August
Thursday, August 1
Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èmi tí fẹ́, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́.—Mát. 26:39.
Tẹ́nì kan bá fẹ́ jẹ́ olùkọ́ tó dáa, òun fúnra ẹ̀ gbọ́dọ̀ gbẹ̀kọ́ dáadáa. (1 Tím. 4:15, 16) Torí náà, ó yẹ káwọn tí Jèhófà fún láṣẹ láti máa báni wí lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ìyẹn àwọn òbí àtàwọn alàgbà, kí wọ́n sì jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ àwọn sọ́nà. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ káwọn míì bọ̀wọ̀ fún wọn, wọ́n á sì lẹ́nu ọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ bá a wí. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ lára Jésù. Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀, kódà ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tí kò bá tiẹ̀ rọrùn pàápàá. Ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àtọ̀dọ̀ Jèhófà ni ẹ̀kọ́ tóun ń kọ́ wọn ti wá, Jèhófà náà ló sì fún òun lọ́gbọ́n tóun ní. (Jòh. 5:19, 30) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní àti bó ṣe máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ mú kó jẹ́ olùkọ́ tó láàánú tó sì ń tuni lára, ìyẹn sì mú káwọn èèyàn sún mọ́ ọn. (Mát. 11:29) Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìtura bá àwọn tó dà bí òwú àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú, ìyẹn àwọn tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. (Mát. 12:20) Kódà nígbà táwọn èèyàn ṣe ohun tó dùn ún, kàkà kó bínú sí wọn, ṣe ló fìfẹ́ bá wọn lò. Èyí hàn nínú bó ṣe fìfẹ́ bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wí nígbà tí wọ́n ń bá ara wọn fa ọ̀rọ̀ ẹni tó tóbi jù láàárín wọn.—Máàkù 9:33-37; Lúùkù 22:24-27. w18.03 26 ¶15-16
Friday, August 2
Èyí ni ó ń gbà yín là nísinsìnyí pẹ̀lú, èyíinì ni, ìbatisí.—1 Pét. 3:21.
Àpọ́sítélì Pétérù tọ́ka sí bí Nóà ṣe kan ọkọ̀ áàkì. Áàkì tí Nóà kàn mú kó ṣe kedere sáwọn èèyàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni Nóà fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Nóà fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Àwọn ohun tí Nóà ṣe fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́, ìyẹn sì jẹ́ kóun àti ìdílé rẹ̀ rí ìgbàlà. Áàkì yẹn jẹ́ ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí pé Nóà nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Lọ́nà kan náà, ìrìbọmi jẹ́ ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí pé ẹnì kan ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà torí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jésù Kristi. Bíi ti Nóà, àwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ máa ń ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Bí Jèhófà ṣe dá ẹ̀mí Nóà sí nígbà Ìkún Omi, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa dáàbò bo ẹni tó ṣèrìbọmi tó sì jẹ́ adúróṣinṣin nígbà ìparun ayé búburú yìí. (Máàkù 13:10; Ìṣí. 7:9, 10) Èyí mú kó ṣe kedere pé ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ṣe pàtàkì gan-an. Torí náà, tẹ́nì kan bá lọ ń fòní dónìí, fọ̀la dọ́la lórí ìrìbọmi láìnídìí, ìyè àìnípẹ̀kun rẹ̀ ló ń fi ṣeré yẹn! w18.03 4 ¶3-4
Saturday, August 3
Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.—Òwe 22:15.
Àwọn òbí kan máa ń ronú pé, ‘Tí ọmọ mi ò bá kúkú ṣèrìbọmi, wọn ò lè yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.’ Kí nìdí tí èrò yìí ò fi tọ̀nà? (Ják. 1:22) Ó dájú pé àwọn òbí Kristẹni máa fẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, àṣìṣe ló máa jẹ́ tí òbí kan bá ń ronú pé Jèhófà máa gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí ọmọ òun dá torí pé kò tíì ṣèrìbọmi. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ti pé ẹnì kan ò tíì ṣèrìbọmi kò ní kó má jíhìn fún Jèhófà, tó bá ti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ó di dandan kó jíhìn. (Ják. 4:17) Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń sapá láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn, dípò tí wọ́n á fi máa ní kí wọ́n má tíì ṣèrìbọmi. Àtikékeré ni wọ́n ti máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ìlànà Jèhófà kí wọ́n má bàa ṣìwà hù. (Lúùkù 6:40) Ìfẹ́ tí ọmọ rẹ ní fún Jèhófà á jẹ́ kó máa pa àwọn òfin Jèhófà mọ́ nígbà gbogbo.—Aísá. 35:8. w18.03 11 ¶12-13
Sunday, August 4
Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.—Jẹ́n. 6:9.
Nóà ń bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àtààbọ̀ [350] ọdún lẹ́yìn Ìkún Omi. (Jẹ́n. 9:28) A lè jẹ́ onígbọràn ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Nóà Bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa pé ká fi ara wa sábẹ́ àkóso Ọlọ́run, ká má ṣe jẹ́ apá kan ayé, ká sì fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. (Mát. 6:33; Jòh. 15:19) Tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká bi ara wa pé, ṣé ohun táyé ń fẹ́ ni mò ń ṣe àbí ohun tí inú Jèhófà dùn sí? Ìyẹn sì ṣe pàtàkì torí ohun táyé ń gbé lárugẹ yàtọ̀ pátápátá sóhun tí Jèhófà fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ilẹ̀ kan ojú burúkú làwọn kan fi ń wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé à ń tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbéyàwó àti ìbálòpọ̀. (Mál. 3:17, 18) Àmọ́ bíi ti Nóà, Jèhófà là ń bẹ̀rù kì í ṣe àwọn èèyàn torí a mọ̀ pé òun nìkan ló lè fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Lúùkù 12:4, 5) Àmọ́ ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá ṣì máa ‘bá Ọlọ́run rìn’ táwọn míì bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n sì ń ṣàríwísí ẹ? Ṣé wàá máa sin Jèhófà nìṣó tó bá ṣòro fún ẹ láti gbọ́ bùkátà, ṣé wàá gbà pé Olùpèsè ni Jèhófà? Tó o bá nígbàgbọ́, tó o sì jẹ́ onígbọràn bíi ti Nóà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bójú tó ẹ.—Fílí. 4:6, 7. w18.02 4 ¶4, 8; 5 ¶9-10
Monday, August 5
Ènìyàn ti ara kì í gba àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 2:14.
