October
Tuesday, October 1
Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni.—Ják. 1:5.
Jèhófà ni orísun ọgbọ́n, ó sì máa ń fún àwọn míì ní ọgbọ́n rẹ̀. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ní ọgbọ́n Ọlọ́run ni pé ká máa gba ìbáwí rẹ̀. Ọgbọ́n yìí máa ń dáàbò bò wá, torí ó máa ń jẹ́ ká yẹra fáwọn nǹkan tí kò tọ́, ó sì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Òwe 2:10-12) Èyí máa jẹ́ ká lè “pa ara [wa] mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run . . . pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” (Júúdà 21) Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fún wa láti gba ìbáwí, lára ohun tó sì ń fà á ni àìpé wa, ibi tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà àtàwọn nǹkan míì. Àmọ́, tá a bá gbà pé torí pé Jèhófà fẹ́ràn wa ló ṣe ń bá wa wí, èyí máa mú ká mọyì ìbáwí rẹ̀. Òwe 3:11, 12 sọ pé: “Ìwọ ọmọ mi, má kọ ìbáwí Jèhófà, . . . nítorí pé ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà.” Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé, ire wa ni Jèhófà ń wá. (Héb. 12:5-11) Torí pé Jèhófà mọ̀ wá dáadáa, ìbáwí rẹ̀ máa ń tọ́, kò sì ní bá wa wí kọjá bó ṣe yẹ. w18.03 28 ¶1-2
Wednesday, October 2
Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.—1 Pét. 4:9.
Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí sáwọn Kristẹni tó wà láwọn ìjọ ní Éṣíà Kékeré. Onirúurú ẹ̀yà ni àwọn Kristẹni yìí ti wá, wọ́n sì ń fojú winá “àdánwò” tó le. Kí ló máa ran àwọn Kristẹni níbi gbogbo lọ́wọ́ lásìkò tí nǹkan ò dẹrùn yìí? (1 Pét. 1:1; 4:4, 7, 12) Ẹ kíyè sí i pé Pétérù gba àwọn Kristẹni yẹn níyànjú pé kí wọ́n ní ẹ̀mí aájò àlejò sí ‘ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì,’ ìyẹn sí àwọn tí wọ́n mọ̀ rí, tí wọ́n sì jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní? Ó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ra wọn. Ìwọ ńkọ́? Ṣé ẹnì kan ti gbà ẹ́ lálejò rí? Ṣé inú rẹ kì í dùn tó o bá ń rántí ọjọ́ náà? Nígbà tíwọ náà gba àwọn ará kan láti ìjọ yín lálejò, ó dájú pé ìyẹn mú kí àárín yín wọ̀ dáadáa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Tá a bá ń gba ara wa lálejò, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọ ara wa dáadáa ju bá a ṣe lè mọ ara wa nípàdé tàbí lóde ẹ̀rí. Ó yẹ káwọn Kristẹni ìgbà yẹn túbọ̀ sún mọ́ra gan-an torí bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i. Bó sì ṣe yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí.—2 Tím. 3:1. w18.03 14-15 ¶1-3
Thursday, October 3
Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.—Mát. 5:3.
Bíbélì sọ àwọn nǹkan dáadáa nípa àwọn ẹni tẹ̀mí. Ìwé Róòmù 8:6 sọ àǹfààní táwọn ẹni tẹ̀mí máa ń rí, ó ní: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú, ṣùgbọ́n gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” Èyí túmọ̀ sí pé tá a bá gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí, ní báyìí àárín àwa àti Ọlọ́run máa gún régé, àá sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Lọ́jọ́ iwájú, àá ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé inú ayé Èṣù là ń gbé. Torí pé ìfẹ́ tara ló gba àwọn èèyàn tó yí wa ká lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti di ẹni tẹ̀mí, ká má sì jó àjórẹ̀yìn. Tẹ́nì kan bá ń jó àjórẹ̀yìn nípa tẹ̀mí, kò ní lágbára mọ́, wẹ́rẹ́ báyìí ni “afẹ́fẹ́” ayé yìí máa gbé e ṣubú. Júúdà tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn sọ pé ipò ẹni tara máa ń burú débi pé á di “aláìní ìfẹ́ nǹkan tẹ̀mí.”—Júúdà 18, 19. w18.02 19 ¶5, 7; 20 ¶8
Friday, October 4
Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.—2 Tím. 3:13.
Ọ̀pọ̀ nọ́ọ̀sì àtàwọn dókítà ló ń tọ́jú àwọn tó ní àrùn tó lè ranni. Ìdí sì ni pé wọ́n fẹ́ ṣèrànwọ́ fún wọn. Àmọ́ bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn dáàbò bo ara wọn kí àrùn náà má bàa ràn wọ́n. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ wa là ń gbé tá a sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn tí ìwà àti ìṣe wọn lòdì sí ìlànà Bíbélì, èyí sì lè fa ìṣòro fáwa èèyàn Ọlọ́run. Ìwà burúkú ló kúnnú ayé lónìí. Nínú lẹ́tà kejì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ onírúurú ìwà abèṣe táwọn èèyàn tí kò mọ Ọlọ́run á máa hù, kódà ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ṣe lá máa burú sí i bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. (2 Tím. 3:1-5) Ó bani lẹ́rù pé ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń hu àwọn ìwà yìí, tá ò bá sì ṣọ́ra wọ́n lè kéèràn ràn wá. (Òwe 13:20) Torí náà, ó yẹ dáàbò bo ara wa ká má bàa dà bíi wọn bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá jọ́sìn Ọlọ́run. w18.01 27 ¶1-2
Saturday, October 5
Kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.—Mát. 28:19.
