July
Monday, July 1
Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ.—1 Pét. 5:6.
Ṣébínà ni “ẹni tí ń ṣe àbójútó ilé” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti Ọba Hesekáyà, torí náà ipò àṣẹ ló wà. (Aísá. 22:15) Àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, ó sì ń wá ògo fún ara rẹ̀. (Aísá. 22:16-18) Torí pé Ṣébínà ń wá ògo fún ara rẹ̀, Ọlọ́run lé e ‘kúrò ní ipò rẹ̀,’ ó sì fi Élíákímù rọ́pò rẹ̀. (Aísá. 22:19-21) Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà fẹ́ gbógun ja Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, Senakéríbù rán àwọn kan tó wà nípò gíga nínú ìjọba rẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá kí wọ́n lè ṣẹ̀rù ba àwọn Júù, kí wọ́n sì mú kí Hesekáyà túúbá fún wọn. (2 Ọba 18:17-25) Hesekáyà wá rán Élíákímù pé kó lọ rí àwọn tí Senakéríbù rán wá, Élíákímù àtàwọn méjì míì ni wọ́n sì jọ lọ. Ọ̀kan nínú wọn ni Ṣébínà tó ti wá di akọ̀wé báyìí. Ǹjẹ́ èyí kì í ṣe ẹ̀rí pé Ṣébínà gba ìbáwí tí Jèhófà fún un? Kò ráhùn, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fìrẹ̀lẹ̀ gba iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ tí wọ́n fún un. w18.03 25 ¶7-8, 10
Tuesday, July 2
Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.—Gál. 5:16.
Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tara tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọkàn rẹ sábà máa ń fà sí, má jẹ́ kó sú ẹ. Máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Jèhófà á yí èrò inú rẹ pa dà débi pé àwọn nǹkan tó tọ́ láá máa wà lọ́kàn rẹ. (Lúùkù 11:13) Ẹ rántí àpọ́sítélì Pétérù. Àwọn ìgbà kan wà tí kò ṣe ohun tó yẹ kí ẹni tẹ̀mí ṣe. (Mát. 16:22, 23; Lúùkù 22:34, 54-62; Gál. 2:11-14) Àmọ́ kò jẹ́ kó sú òun. Jèhófà ràn án lọ́wọ́ débi pé nígbà tó yá, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi ti Kristi. Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. Nígbà tó yá, Pétérù sọ àwọn ànímọ́ kan tó yẹ ká sapá láti ní. (2 Pét. 1:5-8) Bá a ṣe ń sapá gidigidi láti ní àwọn ànímọ́ bí ìkóra-ẹni-níjàánu, ìfaradà àti ìfẹ́ni ará, ṣe làá túbọ̀ máa dẹni tẹ̀mí. Ó yẹ ká máa bi ara wa lójoojúmọ́ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe lónìí yìí táá mú kí n túbọ̀ dẹni tẹ̀mí?’w18.02 25-26 ¶12-13
Wednesday, July 3
Mo ti fi àsọjáde ẹnu rẹ̀ ṣúra ju ohun tí a lànà sílẹ̀ fún mi.—Jóòbù 23:12.
Jóòbù lóye àwọn ìlànà Ọlọ́run dáadáa. Ó mọ Jèhófà lóòótọ́, ohun tó sì mọ̀ nípa Jèhófà jẹ́ kó ṣe ohun tó tọ́. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan. Jóòbù mọ̀ pé òun ò lè sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kóun sì tún máa hùwà ìkà sáwọn èèyàn. (Jóòbù 6:14) Kò gbé ara rẹ̀ ga ju àwọn míì lọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa ń fàánú hàn sí gbogbo èèyàn yálà olówó ni wọ́n tàbí tálákà. Jóòbù tiẹ̀ sọ pé: “Kì í ha ṣe Ẹni tí ó ṣẹ̀dá mi nínú ikùn ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀”? (Jóòbù 31:13-22) Ó ṣe kedere pé nígbà tí Jóòbù lówó tó sì lẹ́nu láwùjọ, kò fojú pa àwọn míì rẹ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ìwà táwọn olówó àtàwọn gbajúmọ̀ òde òní máa ń hù! Jóòbù ò jẹ́ kí nǹkan míì ṣe pàtàkì sóun ju Jèhófà lọ, títí kan àwọn ohun ìní tara. Ó mọ̀ pé tí òun bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ti sẹ́ “Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wà lókè” nìyẹn. (Jóòbù 31:24-28) Jóòbù mọ̀ pé ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó tó wà láàárín ọkọ àti ìyàwó. Kódà, ó bá ojú rẹ̀ dá májẹ̀mú pé òun ò ní tẹjú mọ́ obìnrin míì.—Jóòbù 31:1. w18.02 11 ¶16; 12 ¶18-19
Thursday, July 4
[Nóà] fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.—Jẹ́n. 6:9.
Kì í ṣe bí Nóà ṣe máa rí ojú rere Ọlọ́run nìkan ló jẹ ẹ́ lógún. Bíbélì tún sọ pé Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo,” torí ó fìgboyà sọ ohun tí Jèhófà máa ṣe fáwọn èèyàn. (2 Pét. 2:5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí, ó dá ayé lẹ́bi.” (Héb. 11:7) Ó ṣeé ṣe kí Nóà kojú àtakò kí wọ́n sì fi ṣe yẹ̀yẹ́, kódà wọ́n tiẹ̀ lè halẹ̀ mọ́ ọn láwọn ìgbà míì. Àmọ́ kò ‘wárìrì nítorí àwọn èèyàn.’ (Òwe 29:25) Dípò kó máa bẹ̀rù, ṣe ló ń fìgboyà ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Lẹ́yìn tí Nóà ti bá Ọlọ́run rìn fún ohun tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ọdún lọ, Ọlọ́run sọ fún un pé kó kan ọkọ̀ áàkì láti fi gba àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko là. (Jẹ́n. 5:32; 6:14) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ tó ń kani láyà gan-an ni, ṣe ló dà bíi pé kò ṣeé ṣe láé. Nóà sì mọ̀ pé iṣẹ́ yìí máa jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ máa fi òun ṣe yẹ̀yẹ́. Síbẹ̀, ó lo ìgbàgbọ́, ó sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe. Bíbélì sọ pé: “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”—Jẹ́n. 6:22. w18.02 4 ¶4, 6-7
Friday, July 5
Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!—Sm. 133:1.
Ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà mú kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa nífẹ̀ẹ́ bíi ti Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Ó dájú pé kò sẹ́nì kankan lára wa tó máa sọ nípa àwọn ará míì pé, “Ṣebí wọ́n ṣáà ti ní ká nífẹ̀ẹ́, mo lè nífẹ̀ẹ́ wọn, àmọ́ kò jù bẹ́ẹ̀ lọ”! Irú èrò bẹ́ẹ̀ lòdì sí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá pé ká máa ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́.’ (Éfé. 4:2) Kì í wulẹ̀ ṣe pé ká kàn máa ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ Ó tún fi kún un pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ “nínú ìfẹ́.” Ẹ kíyè sí i pé ìyàtọ̀ wà níbẹ̀. Onírúurú èèyàn ló wà nínú ìjọ wa, Jèhófà ló sì fa gbogbo wọn wá ṣọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jòh. 6:44) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fà wọ́n ṣọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó dájú pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Báwo la ṣe máa wá sọ pé Kristẹni kan ò yẹ lẹ́ni téèyàn nífẹ̀ẹ́? Torí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa dénú, kì í ṣe ìfẹ́ ojú lásán!—1 Jòh. 4:20, 21. w18.01 16 ¶14
Saturday, July 6
Rántí . . . Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.—Oníw. 12:1.
Àwọn òbí kan ti ronú pé ó máa dáa káwọn ọmọ wọn kọ́kọ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga tàbí kí wọ́n níṣẹ́ gidi lọ́wọ́ kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. Lóòótọ́, ó lè jẹ́ bí nǹkan ṣe máa dáa fáwọn ọmọ náà ni wọ́n ń wá, àmọ́ ṣé ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn ọmọ náà ní ojúlówó ayọ̀? Ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ṣé irú èrò bẹ́ẹ̀ bá Ìwé Mímọ́ mu? Ó ṣe pàtàkì ká máa rántí pé gbogbo ohun tó wà nínú ayé Èṣù yìí ló tako ohun tí Jèhófà fẹ́. (Ják. 4:7, 8; 1 Jòh. 2:15-17; 5:19) Àjọṣe tó dáa tí ọmọ kan ní pẹ̀lú Jèhófà ló máa dáàbò bò ó lọ́wọ́ Sátánì àti ayé búburú yìí. Tó bá jẹ́ pé bí ọmọ kan ṣe máa lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga àti bó ṣe máa níṣẹ́ gidi lọ́wọ́ làwọn òbí rẹ̀ ń lé, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ lè rò pé ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé nìyẹn, èyí sì lè ṣàkóbá fún un. Ohun táyé yìí fẹ́ káwọn èèyàn máa rò ni pé ó dìgbà téèyàn bá wà nípò ńlá kó tó láyọ̀. Ṣé àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn sì máa fẹ́ kí ọmọ wọn ní irú èrò bẹ́ẹ̀? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìgbà téèyàn bá fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀ nìkan ló tó lè ní ayọ̀ tòótọ́ kó sì ṣàṣeyọrí.—Sm. 1:2, 3. w18.03 10-11 ¶10-11
Sunday, July 7
[Wá] Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.—Mát. 6:33.
Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé àwọn ń láyọ̀ àwọn sì túbọ̀ ń ráyè sin Jèhófà báwọn ṣe jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ àwọn lọ́rùn. Arákùnrin Jack ta ilé àti ilé iṣẹ́ rẹ̀ kó lè ráyè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà bíi ti ìyàwó rẹ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ló jẹ́ pé inú mi kì í dùn tí mo bá dé láti ibi iṣẹ́, nítorí àwọn ìṣòro tí mo máa ń kojú níbẹ̀. Àmọ́ ṣe ni inú ìyàwó mi tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé máa ń dùn ní tiẹ̀. Ó máa ń sọ fún mi pé, ‘Ọ̀gá tó dáa jù lọ ni mò ń bá ṣiṣẹ́!’ Ní báyìí témi náà ti di aṣáájú-ọ̀nà, a ti jọ wà lábẹ́ Ọ̀gá kan náà, ìyẹn Jèhófà.” Tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ owó, á dáa ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí, ká má sì tan ara wa jẹ. A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ nípa owó, ṣé àwọn ìlànà yẹn ló sì ń darí mi? Ṣé bí mo ṣe máa lówó ló gbawájú láyé mi? Ṣé àwọn nǹkan tara ló jẹ mí lógún jù àbí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn èèyàn? Ṣé mo gbà lóòótọ́ pé Jèhófà lè bójú tó àwọn ohun tí mo nílò?’ Ó dá wa lójú pé Jèhófà kò ní já àwọn tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ kulẹ̀, ó ṣe tán, adúró-ti-Olúwa kò ní jogún òfo. w18.01 25 ¶12-13
Monday, July 8
Lọ́nà tí ẹ ń gbà ṣègbọràn nígbà gbogbo, . . . ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.—Fílí. 2:12.
