàánu láwọn apá ibì kan, gbà pé ibi tó o kù sí nìyẹn, kó o sì wá nǹkan ṣe nípa rẹ̀. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà, kó o sì sapá láti ṣàtúnṣe. (Ják. 1:5) Tó o bá ṣèwádìí nípa ohun tó o fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. w17.09 6 ¶15-16
Monday, May 20
Ẹ fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.—Kól. 3:10.
“Àkópọ̀ ìwà tuntun” ń tọ́ka sí àwọn ìwà tó bá “ìfẹ́ Ọlọ́run” mu. (Éfé. 4:24) Ó sì dájú pé àwa èèyàn lè ní àwọn ànímọ́ yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé, Jèhófà dá wa ní àwòrán rẹ̀, èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ. (Jẹ́n. 1:26, 27; Éfé. 5:1) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé ká gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, ó tẹnu mọ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ànímọ́ tó yẹ ká ní, ìyẹn ni pé ká má ṣe ojúsàájú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Kò sí Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, Síkítíánì, ẹrú tàbí òmìnira.’ Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ka ara wa sí pàtàkì ju àwọn míì lọ nínú ìjọ, bóyá torí ẹ̀yà wa, orílẹ̀-èdè wa tàbí ipò wa láwùjọ? Ìdí ni pé ‘ọ̀kan ṣoṣo ni gbogbo’ àwa ọmọlẹ́yìn Kristi. (Kól. 3:11; Gál. 3:28) Tá a bá gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, àá máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn láìka ipò wọn láwùjọ tàbí ibi tí wọ́n ti wá sí.—Róòmù 2:11. w17.08 22 ¶1; 23 ¶3-4
Tuesday, May 21
Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà.—Aísá. 30:18.
Tó bá di pé ká ní sùúrù, Jèhófà ò retí pé ká ṣe ohun tí òun alára ò ní ṣe. Òun ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká ní sùúrù. (2 Pét. 3:9) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni Jèhófà ti fi ń mú sùúrù kí ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì lè yanjú pátápátá. Ó ń mú sùúrù, ó sì ń dúró de ìgbà tó máa ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́. Ìbùkún ńlá lèyí máa jẹ́ fáwọn tó “ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.” (Aísá. 30:18) Jésù náà ń mú sùúrù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú nígbà tó wà láyé, tó sì gbé ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀ lọ sọ́run lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, síbẹ̀ ó ní láti dúró títí di ọdún 1914 kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. (Ìṣe 2:33-35; Héb. 10:12, 13) Bákan náà, ó dìgbà tí ìṣàkóso rẹ̀ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún bá parí kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó parun. (1 Kọ́r. 15:25) Àmọ́ ó dájú pé sùúrù tí Jésù ní tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. w17.08 7 ¶16-17
Wednesday, May 22
Ọlọ́run . . . ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.—2 Kọ́r. 1:3, 4.
Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Susi sọ pé: “Ọkàn wa ṣì máa ń gbọgbẹ́ kódà lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan tí ọmọkùnrin wa kú.” Arákùnrin míì tí ìyàwó rẹ̀ kú lójijì sọ pé “ikú ìyàwó mi dá nǹkan sí mi lára.” Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn nirú àdánù yìí ti ṣẹlẹ̀ sí. Ọ̀pọ̀ wa ló gbà pé àwa àtàwọn èèyàn wa jọ máa la Amágẹ́dọ́nì já, àá sì fẹsẹ̀ rìn wọnú ayé tuntun, a kì í ronú ẹ̀ pé ẹnikẹ́ni máa kú lára wa. Yálà a ti pàdánù èèyàn wa kan nínú ikú tàbí a mọ ẹnì kan tó ń ṣọ̀fọ̀, ó ṣeé ṣe ká máa ronú pé, ‘Báwo làwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣe lè rí ìtùnú?’ Bóyá o ti gbọ́ táwọn èèyàn máa ń sọ pé kò dé lara ò gbà, bópẹ́ bóyá, ọgbẹ́ ọkàn máa jinná. Àmọ́, ṣé lóòótọ́ ni pé èèyàn á gbàgbé ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ ẹ́ tí ìgbà bá ti kọjá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀? Obìnrin kan tó jẹ́ opó sọ pé, “Ohun tí mo gbà pé ó lè jẹ́ kí ọgbẹ́ ọkàn náà jinná ni ohun téèyàn bá fi àkókò náà ṣe.” Ọ̀rọ̀ náà wá dà bí ìgbà téèyàn ní egbò lára, téèyàn bá tọ́jú rẹ̀ dáadáa bópẹ́ bóyá ó máa jinná. w17.07 12-13 ¶1-3
Thursday, May 23
Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, Òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.—Sm. 37:4.
