ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es19 ojú ìwé 108-118
  • November

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • November
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, November 1
  • Saturday, November 2
  • Sunday, November 3
  • Monday, November 4
  • Tuesday, November 5
  • Wednesday, November 6
  • Thursday, November 7
  • Friday, November 8
  • Saturday, November 9
  • Sunday, November 10
  • Monday, November 11
  • Tuesday, November 12
  • Wednesday, November 13
  • Thursday, November 14
  • Friday, November 15
  • Saturday, November 16
  • Sunday, November 17
  • Monday, November 18
  • Tuesday, November 19
  • Wednesday, November 20
  • Thursday, November 21
  • Friday, November 22
  • Saturday, November 23
  • Sunday, November 24
  • Monday, November 25
  • Tuesday, November 26
  • Wednesday, November 27
  • Thursday, November 28
  • Friday, November 29
  • Saturday, November 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
es19 ojú ìwé 108-118

November

Friday, November 1

Ẹ kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ayé [kí ẹ sì máa] gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run.​—Títù 2:12.

Ẹni tó ń kó ara rẹ̀ níjàánu máa ń kíyè sára kí èrò àti ìṣe rẹ̀ lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. A kì í bí ìkóra-ẹni-níjàánu mọ́ni, èèyàn máa ń kọ́ ọ ni. Táwọn òbí bá ń fi sùúrù kọ́ àwọn ọmọ wọn “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” tí wọn ò sì jẹ́ kó sú wọn, ṣe nìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ bí wọ́n ṣe lè kó ara wọn níjàánu, wọ́n á sì gbọ́n. (Éfé. 6:4) Bó ṣe máa ń rí fáwọn tó ti dàgbà kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ náà nìyẹn. Lóòótọ́, wọ́n lè ti ní ìkóra-ẹni-níjàánu dé ìwọ̀n àyè kan tẹ́lẹ̀, àmọ́ téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, bí ìkókó ló ṣe rí. Síbẹ̀, bí wọ́n ṣe ń gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, tí wọ́n sì ń sapá láti fara wé Jésù, wọ́n á túbọ̀ máa dàgbà nípa tẹ̀mí. (Éfé. 4:​23, 24) Ìkóra-ẹni-níjàánu wà lára ohun táá jẹ́ kẹ́ni náà dàgbà nípa tẹ̀mí. w18.03 29 ¶3-4

Saturday, November 2

Ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.​—Róòmù 12:13.

Gbogbo àwọn tó bá wá sípàdé la máa ń gbà tọwọ́tẹsẹ̀ torí pé àlejò ni gbogbo wa. Jèhófà àti ètò rẹ̀ ló sì gbà wá lálejò. (Róòmù 15:7) Táwọn ẹni tuntun bá wá sípàdé, ó yẹ káwa náà fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí wọn. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fọ̀yàyà kí wọn láìka irú aṣọ tí wọ́n wọ̀ tàbí bí wọ́n ṣe múra sí. (Ják. 2:​1-4) Tá a bá rí i pé ẹni tuntun kan dá jókòó, a lè lọ jókòó tì í tàbí ká ní kó wá jókòó tì wá. Ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn tó bá rẹ́ni bá a ṣí Bíbélì kó lè máa fọkàn bá ìpàdé náà lọ. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń “tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.” Inú wa máa ń dùn táwọn arákùnrin kan bá wá sọ àsọyé níjọ wa. Wọ́n lè jẹ́ àlejò láti ìjọ míì, alábòójútó àyíká tàbí aṣojú tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá. A máa ń lo àwọn àǹfààní yẹn láti ṣe àwọn arákùnrin yìí lálejò. (3 Jòh. 5-8) A lè ṣètò ìpápánu tàbí ká tiẹ̀ dáná fún wọn pàápàá. Ṣé ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀? w18.03 15 ¶5, 7

Sunday, November 3

Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?​—Ìṣe 8:36.

Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin Júù kan tó ti máa ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run yà sí mímọ́ fún ara rẹ̀ ni wọ́n bí i sí. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn Júù pàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà. Ọkùnrin tá à ń wí yìí nítara gan-an fún ìsìn àwọn Júù, àmọ́ nǹkan máa tó yé e. Jésù Kristi tó ti wà lọ́run ló wàásù fún un. Kí lọkùnrin náà wá ṣe? Ó gbà kí Ananíà tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ran òun lọ́wọ́. Nígbà tí Bíbélì ń ròyìn ohun tí ọkùnrin náà ṣe, ó ní: “Ó dìde, a sì batisí rẹ̀.” (Ìṣe 9:​17, 18; Gál. 1:14) Ó dájú pé ẹ mọ ẹni tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, àbí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni. Àmọ́ ṣé ẹ rántí ohun tó ṣe ní gbàrà tó lóye ipa tí Jésù kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ? Kíá ló ṣèrìbọmi. (Ìṣe 22:​12-16) Irú ìgbésẹ̀ táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónìí máa ń gbé nìyẹn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà. w18.03 5-6 ¶9-11

Monday, November 4

Èmi kò lè bá yín sọ̀rọ̀ bí ẹní ń bá àwọn ènìyàn ti ẹ̀mí sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n bí ẹní ń bá àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara sọ̀rọ̀.​—1 Kọ́r. 3:1.