O ti rí i pé iṣẹ́ ńlá ni tó o bá máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí. Ó ṣe kedere pé o gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì kó o sì máa ṣàṣàrò, kó o máa gbàdúrà, kó o sì máa ronú nípa àwọn ìbùkún tó o ti rí. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, á jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà, wàá sì máa fi ìdánilójú sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì. (Sm. 73:28) Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mát. 16:24) Kò sí àní-àní pé kẹ́nì kan tó lè di ọmọlẹ́yìn Kristi, ó gbọ́dọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìbùkún lo máa rí nísinsìnyí, wàá sì tún gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé kó o rí i dájú pé o ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí! w17.12 27 ¶18-19
Tuesday, July 9
Ẹ fi . . . ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.—Kól. 3:12.
Táwọn òbí bá ń fi sùúrù kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, á ṣeé ṣe fáwọn ọmọ wọn láti lóye “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́. (Éfé. 3:18) Ẹ máa lo àwọn ìtẹ̀jáde tó bá ọjọ́ orí wọn mu, tí wọ́n á sì tètè lóye. Bí ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣe túbọ̀ ń dá wọn lójú, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ rọrùn fún wọn láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì títí kan àwọn ọmọléèwé wọn. (1 Pét. 3:15) Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn ọmọ rẹ lè ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? Ǹjẹ́ àlàyé tí Bíbélì ṣe dá àwọn ọmọ rẹ lójú? Ó ṣe kedere pé kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó lè wọ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn, wàá ní láti mú sùúrù. Àmọ́, gbogbo ìsapá rẹ láti mú kí wọ́n lóye òtítọ́ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Diu. 6:6, 7) Àpẹẹrẹ ẹ̀yin òbí tún ṣe pàtàkì tẹ́ ẹ bá fẹ́ káwọn ọmọ yín nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Arábìnrin Stephanie, tó ní ọmọbìnrin mẹ́ta sọ pé: ‘Mo máa ń bi ara mi pé ṣé mo máa ń jẹ́ káwọn ọmọ mi mọ ìdí tí mo fi gbà pé Jèhófà wà lóòótọ́, pé ó nífẹ̀ẹ́ wa àti pé àwọn ìlànà rẹ̀ bọ́gbọ́n mu? Mi ò lè retí pé kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn tí kò bá jinlẹ̀ lọ́kàn tèmi alára.’ w17.12 20 ¶8-10
Wednesday, July 10
Arákùnrin rẹ yóò dìde.—Jòh. 11:23.
Kí ló mú kó dá Màtá lójú pé arákùnrin rẹ̀ yóò jíǹde? Àwọn iṣẹ́ ìyanu táwọn wòlíì ti ṣe kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló jẹ́ kí Màtá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú bẹ́ẹ̀. Ìgbà tí Màtá wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti kọ́ nípa àwọn àjíǹde yìí nílé àti nínú sínágọ́gù. Ó ṣeé ṣe kó rántí àwọn àjíǹde mẹ́ta tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Nígbà tí Èlíjà wà láyé, Ọlọ́run fún un lágbára láti jí òkú dìde, ìyẹn sì ni àjíǹde àkọ́kọ́ tó wáyé. Ní Sáréfátì, ìyẹn ìlú kan tó wà ní etíkun Fòníṣíà, opó aláìní kan fi inú rere hàn sí wòlíì Èlíjà. Ọlọ́run wá mú kí ìyẹ̀fun àti òróró obìnrin náà pọ̀ lọ́nà ìyanu débi pé obìnrin náà àti ọmọ rẹ̀ ń jẹun lọ títí ìyàn tó mú nígbà yẹn fi dópin. (1 Ọba 17:8-16) Nígbà tó yá, ọmọ obìnrin náà ṣàìsàn, ó sì kú. Bí Èlíjà ṣe wá ràn án lọ́wọ́ nìyẹn. Èlíjà na ara lé òkú ọmọ náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé: “Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ọkàn ọmọ yìí padà wá sínú rẹ̀.” Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Èlíjà, ẹ̀mí ọmọ náà sì pa dà sínú rẹ̀. Àjíǹde àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn nìyẹn. (1 Ọba 17:17-24) Ó dájú pé Màtá ti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu yìí. w17.12 3 ¶1; 4 ¶3, 5-6
Thursday, July 11
Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.—Mát. 6:24.
Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rọ̀ wá pé ká kàwé dáadáa, ká sì tẹra mọ́ṣẹ́ ká lè tètè dépò gíga. Wọ́n gbà pé tá a bá wà nípò gíga lẹ́nu iṣẹ́, àá gbayì, àá lẹ́nu láwùjọ àá sì rí towó ṣe. Torí pé ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lé nìyẹn, Kristẹni kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í nírú èrò yìí. Ṣé òótọ́ ni pé èèyàn á ní ojúlówó ayọ̀ téèyàn bá wà nípò gíga lẹ́nu iṣẹ́, téèyàn sì gbayì láwùjọ? Rárá o. Ṣé o rántí pé ohun tó mú kí Sátánì kẹ̀yìn sí Ọlọ́run ni pé ó fẹ́ káwọn èèyàn máa wárí fún òun, kóun sì máa darí wọn? Àmọ́ ṣéyẹn mú kó láyọ̀? Rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń bínú. (Mát. 4:8, 9; Ìṣí. 12:12) Lónìí, à ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ táá jẹ́ kí wọ́n ní ìyè àìnípẹ̀kun, èyí sì ń fún wa láyọ̀. Kò sí bí ipò èèyàn ṣe lè ga tó nídìí iṣẹ́ èyíkéyìí táá ní irú ayọ̀ tá à ń rí. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí ìbánidíje ló gba ayé kan, ó ń mú káwọn èèyàn máa wá bí wọ́n á ṣe ta àwọn míì yọ, ó sì ń mú kí wọ́n máa jowú ara wọn. Á wá di asán lórí asán àti “lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníw. 4:4. w17.11 23 ¶11-13
Friday, July 12
Lẹ́yìn kíkọrin ìyìn, wọ́n jáde lọ sí Òkè Ńlá Ólífì.—Mát. 26:30.