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó fara han àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kódà ó ṣeé ṣe káwọn ọmọdé náà wà níbẹ̀. Ó lè jẹ́ ìgbà yẹn ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí. (1 Kọ́r. 15:6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọlẹ́yìn ló wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù pàṣẹ pé kí wọ́n máa sọ àwọn míì di ọmọ ẹ̀yìn. Jésù fi hàn pé ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwọn tó bá máa di Kristẹni ṣèrìbọmi. (Mát. 11:29, 30) Ẹni tó bá máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù ni Jèhófà ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ẹ̀yìn ìyẹn lonítọ̀hún lè ṣèrìbọmi. Irú ìrìbọmi yìí nìkan ni Jèhófà fọwọ́ sí. Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àwọn tó di ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn ṣèrìbọmi. Torí náà, wọn ò fi ìrìbọmi falẹ̀ rárá.—Ìṣe 2:41; 9:18; 16:14, 15, 32, 33. w18.03 5 ¶8
Sunday, October 6
Dáníẹ́lì, ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.—Dán. 10:11.
Inú ayé tó ti bàjẹ́ bàlùmọ̀ là ń gbé. Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ àwọn ìsìn èké ayé ti ba ayé yìí jẹ́ débi pé àwọn èèyàn ò ka ìṣekúṣe sí nǹkan bàbàrà mọ́, wọ́n sì ti mú káwọn èèyàn di ọ̀tá Ọlọ́run. Kódà, Bíbélì sọ pé Bábílónì Ńlá ti di “ibi gbígbé àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Ìṣí. 18:2) Torí pé a yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé, ṣe ni wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. (Máàkù 13:13) Torí náà bíi ti Dáníẹ́lì, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti onígbọràn, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwa náà máa jẹ́ ẹni fífani lọ́kàn mọ́ra lójú rẹ̀. (Hág. 2:7) Ẹ̀yin òbí lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òbí Dáníẹ́lì. Lọ́nà wo? Láìka bí ìwà ìkà ṣe kún ilẹ̀ Júdà nígbà tí Dáníẹ́lì wà ní kékeré, Dáníẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kò kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ o, àwọn òbí rẹ̀ ló kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Òwe 22:6) Ìtumọ̀ orúkọ Dáníẹ́lì ni “Ọlọ́run Ni Onídàájọ́ Mi,” èyí sì jẹ́ ká mọ̀ pé olùjọ́sìn Ọlọ́run làwọn òbí rẹ̀. Torí náà ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn ọmọ yín sú yín láé, ṣe ni kẹ́ ẹ máa fi sùúrù kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Éfé. 6:4) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ máa gbàdúrà pẹ̀lú wọn, kẹ́ ẹ sì máa gbàdúrà fún wọn. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti gbin òtítọ́ Bíbélì sọ́kàn wọn, Jèhófà máa bù kún ìsapá yín.—Sm. 37:5. w18.02 5 ¶12; 6 ¶14-15
Monday, October 7
Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, láti ọwọ́ rẹ wá sì ni a ti fi fún ọ.—1 Kíró. 29:14.
Ọrẹ ṣíṣe wà lára ìjọsìn wa sí Jèhófà. Nínú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù gbọ́ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà lọ́run ń sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣí. 4:11) Ǹjẹ́ ìwọ náà gbà pé Jèhófà yẹ lẹ́ni tó yẹ ká fi gbogbo ọlá àti ògo fún, ká sì máa fún lóhun tó dáa jù? Jèhófà tipasẹ̀ Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa wá síwájú òun fún àjọyọ̀ lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún. Torí pé ọrẹ ṣíṣe jẹ́ apá pàtàkì lára ìjọsìn wọn tí wọ́n bá lọ síbi àjọyọ̀ yẹn, Jèhófà pàṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ “fara hàn níwájú [òun] lọ́wọ́ òfo.” (Diu. 16:16) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ó ṣe pàtàkì káwa náà máa fi ọrẹ ti ìjọsìn Jèhófà lẹ́yìn. Ìdí sì ni pé a mọyì iṣẹ́ ribiribi tí ètò Jèhófà ń ṣe àti pé apá pàtàkì lára ìjọsìn wa ni. w18.01 18 ¶4-5
Tuesday, October 8
Èmi yóò tù yín lára.—Mát. 11:28.
Jésù fi kún un pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín . . . Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:29, 30) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí! Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ lọ sípàdé tàbí òde ẹ̀rí nígbà míì, ó lè rẹ̀ wá ká tó kúrò nílé. Àmọ́ nígbà tá a bá pa dà dé, báwo lara wa ṣe máa ń rí? Ṣe lara máa ń tù wá pẹ̀sẹ̀, á sì rọrùn fún wa láti kojú àwọn ìṣòro tá a ní. Ẹ ò rí i pé àjàgà Jésù rọrùn lóòótọ́! Arábìnrin wa kan ní àrùn tó máa ń jẹ́ kó rẹni, tí kì í sì í jẹ́ kéèyàn rí oorun sùn. Yàtọ̀ síyẹn, inú rẹ̀ kì í dùn, gbogbo ìgbà lorí sì máa ń fọ́ ọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í lè lọ sípàdé nítorí àìlera ẹ̀. Àmọ́ lọ́jọ́ kan ó rọ́jú wá sípàdé, lẹ́yìn ìpàdé náà ó sọ pé: “Ohun tí àsọyé tí wọ́n sọ lọ́jọ́ yẹn dá lé ni ìrẹ̀wẹ̀sì. Àsọyé yẹn jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti pé ó ń gba tiwa rò. Ọ̀rọ̀ náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, kódà mi ò mọ ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú. Àsọyé yẹn tún jẹ́ kí n rí i pé ó ṣe pàtàkì kí n máa wá sípàdé tí mo bá máa rókun gbà.” Ó dájú pé inú rẹ̀ dùn gan-an pé ó wá sí ìpàdé lọ́jọ́ yẹn! w18.01 8-9 ¶6-7
Wednesday, October 9
Ẹsẹ̀ mi fẹ́ẹ̀rẹ́ yà kúrò lọ́nà.—Sm. 73:2.