Nǹkan ò rọrùn fún Jékọ́bù nígbà ayé rẹ̀. Ó ní láti fara dà á fún Ísọ̀ ìkejì rẹ̀ torí pé ìyẹn ò mọ̀ ju nǹkan tara lọ àti pé Ísọ̀ tiẹ̀ ń wọ́nà bó ṣe máa pa á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn “ènìyàn ti ara” ló yí Jékọ́bù ká, kò ṣìwà hù, àwọn nǹkan tẹ̀mí ló jẹ ẹ́ lógún. (1 Kọ́r. 2:​14-16) Ó nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù, ó sì bójú tó ìdílé rẹ̀ dáadáa torí ó mọ̀ pé ìdílé òun ni Mèsáyà ti máa jáde táá sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. (Jẹ́n. 28:​10-15) Jékọ́bù fi hàn lọ́rọ̀ àti ní ìṣe pé ìlànà Ọlọ́run lòun ń tẹ̀ lé, ìfẹ́ rẹ̀ lòun sì ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹ̀rù ń bà á pé Ísọ̀ lè gba ẹ̀mí òun, Jékọ́bù gbàdúrà pé: “Mo bẹ̀ ọ́, dá mi nídè . . . Ìwọ ti sọ pé, ‘Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, èmi yóò ṣe dáadáa sí ọ, èmi yóò sì mú irú-ọmọ rẹ dà bí àwọn egunrín iyanrìn òkun.’ ” (Jẹ́n. 32:​6-12) Ó ṣe kedere pé Jékọ́bù nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ. w18.02 20 ¶9-10

Tuesday, November 5

Ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.​—Jóòbù 1:8.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la rí kọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé Jóòbù. Kí Jóòbù tó níṣòro, Bíbélì sọ pé òun ló lọ́lá jù nínú gbogbo àwọn èèyàn Ìlà-Oòrùn. (Jóòbù 1:3) Ó lówó, ó gbajúmọ̀, àwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an. (Jóòbù 29:​7-16) Síbẹ̀, Jóòbù kò tìtorí ìyẹn di agbéraga tàbí kó má rí ti Ọlọ́run rò. Kódà, Jèhófà pè é ní “ìránṣẹ́ mi.” Sátánì mú kí ìyà jẹ Jóòbù gan-an débi pé Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Ọlọ́run ló ń fa ìṣòro òun. (Jóòbù 1:​13-21) Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn olùtùnú èké mẹ́ta wá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí Jóòbù, wọ́n sọ pé ohun tó tọ́ sí Jóòbù ni Ọlọ́run jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí i. (Jóòbù 2:11; 22:​1, 5-10) Síbẹ̀, Jóòbù jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Nígbà tí Jóòbù bọ́ nínú ìṣòro, Jèhófà fún un ní ìlọ́po méjì gbogbo ohun tó ní tẹ́lẹ̀, ó sì tún jẹ́ kó gbé fún ogóje [140] ọdún lẹ́yìn náà. (Ják. 5:11) Jóòbù ń bá a lọ láti fi ọkàn pípé sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. w18.02 6 ¶16; 7 ¶18

Wednesday, November 6

Àwọn ènìyàn yóò jẹ . . . ajọra-ẹni-lójú, onírera, . . . awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.​—2 Tím. 3:​2, 4.

Àwọn tó nírú ẹ̀mí yìí fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ kí wọ́n sì máa gbógo fún àwọn. Ọ̀mọ̀wé kan sọ ohun tí agbéraga èèyàn máa ń ṣe, ó ní: “Ó ka ara rẹ̀ sí ọlọ́run kan, ó sì máa ń júbà ara rẹ̀.” Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé agbéraga èèyàn kì í fẹ́ kí ẹlòmíì gbéra ga tàbí fọ́nnu lójú òun. Jèhófà kórìíra ìgbéraga. Bíbélì sọ pé Jèhófà kórìíra “ojú gíga fíofío.” (Òwe 6:​16, 17) Ìgbéraga máa ń jẹ́ kéèyàn jìnnà sí Ọlọ́run. (Sm. 10:4) Èṣù lẹni tó ń gbéra ga fìwà jọ. (1 Tím. 3:6) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ti jẹ́ kí ìgbéraga wọ àwọn lẹ́wù. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni Ùsáyà ọba Júdà fi sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àmọ́ nígbà tó yá, Bíbélì sọ pé “gbàrà tí ó di alágbára, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera àní títí dé àyè tí ń fa ìparun, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, tí ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọba Hesekáyà náà hùwà ìgbéraga, àmọ́ ó tètè ronú pìwà dà.​—2 Kíró. 26:16; 32:​25, 26. w18.01 28 ¶4-5

Thursday, November 7

Kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lè máa láásìkí.​—1 Kọ́r. 16:2.

Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn fi àwọn ohun ìní wọn ta Jèhófà lọ́rẹ. Àwọn ìgbà kan wà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ọrẹ láti ṣe àwọn iṣẹ́ pàtó kan. (Ẹ́kís. 35:5; 2 Ọba 12:​4, 5; 1 Kíró. 29:​5-9) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, nígbà táwọn ará gbọ́ pé àwọn Kristẹni bíi tiwọn nílò ìrànwọ́ torí ìyàn tó mú, wọ́n “pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà.” (Ìṣe 11:​27-30) Ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ṣe ọrẹ yàtọ̀ síra. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni kan ta ohun tí wọ́n ní, bí ilẹ̀ tàbí ilé, wọ́n sì kó owó náà fáwọn àpọ́sítélì. Àwọn àpọ́sítélì náà sì pín owó yìí fáwọn tó wà nípò àìní. (Ìṣe 4:​34, 35) Àwọn míì máa ń dìídì ya iye kan sọ́tọ̀ kí wọ́n lè fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ọlọ́run. Kò sí àní-àní pé àtolówó àti tálákà ló ń ṣètìlẹ́yìn kí iṣẹ́ Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú.​—Lúùkù 21:​1-4. w18.01 18 ¶7; 19 ¶9

Friday, November 8

Àárẹ̀ yóò mú àwọn ọmọdékùnrin, agara yóò sì dá wọn.​—Aísá. 40:30.