Nínú ayé lónìí, báwọn èèyàn ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn ló jẹ wọ́n lógún. Pọ́ọ̀lù pe ohun tó ń darí àwọn èèyàn náà ní “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” (Éfé. 2:2) Ẹ̀mí yìí ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa hùwà kan náà, ibi táyé bá kọjú sí làwọn náà máa ń kọjú sí. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó tọ́ lójú ara wọn ni ọ̀pọ̀ ń ṣe, kò sóhun tó kàn wọ́n nípa ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́ tàbí kò tọ́. Ohun tó jẹ ẹni tara lọ́kàn kò ju bó ṣe máa wà nípò gíga, táá sì lówó lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ láìgba tàwọn míì rò. Ẹni tara ni ẹni tó bá ń lọ́wọ́ nínú ohun tí Bíbélì pè ní “àwọn iṣẹ́ ti ara.” (Gál. 5:19-21) Díẹ̀ rèé lára ohun táwọn ẹni tara máa ń ṣe: Wọ́n máa ń fa ìpínyà, wọ́n máa ń gbè sẹ́yìn àwọn tó ń fa aáwọ̀, wọ́n máa ń gba ìwà ọ̀tẹ̀ láyè, wọ́n máa ń gbé ara wọn lọ sílé ẹjọ́, wọn kì í bọ̀wọ̀ fún ipò orí, wọ́n sì máa ń ṣàṣejù nídìí oúnjẹ àti ọtí. Yàtọ̀ síyẹn, wẹ́rẹ́ ni ẹni tara máa ń ṣubú sínú ìdẹwò.—Òwe 7:21, 22. w18.02 19 ¶3-5
Tuesday, August 6
Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . olùfẹ́ adùn.—2 Tím. 3:2, 4.
Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn gbádùn ara rẹ̀ tàbí kéèyàn ṣe fàájì níwọ̀ntúnwọ̀nsì, bó ṣe jẹ́ pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ tàbí kéèyàn lówó lọ́wọ́. Jèhófà ò fẹ́ ká máa fìyà jẹ ara wa, kò ní ká má gbádùn ara wa, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ká má ṣe fàájì. Bíbélì tiẹ̀ gba àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà níyànjú pé: “Máa lọ, máa fi ayọ̀ yíyọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ kí o sì máa fi ọkàn-àyà tí ó yá gágá mu wáìnì rẹ.” (Oníw. 9:7) Àwọn tí 2 Tímótì 3:4 pè ní olùfẹ́ adùn làwọn tí kò rí ti Ọlọ́run rò torí fàájì. Ẹ kíyè sí i pé ẹsẹ yìí ò sọ pé àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ adùn ju Ọlọ́run lọ, bí ẹni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run déwọ̀n àyè kan. Ohun tó ń sọ ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ adùn ‘dípò Ọlọ́run.’ Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kò sọ pé àwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run déwọ̀n àyè kan. Ohun tó ń sọ ni pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run rárá àti rárá.” Ẹ ò rí i pé ìkìlọ̀ ńlá lèyí jẹ́ fáwọn tí ìfẹ́ adùn ti gbà lọ́kàn, débi pé wọn ò ronú nǹkan míì ju bí wọ́n ṣe máa jayé orí wọn! Torí náà, gbólóhùn náà, “olùfẹ́ adùn” ṣàpèjúwe àwọn tí “adùn ìgbésí ayé yìí gbé lọ.”—Lúùkù 8:14. w18.01 25 ¶14-15
Wednesday, August 7
Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.—Òwe 3:9.
Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run. Òun ló fún wa ní gbogbo ohun tá a ní. Jèhófà ló ni wúrà, fàdákà àti gbogbo ohun àdáyébá míì, ó sì ń lò wọ́n láti gbé gbogbo ohun alààyè ró. (Sm. 104:13-15; Hág. 2:8) Ogójì ọdún [40] ni Jèhófà fi pèsè mánà àti omi fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù. (Ẹ́kís. 16:35; Neh. 9:20, 21) Jèhófà lo wòlíì Èlíṣà láti mú kí ìwọ̀nba òróró tí opó kan ní di rẹpẹtẹ lọ́nà ìyanu. Oore tí Ọlọ́run ṣe fún un yìí mú kó lè san gbogbo gbèsè tó jẹ, kódà owó tó kù lòun àti ọmọ rẹ̀ fi gbéra lẹ́yìn náà. (2 Ọba 4:1-7) Jèhófà mú kí Jésù pèsè oúnjẹ fáwọn èèyàn, ó sì tún pèsè owó lọ́nà ìyanu nígbà tí wọ́n nílò rẹ̀. (Mát. 15:35-38; 17:27) Àìlóǹkà ohun àmúṣorọ̀ ló wà níkàáwọ́ Jèhófà tó ń mú kí gbogbo ohun tó dá sórí ilẹ̀ ayé lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Síbẹ̀, ó ń rọ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ká fi àwọn ohun ìní wa ti ìjọsìn rẹ̀ lẹ́yìn.—Ẹ́kís. 36:3-7. w18.01 17 ¶1-3
Thursday, August 8
Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò.—1 Ọba 19:4.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé àtijọ́ gbà pé ìṣòro àwọn kọjá nǹkan táwọn lè fara dà. (Jóòbù 7:7) Àmọ́ dípò tí wọ́n fi máa bọ́hùn, ṣe ni wọ́n bẹ Jèhófà pé kó fún wọn lókun. Jèhófà dáhùn àdúrà wọn torí pé Jèhófà Ọlọ́run wa máa ń “fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀.” (Aísá. 40:29) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan lára wa ronú pé á dáa táwọn bá jáwọ́ fúngbà díẹ̀ ná, táwọn bá ti yanjú ìṣòro àwọn tán àwọn á pa dà wá sin Jèhófà. Lójú wọn, ṣe ló dà bíi pé ẹrù ìnira làwọn ìgbòkègbodò tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà dípò ìbùkún. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kì í ka Bíbélì mọ́, wọn ò wá sípàdé mọ́, wọn ò sì lọ sóde ẹ̀rí mọ́. Àṣìṣe gbáà nìyẹn jẹ́, ohun tí Sátánì sì fẹ́ kí wọ́n ṣe gan-an nìyẹn. Sátánì mọ̀ pé a máa lókun nípa tẹ̀mí tá a bá ń fìtara kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni, àmọ́ kò fẹ́ ká rókun gbà. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò lókun mọ́, má ṣe fi Jèhófà sílẹ̀. Ìgbà yẹn gan-an ló yẹ kó o sún mọ́ ọn torí pé á ‘fìdí rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ ẹ́ di alágbára.’—1 Pét. 5:10; Ják. 4:8. w18.01 7-8 ¶2-3
Friday, August 9
Jèhófà jẹ́ . . . olùmúni sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù, ó sì ń múni gòkè wá.—1 Sám. 2:6.
Wòlíì Èlíṣà tí Èlíjà gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ló ṣe àjíǹde kejì tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn. Obìnrin ará Ṣúnémù kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì gba Èlíṣà lálejò, ó sì tọ́jú rẹ̀ gan-an, àmọ́ obìnrin náà ò rọ́mọ bí. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí Jèhófà nípasẹ̀ wòlíì Èlíṣà, Jèhófà mú kí obìnrin tó yàgàn yìí àti ọkọ rẹ̀ tó ti dàgbà ní ọmọkùnrin kan. Lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ọmọ náà kú. Ẹ wo bí inú ìyá ọmọ yẹn ṣe máa bà jẹ́ tó. Ó tọrọ àyè lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀, ó sì rìnrìn-àjò nǹkan tó tó máìlì mọ́kàndínlógún [19] (tàbí 30 km) lọ bá Èlíṣà lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì. Wòlíì Èlíṣà kọ́kọ́ rán Géhásì ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Ṣúnémù kó lè jí ọmọ náà dìde, àmọ́ Géhásì ò rí i ṣe. Ẹ̀yìn ìyẹn ni màmá ọmọ náà àti Èlíṣà wá dé. (2 Ọba 4:8-31) Nígbà tí wọ́n dẹ́bẹ̀, Èlíṣà dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú ọmọ náà, ó sì gbàdúrà. Jèhófà jí ọmọ náà dìde, ìyẹn sì múnú màmá rẹ̀ dùn gan-an. (2 Ọba 4:32-37) Ọlọ́run jí ọmọdékùnrin tó wà ní Ṣúnémù dìde, èyí sì fi hàn pé ó lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde. w17.12 4 ¶7-8
Saturday, August 10
Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.—Òwe 22:15.
Ó ṣe kedere nígbà náà pé ọgbọ́n tí ẹnì kan ní la fi ń mọ̀ pé ó dàgbà nípa tẹ̀mí. Kì í ṣe ọjọ́ orí la fi ń mọ̀ pé ẹnì kan dàgbà nípa tẹ̀mí, kàkà bẹ́ẹ̀ bí onítọ̀hún ṣe ń bẹ̀rù Jèhófà tó sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò ló ń fi hàn bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 111:10) Àwọn ọmọ tó dàgbà nípa tẹ̀mí dé ìwọ̀n tí ọjọ́ orí wọn mọ kì í jẹ́ kí àwọn ojúgbà wọn tàbí ìfẹ́ ọkàn tiwọn máa “bì [wọ́n] kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún.” (Éfé. 4:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń tẹ̀ síwájú bí wọ́n ṣe ń lo “agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Wọ́n ń fi hàn pé àwọn túbọ̀ ń dàgbà nípa tẹ̀mí tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tí wọ́n bá máa rí ìgbàlà. (Òwe 24:14) Nítorí náà, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń kọ́ wọn láwọn ìlànà Bíbélì, ẹ sì jẹ́ kí wọ́n máa rí i nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe yín pé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ lẹ̀yin náà ń tẹ̀ lé.—Róòmù 2:21-23. w17.12 20-21 ¶12-13
Sunday, August 11
Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn tí ń bẹ lóde . . . [ẹ] mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.—Kól. 4:5, 6.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwa èèyàn lè dá yanjú ìṣòro ayé. Kí nìdí? Wọ́n gbà pé táwọn bá lè dá yanjú ìṣòro ayé, a jẹ́ pé àwọn ò nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run àti pé àwọn lè máa ṣe báwọn ṣe fẹ́. Ohun míì tó mú káwọn èèyàn gbà bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé ogun, ìwà ọ̀daràn, àìsàn àti ipò òṣì ti ń dín kù láwùjọ. Ìwádìí kan tiẹ̀ sọ pé: “Nǹkan túbọ̀ ń dáa sí i láyé yìí torí pé àwọn èèyàn ti pawọ́ pọ̀ láti mú kí nǹkan ṣẹnuure.” Táwọn èèyàn bá sọ èrò kan tó lòdì sóhun tó o gbà gbọ́, ṣèwádìí nípa ọ̀rọ̀ náà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì tún jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Mọ ìdí táwọn èèyàn fi ní èrò náà, ìdí tí kò fi jóòótọ́ àti ohun tó o lè ṣe kí èrò náà má bàa nípa lórí rẹ. Ó ṣe kedere pé tá a bá ń fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní sílò, àwọn èèyàn ayé kò ní kéèràn ràn wá. w17.11 24 ¶14, 17
Monday, August 12
Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé èmi kò rí bí àwọn ènìyàn yòókù.—Lúùkù 18:11.
