ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es19 ojú ìwé 57-67
  • June

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • June
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Saturday, June 1
  • Sunday, June 2
  • Monday, June 3
  • Tuesday, June 4
  • Wednesday, June 5
  • Thursday, June 6
  • Friday, June 7
  • Saturday, June 8
  • Sunday, June 9
  • Monday, June 10
  • Tuesday, June 11
  • Wednesday, June 12
  • Thursday, June 13
  • Friday, June 14
  • Saturday, June 15
  • Sunday, June 16
  • Monday, June 17
  • Tuesday, June 18
  • Wednesday, June 19
  • Thursday, June 20
  • Friday, June 21
  • Saturday, June 22
  • Sunday, June 23
  • Monday, June 24
  • Tuesday, June 25
  • Wednesday, June 26
  • Thursday, June 27
  • Friday, June 28
  • Saturday, June 29
  • Sunday, June 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
es19 ojú ìwé 57-67

June

Saturday, June 1

Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.​—1 Jòh. 4:16.

Jèhófà máa ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì máa ń kọ́ wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ó fẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ òun, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìyè àìnípẹ̀kun. Nígbà míì, ìbáwí lè gba pé kí wọ́n ká ẹnì kan lọ́wọ́ kò. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè pàdánù àwọn àǹfààní kan nínú ìjọ. Kódà tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, irú ìbáwí yẹn ṣì fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá pàdánù àwọn àǹfààní tó ní nínú ìjọ, ìyẹn á jẹ́ kó rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, kó máa ṣàṣàrò, kó sì máa gbàdúrà. Nípa bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Sm. 19:7) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó lè pa dà wá ní àwọn àǹfààní míì nínú ìjọ. Kódà tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ìyẹn náà fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa torí pé ìwà burúkú yẹn ò ní ran àwọn míì nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:​6, 7, 11) Bákan náà, torí pé Jèhófà máa ń báni wí dé ìwọ̀n tó tọ́, ìyẹn á jẹ́ kẹ́ni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ mọ̀ pé ohun tóun ṣe burú gan-an, ó sì lè mú kó ronú pìwà dà.​—Ìṣe 3:19. w18.03 24 ¶5-6

Sunday, June 2

Òun àti àwọn tirẹ̀ ni a sì batisí láìjáfara.​—Ìṣe 16:33.

Ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ò mọ nǹkan kan nípa Ìwé Mímọ́. Torí náà, kó tó lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú Ìwé Mímọ́, kó mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe, kó sì pinnu pé òun á máa pa àwọn àṣẹ Jésù mọ́. Láàárín àsìkò díẹ̀, ó mọyì ohun tó kọ́, ìyẹn ló sì jẹ́ kó ṣèrìbọmi láìjáfara. (Ìṣe 16:​25-33) Ó dájú pé lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Torí náà, tí ọmọ rẹ bá ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì, tó mọyì ohun tó kọ́, tó sì ṣe kedere pé ó ti mọ ohun tí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi túmọ̀ sí, kí lo máa ṣe? O lè sọ fún un pé kó lọ rí àwọn alàgbà kí wọ́n lè gbé e yẹ̀ wò bóyá ó tóótun láti ṣèrìbọmi. Bíi tàwa yòókù, òun náà á ṣì máa gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, kódà títí láé láá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.​—⁠Róòmù 11:​33, 34. w18.03 10 ¶8-9

Monday, June 3

[Ẹ] ní . . . láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.​—Róòmù 15:5.

Bá a ṣe ń sapá láti dẹni tẹ̀mí, ẹ̀mí mímọ́ máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè yí èrò inú wa pa dà. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi ti Kristi. Yàtọ̀ síyẹn, á tún ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ká sì ní àwọn ànímọ́ táá múnú Ọlọ́run dùn. Tá a bá ní èrò inú Kristi, ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ wa, ìṣe wa níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé, àti nínú àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lójoojúmọ́. Àwọn ìpinnu tá à ń ṣe máa fi hàn bóyá à ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Tá a bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Tá a bá ń hùwà bíi Kristi, a máa borí ìdẹwò èyíkéyìí tó bá yọjú. Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, á dáa ká bi ara wa pé: ‘Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu? Ká ní Jésù ló fẹ́ ṣe ìpinnu tí mo fẹ́ ṣe yìí, kí ló máa ṣe? Tí mo bá ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí, ṣé inú Jèhófà máa dùn sí mi?’ w18.02 25 ¶12; 26 ¶14

Tuesday, June 4

Nóà rí ojú rere ní ojú Jèhófà.​—Jẹ́n. 6:8.

Nígbà ayé Énọ́kù baba ńlá Nóà, ìwà àwọn èèyàn ti burú kọjá àfẹnusọ. Kódà, wọ́n ń sọ àwọn “ohun amúnigbọ̀nrìrì” lòdì sí Jèhófà. (Júúdà 14, 15) Ojoojúmọ́ ni ìwà ipá wọn ń peléke sí i. Kódà nígbà tó máa fi di ìgbà ayé Nóà, ‘ilẹ̀ ayé ti kún fún ìwà ipá.’ Àwọn áńgẹ́lì búburú kan para dà di èèyàn, wọ́n fẹ́ ìyàwó, wọ́n sì bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tó jẹ́ oníwà ipá. (Jẹ́n. 6:​2-4, 11, 12) Àmọ́ Nóà yàtọ̀ sí wọn ní tiẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́n. 6:9) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tíyẹn túmọ̀ sí. Kì í wulẹ̀ ṣe àádọ́rin [70] ọdún tàbí ọgọ́rin [80] ọdún tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò láyé lónìí ni Nóà fi bá Ọlọ́run rìn nínú ayé burúkú yẹn, odindi ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ọdún ló fi bá Ọlọ́run rìn kí Ìkún Omi náà tó dé! (Jẹ́n. 7:11) Bákan náà, Nóà ò nírú àǹfààní táwa ní lónìí, a láwọn tá a jọ ń sin Jèhófà tá a sì jọ ń gbé ara wa ró, àmọ́ Nóà ò ní irú ẹ̀ kódà àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀ kò sin Jèhófà. w18.02 4 ¶4-5