Bó ti wù ká ní òye tàbí ìrírí tó, ó lójú ohun tá a lè dá ṣe. Kókó pàtàkì nìyí, ó sì yẹ ká máa fi í sọ́kàn. Àpẹẹrẹ kan ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣe, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ohun tó wù ú láti ṣe ló ṣe torí pé ẹlẹ́ran ara lòun náà. Nígbà tó sọ bó ṣe rí lára rẹ̀ fún Ọlọ́run, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Ohun tí Ọlọ́run sọ yé Pọ́ọ̀lù dáadáa, abájọ tó fi sọ pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́r. 12:​7-10) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé láìsí ìrànwọ́ Ọlọ́run, ó lójú ohun tí òun lè dá ṣe. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kí Pọ́ọ̀lù ní agbára. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún mú kí Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn nǹkan tó ju agbára òun fúnra rẹ̀ lọ. Bíi ti Pọ́ọ̀lù lọ̀rọ̀ tiwa náà rí. Tá a bá rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó dájú pé àwa náà máa ní agbára láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́! w18.01 9 ¶8-9

Saturday, November 9

Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.​—2 Tím. 3:15.

Tí ọmọ rẹ bá sọ pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi, ṣàyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn tí ètò Ọlọ́run fún ẹ̀yin òbí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọmọ rẹ á rí bí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ti ṣe pàtàkì tó àtàwọn ìbùkún tó wà nínú ẹ̀. Àǹfààní ńlá lẹ̀yin òbí ní, ó sì tún jẹ́ ojúṣe pàtàkì láti tọ́ àwọn ọmọ yín dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Kì í kàn ṣe pé kẹ́ ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nìkan, ó tún ṣe pàtàkì pé kí ohun tí wọ́n ń kọ́ dá wọn lójú. Kò sí àní-àní pé tí ohun tí wọ́n kọ́ bá dá wọn lójú dáadáa, wọ́n á ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n á sì máa sìn ín tọkàntọkàn. Àdúrà wa ni pé kí Ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìsapá ẹ̀yin òbí mú káwọn ọmọ yín “di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” w17.12 22 ¶17, 19

Sunday, November 10

Ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.​—Dán. 12:13.

Dáníẹ́lì ti darúgbó, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún. Ṣé Dáníẹ́lì máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú? Bẹ́ẹ̀ ni! Ní ẹsẹ tó kẹ́yìn nínú ìwé Dáníẹ́lì, áńgẹ́lì yẹn sọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún Dáníẹ́lì lọ́jọ́ iwájú, ó ní: “Ní ti ìwọ fúnra rẹ, máa lọ síhà òpin; ìwọ yóò sì sinmi.” Dáníẹ́lì tó ti darúgbó mọ̀ pé àwọn tó ti kú ń sinmi ni, wọn ò sì ní “ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù.” Ibi tí Dáníẹ́lì náà sì máa tó lọ nìyẹn. (Oníw. 9:10) Àmọ́, kò ní wà níbẹ̀ títí lọ gbére. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa jí i dìde. Áńgẹ́lì náà tún sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwẹ́ Mímọ́ òní fún Dáníẹ́lì. Áńgẹ́lì yẹn ò sọ ọjọ́ tàbí àsìkò tí ìyẹn máa ṣẹlẹ̀. Dáníẹ́lì máa kú, ó sì máa sinmi. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tó sọ fún un pé ‘ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ’ túmọ̀ sí pé ó máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú, bó bá tiẹ̀ kú tó sì lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ nínú sàréè. Ìyẹn sì máa jẹ́ “ní òpin àwọn ọjọ́.” Bíbélì Jerusalem Bible sọ pé: “Ìwọ yóò dìde, ìwọ yóò sì gba ìpín rẹ ní ìkẹyìn ọjọ́.” w17.12 7 ¶17-18

Monday, November 11

Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kì yóò jẹ́rìí lòdì sí ọkàn kan fún un láti kú. ​—Núm. 35:30.

Jèhófà pàṣẹ fáwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa ṣèdájọ́ òdodo bíi tòun. Ohun àkọ́kọ́ ni pé kí wọ́n wádìí bóyá ẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn ni àbí ó ṣèèṣì. Lẹ́yìn náà, wọ́n á rí i pé àwọn lóye ohun tó mú kí ẹ̀mí èèyàn tọwọ́ rẹ̀ bọ́, bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, àti irú ẹni tó jẹ́ látẹ̀yìnwá, èyí á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá káwọn fàánú hàn sí i tàbí káwọn má ṣe bẹ́ẹ̀. Kí wọ́n lè ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ bóyá ẹni tó pààyàn náà ṣe bẹ́ẹ̀ “láti inú ìkórìíra” àti pé ṣe ló “lúgọ dè é kí ó bàa lè kú.” (Núm. 35:​20-24) Tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá ṣojú àwọn míì, ó kéré tán ẹni méjì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí i bóyá ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ pa ẹni náà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Lẹ́yìn táwọn àgbà ọkùnrin bá ti rí òkodoro ọ̀rọ̀, wọ́n á fún ẹni náà láfiyèsí dípò ohun tó ṣe. Èyí gba pé kí wọ́n lo ìjìnlẹ̀ òye, kí wọ́n wo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà àtohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn sójútáyé. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wọ́n nílò ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà kí wọ́n lè lo ìjìnlẹ̀ òye àti àánú, kí wọ́n sì ṣèdájọ́ òdodo.​—Ẹ́kís. 34:​6, 7. w17.11 16 ¶13-14

Tuesday, November 12

Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí.​—1 Tím. 4:15.

Ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run la túbọ̀ ń lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye. A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ni Olùfúnni-ní-ìyè, àti pé ó nídìí tó fi dá àwa èèyàn. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ pèsè ìràpadà fún wa ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Láfikún síyẹn, a tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, a sì nírètí àtigbé títí láé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run níbi tá a ti máa láyọ̀ tí àlàáfíà sì máa jọba. (Jòh. 3:16; Ìṣí. 4:11; 21:​3, 4) Látìgbàdégbà ni àtúnṣe máa ń bá òye tá a ní nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tàbí àwọn àlàyé tá a ṣe lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Tírú ìlàlóye bẹ́ẹ̀ bá wáyé, ó yẹ ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ wọn, ká sì ṣàṣàrò nípa wọn. (Ìṣe 17:11) Bá a ṣe ń sapá láti lóye àwọn àtúnṣe tó ṣe gbòógì, bẹ́ẹ̀ náà làá gbìyànjú láti lóye àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ tó wà láàárín òye tá a ní tẹ́lẹ̀ àti òye tuntun. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi àwọn òtítọ́ tuntun náà síbi ìṣúra wa, a sì ń dáàbò bò ó. w17.06 12-13 ¶15-16

Wednesday, November 13

Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo.​—Kól. 3:5.

Ó ṣe pàtàkì pé ká wà lójúfò pàápàá nígbà tá a bá bára wa láwọn ipò kan tó ti lè rọrùn láti ṣèṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, àtìbẹ̀rẹ̀ ló ti yẹ káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà jíròrò ibi táwọn lè fìfẹ́ hàn síra wọn dé. Ó gba pé kí wọ́n kíyè sára tó bá dọ̀rọ̀ ìfẹnukonu, gbígbá ara wọn mọ́ra tàbí wíwà pa pọ̀ láwọn nìkan. (Òwe 22:3) Yàtọ̀ síyẹn, tí iṣẹ́ Kristẹni kan bá gba pé kó rìnrìn-àjò tàbí kó bá ẹ̀yà kejì ṣiṣẹ́, ó yẹ kó kíyè sára. (Òwe 2:​10-12, 16) Ó tún yẹ ká wà lójúfò nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn tàbí tá ò rẹ́ni fojú jọ. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká rẹ́ni fà wá mọ́ra. A sì lè máa wá ẹni tó máa tù wá nínú tàbí ẹni tó máa gba tiwa rò láìka ẹni yòówù kó jẹ́. Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká yíjú sí Jèhófà àtàwọn ará fún ìrànlọ́wọ́.​—Sm. 34:18; Òwe 13:20. w17.11 26 ¶4-5

Thursday, November 14

Ẹ pèsè àwọn ìlú ńlá ìsádi fún ara yín.​—Jóṣ. 20:2.

Ọwọ́ kékeré kọ́ ni Jèhófà fi mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. Òfin Ọlọ́run sọ pé bí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn, kí wọ́n pa onítọ̀hún. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ìbátan tímọ́tímọ́ ẹni tí wọ́n pa ló máa gbẹ̀san ikú rẹ̀, òun sì ni Bíbélì pè ní “olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.” (Núm. 35:19) Ìgbésẹ̀ yẹn máa mú kí apààyàn náà jìyà ohun tó ṣe. Bákan náà, wọn kì í fi ìdájọ́ yìí falẹ̀ kí Ilẹ̀ Ìlérí má bàa di ẹlẹ́gbin, torí Jèhófà pàṣẹ pé: “Kí ẹ má sì sọ ilẹ̀ tí ẹ wà nínú rẹ̀ di eléèérí; nítorí pé [títa ẹ̀jẹ̀ èèyàn sílẹ̀] ní ń sọ ilẹ̀ di eléèérí.” (Núm. 35:​33, 34) Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀ọ́mọ̀, síbẹ̀ ó ṣì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí pé ẹ̀mí èèyàn ti ọwọ́ rẹ̀ bọ́. (Jẹ́n. 9:5) Àmọ́ torí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó gbà kí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò mẹ́fà kí ọwọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa tẹ̀ ẹ́. Á rí ààbò níbẹ̀ àmọ́ kò gbọ́dọ̀ jáde nílùú ààbò yẹn títí tí àlùfáà àgbà fi máa kú.​—Núm. 35:​15, 28. w17.11 9 ¶3-5

Friday, November 15

Afọgbọ́nhùwà a máa bo àbùkù mọ́lẹ̀.​—Òwe 12:16.

Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Bàbá ọkọ mi kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an. Nígbàkigbà témi àti ọkọ mi bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ wọn, ṣe la máa ń kọ́kọ́ gbàdúrà ká lè fohùn pẹ̀lẹ́ dá wọn lóhùn tí wọ́n bá fi ìbínú sọ̀rọ̀. Torí pé a ò fẹ́ kí ìjíròrò wa débi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tó lè fa àríyànjiyàn, a kì í pẹ́ jù tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀.” Ohun kan ni pé, bó ti wù ká ṣe tó, àwọn mọ̀lẹ́bí wa ṣì lè gba ọ̀rọ̀ wa sódì. Ó lè máa ṣe wá bíi pé àwa la fà á, pàápàá torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, a ò sì fẹ́ múnú bí wọn. Tó bá ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀, rántí pé àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà ṣe pàtàkì ju àjọṣe ìwọ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ lọ. Tí wọ́n bá rí ọwọ́ tó o fi mú òtítọ́, wọ́n á mọ̀ pé kò sóhun táwọn lè ṣe láti dí ẹ lọ́wọ́. Bó ti wù kó rí, fi sọ́kàn pé o ò lè fipá mú ẹnikẹ́ni láti di Ẹlẹ́rìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí wọ́n rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa sin Jèhófà nínú ìwà rẹ. Ó ṣe tán, gbogbo èèyàn pátá ni Baba wa onífẹ̀ẹ́ fún láǹfààní láti wá jọ́sìn rẹ̀.​—Aísá. 48:​17, 18. w17.10 15-16 ¶15-16

Saturday, November 16

Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.​—1 Jòh. 3:18.

Ìfẹ́ wa ò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìfẹ́ orí ahọ́n, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni náà nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì. Bí àpẹẹrẹ, tí Kristẹni kan bá nílò àwọn nǹkan bí oúnjẹ, aṣọ àtàwọn ohun ìgbẹ́mìíró míì, a gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́, kì í ṣe ká kàn kí i pẹ̀lẹ́. (Ják. 2:​15, 16) Bákan náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa, a ò kàn ní máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ‘rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde fún ìkórè,’ kàkà bẹ́ẹ̀ àá máa fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Mát. 9:38) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé a gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ “ní ìṣe àti òtítọ́.” Torí náà, ìfẹ́ tá a ní gbọ́dọ̀ wà “láìsí àgàbàgebè.” (Róòmù 12:9; 2 Kọ́r. 6:6) Ìyẹn túmọ̀ sí pé a ò lè máa sọ pé à ń fìfẹ́ hàn tó sì jẹ́ pé ojú ayé lásán là ń ṣe. Ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ìfẹ́ tòótọ́ lè ní àgàbàgebè nínú?’ Kò sóhun tó jọ ọ́. Ká sòótọ́, tí ìfẹ́ bá ti ní àgàbàgebè nínú, kì í ṣe ìfẹ́ rárá, gbàrọgùdù lásán ni. w17.10 8 ¶5-6

Sunday, November 17

Kí o máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, . . . nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.​—Jóṣ. 1:8.

Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sa agbára láyé wa, a gbọ́dọ̀ máa kà á lójoojúmọ́. Òótọ́ ni pé kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé lè mú kí ọwọ́ wa dí gan-an, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ àtimáa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Kódà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ojúṣe pàtàkì tá a ní dí wa lọ́wọ́. (Éfé. 5:​15, 16) Ọ̀pọ̀ lára wa máa ń wáyè ka Bíbélì lójoojúmọ́, ì báà jẹ́ láàárọ̀, lálẹ́ tàbí lásìkò míì tó rọrùn fún wa. Ó máa ń ṣe wá bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sm. 119:97) Yàtọ̀ sí kíka Bíbélì lójoojúmọ́, ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà. (Sm. 1:​1-3) Ó dígbà tá a bá ṣàṣàrò ká tó mọ bó ṣe kàn wá àti bá a ṣe lè fi í sílò nígbèésí ayé wa. Ì báà jẹ́ Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ jáde tàbí ti orí fóònù là ń kà, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká jẹ́ kí ohun tá à ń kà wọ̀ wá lọ́kàn. w17.09 24 ¶4-5

Monday, November 18

Gbogbo yín, ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.​—1 Pét. 3:8.

Àwọn ìgbà míì wà tí kò tọ́ láti fàánú hàn. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Sọ́ọ̀lù gbà pé ṣe lòun ń ṣàánú Ágágì tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà tó dá ẹ̀mí rẹ̀ sí. Àmọ́ òdìkejì ohun tí Jèhófà sọ fún un ló ṣe, torí náà Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba. (1 Sám. 15:​3, 9, 15) Jèhófà jẹ́ Onídàájọ́ òdodo, ó mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, ó sì mọ ìgbà tí kò tọ́ láti fi àánú hàn. (Ìdárò 2:17; Ìsík. 5:11) Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn tó ń tàpá sí òfin àti ìlànà rẹ̀. (2 Tẹs. 1:​6-10) Kì í ṣe ìgbà yẹn ni Jèhófà máa fàánú hàn sí àwọn ẹni burúkú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àánú tí Jèhófà ní fáwọn olódodo máa jẹ́ kó pa àwọn ẹni ibi run, á sì dá ẹ̀mí àwọn olódodo sí. Ó ṣe kedere pé kì í ṣe tiwa láti pinnu àwọn tí Jèhófà máa pa run tàbí tó máa dá sí. Iṣẹ́ tiwa ni pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nísinsìnyí láti mọ Jèhófà. w17.09 10-11 ¶10-12

Tuesday, November 19

Èso ti ẹ̀mí ni . . . ìkóra-ẹni-níjàánu.​—Gál. 5:​22, 23.