Ìpinnu wo ni Jèhófà fẹ́ kó o ṣe? Táwa èèyàn bá máa láyọ̀, a gbọ́dọ̀ mọ Jèhófà ká sì jọ́sìn rẹ̀ tọkàntọkàn. (Sm. 128:1; Mát. 5:3) Èyí mú ká yàtọ̀ sáwọn ẹranko torí pé wọn ò mọ̀ ju kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì bímọ. Àmọ́ Jèhófà ò fẹ́ ká gbé ìgbé ayé wa bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká ṣèpinnu táá mú ká láyọ̀, kí ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀. Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ “Ọlọ́run ìfẹ́” àti “Ọlọ́run aláyọ̀,” ìdí nìyẹn tó fi dá àwa èèyàn “ní àwòrán rẹ̀.” (2 Kọ́r. 13:11; 1 Tím. 1:11; Jẹ́n. 1:27) Wàá láyọ̀ tó o bá fara wé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Ṣé ìwọ náà gbà pé òótọ́ lohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ”? (Ìṣe 20:35) Òótọ́ pọ́ńbélé lèyí. Torí náà, Jèhófà fẹ́ kó o ṣe àwọn ìpinnu táá fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ òun àtàwọn míì.—Mát. 22:36-39. w17.07 23 ¶3
Friday, May 24
Jèhófà tìkára rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.—Sm. 84:11.
Ọlọ́run máa ń buyì kún àwa èèyàn tá à ń sìn ín, ó sì máa ń pọ́n wa lé. Ó ń bójú tó wa ju bá a ṣe lè bójú tó ara wa lọ. Kì í ṣe pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ nìkan, ó tún nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún ni Jèhófà fi yan àwọn onídàájọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fún wọn lágbára láti dá àwọn èèyàn náà nídè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan nira fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìgbà yẹn, síbẹ̀ Jèhófà kíyè sí Rúùtù ọmọ ilẹ̀ Móábù tó fi ẹbí àtọ̀rẹ́ sílẹ̀ kó lè di olùjọsìn Jèhófà. Jèhófà bù kún Rúùtù, ó rọ́kọ fẹ́, ó sì tún bí ọmọkùnrin kan. Kò tán síbẹ̀ o. Nígbà tí Rúùtù bá jíǹde, ó máa gbọ́ pé àtọmọdọ́mọ òun ló di Mèsáyà. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ti máa dùn tó nígbà tó bá wá mọ̀ pé ìtàn ìgbésí ayé òun wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì àti pé orúkọ òun ni ìwé náà ń jẹ́!—Rúùtù 4:13; Mát. 1:5, 16. w17.06 28-29 ¶8-9
Saturday, May 25
Ẹ̀mí mímọ́ . . . yóò . . . mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.—Jòh. 14:26.
Lọ́dún 1970, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Peter wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], kò sì pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Lọ́jọ́ kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé, ó pàdé aṣáájú ẹ̀sìn Júù kan. Peter béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà bóyá ó máa fẹ́ lóye Bíbélì. Ìbéèrè yìí ya ọkùnrin náà lẹ́nu, ó wá sọ pé ṣé o kò mọ̀ pé ilé àwọn rábì nìyí ni? Àmọ́ kó lè dán Peter wò, ó bi í pé: “Ọmọ dáadáa, èdè wo lo rò pé wọ́n fi kọ ìwé Dáníẹ́lì?” Peter sọ pé: “Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ apá kan nínú rẹ̀.” Peter wá sọ pé: “Ẹnu ya rábì náà gan-an pé mo mọ ìdáhùn, àmọ́ ẹnu kò yà á tó mi! Báwo ni mo ṣe mọ ìdáhùn ìbéèrè náà? Nígbà tí mo délé, mo lọ wo àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí mo ti kà láwọn oṣù mélòó kan sẹ́yìn, mo sì rí àpilẹ̀kọ kan tó sọ pé èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ ìwé Dáníẹ́lì.” (Dán. 2:4) Ó ṣe kedere pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè mú ká rántí àwọn ohun tá a ti kọ́ tẹ́lẹ̀.—Lúùkù 12:11, 12; 21:13-15. w17.06 13 ¶17
Sunday, May 26
Àwọn tí wọ́n [gbéyàwó] yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.—1 Kọ́r. 7:28.