Wednesday, June 5

Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . olùfẹ́ owó.​—2 Tím. 3:2.

Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó kì í ní ìtẹ́lọ́rùn, bí wọ́n ṣe máa ní owó púpọ̀ sí i ni wọ́n ń lépa, èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora.” (1 Tím. 6:​9, 10; Oníw. 5:10) Gbogbo wa la nílò owó, torí pé ó máa ń dáàbò boni déwọ̀n àyè kan. (Oníw. 7:12) Àmọ́ ṣé èèyàn á láyọ̀ lóòótọ́ tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba owó táá fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ nìkan ló ní? Bẹ́ẹ̀ ni! (Oníw. 5:12) Ágúrì ọmọkùnrin Jákè sọ pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀. Jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀n oúnjẹ tí ó jẹ́ ìpín tèmi.” A lóye ìdí tó fi bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kóun tòṣì. Ó sọ síwájú sí i pé òun ò fẹ́ jalè torí pé ìyẹn máa tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́ kí nìdí tó fi gbàdúrà pé kí Ọlọ́run má ṣe fún òun ní ọrọ̀? Ó ní: “Kí n má bàa yó tán kí n sì sẹ́ ọ ní ti tòótọ́, kí n sì wí pé: ‘Ta ni Jèhófà?’ ” (Òwe 30:​8, 9) Jésù sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.”​—Mát. 6:24. w18.01 24 ¶9-11

Thursday, June 6

Ọ̀nà kan náà ni Baba mi ọ̀run yóò gbà bá yín lò pẹ̀lú bí olúkúlùkù yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà yín wá.​—Mát. 18:35.

Ọ̀nà tá a lè gbà mú kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa dárí ji ara wa ní fàlàlà. Tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, ṣe là ń fi hàn pé a mọrírì bí Jèhófà ṣe ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiwa náà jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi. Ṣó o rántí ìtàn tí Jésù sọ nípa ọba kan àtàwọn ẹrú rẹ̀ nínú Mátíù 18:​23-34? Pẹ̀lú ìtàn yẹn lọ́kàn rẹ, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń fi ohun tí Jésù kọ́ wa sílò? Ǹjẹ́ mo máa ń fi sùúrù bá àwọn ará lò, ṣé mo sì máa ń gba tiwọn rò? Ṣé mo ṣe tán láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ mí?’ Lóòótọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó lè nira gan-an fún àwa èèyàn láti dárí rẹ̀ jini. Síbẹ̀, àpèjúwe yẹn sọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe. Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ò ní dárí jì wá tá ò bá dárí ji àwọn ará wa nígbà tó bá yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn gbàrònú! Tá a bá ń dárí ji àwọn ẹlòmíì bí Jésù ṣe kọ́ wa, àá mú kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa túbọ̀ lágbára, ohunkóhun ò sì ní da àárín wa rú. w18.01 15 ¶12

Friday, June 7

Ẹnì yòówù tí ó bá ṣe ìtọrọ lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe lọ́wọ́ rẹ, ọba, ni kí a sọ sínú ihò kìnnìún.​—Dán. 6:7.

Bí Dáníẹ́lì tiẹ̀ mọ̀ pé ẹ̀mí òun wà nínú ewu, ó pinnu pé òun á ṣì máa gbàdúrà bí òun ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ kí wọ́n má bàa rò pé òun ò sin Jèhófà mọ́. Dáníẹ́lì lo ìgboyà ó sì jẹ́ adúróṣinṣin, torí náà Jèhófà san án lẹ́san nígbà tó gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú oró. Kódà, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ káwọn èèyàn ní gbogbo Ilẹ̀ Ọba Mídíà àti Páṣíà mọ̀ pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́. (Dán. 6:​25-27) Báwo la ṣe lè nígbàgbọ́ bíi ti Dáníẹ́lì? Tá a bá fẹ́ nígbàgbọ́ tó lágbára, kì í ṣe pé ká kàn máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ni, ó yẹ kí òye ohun tá à ń kà yé wa. (Mát. 13:23) A fẹ́ mọ èrò Jèhófà nípa ohun tá a fẹ́ ṣe, ìyẹn sì gba pé ká lóye àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ dáadáa. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tá à ń kà. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà àtọkànwá nígbà gbogbo pàápàá tá a bá níṣòro tàbí tá a kojú àdánwò. Tá a bá bẹ Jèhófà pé kó fún wa lọ́gbọ́n àti agbára láti kojú àwọn ìṣòro náà, tá a sì nígbàgbọ́, ó dájú pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà wa.​—Ják. 1:5. w18.02 10-11 ¶13-15

Saturday, June 8

Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.​—Sm. 34:8.

Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó ti ṣèrìbọmi, wàá ríi pé ẹni rere ni Jèhófà tó o bá ń kíyè sí bó ṣe ń fún ẹ nígboyà láti wàásù fáwọn èèyàn yálà lóde ẹ̀rí tàbí nílé ìwé. Àwọn ọ̀dọ́ kan kì í lè wàásù fáwọn ojúgbà wọn níléèwé. Bóyá irú ẹ̀ ti ṣe ìwọ náà rí. O ò mọ irú ojú táwọn ọmọ iléèwé rẹ máa fi wo ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ bá wọn sọ. Ká sòótọ́, kéèyàn wàásù fún ọmọ iléèwé kan ṣoṣo rọrùn ju kéèyàn wàásù fún àgbájọ àwọn ọmọ iléèwé. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Lákọ̀ọ́kọ́, ronú nípa ìdí tó o fi gbà pé òótọ́ lohun tó o gbà gbọ́. Ṣó o ti lo àrànṣe tá a pè ní Atọ́nà Ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lórí ìkànnì jw.org/⁠yo? Tó ò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, gbìyànjú rẹ̀ wò. A dìídì ṣe é kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni, á jẹ́ kó o ronú lórí ohun tó o gbà gbọ́, ìdí tó o fi gbà á gbọ́ àti bó o ṣe lè ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ fáwọn míì. Tí ohun tó o gbà gbọ́ bá dá ẹ lójú, tó o sì múra sílẹ̀ dáadáa, á yá ẹ lára láti sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn.​—Jer. 20:​8, 9. w17.12 26 ¶12, 14-15

Sunday, June 9

Máa báa lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́.​—2 Tím. 3:14.

Tẹ́ ẹ bá máa gbin òtítọ́ sọ́kàn wọn, ohun tẹ́ ẹ máa kọ́ wọn kọjá ìtàn nípa àwọn èèyàn àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Pọ́ọ̀lù sọ pé a yí Tímótì “lérò padà láti gbà gbọ́.” Èdè Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò fún gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí pé “kí ohun kan dáni lójú kéèyàn sì gbà gbọ́ pé òótọ́ ni.” Àtikékeré ni Tímótì ti mọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó rí àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó dá a lójú pé Jésù ni Mèsáyà. Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì dẹni tá a yí lérò pa dà, bíi ti Tímótì? Lákọ̀ọ́kọ́, o gbọ́dọ̀ mú sùúrù. Èèyàn ò lè di Kristẹni ní ọ̀sán kan òru kan, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́ kì í ṣe ogún ìdílé tó o lè fún àwọn ọmọ rẹ. Ọmọ kọ̀ọ̀kan ló máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ̀ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè dá a lójú kó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (Róòmù 12:1) Bó ti wù kó rí, iṣẹ́ ńlá lẹ̀yin òbí máa ṣe kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, pàápàá nígbà táwọn ọmọ yín bá ń bi yín láwọn ìbéèrè. w17.12 19 ¶3, 5-6

Monday, June 10

Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.​—Jòh. 11:24.

Màtá tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀. Ìdí sì ni pé Lásárù àbúrò rẹ̀ ti kú. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tó lè tù ú nínú? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé Jésù fi dá a lójú pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” (Jòh. 11:​20-23) Ó dá Màtá lójú pé àjíǹde máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. Jésù wá ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó jí Lásárù dìde lọ́jọ́ yẹn gan-an. A ò lè retí pé kí Jésù tàbí Jèhófà Baba rẹ̀ ṣe irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ fún wa lónìí. Àmọ́, ǹjẹ́ ó dá ẹ lójú bíi ti Màtá pé èèyàn rẹ tó kú máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú? Bóyá ọkọ tàbí aya rẹ ló kú, ó sì lè jẹ́ bàbá rẹ, ìyá rẹ tàbí àwọn òbí rẹ àgbà. Bóyá ọmọ rẹ ni kò sì sí mọ́. Ó ń ṣe ẹ́ bíi pé kọ́jọ́ náà ti dé kẹ́ ẹ lè dì mọ́ra, kẹ́ ẹ bá ara yín sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ sì jọ máa rẹ́rìn-ín. Bíi ti Màtá, ìwọ náà lè fi ìdánilójú sọ pé: ‘Mo mọ̀ pé èèyàn mi tó kú máa jíǹde nígbà àjíǹde.’ Síbẹ̀, á dáa kí olúkúlùkù wa ronú lórí ìdí tí òun fi gbà pé lóòótọ́ ni àjíǹde máa wáyé. w17.12 3 ¶1-2

Tuesday, June 11

Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.​—Sm. 40:8.

Jésù nífẹ̀ẹ́ Òfin Mósè gan-an. Kò sì yani lẹ́nu torí pé Jèhófà ló ṣòfin náà, Òun sì lẹni tó ṣe pàtàkì jù sí Jésù láyé àti lọ́run. Jésù nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run gan-an bá a ṣe rí i nínú ẹ̀kọ́ ojúmọ́ tòní. Jésù fi hàn lọ́rọ̀ àti níṣe pé Òfin Ọlọ́run jẹ́ pípé, ó ṣàǹfààní, gbogbo ohun tó wà nínú òfin náà ló sì máa ṣẹ. (Mát. 5:​17-19) Ẹ wo bó ṣe máa dun Jésù tó nígbà tó rí báwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ṣe ń lọ́ Òfin Bàbá rẹ̀ lọ́rùn! Wọ́n ń pa àwọn òfin kéékèèké mọ́ dórí bíńtín, ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá efinrin àti ewéko dílì àti ewéko kúmínì.” Kí wá nìṣòro wọn? Jésù sọ pé: “Ṣùgbọ́n ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.” (Mát. 23:23) Ó ṣe kedere pé arinkinkin mọ́ òfin làwọn Farisí. Àmọ́ Jésù ní tiẹ̀ lóye àwọn ìlànà tó wà nínú Òfin, ó sì mọ bí òfin kọ̀ọ̀kan ṣe gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ. w17.11 13 ¶1-2

Wednesday, June 12

Èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, sísọ yín di mímọ́, pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè.​—1 Tẹs. 4:3.