Nígbà tí Jésù wà láyé, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú orin kíkọ nínú ìjọsìn wọn. Bí àpẹẹrẹ, lálẹ́ ọjọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn, Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì kọrin lẹ́yìn tí wọ́n ṣe tán. Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá di pé ká fi orin yin Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ilé àdáni ni wọ́n ti sábà máa ń péjọ, wọn ò jẹ́ kíyẹn dí wọn lọ́wọ́ àtimáa fìtara kọrin sí Jèhófà. Kódà, Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ìgbà yẹn ní ìtọ́ni, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní kíkọ́ ara yín àti ní ṣíṣí ara yín létí lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú àwọn sáàmù, àwọn ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin tẹ̀mí pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, kí ẹ máa kọrin nínú ọkàn-àyà yín sí Jèhófà.” (Kól. 3:16) Àwọn orin tẹ̀mí ló wà nínú ìwé orin wa, ó sì yẹ ká máa fi ẹ̀mí ìmoore kọ wọ́n. Àwọn orin yìí wà lára oúnjẹ tẹ̀mí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè fún wa.—Mát. 24:45. w17.11 4 ¶7-8
Saturday, July 13
Yan àwọn ìlú ńlá tí ó wọ̀ fún ara yín. Wọn yóò jẹ́ àwọn ìlú ńlá ìsádi fún yín.—Núm. 35:11.
Ó rọrùn fáwọn èèyàn láti dé àwọn ìlú ààbò mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣètò ìlú ààbò mẹ́ta sí apá ọ̀tún Odò Jọ́dánì àti mẹ́ta míì sí apá òsì. Ìdí sì ni pé ó fẹ́ kó rọrùn fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn láti tètè dé ìlú ààbò tó sún mọ́ ọn jù. (Núm. 35:12-14) Wọ́n máa ń bójú tó ọ̀nà tó lọ sáwọn ìlú ààbò náà dáadáa. (Diu. 19:3) Wọ́n sì máa ń gbé àwọn àmì sójú ọ̀nà láti tọ́ka síbi tí ìlú ààbò wà. Torí pé kò ṣòro láti dé àwọn ìlú ààbò yẹn, ẹni tó ṣèèṣì pààyàn ò ní sá lọ sórílẹ̀-èdè míì, kó má bàa di pé á dara pọ̀ mọ́ àwọn abọ̀rìṣà. Rò ó wò ná: Jèhófà ló ní kí wọ́n pa ẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn, òun náà ló sì ní kí wọ́n fàánú hàn sí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn, kí wọ́n sì dáàbò bò ó. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Òfin yẹn ṣe kedere, ó rọrùn, kò sì nira láti tẹ̀ lé. Ó jẹ́ ká rí i pé aláàánú ni Ọlọ́run.” Jèhófà kì í ṣe òǹrorò, tí kò mọ̀ ju kó máa fìyà jẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú àánú.”—Éfé. 2:4. w17.11 14 ¶4-5
Sunday, July 14
Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.—Sek. 1:3.
Àkájọ ìwé kan tó ń fò lókè, obìnrin kan tí wọ́n dé mọ́nú apẹ̀rẹ̀ ńlá àtàwọn obìnrin méjì tí wọ́n ní ìyẹ́ apá bíi ti ẹyẹ àkọ̀, tí wọ́n sì ń fò lójú ọ̀run. (Sek. 5:1, 7-9) Kí nìdí tí Jèhófà fi fi ìran yìí han wòlíì náà? Ìkìlọ̀ gidi ni ìran kẹfà àti keje tí Sekaráyà rí jẹ́ fún àwọn tó ń jalè tàbí tó ń hùwà àìṣòótọ́ èyíkéyìí. Ó tún rán wa létí pé Jèhófà kò ní fàyè gba ìwà burúkú èyíkéyìí. Bákan náà, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ kórìíra ìwà burúkú ní gbogbo ọ̀nà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìran yẹn tún jẹ́ káwọn ìlérí Baba wa ọ̀run túbọ̀ dá wa lójú. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múnú Ọlọ́run dùn, a ò ní sí lára àwọn tí Jèhófà máa gégùn-ún fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dáàbò bò wá, á sì bù kún wa. Ká má ṣe jẹ́ kó sú wa bá a ṣe ń sapá láti wà ní mímọ́ nínú ayé búburú yìí torí pé ìsapá wa kò ní já sásán. Ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. w17.10 21 ¶1; 25 ¶19
Monday, July 15
Kí àwọn àgbàlagbà obìnrin jẹ́ onífọkànsìn nínú ìhùwàsí, . . . kí wọ́n lè pe orí àwọn ọ̀dọ́bìnrin wálé.—Títù 2:3, 4.
Ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ló wà fún àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n lè lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, wọ́n lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ, wọ́n sì lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn kan lára wọn tiẹ̀ ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára àwọn àgbà obìnrin lè má fi bẹ́ẹ̀ gbé ọ̀pọ̀ lára àwọn iṣẹ́ yìí, síbẹ̀ iṣẹ́ ribiribi ní wọ́n ń ṣe nínú ìjọ. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fi àwọn arábìnrin yìí jíǹkí wa! Lóòótọ́ agbára wọn lè má fi bẹ́ẹ̀ gbé ohun tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà, síbẹ̀ wọ́n ṣì ń fi ìgboyà ṣe ohun tágbára wọn gbé. Bí àpẹẹrẹ, ó gba ìgboyà tí wọ́n bá ní kí àgbà obìnrin kan bá ọ̀dọ́bìnrin kan sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ń múra. Àgbà obìnrin náà kò ní kàn án lábùkù, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa gbà á níyànjú pé kó ṣàtúnṣe káwọn míì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. (1 Tím. 2:9, 10) Táwọn àgbà obìnrin bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á gbé ìjọ ró. w17.09 31-32 ¶17-18
Tuesday, July 16
Ìwọ yóò rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.—Òwe 2:5.