Kí ló yẹ kó o ṣe tí ọmọ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì lẹ́yìn tó ti ṣèrìbọmi? Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan ayé lè bẹ̀rẹ̀ sí í wu ọmọ rẹ tó ti ṣèrìbọmi, ó sì lè máa ronú pé òun ò rídìí tó fi yẹ kóun máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. (Sm. 73:1 ,3, 12, 13) Ó ṣe pàtàkì pé kẹ́yin òbí kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe máa bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, torí pé ọ̀nà tẹ́ ẹ bá gbà bójú tó ọ̀rọ̀ náà ló máa pinnu bóyá ọmọ yín á fọwọ́ gidi mú òtítọ́ tàbí á fi òtítọ́ sílẹ̀. Ẹ rí i pé ẹ ò gbaná jẹ tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, yálà ọmọ yín ṣì kéré tàbí ó ti dàgbà díẹ̀. Bẹ́ ẹ ṣe máa ràn án lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́ táá sì pa dà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló yẹ kó jẹ yín lógún. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kí ọmọ kan tó ṣèrìbọmi, ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣèlérí pé òun á nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn àti pé ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa gbawájú láyé òun. (Máàkù 12:30) Jèhófà ò fojú kékeré wo ìlérí yẹn, ẹnikẹ́ni lára wa kò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ìlérí tá a ṣe.—Oníw. 5:4, 5. w17.12 22 ¶16-17
Thursday, October 10
Mo mọ̀ pé [àbúrò mi] yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.—Jòh. 11:24.
Bíi ti Màtá, ó yẹ kó dá ìwọ náà lójú pé Ọlọ́run lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde. Ẹ ronú nípa ohun tí Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù ṣe fún Ísákì, ìyẹn ọmọ kan ṣoṣo tó fi ọjọ́ ogbó bí tó sì ti ń wá tipẹ́. Jèhófà sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, . . . kí o sì fi í rúbọ . . . gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” (Jẹ́n. 22:2) Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe máa rí lára Ábúráhámù. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti ṣèlérí pé nípasẹ̀ ọmọ Ábúráhámù ni gbogbo orílẹ̀-èdè máa bù kún ara wọn. (Jẹ́n. 13:14-16; 18:18; Róòmù 4:17, 18) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jèhófà tún sọ pé irú-ọmọ náà máa wá “nípasẹ̀ Ísákì.” (Jẹ́n. 21:12) Àmọ́ báwo ni gbogbo ìyẹn ṣe máa ṣeé ṣe tí Ábúráhámù bá fi Ísákì rúbọ? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Ábúráhámù gbà pé Ọlọ́run lè jí Ísákì dìde. (Héb. 11:17-19) Ábúráhámù ò mọ ìgbà tí ọmọ òun máa jíǹde, àmọ́ ó gbà gbọ́ pé Jèhófà máa jí Ísákì dìde. w17.12 5-6 ¶12-14
Friday, October 11
Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.—Ìṣe 20:26.
Bí ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, a fẹ́ fojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn wò ó. Jèhófà “fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pét. 3:9) Ìwọ ńkọ́? Tó o bá jẹ́ kí àánú àwọn èèyàn máa ṣe ẹ́, wàá túbọ̀ máa fìtara wàásù, wàá sì máa láyọ̀ bó o ṣe ń ṣe é. Tá a bá ń fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò, à ń fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí làwa náà fi ń wò ó. Kò yẹ ká máa wakọ̀ níwàkuwà, ó sì yẹ ká fọwọ́ gidi mú ọ̀rọ̀ ààbò níbiṣẹ́ àti láwọn ìgbà míì, títí kan ìgbà tá a bá ń kọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa tàbí nígbà tá a bá ń ṣàtúnṣe sí wọn. Ó tún yẹ kọ́rọ̀ ààbò jẹ wá lọ́kàn tá a bá ń lọ sípàdé tàbí àwọn àpéjọ wa. Kò yẹ ká fọwọ́ kékeré mú ọ̀rọ̀ ààbò àti ìlera wa torí ká lè tètè parí iṣẹ́ wa tàbí torí owó tá a máa rí nídìí rẹ̀. Ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ, ó sì yẹ ká fara wé e. Ó yẹ káwọn alàgbà máa rí i pé kò sóhun tó lè fi ẹ̀mí tiwọn tàbí tàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sínú ewu. (Òwe 22:3) Bí alàgbà kan bá rán ẹ létí pé kó o yẹra fún ohun tó lè wu ẹ̀mí rẹ léwu, tètè fi ìmọ̀ràn náà sílò. (Gál. 6:1) Torí náà, ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn ni kó o fi máa wò ó, kó má bàa “sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kankan lórí rẹ.”—Diu. 19:10. w17.11 16 ¶11-12
Saturday, October 12
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fi ẹ̀bùn eré ìje náà dù yín.—Kól. 2:18.
Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró máa gba èrè kan, ìyẹn “ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè.” (Fílí. 3:14) Wọ́n ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù Kristi, tí wọ́n á sì mú kí aráyé di pípé. (Ìṣí. 20:6) Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn! Àwọn àgùntàn mìíràn náà ní ìrètí àgbàyanu tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún. Wọ́n ń retí ìgbà tí wọ́n máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ó dájú pé ìrètí àgbàyanu lèyí náà jẹ́. (2 Pét. 3:13) Kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lè jẹ́ olóòótọ́ dé òpin, kí wọ́n sì gba èrè náà, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa gbé èrò inú yín ka àwọn nǹkan ti òkè.” (Kól. 3:2) Ìyẹn ni pé kí wọ́n jẹ́ kí ìrètí àtigbé lọ́run máa wà lọ́kàn wọn nígbà gbogbo. (Kól. 1:4, 5) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tá a bá ń ronú nípa àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí fún wa, ìyẹn á jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí èrè náà.—1 Kọ́r. 9:24. w17.11 25 ¶1-2
Sunday, October 13
Ẹ kọrin sí Jèhófà.—Sm. 96:1.