Àwọn èèyàn lè sọ fún wa pé: “Jayé orí ẹ kí wọ́n má bàa jẹ ọ́ máyé. Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni.” Kò yẹ kí Kristẹni kan gba èrò yìí gbọ́. Ìdí sì ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dẹ́bi fún ìṣekúṣe. (1 Tẹs. 4:​4-8) Torí pé Jèhófà ló dá wa, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa lófin. Òfin Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tọkọtaya nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ní ìbálòpọ̀. Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn òfin, tá a bá sì pa wọ́n mọ́, á ṣe wá láǹfààní. Àwọn tọkọtaya àtàwọn ọmọ tó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ máa ń láyọ̀, wọn kì í fura sí ara wọn, wọ́n máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò ní fojúure wo ẹnikẹ́ni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀. (Héb. 13:⁠4) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe tá ò fi ní lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Ohun pàtàkì kan ni pé ká ṣọ́ ohun tá à ń wò. (Mát. 5:​28, 29) Torí náà, kò yẹ kí Kristẹni máa wo àwòrán oníhòòhò, kò sì yẹ kó máa gbọ́ àwọn orin tó kún fún ọ̀rọ̀ rírùn.​—Éfé. 5:​3-5. w17.11 22 ¶9-10

Thursday, June 13

Ó dára láti máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run wa.​—Sm. 147:1.

Ọjọ́ pẹ́ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti máa ń fi orin yin Jèhófà. Lásìkò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, apá pàtàkì ni orin kíkọ jẹ́ nínú ìjọsìn wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Dáfídì ń ṣètò àwọn táá máa sìn ní tẹ́ńpìlì, ó ṣètò pé kí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] àwọn ọmọ Léfì máa kọrin ìyìn. Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín méjìlá [288] lára wọn ló jẹ́ àwọn “tí a kọ́ ní iṣẹ́ orin kíkọ sí Jèhófà,” gbogbo wọn sì ni akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. (1 Kíró. 23:5; 25:7) Lásìkò tí wọ́n ń ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́, orin kíkọ kó ipa pàtàkì. Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn afunkàkàkí àti àwọn akọrin ṣe ọ̀kan ní mímú kí a gbọ́ ìró kan ní yíyin Jèhófà àti dídúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, gbàrà tí wọ́n sì mú ìró náà dún sókè pẹ̀lú kàkàkí àti pẹ̀lú aro àti pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin ní yíyin Jèhófà, . . . ògo Jèhófà kún ilé Ọlọ́run tòótọ́.” Ẹ ò rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn máa mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára!​—⁠2 Kíró. 5:​13, 14; 7:6. w17.11 4 ¶4-5

Friday, June 14

Ẹ má rò pé mo wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé; èmi kò wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀, bí kò ṣe idà.​—Mát. 10:34.

Jésù mọ̀ pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa fa ìpínyà láàárín àwọn èèyàn, àti pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa nílò ìgboyà nígbà táwọn èèyàn bá ta kò wọ́n. Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Jésù fi ń kọ́ni, kì í ṣe pé ó fẹ́ kí àárín àwọn èèyàn dàrú. (Jòh. 18:37) Bó ti wù kó rí, ó lè nira fún ẹnì kan láti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù táwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Torí pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi fẹ́ ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, wọ́n fara da ọ̀pọ̀ nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, kódà wọ́n tiẹ̀ kẹ̀yìn sáwọn míì nínú wọn. Síbẹ̀, ohun tí wọ́n rí gbà ti ju ohun tí wọ́n pàdánù lọ fíìfíì. (Máàkù 10:​29, 30) Táwọn mọ̀lẹ́bí wa bá ta kò wá torí pé à ń jọ́sìn Jèhófà, a kì í foró yaró, kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ rántí pé ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti Kristi ló gbọ́dọ̀ ṣáájú. (Mát. 10:37) Ó tún yẹ ká ṣọ́ra kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn mọ̀lẹ́bí wa má lọ mú ká ṣe ohun tí Jèhófà kò fẹ́, torí pé ohun tí Sátánì fẹ́ gan-an nìyẹn. w17.10 13 ¶3-6

Saturday, June 15

Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ju [Ìwà Burúkú] padà sáàárín òṣùwọ̀n eéfà náà, lẹ́yìn èyí, ó fi òjé títẹ̀wọ̀n náà dé ẹnu rẹ̀.​—Sek. 5:8.