Kí nìdí táwọn Farisí fi burú tó bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé wọ́n “ka àwọn yòókù sí aláìjámọ́ nǹkan kan.” (Lúùkù 18:9-14) Jèhófà ni kó o fara wé, má ṣe fara wé àwọn Farisí. Torí náà, máa fi àánú hàn. (Kól. 3:13) Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o jẹ́ kó rọrùn fáwọn èèyàn láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ. (Lúùkù 17:3, 4) Torí náà bi ara rẹ pé: ‘Ṣó máa ń wù mí láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ mí, títí kan àwọn tó ṣẹ̀ mí lọ́pọ̀ ìgbà? Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ mí tàbí tó ṣàìdáa sí mi, ṣó máa ń yá mi lára láti yanjú ọ̀rọ̀ náà?’ Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, á rọrùn fún wa láti dárí ji àwọn èèyàn. Àwọn Farisí kì í dárí jini torí pé àwọn èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan lójú wọn. Àmọ́ àwa Kristẹni lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a sì gbà pé “àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù” wá lọ, ó sì yẹ ká dárí jì wọ́n. (Fílí. 2:3) Ṣé wàá fara wé Jèhófà, kó o sì fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó wù ẹ́ láti dárí jì wọ́n, ìyẹn á sì mú kó rọrùn fáwọn náà láti wá tọrọ àforíjì. Má ṣe tètè máa bínú, kàkà bẹ́ẹ̀ máa mú sùúrù, kó o sì máa fàánú hàn.—Oníw. 7:8, 9. w17.11 14-15 ¶6-8
Tuesday, August 13
Ó dára láti máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run wa.—Sm. 147:1.
Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ yá ẹ lára tàbí kí ojú máa tì ẹ́ torí pé o ò lóhùn bíi tàwọn olórin inú ayé. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kíyẹn dí ẹ lọ́wọ́ àtimáa fi orin yin Jèhófà lógo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o gbé ìwé orin rẹ sókè, gbé orí rẹ sókè kó o sì fìtara kọrin jáde. (Ẹ́sírà 3:11) Lóde òní, ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba ló máa ń gbé ọ̀rọ̀ àwọn orin wa sójú tẹlifíṣọ̀n, káwọn ará lè kọrin sókè. Yàtọ̀ síyẹn, orin kíkọ ti wá wà lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ táwọn alàgbà ń gbádùn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Èyí mú káwọn alàgbà rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn máa múpò iwájú nínú kíkọ orin nípàdé. Ìbẹ̀rù wà lára ohun tí kì í jẹ́ káwọn kan fi gbogbo ẹnu kọrin. Wọ́n lè máa bẹ̀rù pé ohùn àwọn máa dá yàtọ̀ láàárín àwọn tó kù. Àmọ́, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà” nínú ọ̀rọ̀ sísọ. (Ják. 3:2) Síbẹ̀, ìyẹn ò ní ká má sọ̀rọ̀ mọ́. Torí náà, ṣó wá yẹ ká tìtorí pé ohùn wa ò fi bẹ́ẹ̀ dáa, ká wá dákẹ́? w17.11 4-5 ¶9-10
Wednesday, August 14
Yóò sì ṣẹlẹ̀ láìkùnà—bí ẹ bá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.—Sek. 6:15.
Lẹ́yìn tí Sekaráyà rí ìran keje, ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan láá máa rò. Jèhófà sọ pé òun máa fìyà jẹ àwọn olè àtàwọn tó ń hùwà àìṣòótọ́ míì nítorí ìwà burúkú wọn. Ó dájú pé ohun tí Jèhófà sọ yìí máa fún Sekaráyà lókun gan-an. Síbẹ̀, nǹkan ò yí pa dà, ṣe làwọn olè àtàwọn tó ń hùwà burúkú míì túbọ̀ ń gbilẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn náà ò rí ti tẹ́ńpìlì Jèhófà rò rárá. Ṣé ó dáa báwọn Júù yẹn ṣe pa iṣẹ́ tí Jèhófà fún wọn tì? Ṣé tìtorí iṣẹ́ tara wọn ni Jèhófà ṣe dá wọn nídè? Ó dájú pé Jèhófà mọ ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fi ìran kẹjọ han Sekaráyà káwọn Júù náà lè mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì mọyì gbogbo akitiyan wọn. Ìràn náà tún jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà máa dáàbò bò wọ́n tí wọ́n bá pa dà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Táwọn Júù yẹn bá pa dà sẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà, Ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wọn ló wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní. w17.10 26 ¶1; 27 ¶5
Thursday, August 15
Ọlọ́run . . . ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.—Fílí. 2:13.
Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run làwọn arákùnrin tó nígboyà, tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sìn nínú ìjọ. (1 Tím. 3:1) Àmọ́, àwọn kan kì í fẹ́ gba àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ. Wọ́n lè ti ṣe àṣìṣe nígbà kan rí, kí wọ́n wá máa ronú pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tó ń di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Àwọn arákùnrin míì sì lè máa ronú pé àwọn ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà bí iṣẹ́. Tó bá jẹ́ pé ohun tó ò ń rò nìyẹn, Jèhófà á mú kó o nígboyà. (Fílí. 4:13) Rántí pé ìgbà kan wà tí Mósè náà rò pé òun ò ní lè ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. (Ẹ́kís. 3:11) Síbẹ̀ Jèhófà ràn án lọ́wọ́, nígbà tó sì yá Mósè dẹni tó nígboyà tó sì ṣe iṣẹ́ náà yanjú. Àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi náà lè nígboyà tí wọ́n bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, tí wọ́n sì ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn tó lo ìgboyà nínú Bíbélì. Wọ́n lè fìrẹ̀lẹ̀ bẹ àwọn alàgbà pé kí wọ́n dá àwọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì jẹ́ káwọn alàgbà mọ̀ pé àwọn ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá wà. w17.09 32 ¶19
Friday, August 16
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.—Aísá. 40:8.