Àwọn ìgbà kan wà táwọn aláṣẹ kò jẹ́ káwọn aráàlú ní Bíbélì. Àmọ́, àwọn kan tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fàáké kọ́rí pé kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti John Wycliffe tó gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá. Ọkùnrin yìí gbà pé gbogbo èèyàn ló yẹ kó ní Bíbélì kí wọ́n sì máa kà á. Àmọ́ lásìkò tá à ń sọ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè England ni kò ní Bíbélì. Nígbà tó yá, John Wycliffe túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde lọ́dún 1382. Kíá làwọn Lollard, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Wycliffe bẹ̀rẹ̀ sí í lo Bíbélì náà. Wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn láti abúlé kan sí òmíì lórílẹ̀-èdè England kí wọ́n lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n máa ń ka Bíbélì Wycliffe fún àwọn èèyàn tí wọ́n bá pàdé, wọ́n á sì fún wọn ní apá kan ẹ̀dà rẹ̀ tí wọ́n fọwọ́ kọ. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn kan nílẹ̀ Yúróòpù àti láwọn ilẹ̀ míì bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sáwọn èdè míì, wọ́n sì ń pín in fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. w17.09 20-21 ¶10-12
Wednesday, July 17
Àwọn tí wọ́n [gbéyàwó] yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.—1 Kọ́r. 7:28.
‘Ìpọ́njú nínú ẹran ara’ náà ni àìrọ́mọbí jẹ́. (Òwe 13:12) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ohun ìtìjú àti ìbànújẹ́ ló máa ń jẹ́ fún obìnrin tí kò rọ́mọ bí. Bí àpẹẹrẹ, inú Rákélì ìyàwó Jékọ́bù kò dùn bó ṣe ń rí i tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń bímọ lémọ. (Jẹ́n. 30:1, 2) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó, ìṣòro kan wà tí kì í sábà wá síni lọ́kàn, ìyẹn kéèyàn pàdánù ọkọ tàbí aya rẹ̀. Àdánù ńlá ni ikú ọkọ tàbí aya jẹ́, èyí sì ti fa ìṣòro tó lé kenkà fún ọ̀pọ̀. Àwọn tí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí kì í ronú pé ó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn láé. Àmọ́ a dúpẹ́ pé a nírètí àjíǹde bí Jésù ti ṣèlérí. (Jòh. 5:28, 29) Kí ni ìrètí yìí lè ṣe fún ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú? Ó máa tù ú nínú, á sì fi í lọ́kàn balẹ̀. Ọ̀nà kan rèé tí Jèhófà Baba wa ń gbà fi Bíbélì tù wá nínú nígbà ìṣòro. w17.06 4 ¶1; 5 ¶6; 6 ¶9
Thursday, July 18
Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́.—Ẹ́kís. 34:6.
Ìgbà kan wà tí Jèhófà polongo orúkọ rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ fún Mósè. Ohun tí Jèhófà kọ́kọ́ mẹ́nu kàn ni bóun ṣe jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́. (Ẹ́kís. 34:5-7) Jèhófà lè kọ́kọ́ sọ bóun ṣe lágbára tó àti bọ́gbọ́n òun ṣe jinlẹ̀ tó. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kó dá Mósè lójú pé òun máa tì í lẹ́yìn ló sọ. (Ẹ́kís. 33:13) Síbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àánú wà lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà dá mọ́ wa, àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù kì í jẹ́ ká fàánú hàn nígbà míì. Kì í rọrùn fún wa láti pinnu bóyá ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tàbí ká má ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ìgbà tó yẹ káwọn fàánú hàn àti ìgbà tí kò yẹ. Kí láá jẹ́ kó o mọ̀gbà tó yẹ kó o fàánú hàn? Àkọ́kọ́, fara balẹ̀ ronú lórí bí Jèhófà ṣe fàánú hàn àti báwọn míì náà ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Èkejì, ronú nípa bó o ṣe lè fara wé Jèhófà àti àǹfààní tó o máa rí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. w17.09 8 ¶1; 9 ¶3
Friday, July 19
Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.—Fílí. 2:3.
Ó yẹ ká ní èrò tó tọ́ nípa fífi àkọ́pọ̀ ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ. Kò yẹ kó jẹ́ torí káwọn èèyàn lè máa yìn wá la ṣe ń gbé àkọ́pọ̀ ìwà tuntun wọ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ torí àtibọlá fún Jèhófà. Ẹ rántí pé áńgẹ́lì pípé kan di aláìṣòótọ́ torí pé ó jẹ́ kí ìgbéraga wọ òun lẹ́wù. (Fi wé Ìsíkíẹ́lì 28:17.) Tí áńgẹ́lì pípé kan bá lè di agbéraga, ẹ ò rí i pé ó máa gba ìsapá gan-an fáwa èèyàn aláìpé láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Síbẹ̀, a lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara wa láṣọ. Kí láá jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ká lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. (Diu. 17:18-20) Ní pàtàkì, ó yẹ ká máa ronú lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wa àti bó ṣe fi hàn pé òun ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. (Mát. 20:28) Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tó wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. (Jòh. 13:12-17) Tá a bá ń ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ, ó yẹ ká gbàdúrà pé kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn.—Gál. 6:3, 4. w17.08 25 ¶11-12
Saturday, July 20
Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.—Fílí. 4:6, 7.
Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti ṣe àwọn ìpinnu kan tó o gbà pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe lo ṣe, àmọ́ tí nǹkan ò wá rí bó o ṣe rò. Bóyá ṣe lo kan ìṣòro tàbí ohun kan ló ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé rẹ pa dà pátápátá. (Oníw. 9:11) Kí ni kò ní jẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, táá sì mú ká ní “àlàáfíà Ọlọ́run”? Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Fílípì pé àdúrà lòògùn àníyàn. Nígbà tá a bá ń ṣàníyàn, ṣe ló yẹ ká tú gbogbo ọkàn wa jáde nínú àdúrà. (1 Pét. 5:6, 7) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó yẹ kó dá wa lójú pé á gbọ́ wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ àwọn oore tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa. Tá a bá ń rántí pé Jèhófà “lè ṣe ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò,” ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ máa túbọ̀ lágbára.—Éfé. 3:20. w17.08 9 ¶4, 6; 10 ¶10
Sunday, July 21
Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.—Òwe 15:22.
Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n láyọ̀. O ò ṣe bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o lè fayé rẹ ṣe? Àwọn ẹni tẹ̀mí yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ pé iṣẹ́ aláyọ̀ ni iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, á sì mú kó o túbọ̀ ní ọgbọ́n táá ṣe ẹ́ láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Kódà lẹ́yìn tí Jésù ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run, ó tún gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nígbà tó ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. Bí àpẹẹrẹ, òun fúnra rẹ̀ rí i pé ayọ̀ wà nínú bóun ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run àti bóun ṣe jẹ́ olóòótọ́ lójú àdánwò. (Aísá. 50:4; Héb. 5:8; 12:2) Jésù sọ pé: ‘Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa kọ́ wọn.’ (Mát. 28:19, 20) Tó o bá pinnu pé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lo fẹ́ fayé rẹ ṣe, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìpinnu tó dáa jù lo ṣe yẹn torí pé á múnú Ọlọ́run dùn. Àmọ́ o, bíi tàwọn iṣẹ́ míì, wàá nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kó o tó lè di ọ̀jáfáfá. w17.07 23 ¶6-7
Monday, July 22
Emi fúnra mi yóò máa tù yín nínú.—Aísá. 66:13.
Tó bá di pé ká tu èèyàn nínú, kò sẹ́ni tó lè tuni nínú bíi Jèhófà Baba wa ọ̀run tó jẹ́ Ọlọ́run àánú. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ tún lè rí ìtùnú nínú ìjọ Kristẹni. (1 Tẹs. 5:11) Kí la lè ṣe láti tu àwọn “tí ìdààmú bá” nínú, ká sì gbé wọn ró? (Òwe 17:22) Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:7) Arábìnrin Dalene tọ́kọ rẹ̀ ti kú sọ pé: “Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń fẹ́ tú gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde. Torí náà, ohun tó dáa jù téèyàn lè ṣe fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ni pé kéèyàn tẹ́tí sí wọn dáadáa, kó má sì dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.” Arábìnrin Junia tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin pa ara rẹ̀ sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bó o ṣe lè lóye bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn gan-an, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kó o gbìyànjú láti fi ara rẹ sí ipò wọn.” Bákan náà, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa yàtọ̀ síra, ìyàtọ̀ sì wà nínú bí kálukú ṣe máa ń fi ẹ̀dùn ọkàn hàn. w17.07 13 ¶3; 14 ¶11-13
Tuesday, July 23
Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.—Sm. 83:18.
Owó lọ̀pọ̀ èèyàn kà sí pàtàkì jù lóde òní. Ohun tó jẹ wọ́n lógún kò ju bí wọ́n á ṣe dọlọ́rọ̀ tàbí bí ọlá wọn kò ṣe ní rẹ̀yìn. Ohun tó sì gba àwọn míì lọ́kàn kò ju ọ̀rọ̀ ìdílé wọn, ìlera wọn àti bí wọ́n ṣe máa mókè nínú nǹkan tí wọ́n dáwọ́ lé. Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kó gba aráyé lọ́kàn ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe jẹ́ kí ohun míì gbà wá lọ́kàn. Kí làwọn nǹkan míì tó tún lè gbà wá lọ́kàn? Ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu lè gbà wá lọ́kàn débi pé a lè má rántí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Àwọn ìṣòro wa sì lè gbà wá lọ́kàn débi pé a ò ní fohun tó ṣe pàtàkì jù yìí sọ́kàn mọ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, ó máa rọrùn fún wa láti kojú àwọn ìṣòro wa. Nípa bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. w17.06 22 ¶1-2
Wednesday, July 24
Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.—1 Kọ́r. 11:1.
Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn olórí ìdílé àtàwọn alàgbà tó mọyì ìṣàkóso Jèhófà kì í jẹ gàba lé àwọn tó wà lábẹ́ wọn lórí, bí ẹni pé wọ́n gbé ìjọba tiwọn kalẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Jèhófà ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù, ọ̀kan ni Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù kì í dójú ti àwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í fipá mú wọn ṣe ohun tó tọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń rọ̀ wọ́n. (Róòmù 12:1; Éfé. 4:1; Fílém. 8-10) Bí Jèhófà ṣe máa ń ṣe nǹkan nìyẹn. Torí náà, bó ṣe yẹ kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ máa ṣe nìyẹn. Báwo ló ṣe yẹ ká hùwà sáwọn tí Jèhófà yàn sípò? Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn, ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. À ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà. Ká tiẹ̀ sọ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ìpinnu tí wọ́n ṣe tàbí pé ìpinnu náà kò tẹ́ wa lọ́rùn, ẹ jẹ́ ká ṣègbọràn torí pé Jèhófà ló yàn wọ́n sípò. Ṣe làwọn èèyàn inú ayé máa ń fàáké kọ́rí tí wọn ò bá fara mọ́ ìpinnu táwọn aláṣẹ bá ṣe, àmọ́ tiwa ò rí bẹ́ẹ̀ torí pé Jèhófà ló ń ṣàkóso wa.—Éfé. 5:22, 23; 6:1-3; Héb. 13:17. w17.06 30 ¶14-15
Thursday, July 25
Ọlọ́run ti kọ́ . . . yín láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.—1 Tẹs. 4:9.