Ìran yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà kò ní fàyè gba ìwà burúkú èyíkéyìí láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Kò ní jẹ́ kẹ́ni burúkú kó èèràn ran àwọn míì, kíá ló sì máa mú ìwà burúkú kúrò. (1 Kọ́r. 5:13) Bí áńgẹ́lì yẹn ṣe dé obìnrin náà mọ́nú apẹ̀rẹ̀ yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fàyè gba ìwà burúkú. Ẹ wo bí ìran yẹn ṣe máa múnú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbáyé nígbà ayé Sekaráyà dùn tó! Jèhófà mú kó dá wọn lójú pé kò sí ohunkóhun tó máa ba ìjọsìn mímọ́ òun jẹ́! Bó ti wù kó rí, ìran yẹn náà tún jẹ́ káwọn Júù mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ohunkóhun kò ba ìjọsìn mímọ́ wọn jẹ́. Ìwà burúkú èyíkéyìí kò gbọ́dọ̀ wáyé láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run, tó bá sì wáyé, wọn ò gbọ́dọ̀ fàyè gbà á. Ní báyìí táwa náà wà nínú ètò Jèhófà, tá a sì ń gbádùn ààbò àti ìfẹ́ rẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ẹ̀gbin èyíkéyìí nínú ètò náà. Ṣé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí ilé Jèhófà wà ní mímọ́? Kò sáyè fún ìwà burúkú èyíkéyìí nínú Párádísè tẹ̀mí tá a wà yìí. w17.10 24 ¶14-15; 25 ¶17-18

Sunday, June 16

Òfin rẹ ni mo nífẹ̀ẹ́.​—Sm. 119:163.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló kọ ìwé mọ́kàndínlógójì [39] àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ìkáwọ́ wọn ni Ọlọ́run kọ́kọ́ “fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run sí.” (Róòmù 3:​1, 2) Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni kò fi bẹ́ẹ̀ lóye èdè Hébérù mọ́. Ohun tó sì fà á ni pé bí Alẹkisáńdà Ńlá tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Gíríìsì ṣe ń ṣẹ́gun àwọn ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ ọba rẹ̀ ń gbòòrò sí i. (Dán. 8:​5-7, 20, 21) Torí pé Gíríìkì ni èdè wọn, èdè yẹn lọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lábẹ́ àkóso wọn ń sọ, títí kan àwọn Júù. Bí èdè Gíríìkì ṣe túbọ̀ ń yọ̀ mọ́ àwọn Júù lẹ́nu, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń ṣòro fún wọn láti lóye Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Kí wá ni Jèhófà ṣe káwọn èèyàn lè lóye ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ní nǹkan bí ọdún 250 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n túmọ̀ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì. Nígbà tó yá, wọ́n túmọ̀ àwọn ìwé tó kù nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì. Torí náà, èdè Gíríìkì ni wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ àpapọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí. Àpapọ̀ àwọn ìwé yìí la wá mọ̀ sí Bíbélì Septuagint. w17.09 20 ¶7-9

Monday, June 17

Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.​—Héb. 13:5.

Ọ̀gá yín níbi iṣẹ́ lè ní kẹ́ ẹ máa fi ojoojúmọ́ ṣe àṣekún iṣẹ́, títí kan òpin ọ̀sẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìyẹn sì máa dí ìjọsìn ìdílé yín lọ́wọ́, títí kan òde ẹ̀rí àti ìpàdé. Ó gba ìgboyà kẹ́ ẹ tó lè sọ fún ọ̀gá yín pé ẹ ò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀. Tẹ́ ẹ bá dúró lórí ìpinnu yín, àpẹẹrẹ tó dáa lẹ̀ ń fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ yín. Ó tún gba ìgboyà ká tó lè ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run síwájú láyé wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí kan kì í gba àwọn ọmọ wọn níyànjú pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kí wọ́n lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, kí wọ́n lọ sí Bẹ́tẹ́lì tàbí kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́ ibi ìjọsìn wa. Àwọn òbí bẹ́ẹ̀ máa ń bẹ̀rù pé àwọn ọmọ àwọn kò ní lè tọ́jú àwọn lọ́jọ́ ogbó. Àmọ́ àwọn òbí tó gbọ́n máa ń lo ìgboyà, wọ́n sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa bójú tó àwọn. (Sm. 37:25) Tẹ́ ẹ bá nígboyà, tẹ́ ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwọn ọmọ yín náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.​—1 Sám. 1:​27, 28; 2 Tím. 3:​14, 15. w17.09 30 ¶14-15

Tuesday, June 18

Èso ti ẹ̀mí ni . . . ìkóra-ẹni-níjàánu.​—Gál. 5:​22, 23.

Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ káwọn náà lè ní ìkóra-ẹni-níjàánu? Àwọn òbí mọ̀ pé a kì í bí ànímọ́ rere mọ́ni, èèyàn máa kọ́ ọ ni. Torí náà, ó yẹ káwọn òbí fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. (Éfé. 6:4) Tẹ́ ẹ bá kíyè sí pé kò rọrùn fáwọn ọmọ yín láti kó ara wọn níjàánu, ẹ wò ó bóyá ẹ̀ ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. Lára ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ni pé kẹ́ ẹ máa lọ sóde ẹ̀rí déédéé, kẹ́ ẹ máa lọ sípàdé déédéé, kẹ́ ẹ sì máa ṣe ìjọsìn ìdílé yín déédéé. Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n fẹ́ lẹ máa fún wọn. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà fún Ádámù àti Éfà náà lófin, òfin yìí ló sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ kọjá àyè ara wọn, àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà. Bó ṣe rí nínú ìdílé náà nìyẹn, tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín, tẹ́ ẹ sì ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, àwọn ọmọ yín á lè máa kó ara wọn níjàánu. Lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kẹ́ ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò.​—Òwe 1:​5, 7, 8. w17.09 7 ¶17

Wednesday, June 19

Kí ó má bàa sí ìpínyà kankan nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ lè ní aájò kan náà fún ara wọn.​—1 Kọ́r. 12:25.