Látìgbà tí ìyàwó kan bá ti sọ fún ọkọ rẹ̀ pé òun ti lóyún ni àwọn méjèèjì á ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn ayọ̀ lèyí, síbẹ̀ wọ́n lè máa ṣàníyàn nípa ìlera obìnrin náà nígbà tó wà nínú oyún àti lẹ́yìn tó bá bímọ. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí wọ́n ń náwó lé á máa pọ̀ sí i bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Wọ́n á tún ṣe ọ̀pọ̀ àyípadà lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ. Bí àpẹẹrẹ, bí ìyá náà ṣe máa tọ́jú ọmọ rẹ̀ ló máa gbà á lọ́kàn, ó sì lè má fi bẹ́ẹ̀ rí tọkọ rẹ̀ rò mọ́. Èyí lè mú káwọn ọkọ kan máa ronú pé ìyàwó àwọn ti pa àwọn tì. Yàtọ̀ síyẹn, bùkátà ọkùnrin náà tún ti pọ̀ sí i. Ní báyìí tọ́mọ ti wà láàárín wọn, ó gbọ́dọ̀ wá bó ṣe máa tọ́jú rẹ̀, kó sì pèsè fún un. Ìṣòro kan tún wà táwọn tọkọtaya míì máa ń ní. Wọ́n lè máa wá ọmọ lójú méjèèjì, síbẹ̀ kí wọ́n má rọ́mọ bí. Tí obìnrin kan ò bá rọ́mọ bí, ó lè ní ẹ̀dùn ọkàn. w17.06 4 ¶1; 5 ¶5-6
Monday, May 27
Àwọn àsọjáde rẹ mà dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in mọ́ òkè ẹnu mi o, ó dùn ju oyin lọ lẹ́nu mi!—Sm. 119:103.
Àwa Kristẹni nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a sì ń jẹ́ kó darí wa. Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la sì ti lè rí òtítọ́. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, ó sọ fún Baba rẹ̀ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17) Torí náà, ká tó lè nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó péye nínú Bíbélì. (Kól. 1:10) Àmọ́, èyí kọjá kéèyàn kàn kó ìmọ̀ sórí. Ẹni tó kọ Sáàmù 119 sọ ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́. (Sm. 119:97-100) Ṣé a máa ń wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé a sì máa ń ṣàṣàrò lé e lójoojúmọ́? Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, tá a sì ń rí bó ṣe ń ṣe wá láǹfààní, àá túbọ̀ mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́. Àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run ń pèsè fún wa dà bí oúnjẹ aládùn. Tá a bá gbádùn oúnjẹ kan, a máa ń fara balẹ̀ jẹ ẹ́. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa gbádùn “àwọn ọ̀rọ̀ dídùn” tó wà nínú rẹ̀, àá sì lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́.—Oníw. 12:10. w17.05 19-20 ¶11-12
Tuesday, May 28
Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.—1 Kọ́r. 14:25.
Bíi ti ará Samáríà inú àpèjúwe Jésù, àwa náà fẹ́ ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́ títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Lúùkù 10:33-37) Ọ̀nà tó dáa jù tá a sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká sọ ìhìn rere fún wọn. Alàgbà kan tó ti ran ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ibi ìsádi lọ́wọ́ sọ pé: “Gbàrà tá a bá ti débẹ̀ ló yẹ ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àti pé ìhìn rere la wá sọ fún wọn, kì í ṣe owó tàbí àwọn nǹkan míì la mú wá. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n lè gbà wá láyè nítorí nǹkan tí wọ́n máa rí gbà lọ́wọ́ wa.” Ìfẹ́ táwa Kristẹni ń fi hàn sáwọn àjèjì máa ń sèso rere. (Sm. 146:9) Arábìnrin kan sọ pé ìdílé òun sá kúrò ní orílẹ̀-èdè Eritrea torí inúnibíni. Lẹ́yìn tí mẹ́rin lára àwọn ọmọ rẹ̀ rìnrìn àrìnwọ́dìí gba inú aṣálẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́jọ, wọ́n dé orílẹ̀-èdè Sudan. Arábìnrin náà sọ pé: “Ṣe làwọn ará gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ àfi bí ọmọ ìyá, wọ́n fún wọn lóúnjẹ àti aṣọ, kódà wọ́n pèsè ibi tí wọ́n máa gbé, wọ́n sì máa ń fún wọn lówó tí wọ́n lè fi wọkọ̀.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn wo ló lè gba ẹni tí wọn ò mọ̀ rí sílé torí pé wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni!”—Jòh. 13:35. w17.05 7 ¶17, 19-20
Wednesday, May 29
Ẹ kò sọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa mi, bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ti ṣe.—Jóòbù 42:8.