Ọ̀pọ̀ àwọn orin tó wà nínú ìwé orin “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà ló dà bí àdúrà. Tá a bá ń kọ àwọn orin yìí, ńṣe là ń tú ọkàn wa jáde fún Jèhófà. Àwọn orin míì tó wà nínú rẹ̀ máa jẹ́ ká lè “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Héb. 10:24) Ó dájú pé a máa fẹ́ mọ ohùn àwọn orin náà, ká mọ ọ̀rọ̀ inú wọn ká sì rí i pé a mọ àwọn orin náà kọ dáadáa. A tún lè mọ àwọn orin yìí tá a bá ń gbọ́ àwọn orin tá a fẹnu kọ lórí ìkànnì jw.org. Tó o bá ń kọ àwọn orin yìí nílé, wàá lè túbọ̀ máa fìtara kọ àwọn orin náà látọkàn wá. Ká rántí pé apá pàtàkì ni orin jẹ́ nínú ìjọsìn wa. Tá a bá ń fayọ̀ kọrin, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì rẹ̀. (Aísá. 12:5) Tó o bá ń fayọ̀ kọrin tó o sì gbóhùn sókè, wàá mú kó túbọ̀ yá àwọn míì lára láti máa fìtara kọrin. Gbogbo wa pátá ló yẹ ká máa fìtara kọrin sókè sí Jèhófà, yálà a jẹ́ ọmọdé, àgbàlagbà tàbí ẹni tuntun. Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ àtimáa kọrin sókè. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ jẹ́ ká máa fayọ̀ kọrin! w17.11 7 ¶18-19
Monday, October 14
Ẹ jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.—Mát. 10:16.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń wá ibi ìsádi ló wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará tó ń fìtara wàásù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń gbọ́ “ọ̀rọ̀ ìjọba náà” fúngbà àkọ́kọ́. (Mát. 13:19, 23) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ wọn ni ìṣòro ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá, àmọ́ tí wọ́n bá wá sípàdé wa, ara máa ń tù wọ́n, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ wọn sọ pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.” (Mát. 11:28-30; 1 Kọ́r. 14:25) Àwọn tó bá ń wàásù fáwọn tó ń wá ibi ìsádi gbọ́dọ̀ “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra,” kí wọ́n sì tún jẹ́ “afọgbọ́nhùwà.” (Òwe 22:3) Ó yẹ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn tá à ń wàásù fún, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ òṣèlú pẹ̀lú wọn. Ẹ tẹ̀ lé ìtọ́ni ìjọba àti ìmọ̀ràn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá fún yín, kẹ́ ẹ má lọ fi ẹ̀mí ara yín àti tàwọn míì sínú ewu. Sapá láti mọ ẹ̀sìn àti àṣà ìbílẹ̀ wọn, kó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó wá láti àwọn ilẹ̀ kan kì í fẹ́ káwọn obìnrin wọ irú àwọn aṣọ kan. Torí náà, tá a bá lọ wàásù fún wọn, ká má ṣe wọ àwọn aṣọ tó lè múnú bí wọn. w17.05 7 ¶17-18
Tuesday, October 15
Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.—Kól. 4:6.
Á dáa ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó lè darí wa nígbà tá a bá ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí wa tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀. Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa sọ fún wọn pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ kò tọ̀nà. Tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tí kò dáa sí wa, ẹ jẹ́ ká fara wé àwọn àpọ́sítélì Jésù. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn wa, àwa ń súre; nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń mú un mọ́ra; nígbà tí wọ́n ń bà wá lórúkọ jẹ́, àwa ń pàrọwà.” (1 Kọ́r. 4:12, 13) Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ tútù lè pẹ̀tù sáwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ́kàn, síbẹ̀ ká rántí pé ìwà rere lẹ̀ṣọ́ ènìyàn. (1 Pét. 3:1, 2, 16) Jẹ́ kí àwọn ẹbí rẹ rí i nínú ìwà rẹ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn ìgbéyàwó wa, à ń tọ́jú àwọn ọmọ wa, a kì í hùwàkiwà, ìgbésí ayé wa sì máa ń nítumọ̀. Kódà báwọn mọ̀lẹ́bí wa kò bá tiẹ̀ di Ẹlẹ́rìí, àá máa láyọ̀ torí pé à ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. w17.10 15 ¶13-14
Wednesday, October 16
Fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà.—2 Tím. 2:15.
Ṣó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ lónìí ló ti yí ìgbésí ayé wọn pa dà lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Rárá o. Àwọn ìrírí yìí máa ń jẹ́ ká rántí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n nírètí àtigbé lọ́run. (1 Kọ́r. 6:9-11) Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ irú àwọn tí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run, ó sọ nípa àwọn Kristẹni yẹn pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn.” Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà yẹn. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí àwọn kan di Kristẹni, wọ́n ṣì ń hu àwọn ìwà tí inú Jèhófà ò dùn sí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹni àmì òróró kan nígbà yẹn lọ́hùn-ún tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, àmọ́ tí wọ́n gbà pa dà lẹ́yìn tó ṣàtúnṣe. (1 Kọ́r. 5:1-5; 2 Kọ́r. 2:5-8) Ǹjẹ́ inú wa kì í dùn tá a bá ń kà nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran àwọn Kristẹni kan lọ́wọ́ láti borí onírúurú ìṣòro tí wọ́n ní? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára gan-an. Torí pé Jèhófà ti fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó yẹ ká máa lò ó lọ́nà tó tọ́. w17.09 23-24 ¶2-3
Thursday, October 17
Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.—1 Jòh. 3:18.
Ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà, ìyẹn a·gaʹpe, ni ìfẹ́ tó ga jù. Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run sì ni ìfẹ́ yìí ti wá. (1 Jòh. 4:7) Yàtọ̀ sí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìfẹ́ yìí ti wá, ó tún fi ẹ̀bùn yìí jíǹkí wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ yìí máa ń mú ká lọ́yàyà, ká sì kóni mọ́ra, ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi í hàn ni pé ká máa lo ara wa fáwọn míì. Ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé ìfẹ́ a·gaʹpe “kì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n, ohun téèyàn bá ṣe ló máa fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́.” Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn tàbí tí wọ́n ń fìfẹ́ hàn sí wa, inú wa máa dùn, àá láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì nítumọ̀. Kí Jèhófà tó dá àwa èèyàn ló ti nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, kó tó dá Ádámù àti Éfà ló ti ṣe ilẹ̀ ayé lọ́nà tó máa dùn ún gbé fún wa. Àwọn nǹkan tó dá síbẹ̀ fi hàn pé ó fẹ́ ká gbádùn ayé wa títí láé, kì í kàn ṣe pé ká máa gbébẹ̀. Torí tiwa ni Jèhófà fi ṣe àwọn nǹkan yìí, kì í ṣe fún àǹfààní ara rẹ̀. Ó tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́ ní ti pé ó dá wa ká lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè. w17.10 7 ¶1-2
Friday, October 18
Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.—Ják. 2:8.
Jákọ́bù wá fi kún un pé à ń dẹ́ṣẹ̀ bí a bá ń ṣe ojúsàájú. (Ják. 2:9) Lọ́wọ́ kejì, ìfẹ́ ò ní jẹ́ ká máa ka àwọn kan sí ju àwọn míì lọ bóyá torí ipò wọn láwùjọ, ẹ̀yà wọn tàbí torí pé wọ́n kàwé. Kò yẹ ká máa díbọ́n bíi pé gbogbo èèyàn la nífẹ̀ẹ́. Ṣe ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn láìṣe ojúsàájú. Bákan náà, ìfẹ́ máa ń ní ‘ìpamọ́ra àti inú rere, kì í sì í wú fùkẹ̀.’ (1 Kọ́r. 13:4) Ó gba pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká jẹ́ onínúure, ká sì ní sùúrù ká tó lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó. (Mát. 28:19) Àwọn ànímọ́ yìí sì tún máa ń mú kó rọrùn fún wa láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ. Ìbùkún wo la máa rí tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará? Ó máa jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ, èyí á bọlá fún Jèhófà, á sì mú káwọn míì wá sínú ètò Ọlọ́run. Bí Bíbélì ṣe parí ọ̀rọ̀ nípa àkópọ̀ ìwà tuntun bá a mu wẹ́kú, ó ní: “Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kól. 3:14. w17.08 26 ¶18-19
Saturday, October 19
Jèhófà [kìlọ̀ fún wọn] léraléra, nítorí pé ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀.—2 Kíró. 36:15.
Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà fàánú hàn sáwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì rí ojúure Ọlọ́run? Ó ṣe tán, Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run nínú ogun Amágẹ́dọ́nì. (2 Pét. 3:9) Torí náà, títí dìgbà tí Jèhófà máa pa àwọn ẹni búburú run, ẹ jẹ́ ká máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n yí pa dà, kí Ọlọ́run lè fàánú hàn sí wọn. A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù. Àánú àwọn èrò tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣe é, torí pé “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Kí ni Jésù wá ṣe fún wọn? Bíbélì sọ pé: ‘Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.’ (Mát. 9:36; Máàkù 6:34) Ojú tí Jésù fi wo àwọn èèyàn náà yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn Farisí tí kò ṣe tán àtiran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́. (Mát. 12:9-14; 23:4; Jòh. 7:49) Ǹjẹ́ kì í wu ìwọ náà pé kó o ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà bí Jésù ti ṣe? w17.09 9 ¶6; 10 ¶9
Sunday, October 20
Èmi yóò gbé kánkán ṣiṣẹ́, ta sì ni ó lè yí i padà?—Aísá. 43:13.
Nígbà tí Jósẹ́fù wà lẹ́wọ̀n ní Íjíbítì, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ lè ronú pé òun máa di igbákejì Fáráò ọba Íjíbítì, tàbí pé Jèhófà máa lo òun láti gba ìdílé òun lọ́wọ́ ìyàn? (Jẹ́n. 40:15; 41:39-43; 50:20) Ó dájú pé ohun tí Jèhófà ṣe kọjá gbogbo ohun tí Jósẹ́fù lérò. Tún ronú nípa Sárà tó jẹ́ ìyá àgbà fún Jósẹ́fù. Ṣé Sárà gbà pé Jèhófà lè jẹ́ kóun bímọ pẹ̀lú ọjọ́ orí òun, Ká sòótọ́, Sárà ò lè ronú ẹ̀ láé pé Jèhófà lè jẹ́ kóun bímọ. (Jẹ́n. 21:1-3, 6, 7) Ohun kan ni pé, a ò retí pé kí Jèhófà gba ọ̀nà àrà mú gbogbo ìṣòro wa kúrò kí ayé tuntun tó dé. Àwa kọ́ la sì máa sọ fún Jèhófà pé kó ṣe iṣẹ́ ìyanu láyé wa. Síbẹ̀, Jèhófà ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ìgbàanì lọ́wọ́ lọ́nà àrà, kò sì tíì yí pa dà. (Aísá. 43:10-12) Ó dá wa lójú pé Jèhófà lè ṣe ohunkóhun tó bá gbà ká lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 4:7-9) Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, á ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó dà bíi pé kò ṣeé borí. w17.08 11-12 ¶13-14
Monday, October 21
Yí àwọn iṣẹ́ rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀, a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.—Òwe 16:3.
Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa jẹ́ kó o láwọn ọ̀rẹ́ táwọn náà jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìyẹn á sì jẹ́ kó o túbọ̀ dàgbà dénú. Àwọn tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà ọ̀dọ́ rí i pé iṣẹ́ náà mú kí ìgbéyàwó àwọn lárinrin. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó fẹ́ra wọn jọ máa ń gbádùn iṣẹ́ náà lọ lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn. (Róòmù 16:3, 4) Ohun tó wà lọ́kàn rẹ ló máa pinnu bí wàá ṣe lo ayé rẹ. Sáàmù 20:4 sọ nípa Jèhófà pé: “Kí ó fi fún ọ ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn-àyà rẹ, kí ó sì mú gbogbo ète rẹ ṣẹ.” Torí náà, ronú ohun tó o fẹ́ fayé rẹ ṣe. Fara balẹ̀ kíyè sí ohun tí Jèhófà ń ṣe lásìkò wa yìí, kó o sì ronú bíwọ náà ṣe lè kọ́wọ́ ti iṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, pinnu pé wàá ṣe ohun táá múnú rẹ̀ dùn. Tó o bá fayé rẹ sin Jèhófà, ìgbésí ayé rẹ máa nítumọ̀ torí pé ohun tó ń múnú Ọlọ́run dùn lò ń ṣe. Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé: “Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”—Sm. 37:4. w17.07 26 ¶15-18
Tuesday, October 22
Ẹ yin Jáà, . . . Nítorí tí ó dùn mọ́ni-ìyìn yẹ ẹ́.—Sm. 147:1.
Bí ẹnì kan bá ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un lọ́nà tó wúni lórí tàbí tó bá hùwà ọmọlúàbí, a máa ń gbóríyìn fún un. Tá a bá ní láti gbóríyìn fún àwọn èèyàn torí pé wọ́n ṣe dáadáa, ǹjẹ́ kò yẹ ká yin Jèhófà, Ọlọ́run wa? Ó yẹ ká yin Ọlọ́run torí agbára rẹ̀ tó kàmàmà, a sì rí èyí nínú àwọn nǹkan àgbàyanu tó dá. A tún lè yìn ín torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, pàápàá bó ṣe rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé kó lè rà wá pa dà. Ẹni tó kọ Sáàmù kẹtàdínláàádọ́jọ [147] yin Jèhófà torí àwọn ohun ribiribi tó ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún rọ àwọn míì pé kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ òun láti yin Ọlọ́run. (Sm. 147:7, 12) A ò mọ ẹni tó kọ Sáàmù yìí, àmọ́ ó jọ pé ìgbà tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ nígbèkùn Bábílónì tí wọ́n sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù ni onísáàmù náà gbáyé. (Sm. 147:2) Bí Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kí wọ́n lè pa dà máa jọ́sìn rẹ̀ wú onísáàmù náà lórí, ìyẹn ló sì mú kó máa yin Jèhófà. Kí nìdí tó fi yẹ kí ìwọ náà máa yin Jáà?—Sm. 147:1. w17.07 17 ¶1-3
Wednesday, October 23
Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo, kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá kùnà, wọn yóò lè gbà yín sínú àwọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.—Lúùkù 16:9.
Jésù mọ̀ pé nǹkan lè nira fáwa ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àá sì wá bá a ṣe máa gbọ́ bùkátà ara wa nínú ayé yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò sọ ìdí tó fi pe ọrọ̀ ní “àìṣòdodo,” Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ káràkátà kò sí lára ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé. Ó ṣe tán, gbogbo ohun tí Ádámù àti Éfà nílò ni Jèhófà fún wọn lọ́pọ̀ yanturu nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 2:15, 16) Bákan náà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ẹ̀mí mímọ́ darí àwọn Kristẹni ìgbà yẹn tó fi jẹ́ pé “kò tilẹ̀ sí ẹni tí ń sọ pé èyíkéyìí lára àwọn ohun tí òun ní jẹ́ tòun; ṣùgbọ́n wọ́n ní ohun gbogbo ní àpapọ̀.” (Ìṣe 4:32) Wòlíì Aísáyà tiẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn máa gbádùn gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá sáyé. (Aísá. 25:6-9; 65:21, 22) Àmọ́ ní báyìí ná, àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní láti máa fọgbọ́n lo àwọn “ọrọ̀ àìṣòdodo” tá a ní nínú ayé yìí bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà.—Lúùkù 16:8. w17.07 8 ¶4-6
Thursday, October 24
Ohun gbogbo tí ó ní wà ní ọwọ́ rẹ.—Jóòbù 1:12.
Nínú ìwé Jóòbù tó wà lára àwọn ìwé tí wọ́n kọ́kọ́ kọ nínú Bíbélì, a rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn ní òye tó tọ́ nípa ìṣòro tó ń dé bá wa. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì sọ pé tí ojú bá pọ́n Jóòbù gan-an, á gbàgbé Ọlọ́run. Sátánì tiẹ̀ dábàá pé kí Jèhófà fúnra rẹ̀ fìyà jẹ Jóòbù. Àmọ́ Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló gba Sátánì láyè láti dán Jóòbù wò. Bí ìṣòro ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ lura fún Jóòbù nìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kú, gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ run pátápátá, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá sì kú. Sátánì kọlu Jóòbù lọ́nà tó mú kó dà bíi pé Ọlọ́run gan-an ló ń fìyà jẹ ẹ́. (Jóòbù 1:13-19) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Sátánì fi àìsàn burúkú kọlu Jóòbù. (Jóòbù 2:7) Ẹ̀dùn ọkàn tó bá Jóòbù tún peléke nígbà tí ìyàwó rẹ̀ fún un nímọ̀ràn tí kò bọ́gbọ́n mu táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta sì sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. (Jóòbù 2:9; 3:11; 16:2) Kí wá la lè sọ nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jóòbù? Ó ṣe kedere pé irọ́ ni ẹ̀sùn náà já sí. Ìdí sì ni pé Jóòbù kò fi Jèhófà sílẹ̀.—Jóòbù 27:5. w17.06 24 ¶9-10
Friday, October 25
Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́.—1 Tím. 5:8.