Ìkóra-ẹni-níjàánu wà lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn rẹ̀ ní. Jèhófà máa ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu ní gbogbo ọ̀nà láìkù síbì kan. Torí pé aláìpé làwa èèyàn, ìdí nìyẹn tá a fi ń sapá ká lè ní ànímọ́ yìí. Ká sòótọ́, àìní ìkóra-ẹni-níjàánu ló fa ọ̀pọ̀ ìṣòro táwa èèyàn ní lónìí. Bí àpẹẹrẹ, òun ló ń jẹ́ káwọn kan máa fi nǹkan falẹ̀, òun ni kì í jẹ́ kí wọ́n ṣe dáadáa níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé. Àìsí ìkóra-ẹni-níjàánu ló ń mú káwọn èèyàn máa bú èébú, kí wọ́n máa mutí yó, kí wọ́n máa fa wàhálà, kí wọ́n tọrùn bọ gbèsè, òun ló sì ń fà á táwọn ìgbéyàwó kan fi ń tú ká. Kódà, àìní ìkóra-ẹni-níjàánu lè mú kéèyàn ṣẹ̀wọ̀n, kéèyàn kó àrùn ìbálòpọ̀, kéèyàn lóyún ẹ̀sín, ó sì lè paná ayọ̀ téèyàn ní, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Sm. 34:​11-14) Ṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń di aláìníjàánu. Láwọn ọdún 1940, wọ́n ṣe ìwádìí nípa báwọn èèyàn ṣe ń kó ara wọn níjàánu tó, àmọ́ ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn èèyàn ò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n máa kóra wọn níjàánu mọ́. Kò sì yà wá lẹ́nu torí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn máa jẹ́ “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.”​—2 Tím. 3:​1-3. w17.09 3 ¶1-2

Wednesday, November 20

Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín.​—Fílí. 4:7.

Tá a bá ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ọkàn wa máa balẹ̀, ara sì máa tù wá. A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ káyé wa dùn kó sì lóyin. (1 Pét. 5:10) Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, kì í sì í jẹ́ kí àníyàn bò wá mọ́lẹ̀. Láìpẹ́, aráyé máa dojú kọ ìpọ́njú tó tíì le jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé. (Mát. 24:​21, 22) A ò mọ bí nǹkan ṣe máa rí fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nígbà yẹn, síbẹ̀ kò sídìí fún wa láti máa ṣàníyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ gbogbo ohun tí Jèhófà máa ṣe, síbẹ̀ a mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. A ti rí i nínú àwọn ohun tó ti ṣe sẹ́yìn pé kò sí ohun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá ní lọ́kàn, ó sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà àrà. Gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún wa lọkàn wa máa balẹ̀, a sì máa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” w17.08 12 ¶16-17

Thursday, November 21

Ẹ mú sùúrù . . . títí di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa.​—Ják. 5:7.

Wòlíì Aísáyà àti Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Yóò ti pẹ́ tó?” (Aísá. 6:11; Háb. 1:2) Kódà Jésù Kristi Olúwa wa náà béèrè ìbéèrè yìí nígbà kan tó ń bá àwọn èèyàn tí kò nígbàgbọ́ sọ̀rọ̀. (Mát. 17:17) Torí náà, kò burú tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwa náà béèrè irú ìbéèrè yìí. Ó lè jẹ́ torí pé wọ́n fẹ̀tọ́ wa dù wá tàbí torí pé wọ́n hùwà àìdáa sí wa. Ó sì lè jẹ́ torí àìsàn tàbí ara tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ torí ọjọ́ ogbó. Bákan náà, ó lè jẹ́ àwọn ìṣòro tá à ń kojú nítorí bí nǹkan ṣe le koko lásìkò tá a wà yìí. (2 Tím. 3:1) Yàtọ̀ síyẹn, ìwàkiwà táwọn tó yí wa ká ń hù lè máa ni wá lára. Ohun yòówù kó jẹ́, ọkàn wa balẹ̀ pé kò burú tá a bá béèrè ìbéèrè yẹn torí pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ náà ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ò sì bínú sí wọn. Tá a bá bára wa nírú àwọn ipò yìí, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́? Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù tó jẹ́ àbúrò Jésù dáhùn ìbéèrè yìí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní. w17.08 3-4 ¶1-3

Friday, November 22

Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo.​—Lúùkù 16:9.

Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fi “ọrọ̀ àìṣòdodo” bá òun àti Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́. Ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ nínú bá a ṣe ń lo ọrọ̀ wa ni tá a bá ń fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀. (Mát. 24:14) Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kékeré kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà ní kóló kékeré kan, ó sì máa ń fowó sínú rẹ̀ lóòrèkóòrè, kódà ó máa ń fi owó tó yẹ kó fi ra nǹkan ìṣeré sínú kóló náà. Nígbà tí kóló náà kún, ọmọbìnrin náà fi gbogbo owó inú rẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Arákùnrin míì lórílẹ̀-èdè Íńdíà ní oko àgbọn. Ìgbà kan wà tó kó àgbọn rẹpẹtẹ wá sí ọ́fíìsì àwọn tó ń túmọ̀ èdè Malayalam, ó mọ̀ pé wọ́n máa ń nílò àgbọn, tóun bá sì fún wọn lágbọn, ìyẹn á dín ìnáwó wọn kù. Ká sòótọ́, ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ làwọn tá a sọ yìí lò. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará nílẹ̀ Gíríìsì máa ń fi òróró ólífì, wàràkàṣì àtàwọn oúnjẹ míì ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì. w17.07 8 ¶7-8