Níwọ̀n ìgbà tá a ṣì wà nínú ayé Sátánì yìí, kò sígbà tá ò ní máa ní ìṣòro. Nígbà míì, a lè má níṣẹ́ lọ́wọ́, a lè máa ṣàìsàn tó le gan-an, wọ́n lè máa ṣe inúnibíni sí wa, a lè pàdánù àwọn nǹkan ìní wa tàbí kí àjálù tiẹ̀ dé bá wa. Torí náà, tá a bá fẹ́ ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Ìfẹ́ tá a ní sí wọn á mú ká máa ṣe inú rere sí wọn. (Éfé. 4:32) Àwọn ànímọ́ yìí máa jẹ́ ká fara wé Ọlọ́run, àá sì lè tu àwọn míì nínú. (2 Kọ́r. 1:​3, 4) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì àtàwọn tó níṣòro nínú ìjọ? A gbọ́dọ̀ bá irú wọn dọ́rẹ̀ẹ́, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì wọn àti pé wọ́n wúlò láàárín wa. (1 Kọ́r. 12:22) Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn ará ti kọ́ èdè tuntun kí wọ́n lè ran àwọn àjèjì lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 9:23) Èyí sì ti mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. w17.08 23-24 ¶7-9

Thursday, June 20

Jèhófà ni ìpín mi . . . ìdí nìyẹn tí èmi yóò ṣe fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí i.​—Ìdárò 3:24.

Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ní sùúrù. Àmọ́ kí láá jẹ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀? Máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ìdí sì ni pé ìpamọ́ra tàbí sùúrù jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí. (Éfé. 3:16; 6:18; 1 Tẹs. 5:​17-19) Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi sùúrù dúró dè é. Má gbàgbé ohun tó mú kí Ábúráhámù, Jósẹ́fù àti Dáfídì fi sùúrù dúró de àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wọn. Kì í ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ tàbí ohun tó wù wọ́n nìkan ni wọ́n gbájú mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà àti bí wọ́n ṣe ń ronú lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn ló mú kí wọ́n lẹ́mìí ìdúródeni. Táwa náà bá ń ṣàṣàrò lórí ìbùkún tí wọ́n rí, á túbọ̀ máa wù wá láti dúró de Jèhófà. Kódà tá a bá ń kojú àwọn àdánwò tó lékenkà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a máa dúró de Jèhófà. Ká sòótọ́, àwọn ìgbà míì lè wà táwa náà máa béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà?” (Aísá. 6:11) Àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní irú èrò tí Jeremáyà ní nígbà tó sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. w17.08 7 ¶18-20

Friday, June 21

Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.​—Sm. 40:8.

Nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, ó dájú pé ó máa ń ṣeré, ó sì máa ń gbádùn ara rẹ̀. Ó ṣe tán Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ‘ìgbà rírẹ́rìn-ín wà, ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri sì wà.’ (Oníw. 3:4) Jésù tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà. Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ẹnu ya àwọn olùkọ́ tó wà nínú tẹ́ńpìlì torí “òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀” nípa Ìwé Mímọ́. (Lúùkù 2:​42, 46, 47) Jésù láyọ̀ nígbèésí ayé rẹ̀. Kí ló fún un láyọ̀? Ohun tó fún Jésù láyọ̀ ni pé ó ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe ni pé kó “polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, . . . àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú.” (Lúùkù 4:18) Ó sì dájú pé ohun tó ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Inú rẹ̀ máa ń dùn láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Baba rẹ̀ ọ̀run. (Lúùkù 10:21) Nígbà kan tí Jésù ń kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọsìn tòótọ́, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 4:​31-34) Bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn mú kó láyọ̀. Ìwọ náà máa láyọ̀ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. w17.07 23 ¶4-5

Saturday, June 22

Àlàáfíà Ọlọ́run . . . tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.​—Fílí. 4:7.

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ pé òun láàánú àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà Bàbá rẹ̀. (Jòh. 5:19) Jèhófà rán Jésù wá sáyé kó lè tu “àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn” àti “gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀” nínú. (Aísá. 61:​1, 2; Lúùkù 4:​17-21) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jésù láàánú àwọn èèyàn gan-an, ó ń rí ìyà tó ń jẹ wọ́n, ó mọ̀ ọ́n lára, ó sì máa ń wù ú gan-an pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́. (Héb. 2:17) Ìwé Mímọ́ fi dá wa lójú pé “Jésù Kristi jẹ́ ọ̀kan náà lánàá àti lónìí, àti títí láé.” (Héb. 13:8) Torí pé Jésù tí Bíbélì pè ní “Olórí Aṣojú ìyè” mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀, ó lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́. (Ìṣe 3:15; Héb. 2:​10, 18) Jésù ṣì máa ń kíyè sí àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn, ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn, ó sì máa ń tù wọ́n nínú “ní àkókò tí ó tọ́.”​—Héb. 4:​15, 16. w17.07 13 ¶6-7; 14 ¶10

Sunday, June 23

Ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà yín yóò wà pẹ̀lú.​—Lúùkù 12:34.