Àwa Kristẹni mọ̀ pé Jèhófà mí sí àwọn tó kọ Bíbélì. Àmọ́ o, kò mí sí àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Septuagint, Bíbélì Wycliffe, Bíbélì King James Version tàbí èyíkéyìí míì. Síbẹ̀, tá a bá wo àkọsílẹ̀ ìtàn nípa bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn Bíbélì yìí àtàwọn míì, àá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé Ọ̀rọ̀ òun kò ní pa run. Èyí mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlérí yòókù tí Jèhófà ṣe máa ṣẹ dandan, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? (Jóṣ. 23:14) Bí Bíbélì ṣe la onírúurú ìṣòro já títí di àsìkò wa yìí mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ó sì tún mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà túbọ̀ jinlẹ̀. Ó ṣe tán, kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀? Kí nìdí tó fi dáàbò bò ó káwọn èèyàn má bàa pa á run? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká jàǹfààní bí òun ṣe ń kọ́ wa. (Aísá. 48:17, 18) Kí wá ló yẹ ká ṣe? Kò sóhun míì ju pé káwa náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn, ká sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.—1 Jòh. 4:19; 5:3. w17.09 21-22 ¶13-14
Saturday, August 17
Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.—Éfé. 6:2.
Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti kọ́ àwọn ọmọ tí ọ̀kan lára àwọn òbí kò bá jọ́sìn Jèhófà. Síbẹ̀, ó yẹ kó o máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ tàbí aya rẹ káwọn ọmọ rẹ náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan dáadáa tí ọkọ tàbí aya rẹ ń ṣe ni kó o máa sọ, kó o sì máa yìn ín. Má ṣe máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa níṣojú àwọn ọmọ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó yé wọn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa sin Jèhófà tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Táwọn ọmọ rẹ bá ń hùwà rere, ìyẹn lè wú ẹnì kejì rẹ lórí kó sì wá jọ́sìn Jèhófà. Ọkọ kan lè sọ fún ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pé kò gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ òun lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kò sì gbọ́dọ̀ mú wọn lọ sípàdé. Síbẹ̀, á dáa kí arábìnrin náà ṣe ohun tó lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ náà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ìṣe 16:1; 2 Tím. 3:14, 15) Ó ṣe pàtàkì pé kí aya náà bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, síbẹ̀ á máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti sọ nípa Jèhófà fáwọn ọmọ rẹ̀. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ Jèhófà kí wọ́n sì máa hùwà ọmọlúàbí.—Ìṣe 4:19, 20. w17.10 14 ¶9-10
Sunday, August 18
Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.—Éfé. 5:1.
Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ohun tó sì mú káwa èèyàn náà máa fàánú hàn nìyẹn. Kódà àwọn tí kò mọ Ọlọ́run náà máa ń fàánú hàn. (Jẹ́n. 1:27) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni tàwọn aṣẹ́wó méjì tí wọ́n ń bára wọn du ọmọ, tí wọ́n sì gbẹ́jọ́ náà wá sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì. Nígbà tí Sólómọ́nì pàṣẹ pé kí wọ́n gé ọmọ náà sí méjì, kó lè dán wọn wò, àánú ṣe èyí tó jẹ́ ìyá ọmọ náà gangan. Kíá ló bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n gbọ́mọ náà fún obìnrin kejì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ló lọmọ. (1 Ọba 3:23-27) Àpẹẹrẹ míì ni ti ọmọbìnrin Ọba Fáráò tó dá ẹ̀mí Mósè sí nígbà tó wà lọ́mọdé jòjòló. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọba yìí mọ̀ pé àwọn Hébérù ló lọmọ náà àti pé ṣe ló yẹ kí wọ́n pa á, “síbẹ̀ ó káàánú rẹ̀”, ó sì gbà á ṣọmọ.—Ẹ́kís. 2:5, 6. w17.09 8-9 ¶2-3
Monday, August 19
[Jèhófà] ń mú sùúrù fún yín.—2 Pét. 3:9.
Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, èyí sì máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. (Òwe 22:4) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan máa wà nínú ìjọ, Jèhófà sì máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Gbogbo yín, ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pét. 5:5) Nínú ayé lónìí, ojú ọ̀dẹ̀ làwọn èèyàn fi ń wo ẹni tó bá níwà tútù, tó sì ní sùúrù. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Jèhófà Ẹni tó lágbára jù láyé àtọ̀run ló fún wa láwọn ànímọ́ yìí. Òun ló níwà tútù jù, òun ló sì ní sùúrù jù. Ẹ rántí bí Jèhófà ṣe fi sùúrù dá Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì lóhùn nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń bi í níbèérè. (Jẹ́n. 18:22-33; 19:18-21) Bákan náà, ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọdún ni Jèhófà fi ní sùúrù fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ya ọlọ̀tẹ̀.—Ìsík. 33:11. w17.08 25 ¶13-14
Tuesday, August 20
Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín.—Fílí. 4:7.