Élífásì béèrè pé: “Abarapá ọkùnrin ha lè wúlò fún Ọlọ́run, pé ẹni tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò wúlò fún un? Olódùmarè ha ní inú dídùn rárá sí jíjẹ́ tí o jẹ́ olódodo, tàbí èrè èyíkéyìí nínú ṣíṣe tí o ṣe ọ̀nà rẹ ní aláìlẹ́bi?” (Jóòbù 22:1-3) Ǹjẹ́ irú àwọn ìbéèrè yìí ti wá sí ẹ lọ́kàn rí? Nígbà tí Élífásì ará Témánì bi Jóòbù láwọn ìbéèrè yẹn, Élífásì gbà pé bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn wọn. Kódà, ẹnì kejì rẹ̀ tó ń jẹ́ Bílídádì ọmọ Ṣúáhì sọ pé kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run. (Jóòbù 25:4) Àwọn olùtùnú èké yẹn sọ pé bí àwa èèyàn ṣe ń fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà kò nítumọ̀ sí i, àti pé lójú Ọlọ́run, a ò sàn ju òólá, ìdin tàbí kòkòrò mùkúlú. (Jóòbù 4:19; 25:6) Jèhófà jẹ́ ká mọ ojú tóun fi ń wò wá nígbà tó bá Élífásì, Bílídádì àti Sófárì wí. Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé wọn ò sòótọ́ nípa òun, ó sì gbóríyìn fún Jóòbù, kódà ó pè é ní “ìránṣẹ́ mi.” (Jóòbù 42:7) Èyí fi hàn pé àwa èèyàn “wúlò fún Ọlọ́run.” w17.04 28 ¶1-2
Thursday, May 30
Wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.—Sm. 37:11.
Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń gbé inú ayé yìí débi pé a lè má fi taratara kíyè sí báwọn nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń gbé nítòsí títì tàbí ojú irin kì í mọ ariwo ọkọ̀ lára mọ́. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó ń gbé nítòsí ààtàn kì í gbóòórùn ìdọ̀tí mọ́. Àmọ́ tí gbogbo nǹkan yẹn kò bá sí mọ́, pẹ̀sẹ̀ lara máa tù wá! Kí ló máa rọ́pò gbogbo nǹkan tó ń kó wa lọ́kàn sókè? Ṣàkíyèsí ìlérí tó wà nínú ẹsẹ ojoojúmọ́ wa tòní. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí kò múnú rẹ dùn? Ohun tí Jèhófà fẹ́ fún ẹ náà nìyẹn. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe, kó o túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run àti ètò rẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko yìí! Máa ṣìkẹ́ ìrètí tó o ní, jẹ́ kó máa wà lọ́kàn rẹ nígbà gbogbo, kó o sì máa sọ ọ́ fáwọn míì! (1 Tím. 4:15, 16; 1 Pét. 3:15) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á dá ẹ lójú pé o ò ní bá ayé búburú yìí lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wàá wà láyé, wàá wà láàyè, wàá sì máa láyọ̀ títí láé fáàbàdà! w17.04 13 ¶16-17
Friday, May 31
Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.—Ják. 3:2.
A lè gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ nígbà tí àìpé bá mú kí arákùnrin kan ṣẹ̀ wá, ó lè ṣòro fún wa láti gbójú fò ó. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé àwa náà á fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé alàgbà kan sọ ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó nípa rẹ tàbí ibi tó o ti wá, kí lo máa ṣe? Tí alàgbà kan bá sọ̀rọ̀ láìro bó ṣe máa rí lára rẹ, tọ́rọ̀ náà sì dùn ẹ́ gan-an, ṣé wàá jẹ́ kíyẹn mú ẹ kọsẹ̀? Dípò tí wàá fi máa ronú pé irú arákùnrin bẹ́ẹ̀ ò yẹ ní alàgbà mọ́, ṣé wàá ní sùúrù kí Jésù tó jẹ́ orí ìjọ dá sọ́rọ̀ náà? Ṣé wàá gbójú fo àìdáa tó ṣe, kó o sì ronú nípa ọ̀pọ̀ ọdún tí arákùnrin náà ti ń sin Jèhófà bọ̀? Tí arákùnrin náà bá ṣì jẹ́ alàgbà, tó tún wá gba àwọn àfikún iṣẹ́ ìsìn míì, ṣé wàá bá a yọ̀? Tó o bá dárí ji ẹni náà, ìyẹn á fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan nìwọ náà fi ń wò ó.—Mát. 6:14, 15. w17.04 27 ¶18