Gbogbo ọ̀nà ni Sátánì àtàwọn èèyàn inú ayé búburú yìí ń wá láti mú ká dẹwọ́ ká má sì mọyì àwọn ìṣúra tẹ̀mí tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Torí náà, ká má ṣe ronú láé pé irú ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa wù wá láti ṣe iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé, ó sì lè máa wù wá pé lọ́jọ́ kan káwa náà máa náwó yàfùnyàfùn tàbí ká fẹ́ káwọn èèyàn máa kan sárá sí wa torí ohun tá a ní. Àmọ́, àpọ́sítélì Jòhánù rán wa létí pé ayé yìí ń kọjá lọ àtàwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòh. 2:​15-17) Torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti rí i pé a ò gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè, ká má sì jẹ́ kí ìmọrírì wa àti ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ìṣúra tẹ̀mí yingin. Já ara rẹ gbà lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè mú kó o fi Ìjọba Ọlọ́run sípò kejì. Máa fìtara wàásù nìṣó, má sì jẹ́ kó sú ẹ láé torí pé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà ni. Máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ nínú Bíbélì. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa to ìṣúra jọ sí ọ̀run ‘níbi tí olè kò lè dé tàbí kí òólá jẹ run.’​—Lúùkù 12:33. w17.06 13 ¶19-20

Monday, June 24

Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn!​—Sm. 84:10.

Jèhófà kì í ni àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lára, kì í sì í ṣe apàṣẹwàá. Ó fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lómìnira, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n láyọ̀. (2 Kọ́r. 3:17) Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé: “Iyì àti ọlá ńlá ń bẹ níwájú [Ọlọ́run], okun àti ìdùnnú ń bẹ ní ipò rẹ̀.” (1 Kíró. 16:​7, 27) Étánì tóun náà kọ Sáàmù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó mọ igbe ìdùnnú. Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn. Wọ́n ń kún fún ìdùnnú láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ní orúkọ rẹ, a sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ.” (Sm. 89:​15, 16) Tá a bá ń ṣàṣàrò déédéé lórí bí Jèhófà ṣe jẹ́ onínúure, á mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìṣàkóso rẹ̀ ló dáa jù. Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ó mọ àwọn ohun táá jẹ́ ká láyọ̀, ó sì ń fún wa láwọn nǹkan náà lọ́pọ̀ yanturu. Kò sóhun tí Jèhófà ní ká ṣe tí kì í ṣe fún àǹfààní wa, kódà tó bá tiẹ̀ gba pé ká yááfì àwọn nǹkan kan. Tá a bá ṣe ohun tó fẹ́, á ṣe wá láǹfààní, àá sì láyọ̀.​—Aísá. 48:17. w17.06 29 ¶10-11

Tuesday, June 25

Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.​—Òwe 13:12.

Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè England ń wá ọmọ lójú méjèèjì, àmọ́ kò rọ́mọ bí títí tó fi dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ. Arábìnrin náà sọ pé ìbànújẹ́ dorí òun kodò torí òun mọ̀ pé ó di inú ayé tuntun kóun tó lè bímọ. Òun àtọkọ rẹ̀ wá pinnu láti gba ọmọ kan tọ́. Síbẹ̀ arábìnrin náà sọ pé: “Mo ṣì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí mo mọ̀ pé ọmọ téèyàn gbà tọ́ yàtọ̀ sọ́mọ ẹni.” Bíbélì sọ pé “a ó pa [obìnrin kan] mọ́ láìséwu nípasẹ̀ ọmọ bíbí.” (1 Tím. 2:15) Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé tí ẹnì kan bá bímọ, ó máa rí ìyè àìnípẹ̀kun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé tí obìnrin kan bá ní ọmọ tó ń tọ́jú, tó sì tún ń tọ́jú ilé, kò ní ráyè òfófó, kò sì ní máa tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀.​—1 Tím. 5:13. w17.06 5-6 ¶6-8

Wednesday, June 26

Kí ni ìwọ fi fún [Ọlọ́run]; tàbí kí ni ó rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?​—Jóòbù 35:7.

Ṣé ohun tí Élíhù ń sọ ni pé ìjọsìn wa kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run? Rárá o. Ohun tó ń sọ ni pé yálà a sin Ọlọ́run tàbí a ò sìn ín, kò ní kí Jèhófà má jẹ́ Ọba Aláṣẹ. Jèhófà ò ṣaláìní ohunkóhun, torí náà, a ò lè fi kún iyì tàbí agbára rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun yòówù ká ní, ì báà jẹ́ ìwà rere, ẹ̀bùn àbínibí tàbí okun, Jèhófà ló fún wa, ó sì ń kíyè sí bá a ṣe ń lò ó. Jèhófà máa ń kíyè sí ohun rere tá a bá ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì gbà pé òun la ṣe é fún. Òwe 19:17 sọ pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” Ṣé ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni pé Jèhófà ń kíyè sí gbogbo ohun rere tá à ń ṣe fáwọn ẹni rírẹlẹ̀? Ṣé a lè sọ pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé gbà pé òun jẹ èèyàn lásánlàsàn ní gbèsè torí pé onítọ̀hún ṣe rere, táá sì pọn dandan pé kóun san án lẹ́san? Bẹ́ẹ̀ ni, kódà Jésù Ọmọ Ọlọ́run náà jẹ́rìí sí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.​—Lúùkù 14:​13, 14. w17.04 29 ¶3-4

Thursday, June 27

Inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.​—Sm. 1:2.