Àwọn olórí ìdílé mọ̀ pé ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé àwọn lọ́wọ́ ni pé káwọn pèsè fún àwọn tó wà nínú ìdílé wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè bójú tó ojúṣe yẹn. Àmọ́, láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀rọ̀ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ máa ń kóni lọ́kàn sókè. Nítorí pé àwọn tó ń wáṣẹ́ pọ̀ gan-an ju iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ló ń forí ṣe fọrùn ṣe fọ́pọ̀ wákàtí àmọ́ tó jẹ́ pé owó tó ń wọlé fún wọn kò tó nǹkan. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe làwọn iléeṣẹ́ ń mú káwọn òṣìṣẹ́ máa ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó, ìyẹn sì ń tán àwọn òṣìṣẹ́ lókun, kódà ó ń ṣàkóbá fún ìlera wọn. Bí òṣìṣẹ́ kan kò bá sì ṣe tán láti ṣe irú iṣẹ́ àṣekúdórógbó bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ máa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Àwa Kristẹni mọ̀ pé Jèhófà ṣe pàtàkì sí wa ju ọ̀gá tó gbà wá síṣẹ́ lọ. (Lúùkù 10:27) Ìdí tá a fi ń ṣiṣẹ́ ni pé ká lè gbọ́ bùkátà ara wa àti ti ìdílé wa, ká sì lè ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn. Àmọ́ tá ò bá ṣọ́ra, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lè dí ìjọsìn wa lọ́wọ́. w17.05 23 ¶5-7
Saturday, October 26
Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ, má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.—Òwe 23:22.
Nígbà míì, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ máa ń sọ fáwọn tó dàgbà dénú nínú ìjọ pé kí wọ́n bá ọmọ àwọn kẹ́kọ̀ọ́. Tí òbí kan bá sọ pé kẹ́nì kan máa kọ́ ọmọ òun lẹ́kọ̀ọ́, kò yẹ kẹ́ni náà gba ojúṣe òbí náà ṣe. (Éfé. 6:1-4) Àwọn ìgbà míì wà tí wọ́n lè sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé kó máa kọ́ ọmọ táwọn òbí rẹ̀ kò sí nínú ètò lẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀ ó yẹ kí Ẹlẹ́rìí náà fi sọ́kàn pé òun fẹ́ kọ́ ọmọ náà lẹ́kọ̀ọ́ ni, kì í ṣe pé òun fẹ́ di òbí ọmọ náà. Tí wọ́n bá sì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ohun tó dáa jù ni pé kí wọ́n ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nílé àwọn ọmọ náà, kó sì jẹ́ níṣojú àwọn òbí rẹ̀ tàbí níṣojú Ẹlẹ́rìí míì tó dàgbà dénú, wọ́n sì lè ṣe é ní gbangba níbi táwọn èèyàn wà. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn míì ò ní máa ro èròkérò nípa ohun tí wọ́n ń ṣe. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn òbí náà lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí wọ́n sì bójú tó ojúṣe tí Ọlọ́run fún wọn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. w17.06 8 ¶15-16
Sunday, October 27
Bí èmi kò bá lóye ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè sí mi.—1 Kọ́r. 14:11.
Nígbà míì, ọmọ kan máa gbọ́ èdè míì dáadáa ju bó ṣe gbọ́ èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ, ó sì lè jẹ́ pé èdè tó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn nìyẹn. Bí àwọn ọmọ ṣe máa sún mọ́ Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù sáwọn òbí Kristẹni, kì í ṣe ohun táwọn fúnra wọn fẹ́. (1 Kọ́r. 10:24) Arákunrin kan tó ń jẹ́ Samuel sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi kíyè sí àwọn ọmọ wa dáadáa ká lè mọ èdè tó máa jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ̀ wọ́n lọ́kàn, a sì gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà. . . . Nígbà tá a rí i pé àwọn ọmọ wa ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọ́n ń sọ níjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wa, a pinnu pé a máa lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè àdúgbò ibi tá à ń gbé. A jọ máa ń lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí déédéé. A tún máa ń pe àwọn ará pé kí wọ́n wá jẹun nílé wa, ká sì jọ gbafẹ́ jáde. Ohun tó jẹ́ káwọn ọmọ wa mọ àwọn ará dáadáa nìyẹn, ó tún mú kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì rí i bíi Bàbá àti Ọ̀rẹ́ wọn. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa nìyẹn, kì í ṣe pé kí wọ́n ṣáà ti gbọ́ èdè wa.” w17.05 10 ¶11-13
Monday, October 28
Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.—Oníd. 5:2.