Gbàdúrà, wàá sì rí àlàáfíà Ọlọ́run. Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé “àlàáfíà Ọlọ́run . . . ta gbogbo ìrònú yọ.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ohun táwọn atúmọ̀ èdè kan tú gbólóhùn yìí sí ni pé àlàáfíà Ọlọ́run “ju ìmọ̀ gbogbo lọ” tàbí pé “ó tayọ òye eniyan.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé “àlàáfíà Ọlọ́run” kọjá gbogbo ohun tá a lè rò lọ. Nígbà míì, àwa fúnra wa lè má rí ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro wa, àmọ́ Jèhófà mọ ọ̀nà àbáyọ, ó sì lè gba ọ̀nà àrà kó wa yọ nínú ìṣòro náà. (2 Pét. 2:9) Báwo la ṣe lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run” kódà tá a bá níṣòro? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣìkẹ́ àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run wa. Ìràpadà tí “Kristi Jésù” ṣe nìkan ló mú ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fún wa ni bó ṣe pèsè ìràpadà yìí. Jèhófà máa ń tipasẹ̀ ìràpadà dárí jì wá, ìyẹn sì ń jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn, ká sì ní ẹ̀rí ọkàn rere.—Jòh. 14:6; Ják. 4:8; 1 Pét. 3:21. w17.08 10 ¶7; 12 ¶15
Wednesday, August 21
Ọkàn-àyà mọ ìkorò ọkàn ẹni, kò sì sí àjèjì tí yóò tojú bọ ayọ̀ yíyọ̀ rẹ̀.—Òwe 14:10.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nìkan ló mọ bí ẹ̀dùn ọkàn tó ní ṣe pọ̀ tó, torí pé ẹni tó kàn ló mọ̀. Bákan náà, ó lè ṣòro fún un láti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn rẹ̀. Kódà, tí ẹni náà bá tiẹ̀ gbìyànjú láti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn èèyàn láti lóye ohun tó ń sọ. Ká sòótọ́, a lè má mọ ohun tá a máa sọ fún ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Ohun tó dáa jù ni pé ká “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Tó ò bá mọ ohun tó o lè sọ fún ẹni náà, o lè fún un ní lẹ́tà tàbí káàdì tó o kọ ọ̀rọ̀ ìtùnú sí, o sì lè fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i lórí fóònù. O lè kọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó ń tuni nínú, o lè mẹ́nu ba ànímọ́ rere kan tẹ́ni tó kú náà ní tàbí kó o sọ àwọn nǹkan dáadáa tẹ́ ẹ jọ ṣe kẹ́ni náà tó kú. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ máa mọrírì rẹ̀ gan-an tó o bá gbàdúrà fún un tàbí tẹ́ ẹ jọ gbàdúrà. w17.07 14-16 ¶13-16
Thursday, August 22
Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.—Mát. 19:6.
Kí ni àwọn tọkọtaya Kristẹni lè ṣe tí ìgbéyàwó wọn ò bá rí bí wọ́n ṣe rò tàbí tí àárín wọn ò wọ̀ rárá? Á dáa kí wọ́n ronú jinlẹ̀ nípa àjọṣe àárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́. Jèhófà fi ara rẹ̀ wé ọkọ orílẹ̀-èdè náà. (Aísá. 54:5; 62:4) Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì da ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ fún Jèhófà. Síbẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún wọn. Léraléra ló ń fàánú hàn sí wọn, tó sì ń rántí májẹ̀mú tó bá wọn dá. (Sm. 106:43-45) Ǹjẹ́ ìfẹ́ alọ́májàá tí Jèhófà ní yìí kò wú ẹ lórí? Torí náà, àwọn tọkọtaya tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Wọn kì í wá bí wọ́n ṣe máa kọ ara wọn sílẹ̀ lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló so àwọn pọ̀, ó sì fẹ́ káwọn fà mọ́ ara wọn. Ìṣekúṣe nìkan ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ó lè mú kí tọkọtaya yàn láti kọ ara wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíì. (Mát. 19:5, 9) Bí tọkọtaya bá ń sapá láti yanjú ìṣòro wọn, ṣe ni wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà. w17.06 31 ¶17-18
Friday, August 23
Ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run.—Jẹ́n. 3:5.
Sátánì Èṣù dọ́gbọ́n sọ pé Jèhófà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Ó fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ dénú àti pé ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso kò dáa. Kódà, ó dọ́gbọ́n sọ pé àwọn èèyàn á gbádùn tí wọ́n bá ń ṣàkóso ara wọn, nǹkan á sì ṣẹnuure fún wọn. (Jẹ́n. 3:1-4) Sátánì tún sọ pé ojú ayé lásán ni ìjọsìn tá à ń ṣe fún Ọlọ́run àti pé tíyà bá jẹ wá, a máa gbàgbé Jèhófà. (Jóòbù 2:4, 5) Kí Jèhófà lè fi hàn pé ẹ̀sùn tí Èṣù fi kàn án kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ó fàyè gba àwa èèyàn láti ṣàkóso ara wa ká lè rí i pé nǹkan ò lè ṣẹnuure fún wa tá ò bá sí lábẹ́ òun. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà mọ̀ pé irọ́ lẹ̀sùn tí Èṣù fi kan òun. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì pé kó fìdí ẹ̀sùn rẹ̀ múlẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ náà kan gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì. (Sm. 83:18) Ó ṣe tán, Ádámù àti Éfà kọ ìṣàkóso Jèhófà, ọ̀pọ̀ ló sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn náà. Ìyẹn lè mú kí ọ̀pọ̀ máa ronú pé bóyá òótọ́ lẹ̀sùn tí Èṣù fi kan Ọlọ́run. w17.06 22-23 ¶3-4
Saturday, August 24
Ẹ lọ . . . sọ àwọn ènìyàn gbogbo di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19.
Iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn máa ń mú kéèyàn túbọ̀ wúlò gan-an. Bí àpẹẹrẹ, á mú kó o túbọ̀ di ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ń ṣe, wàá mọ bó o ṣe lè báwọn èèyàn sọ̀rọ̀, á jẹ́ kó o nígboyà, wàá sì mọ bó o ṣe lè fọgbọ́n bá àwọn èèyàn lò. (Òwe 21:5; 2 Tím. 2:24) Àmọ́ ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ láyọ̀ nídìí iṣẹ́ náà ni pé wàá túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́, ìyẹn á sì mú kí ohun tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú. Yàtọ̀ síyẹn, á mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 3:9) O lè gbádùn iṣẹ́ yìí kódà táwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kò bá tiẹ̀ tó nǹkan. Ìdí ni pé iṣẹ́ ìwàásù kì í ṣe iṣẹ́ ẹnì kan, gbogbo ìjọ ló ń pawọ́ pọ̀ ṣe é. Ó lè jẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin kan ló kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ títí tónítọ̀hún fi ṣèrìbọmi, síbẹ̀ gbogbo wa là ń láyọ̀ torí pé àjọṣe gbogbo wa ni. Bí àpẹẹrẹ, ọdún mẹ́sàn-án gbáko ni Brandon fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ kan tí kò méso jáde. Ó sọ pé: “Lóòótọ́ kò tíì sí èyíkéyìí lára àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó ṣèrìbọmi, àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn míì ti ṣèrìbọmi. Mo dúpẹ́ pé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ni mò ń fayé mi ṣe.”—Oníw. 11:6. w17.07 23 ¶7; 24 ¶9-10
Sunday, August 25
Ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.—1 Sám. 1:18.
Hánà ìyàwó Ẹlikénà ní ìṣòro kan. Kò rọ́mọ bí àmọ́ Pẹ̀nínà orogún rẹ̀ ń bímọ lémọ. (1 Sám. 1:4-7) Gbogbo ìgbà ni Pẹ̀nínà máa ń fojú pọ́n ọn, èyí sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ bá Hánà. Kó lè rí ìtùnú, ó gbàdúrà sí Jèhófà. (1 Sám. 1:12) Ó dá a lójú pé Jèhófà máa jẹ́ kóun rọ́mọ bí tàbí pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà òun lọ́nà míì. A ò lè sá fún ìṣòro torí a jẹ́ aláìpé àti pé inú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso la wà. (1 Jòh. 5:19) Àmọ́ inú wa dùn pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́r. 1:3) Ọ̀nà kan tá a lè gbà rí ìrànwọ́ nígbà ìṣòro ni pé ká gbàdúrà sí Jèhófà. Nígbà tí Hánà níṣòro, ó tú gbogbo ọkàn rẹ̀ jáde fún Jèhófà. Bákan náà, tá a bá ń kojú ìṣòro, kì í ṣe pé ká kàn sọ ìṣòro tá a ní fún Jèhófà, ṣe ló yẹ ká rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà, ká sọ gbogbo bó ṣe rí lára wa fún un, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn.—Fílí. 4:6, 7. w17.06 6 ¶10-11
Monday, August 26
Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?—Jòh. 21:15.
Jésù tó ti jíǹde dúró sétíkun, ó mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò rẹ́ja pa ní gbogbo òru mọ́jú. Jésù wá sọ fún wọn pé: “ ‘Ẹ ju àwọ̀n sí ìhà ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ ó sì rí díẹ̀.’ Nígbà náà ni wọ́n jù ú, ṣùgbọ́n wọn kò lè fà á wọlé mọ́ nítorí ògìdìgbó ẹja.” (Jòh. 21:1-6) Lẹ́yìn tí Jésù pèsè oúnjẹ àárọ̀ fún wọn, ó yíjú sí Símónì Pétérù, ó sì sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ó ṣe kedere pé Pétérù fẹ́ràn iṣẹ́ ẹja pípa gan-an. Torí náà, ó jọ pé Jésù fẹ́ mọ ohun tí Pétérù fẹ́ràn jù. Ṣé Jésù ni Pétérù fẹ́ràn jù ni àbí iṣẹ́ ẹja pípa? Ṣé àwọn ẹja tó pa lọ́jọ́ yẹn ló gbà á lọ́kàn jù àbí àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn? Pétérù dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” (Jòh. 21:15) Pétérù fi hàn lóòótọ́ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù. Látìgbà yẹn lọ, ṣe ló ń lo gbogbo okun rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù gbé fún wọn. Ó sì gbé iṣẹ́ ribiribi ṣe nínú ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. w17.05 22 ¶1-2
Tuesday, August 27
Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?—Héb. 13:6.
Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà ò ní fi òun sílẹ̀, ohun tó sì mú kó lè fara da àwọn ìṣòro rẹ̀ nìyẹn. Kò jẹ́ kí àwọn ìṣòro rẹ̀ fa ìrẹ̀wẹ̀sì fún un. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó gbára lé “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́r. 1:3, 4) Ká tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà. (Sm. 86:3; 1 Tẹs. 5:17; Róòmù 12:12) Torí náà, tá a bá ń wáyè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé, tá à ń sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa àti bí nǹkan ṣe rí lára wa fún un, a máa túbọ̀ sún mọ́ Baba wa ọ̀run tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Bákan náà, bá a ṣe ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa, ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀. Èyí á wá jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Sm. 145:18) Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà ń fìfẹ́ bójú tó wa, àá lè fara da àdánwò èyíkéyìí tá a bá kojú. w17.05 19 ¶9-10
Wednesday, August 28
Ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.—1 Sám. 16:7.