Saturday, November 23

Ẹ kọ ọ̀kan lára àwọn orin Síónì fún wa.​—Sm. 137:3.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì ò rí ìdí tí wọ́n fi máa kọrin. Wọ́n nílò ìtùnú gan-an. Àmọ́, bí Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀, Kírúsì ọba Páṣíà dá wọn nídè lẹ́yìn tó ṣẹ́gun Bábílónì. Kírúsì kéde pé: “Jèhófà . . . ti fàṣẹ yàn mí pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù . . . Ẹnì yòówù tí ń bẹ láàárín yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀, kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí náà, kí ó gòkè lọ.” (2 Kíró. 36:23) Ó dájú pé inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé ní Bábílónì máa dùn gan-an láti gbọ́ pé àwọn máa tó pa dà sílùú àwọn. Bí Jèhófà ṣe ń tu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú lápapọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ń tù wọ́n nínú lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ohun kan náà ló ń ṣe lónìí. Ọlọ́run “ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sm. 147:3) Ó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́, yálà ẹ̀dùn ọkàn ni wọ́n ní tàbí ìṣòro míì. Ó máa ń wu Jèhófà láti tù wá nínú, pàápàá nígbà tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn. (Sm. 34:18; Aísá. 57:15) Ó sì máa ń fún wa ní ọgbọ́n àti okun tá a nílò ká lè fara da àwọn ìṣòro wa.​—Ják. 1:5. w17.07 18 ¶4-5

Sunday, November 24

Ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà yín yóò wà pẹ̀lú.​—Lúùkù 12:34.

Jèhófà baba wa ọ̀run ló lọ́lá jù lọ láyé àti lọ́run. (1 Kíró. 29:​11, 12) Torí pé ọ̀làwọ́ ni, tinútinú ló fi máa ń fáwa èèyàn lára ohun tó ní pàápàá jù lọ àwọn tó mọyì ọrọ̀ tẹ̀mí. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà fún wa láwọn ìṣúra tẹ̀mí! Lára wọn ni (1) Ìjọba Ọlọ́run, (2) iṣẹ́ ìwàásù tá a fi ń gbẹ̀mí là, àti (3) òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, tá ò bá kíyè sára, a lè má mọyì àwọn nǹkan yìí mọ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ pa wọ́n tì. Tá ò bá fẹ́ káwọn ìṣúra tẹ̀mí yìí bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ mọyì wọn, ká sì máa ṣìkẹ́ wọn nígbà gbogbo. Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ wa ti ṣe àwọn àyípadà kan ká lè di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Róòmù 12:2) Àmọ́ bíná ò bá tán láṣọ, ẹ̀jẹ̀ kì í tán léèékánná. A gbọ́dọ̀ kíyè sára kó má lọ di pé àwọn nǹkan bí ìfẹ́ ọrọ̀ tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara máa gbà wá lọ́kàn débi tí ìfẹ́ tá a ní fún Ìjọba Ọlọ́run máa wá di tútù.​—Òwe 4:23; Mát. 5:​27-29. w17.06 9 ¶1; 10 ¶7

Monday, November 25

Ìwọ ha ti wá mọ̀?​—Jóòbù 38:21.

Kò síbi tí Jèhófà ti sọ ohun tó fa ìyà tó ń jẹ Jóòbù fún un. Jèhófà ò ṣàlàyé ìdí tí Jóòbù fi ń jìyà fún un bí ẹni pé Jèhófà fẹ́ gbèjà ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà fẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé kò ju bíńtín bí orí abẹ́rẹ́ ní ìfiwéra sí òun. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún mú kí Jóòbù rí i pé ọ̀rọ̀ míì wà tó ṣe pàtàkì ju ìyà tó ń jẹ ẹ́ lọ, ìyẹn ló sì yẹ kó fọkàn sí. (Jóòbù 38:​18-20) Ohun tí Jèhófà ṣe yẹn mú kí Jóòbù tún inú rò, ó sì wá ní èrò tó tọ́. Ṣé ìbáwí tó sojú abẹ níkòó tí Jèhófà fún Jóòbù yẹn kò le jù pẹ̀lú gbogbo ohun tójú Jóòbù ti rí? Rárá, kódà Jóòbù alára kò sọ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà le. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà náà ò dẹrùn, síbẹ̀ ó mọrírì ìbáwí tí Jèhófà fún un. Ó tiẹ̀ sọ pé: ‘Mo yíhùn pa dà, mo sì ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.’ Jèhófà sojú abẹ níkòó lóòótọ́, àmọ́ ó tu Jóòbù lára. (Jóòbù 42:​1-6) Lẹ́yìn tí Jóòbù gba ìbáwí tí Jèhófà fún un tó sì tún èrò rẹ̀ pa, Jèhófà jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé inú òun dùn bí Jóòbù ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí òun láìka àdánwò tó kojú.​—Jóòbù 42:​7, 8. w17.06 24-25 ¶11-12

Tuesday, November 26

Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.​—Lúùkù 10:42.

Ká lè mọ̀ bóyá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tá à ń ṣe kò pa àwọn ojúṣe wa nípa tẹ̀mí lára, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé ó máa ń yá mi lára láti ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi, àmọ́ tó bá dọ̀rọ̀ nǹkan tẹ̀mí kì í yá mi lára?’ Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí, á jẹ́ ká mọ ohun tá a fẹ́ràn jù. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan tẹ̀mí ló yẹ kó ṣáájú láyé wa. Nígbà kan tí Jésù lọ sílé Màríà àti Màtá, ṣe ni Màtá ń sá sókè sódò láti se oúnjẹ, àmọ́ Màríà ní tiẹ̀ jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù, ó sì ń tẹ́tí sí i. Nígbà tí Màtá ṣàròyé pé Màríà kò ran òun lọ́wọ́, Jésù dá Màtá lóhùn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní. (Lúùkù 10:​38-42) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ Màtá ní ẹ̀kọ́ pàtàkì. Táwa náà ò bá fẹ́ kí iṣẹ́ wa gbà wá lọ́kàn ju bó ti yẹ lọ, ká sì lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Kristi, a gbọ́dọ̀ “yan ìpín rere,” ká máa fàwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú láyé wa. w17.05 24 ¶9-10

Wednesday, November 27

Fetí sílẹ̀ . . . sí ìbáwí baba rẹ.​—Òwe 1:8.