Yálà wọ́n jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, ẹ jẹ́ ká dúró tì wọ́n, ká tù wọ́n nínú, ká sì gbé wọn ró. (Òwe 12:25; Kól. 4:11) Tá a bá jẹ́ kó ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé ọ̀rọ̀ “àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́” jẹ wá lọ́kàn, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́. (Gál. 6:10) Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé búburú yìí, àwọn èèyàn máa jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan àti oníwọra. (2 Tím. 3:1, 2) Torí náà, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ sapá gan-an kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ òtítọ́ àtàwọn ará wa má bàa di tútù. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan lè fa èdèkòyédè láàárín àwa àti ẹnì kan nínú ìjọ. Síbẹ̀ ó máa dáa, á sì ṣe gbogbo wa láǹfààní tá a bá fìfẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ náà nítùbí-ìnùbí. (Éfé. 4:32; Kól. 3:14) Torí náà, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ará wa túbọ̀ máa lágbára sí i. w17.05 21 ¶17-18
Friday, July 26
Bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: “Àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan,” a ń ṣi ara wa lọ́nà ni.—1 Jòh. 1:8.
Àwa Kristẹni mọ̀ pé kò sí káwọn èèyàn inú ayé má hùwà àìṣòdodo sí wa. Àmọ́ tá a bá kíyè sí ohun tó jọ àìṣe ìdájọ́ òdodo nínú ìjọ tàbí pé ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, ó lè ṣòro fún wa láti fara dà á. Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kí lo máa ṣe? Ṣé wàá jẹ́ kíyẹn mú ẹ kọsẹ̀? Torí pé aláìpé ni gbogbo wa, a sì máa ń dẹ́ṣẹ̀, ó ṣeé ṣe kẹ́nì kan hùwà àìdáa sí wa nínú ìjọ, ó sì lè jẹ́ àwa la máa hùwà àìdáa sáwọn míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé ó lè ṣẹlẹ̀, torí náà kì í yà wọ́n lẹ́nu tó bá ṣẹlẹ̀, wọn kì í sì í jẹ́ kó mú wọn kọsẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fún wa ní àwọn ìmọ̀ràn tó máa ràn wá lọ́wọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tá a bá fi wọ́n sílò, a ò ní kọsẹ̀ kódà táwọn ará bá hùwà àìdáa sí wa.—Sm. 55:12-14. w17.04 19 ¶4-5
Saturday, July 27
Àwọn tí wọ́n [gbéyàwó] yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.—1 Kọ́r. 7:28.
Tí ọkọ tàbí aya rẹ kò bá sin Jèhófà, ìyẹn lè mú kí nǹkan túbọ̀ nira nínú ìgbéyàwó rẹ. Ti pé ọkọ tàbí aya rẹ kò sin Jèhófà kò túmọ̀ sí pé kẹ́ ẹ pínyà tàbí pé kẹ́ ẹ kọ ará yín sílẹ̀. (1 Kọ́r. 7:12-16) Lóòótọ́, ọkọ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kò ní lè múpò iwájú nínú ìdílé tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn, síbẹ̀ ó yẹ kí ìyàwó rẹ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un torí pé òun ni olórí ìdílé. Tó bá sì jẹ́ pé aya ni kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, ó yẹ kí ọkọ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí máa gba ti aya rẹ̀ rò, kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú, kó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀. (Éfé. 5:22, 23, 28, 29) Kí ni wàá ṣe tí ọkọ tàbí aya rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá fẹ́ kó o dín bó o ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà kù? Bí àpẹẹrẹ, ọkọ arábìnrin kan sọ àwọn ọjọ́ pàtó tóun lè yọ̀ǹda fún un láti máa lọ sóde ẹ̀rí láàárín ọ̀sẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ohun tó ń sọ ni pé kí n má sin Jèhófà mọ́? Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé mo lè ṣe ohun tó fẹ́?’ Tó o bá ń gba tẹnì kejì rẹ rò, kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí àìgbọ́ra-ẹni-yé láàárín yín.—Fílí. 4:5. w17.10 13 ¶7-8
Sunday, July 28
Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ.—Diu. 6:7.