Ká sọ pé àwọn alàgbà ṣèpinnu kan tí kò yé ẹ tàbí tó ò fara mọ́, kí lo máa ṣe? Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè dán ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà àti ètò rẹ̀ wò. Báwo lẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lè gbà ràn wá lọ́wọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ ká gbà pé a ò mọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an. Bó ti wù ká mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà tó, Jèhófà nìkan ló mọ ohun tó wà lọ́kàn àwa èèyàn. Tá a bá fi èyí sọ́kàn, ó máa jẹ́ ká rẹ ara wa sílẹ̀, ká gbà pé kì í ṣe gbogbo bí nǹkan ṣe rí ló hàn sí wa, ìyẹn á sì mú ká tún inú rò. Ìkejì, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ ká gba ìpinnu èyíkéyìí táwọn tó ń múpò iwájú bá ṣe, ká sì ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà fi máa dá sọ́rọ̀ náà, táá sì ṣàtúnṣe sí àìṣèdájọ́ òdodo tó wáyé. Bíbélì sọ pé: ‘Yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, ṣùgbọ́n kì yóò dára rárá fún ẹni burúkú, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọjọ́ rẹ̀ kì yóò gùn.’ (Oníw. 8:12, 13) Torí náà, tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kò ní jẹ́ káwa àtàwọn míì tọ́rọ̀ kàn fi Jèhófà sílẹ̀.—1 Pét. 5:5. w17.04 25-26 ¶10-11
Thursday, August 29
Nítorí ní tòótọ́, a jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ àwọn Hébérù ni; àti pé níhìn-ín pẹ̀lú, èmi kò ṣe nǹkan kan rárá tí ó yẹ kí a tìtorí rẹ̀ fi mí sínú ihò ẹ̀wọ̀n.—Jẹ́n. 40:15.
Jósẹ́fù tún ṣàlàyé pé òun kò ṣe ohun tí wọ́n tìtorí rẹ̀ sọ òun sẹ́wọ̀n. Ó wá sọ fún agbọ́tí náà pé kó sọ nípa òun fún Fáráò. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó fẹ́ kó “mú [òun] jáde kúrò” lẹ́wọ̀n. (Jẹ́n. 40:14) Ǹjẹ́ Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ti gba kámú pé kò sí nǹkan tóun lè ṣe sọ́rọ̀ náà? Rárá o. Òun fúnra rẹ̀ mọ̀ dáadáa pé àwọn èèyàn ti ṣe ọ̀pọ̀ àìdáa sóun. Ó ṣàlàyé bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an fún agbọ́tí náà, torí ó mọ̀ pé agbọ́tí náà máa tó wà nípò tó fi lè ran òun lọ́wọ́. Àmọ́ ẹ kíyè sí pé kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ pé Jósẹ́fù sọ fún ẹnikẹ́ni títí kan Fáráò pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ló jí òun gbé. Kódà nígbà tí Jósẹ́fù àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ parí ọ̀rọ̀ wọn ní Íjíbítì, Fáráò gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Ó tiẹ̀ tún sọ fún wọn pé kí wọ́n wá máa gbé ní Íjíbítì, kí wọ́n sì gbádùn “ohun rere gbogbo ilẹ̀” náà.—Jẹ́n. 45:16-20. w17.04 20-21 ¶12-13
Friday, August 30
Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!—Róòmù 11:33.
Ohún kan tó mú kí Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ayé àtọ̀run ni pé ó ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ táá fi bojú tó gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ lágbára láti wo àwọn àìsàn táwọn dókítà ò lè wò sàn. (Mát. 4:23, 24; Máàkù 5:25-29) Àwọn nǹkan yìí kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú Jèhófà torí pé ó mọ bí gbogbo ẹ̀yà ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́, ó sì lè tún ohun tó bá bà jẹ́ lára wa ṣe. Ó tún lágbára láti jí òkú dìde kó sì dènà àwọn àjálù bí ìmìtìtì ilẹ̀, omíyalé àtàwọn àjálù míì. Ayé tó wà lábẹ́ àkóso Sátánì yìí kò lè yanjú rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín ìlú àtèyí to ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Jèhófà nìkan ló ní ọgbọ́n tó lè fi mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé. (Aísá. 2:3, 4; 54:13) Kò sígbà tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀ Jèhófà tí kì í jọ wá lójú. Ó sì máa ń ṣe wá bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní lábẹ́ ìmísí. w17.06 28 ¶6-7
Saturday, August 31
Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.—Máàkù 10:9.
Awọn èèyàn ayé yìí ò fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó. Kí ìṣòro má tíì yọjú nínú ìgbéyàwó wọn, wọ́n á sọ pé àwọn ò ṣe mọ́, wọ́n á sì fi ẹnì kejì wọn sílẹ̀. Àmọ́, kò yẹ kí Kristẹni ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 7:27) Ńṣe lẹni tó bá da ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ̀ pa irọ́ fún Ọlọ́run, a sì mọ̀ pé Ọlọ́run kórìíra àwọn òpùrọ́! (Léf. 19:12; Òwe 6:16-19) Jèhófà tún kórìíra kéèyàn dọ́gbọ́n kọ aya tàbí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. (Mál. 2:13-16) Jésù sọ pé ohun kan ṣoṣo tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀ ni pé tí ẹnì kan lára wọn bá ṣe panṣágà tí ẹnì kejì kò sì dárí jì í. (Mát. 19:9; Héb. 13:4) Ìpínyà ńkọ́? Ohun tí Bíbélì sọ ṣe kedere. (1 Kọ́r. 7:10, 11) Bíbélì ò sọ àwọn nǹkan tó lè mú kí tọkọtaya pínyà. Àmọ́ o, àwọn Kristẹni kan tó ti ṣègbéyàwó máa ń yàn láti pínyà torí àwọn ìdí kan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí ọkọ tàbí aya wọn jẹ́ aluni tàbí apẹ̀yìndà gbà pé ẹ̀mí àwọn wà nínú ewu látàrí lílù tí ẹnì kejì wọn ń lù wọ́n, tàbí pé onítọ̀hún mú kó nira gan-an fún wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n pinnu pé àwọn á pínyà. w17.04 7 ¶14-16