Láìpẹ́, àwọn tó fara wọn sábẹ́ àkóso Jèhófà nìkan ló máa wà láyé. Ṣe ló ń ṣe wá bíi pé kọ́jọ́ náà ti dé! Bíi ti Dèbórà àti Bárákì, àwa náà ń panu pọ̀ sọ pé: “Kí gbogbo ọ̀tá rẹ ṣègbé, Jèhófà, kí àwọn olùfẹ́ rẹ sì rí bí ìgbà tí oòrùn bá jáde lọ nínú agbára ńlá rẹ̀.” (Oníd. 5:31) Jèhófà máa dáhùn àdúrà yìí nígbà tó bá pa Sátánì àti ayé búburú yìí run! Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, kò ní sí pé à ń yọ̀ǹda ara wa láti bá àwọn ọ̀tá Jèhófà jà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la máa ṣe ohun tí Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín.” (2 Kíró. 20:17) Àmọ́ ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká lo gbogbo àǹfààní tá a ní láti máa fìtara àti ìgboyà ṣe iṣẹ́ Jèhófà. “Nítorí tí àwọn ènìyàn náà fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.” Ó ṣe kedere pé Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ ni wọ́n gbógo fún, kì í ṣe ẹ̀dá èyíkéyìí. (Oníd. 5:1, 2) Torí náà, ẹ jẹ́ káwa náà máa bá a lọ láti yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ Jèhófà káwọn míì lè máa yin Jèhófà! w17.04 32 ¶17-18
Tuesday, October 29
Èmi kò ṣe nǹkan kan rárá tí ó yẹ kí a tìtorí rẹ̀ fi mí sínú ihò ẹ̀wọ̀n.—Jẹ́n. 40:15.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù ò gbàgbé àìdáa táwọn èèyàn ṣe sí i, ní gbogbo ọdún mẹ́tàlá tó fi jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí í fapá jánú. (Jẹ́n. 45:5-8) Ní pàtàkì jù, kò jẹ́ kí àìpé àti àṣìṣe àwọn míì mú kó fi Jèhófà sílẹ̀. Bí Jósẹ́fù ṣe jẹ́ adúróṣinṣin jẹ́ kó rí ọwọ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ náà. Jèhófà dá a láre, ó sì bù kún òun àti ìdílé rẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwa náà gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àìpé àwọn ará wa mú ká fi í sílẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Kàkà bẹ́ẹ̀, tẹ́nì kan bá ṣàìdáa sí wa nínú ìjọ, ẹ jẹ́ ká ṣe bíi Jósẹ́fù, ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Tá a bá ti ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, ó yẹ ká fọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́. Ká mọ̀ dájú pé tó bá tásìkò lójú rẹ̀, ó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. w17.04 20 ¶12; 22 ¶15-16
Wednesday, October 30
Bí ìwọ yóò bá . . . fún ẹrúbìnrin rẹ ní ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin ní ti tòótọ́, èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.—1 Sám. 1:11.
Hánà mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Ọlọ́run ṣẹ. Kò tiẹ̀ rò ó pé ẹ̀ẹ̀mejì. Ó mú Sámúẹ́lì lọ bá Élì Àlùfáà Àgbà tó wà níbi àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò, ó wá sọ pé: “Ọmọdékùnrin yìí ni mo gbàdúrà nípa rẹ̀ pé kí Jèhófà yọ̀ǹda ìtọrọ tí mo ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀. Èmi, ẹ̀wẹ̀, sì ti wín Jèhófà. Ní gbogbo ọjọ́ tí ó bá wà, ẹni tí a béèrè fún Jèhófà ni.” (1 Sám. 1:24-28) Níbẹ̀, ‘Sámúẹ́lì ń bá a lọ ní dídàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà.’ (1 Sám. 2:21) Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe rí lára Hánà? Ó dájú pé ó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ gan-an, àmọ́ kò ní sí pẹ̀lú rẹ̀ bó ṣe ń dàgbà. Ká ló wà pẹ̀lú rẹ̀ ni, á ní ìrírí táwọn ìyá tó ń tọ́mọ máa ń ní, bí wọ́n ṣe ń gbé ọmọ wọn mọ́ra, tí wọ́n ń bá a ṣeré, tí wọ́n ń tọ́jú rẹ̀, tí wọ́n sì ń rí bọ́mọ náà ṣe ń sáré síbí sọ́hùn-ún. Láìka gbogbo ìyẹn sí, Hánà kò kábàámọ̀ pé òun mú ẹ̀jẹ́ òun ṣẹ. Ṣe ló ń yọ̀ nínú Jèhófà.—1 Sám. 2:1, 2; Sm. 61:1, 5, 8. w17.04 5 ¶7-8
Thursday, October 31
Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.—2 Tím. 3:1.
Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ọjọ́ ìkẹyìn yìí máa jẹ́ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” ó tún sọ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tím. 3:2-5, 13) Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn nǹkan yìí ti ń ṣẹlẹ̀? Ọ̀pọ̀ lára wa làwọn ìpáǹle, àwọn alákatakítí, àtàwọn jàǹdùkú ti hàn léèmọ̀. Àwọn kan ò fi tiwọn bò, afàwọ̀rajà sì làwọn míì, wọ́n á máa ṣe bí ẹni pé èèyàn rere làwọn, síbẹ̀ ìwà ibi ló kún ọwọ́ wọn. Ká tiẹ̀ ní wọn ò hàn wá léèmọ̀ rí, ìwà ibi wọn ṣì kàn wá. Kò sẹ́ni tínú rẹ̀ kì í bà jẹ́ tó bá gbọ́ nípa ìwà ibi táwọn èèyàn náà ń hù. Ṣé bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n àwọn ọmọdé ni ká sọ ni, tàbí bí wọ́n ṣe ń fojú àwọn àgbàlagbà gbolẹ̀ àtàwọn tí kò ní olùgbèjà? Ìwà táwọn èèyàn burúkú yẹn ń hù kò jọ tèèyàn, ṣe ló dà bíi ti ẹranko àti tàwọn ẹ̀mí èṣù. (Ják. 3:15) Àmọ́, inú wa dùn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan máa tó yí pa dà. w17.04 10 ¶4