Yàtọ̀ sí kíka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, kí la tún lè ṣe kí ìfẹ́ tá a ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè túbọ̀ jinlẹ̀? Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká máa lọ sípàdé déédéé. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a máa ń lo Ilé Ìṣọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí sì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí ètò Ọlọ́run gbà ń kọ́ wa. Ká lè lóye àpilẹ̀kọ tá a máa jíròrò, ó yẹ ká rí i dájú pé a múra sílẹ̀ dáadáa. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ka gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n bá tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà. Lónìí, a lè wa Ilé Ìṣọ́ jáde lónírúurú èdè lórí ìkànnì jw.org tàbí lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library. A ṣe àwọn kan sórí ẹ̀rọ lọ́nà táá mú kéèyàn tètè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà. Síbẹ̀, yálà orí ìwé la ti ń kà á tàbí lórí ẹ̀rọ, tá a bá ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí wọn, ìfẹ́ tá a ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. w17.05 20 ¶14

Friday, June 28

Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.​—Róòmù 14:12.

Lẹ́yìn ìrìbọmi, ó yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa bá a ṣe ń fòótọ́ inú sin Ọlọ́run. Téèyàn bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà, kò lè wọ́gi lé ẹ̀jẹ́ náà. Tẹ́nì kan bá sọ pé ìjọsìn Ọlọ́run ti sú òun tàbí pé òun ò fẹ́ máa gbé ìgbé ayé Kristẹni mọ́, kò lè sọ pé òun ò fìgbà kankan ya ara òun sí mímọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè sọ pé ìrìbọmi òun kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́. Ó ṣe kedere pé gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé onítọ̀hún ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Torí náà, tó bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ó máa jíhìn fún Jèhófà àti ìjọ. Ǹjẹ́ kí wọ́n má sọ nípa wa láé pé a ‘ti fi ìfẹ́ tá a ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí Jésù sọ nípa wa pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ, àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ pọ̀ ju àwọn ti ìṣáájú.” (Ìṣí. 2:​4, 19) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sapá láti máa gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa, tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá múnú Jèhófà dùn. w17.04 6-7 ¶12-13

Saturday, June 29

Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.​—Diu. 32:4.

Ó dá Ábúráhámù lójú pé Jèhófà máa ṣèdájọ́ tó tọ́ fáwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà. Ìdí nìyẹn tó fi béèrè pé: “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” (Jẹ́n. 18:25) Ábúráhámù mọ̀ dájú pé Jèhófà kò ní ṣe ohun tí kò tọ́ láé, kò ní “fi ikú pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú.” Lójú Ábúráhámù, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ “kò ṣeé ronú kàn.” Ó dá a lójú nítorí pé tó bá di pé ká ṣe ìdájọ́ òdodo, kò sẹ́ni tá a lè fi wé Jèhófà. Kódà, ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “ìdájọ́ òdodo” àti “òdodo” sábà máa ń wà pa pọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ohun kan ni pé kò fi bẹ́ẹ̀ síyàtọ̀ láàárín ọ̀rọ̀ méjèèjì. Torí pé Jèhófà ló fún wa ní ìlànà òdodo, ó dájú pé gbogbo ìgbà ni ìdájọ́ rẹ̀ máa ń tọ̀nà. Bákan náà, Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà “jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.”​—Sm. 33:5. w17.04 18 ¶1-2

Sunday, June 30

Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.​—3 Jòh. 4.

Ẹ̀yin òbí, àpẹẹrẹ yín ṣe pàtàkì tẹ́ ẹ bá fẹ́ káwọn ọmọ yín máa rìn lọ́nà tó lọ sí ìyè. Táwọn ọmọ yín bá rí i pé ẹ̀ ń ‘wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́,’ èyí á mú káwọn náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á pèsè ohun tí wọ́n nílò lójoojúmọ́. (Mát. 6:​33, 34) Torí náà, ẹ jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ yín lọ́rùn, ẹ máa yááfì àwọn nǹkan tara torí àwọn nǹkan tẹ̀mí, kì í ṣe pé kẹ́ ẹ máa yááfì àwọn nǹkan tẹ̀mí torí àwọn nǹkan tara. Bákan náà, ẹ má ṣe tọrùn bọ gbèsè. Bẹ́ ẹ ṣe máa ní “ìṣúra ní ọ̀run,” ìyẹn bẹ́ ẹ ṣe máa rí ojúure Jèhófà ni kẹ́ ẹ máa wá, kì í ṣe bẹ́ ẹ ṣe máa kó ọrọ̀ jọ tàbí bẹ́ ẹ ṣe máa rí “ògo ènìyàn.” (Máàkù 10:​21, 22; Jòh. 12:43) Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ yín dí débi tẹ́ ò fi ní ráyè tàwọn ọmọ yín. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú yín máa dùn gan-an tí wọ́n bá fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé wọn dípò kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe dolówó torí kí wọ́n lè tọ́jú ara wọn tàbí kí wọ́n lè tọ́jú ẹ̀yin òbí wọn. Kò yẹ káwa Kristẹni ní irú èrò táwọn èèyàn ní pé ó yẹ kọ́mọ lọ ṣiṣẹ́ owó torí káwọn òbí lè máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ. Ká rántí ohun tí Bíbélì sọ pé, “kò yẹ fún àwọn ọmọ láti to nǹkan jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.”​—2 Kọ́r. 12:14. w17.05 8-9 ¶3-4

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́