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” ló ń wá sínú ètò Ọlọ́run. (Sek. 8:23) Àmọ́ nígbà míì, ìṣòro èdè lè mú kó ṣòro fún àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ẹ máa rántí pé àwọn tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kẹ́ ẹ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì làwọn ọmọ yín. Tí wọ́n bá sì máa rí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú àfi kí wọ́n mọ Jèhófà. (Jòh. 17:3) Kẹ́ ẹ tó lè kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà, ẹ gbọ́dọ̀ ‘máa sọ̀rọ̀ nípa’ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. (Diu. 6:6, 7) Àwọn ọmọ rẹ máa kọ́ èdè tí wọ́n ń sọ nílùú tẹ́ ẹ kó lọ níléèwé tàbí kí wọ́n kọ́ ọ ládùúgbò. Àmọ́ wọ́n máa gbọ́ èdè ìbílẹ̀ yín dáadáa tẹ́ ẹ bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ déédéé lédè yín. Táwọn ọmọ yín bá gbọ́ èdè ìbílẹ̀ yín dáadáa, ọ̀rọ̀ yín á yéra yín. Bákan náà, wọ́n á gbọ́ ju èdè kan lọ, èyí sì máa ṣe wọ́n láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, òye tí wọ́n ní máa pọ̀ sí i, wọ́n á sì lè mọ bí wọ́n á ṣe máa ṣe láwùjọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á tún lè mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i. w17.05 9 ¶5-6
Monday, July 29
Lọ, kí o sì tan ara rẹ ká orí Òkè Ńlá Tábórì. . . . Èmi yóò sì fa Sísérà . . . wá bá ọ, . . . èmi yóò sì fi í lé ọ lọ́wọ́.—Oníd. 4:6, 7.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní nǹkan ìjà tí wọ́n lè fi gbéjà ko àwọn ọ̀tá wọn, wọn ò sì léyìí tí wọ́n á fi dáàbò bo ara wọn tógun bá dé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun onídòjé irin làwọn ọ̀tá wọn ní. (Oníd. 4:1-3, 13; 5:6-8) Síbẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fún Bárákì. Bárákì ò fi nǹkan falẹ̀ rárá láti ṣe ohun tí Jèhófà sọ pé kó ṣe. (Oníd. 4:14-16) Bí wọ́n ṣe ń jagun ní Táánákì, ọ̀wààrà òjò ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, gbogbo ilẹ̀ sì di ẹrẹ̀. Làwọn ọmọ ogun Sísérà bá fẹsẹ̀ fẹ, Bárákì sì lé wọn títí wọ́n fi dé Háróṣétì, tó wà ní nǹkan bíi máìlì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (24 km) sí Táánákì. Nígbà tí Sísérà débì kan, ó sọ̀kalẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Kẹ̀kẹ́ ogun tó ń bani lẹ́rù wá dèyí tí kò wúlò mọ́. Sísérà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sáré títí ó fi dé Sáánánímù, tó ṣeé ṣe kó wà nítòsí Kédéṣì. Ó sá wọnú àgọ́ Jáẹ́lì aya Hébà tó jẹ́ ará Kénì, kó lè forí pa mọ́, Jáẹ́lì sì gbà á sílé. Ó ti rẹ Sísérà tẹnutẹnu, torí náà kò pẹ́ tó sùn lọ fọnfọn. Ni Jáẹ́lì bá ṣọkàn akin, ó sì pa ọkùnrin náà. (Oníd. 4:17-21) Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rẹ́yìn ọ̀tá wọn nìyẹn! w17.04 29-30 ¶6-8
Tuesday, July 30
Ìjà kan wà tí Jèhófà ní pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè. . . . Ní ti àwọn ẹni burúkú, òun yóò fi wọ́n fún idà.—Jer. 25:31.
Ṣé ètò míì máa wà láyé yìí lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì? Bíbélì sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pét. 3:13) Ọ̀run àti ayé ògbólógbòó yìí kò ní sí mọ́, ìyẹn àwọn ìjọba búburú àtàwọn èèyàn burúkú abẹ́ wọn. Kí ló máa wá rọ́pò wọn? Gbólóhùn náà, “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” túmọ̀ sí ìjọba tuntun tó máa ṣàkóso ayé àti àwọn èèyàn tuntun tó máa ṣàkóso lé lórí. Jésù Kristi tó jẹ́ ọba Ìjọba náà máa ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ètò. (1 Kọ́r. 14:33) Torí náà, àwọn nǹkan máa wà létòlétò nínú “ayé tuntun.” Àwọn ọkùnrin rere láá máa bójú tó àwọn nǹkan. (Sm. 45:16) Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n á jọ ṣàkóso láá máa darí àwọn ọkùnrin yẹn. Ẹ wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí ètò kan ṣoṣo, tó jẹ́ mímọ́, tó sì wà níṣọ̀kan bá rọ́pò àwọn ètò búburú ayé yìí! w17.04 11 ¶8-9
Wednesday, July 31
Wọn yóò sì di ara kan.—Jẹ́n. 2:24.
Ohun mímọ́ ni ìgbéyàwó jẹ́. Ìṣojú àwọn ẹlẹ́rìí ni tọkọtaya náà ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ara wọn. Wọ́n máa ń ṣèlérí pé wọ́n á nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n á máa ṣìkẹ́ ara wọn, wọ́n á sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Wọ́n máa ń sọ pé àwọn á ṣe bẹ́ẹ̀ “níwọ̀n ìgbà tí [àwọn] méjèèjì bá fi jọ wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe.” Ọ̀rọ̀ táwọn míì sọ lè yàtọ̀ sí èyí, àmọ́ àwọn náà ṣì jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa ń kéde pé wọ́n ti di tọkọtaya àti pé títí lọ gbére ló fi yẹ kí wọ́n jọ wà. (1 Kọ́r. 7:39) Jésù sọ pé, “nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀,” kódà ọkọ tàbí aya tàbí ẹlòmíì kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, àwọn tọkọtaya tó ń ṣègbéyàwó kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé bọ́rọ̀ ò bá wọ̀, àwọn á kọ ara àwọn sílẹ̀. (Máàkù 10:9) Kò sí bí tọkọtaya ṣe lè mọ̀ ọ́n ṣe tó táwọn kùdìẹ̀ kudiẹ kan ò ní máa jẹ yọ nínú ìgbéyàwó wọn. Ìdí sì ni pé aláìpé làwọn méjèèjì. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé àwọn tó ṣègbéyàwó á máa “ní ìpọ́njú.”—1 Kọ́r. 7:28. w17.04 7 ¶14-15