Ojúṣe tí Jèhófà fáwọn òbí ni pé kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú òtítọ́, kì í ṣe ojúṣe àwọn òbí wọn àgbà tàbí ti ẹlòmíì. (Òwe 31:​10, 27, 28) Síbẹ̀, táwọn òbí kan ò bá gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ ládùúgbò tí wọ́n ṣí lọ, ó lè gba pé káwọn míì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè dọ́kàn àwọn ọmọ náà. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò sọ pé wọ́n ti gbéṣẹ́ wọn fún ẹlòmíì ṣe. Ṣe ni wọ́n fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè ní káwọn alàgbà gba àwọn nímọ̀ràn nípa báwọn ṣe lè máa ṣe ìjọsìn ìdílé àti báwọn ṣe lè rí ọ̀rẹ́ gidi fáwọn ọmọ wọn nínú ètò Ọlọ́run. Látìgbàdégbà, àwọn òbí lè máa pe àwọn ìdílé míì wá sí ìjọsìn ìdílé wọn. Yàtọ̀ síyẹn, táwọn ọ̀dọ́ bá ń bá àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú ṣọ̀rẹ́, wọ́n máa ń tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa bá irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí kí wọ́n jọ lọ gbafẹ́.​—Òwe 27:17. w17.05 11-12 ¶17-18

Thursday, November 28

Sá lọ sí Íjíbítì.​—Mát. 2:13.

Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì Jèhófà kìlọ̀ fún Jósẹ́fù pé Ọba Hẹ́rọ́dù ń wá bó ṣe máa pa Jésù, Jósẹ́fù mú Màríà àti Jésù, wọ́n sì sá lọ sí Íjíbítì. Ibi ìsádi yẹn ni wọ́n wà títí Hẹ́rọ́dù fi kú. (Mát. 2:​14, 19-21) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ṣe inúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, èyí sì mú kí wọ́n “tú ká jákèjádò àwọn ẹkùn ilẹ̀ Jùdíà àti Samáríà.” (Ìṣe 8:1) Jésù náà mọ̀ pé tó bá yá, ó máa pọn dandan fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun láti sá kúrò nílùú wọn. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Nígbà tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín ní ìlú ńlá kan, ẹ sá lọ sí òmíràn.” (Mát. 10:23) Bí nǹkan ṣe rí fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà nìyẹn. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti pàdánù gbogbo ohun ìní wọn, kódà wọ́n ti pàdánù àwọn èèyàn wọn. Ọ̀pọ̀ ewu làwọn tó ń wá ibi ìsádi máa ń kojú tí wọ́n bá ń sá kúrò nílùú àti nígbà tí wọ́n bá dé ibùdó àwọn tó ń wá ibi ìsádi. Ohun tí wọ́n ń ṣe ò ju pé kí wọ́n mutí, kí wọ́n ta tẹ́tẹ́, kí wọ́n jalè, kí wọ́n sì máa ṣèṣekúṣe. Àmọ́ àwọn ará gbà pé bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú aginjù, lọ́jọ́ kan, àwọn náà máa kúrò nínú ibùdó yẹn.​—2 Kọ́r. 4:18. w17.05 3-4 ¶2-5

Friday, November 29

Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ, kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.​—Sm 119:165.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ṣeé ṣe kẹ́nì kan ṣàìdáa sí ẹ nínú ìjọ tàbí sí ẹnì kan tó o mọ̀, ó sì lè jẹ́ pé ṣe lo kàn rò bẹ́ẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, má ṣe jẹ́ kíyẹn mú ẹ kọsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká jẹ́ adúróṣinṣin sí i, ká sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. Bákan náà, ó yẹ ká rántí pé a lè má mọ bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́ gan-an. Ká máa fi sọ́kàn pé ó lè jẹ́ ojú táwa náà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà ni kò tọ́. A ò gbọ́dọ̀ máa sọ ọ̀rọ̀ náà kiri, tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe la kàn máa dá kún ìṣòro tó wà nílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, dípò ká máa wá bá a ṣe máa gbèjà ara wa, ẹ jẹ́ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ká sì ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà máa yanjú ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì bù kún wa. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà, ‘Onídàájọ́ ilẹ̀ ayé,’ máa ń ṣe ohun tó tọ́, “nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.”​—Jẹ́n. 18:25; Diu. 32:4. w17.04 22 ¶17

Saturday, November 30

Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀. Kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí yóò ṣàánú fún un.​—Aísá. 55:7.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò bá yí pa dà, tí wọ́n ń lúwẹ̀ẹ́ nínú ìwà burúkú ayé yìí títí dìgbà ìpọ́njú ńlá? Jèhófà ti pinnu pé gbogbo àwọn èèyàn burúkú lòun máa pa run yán-án-yán. (Sm. 37:10) Àwọn èèyàn burúkú lè rò pé àwọn máa yè bọ́. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti gbówọ́ nínú kéèyàn máa fi ìwà búburú wọn pa mọ́, ó sì jọ pé wọ́n máa ń mú un jẹ nígbà míì. (Jóòbù 21:​7, 9) Bó ti wù kó rí, Bíbélì sọ pé: “Ojú [Ọlọ́run] ń bẹ ní àwọn ọ̀nà ènìyàn, ó sì ń rí ìṣísẹ̀ rẹ̀ gbogbo. Kò sí òkùnkùn tàbí ibú òjìji èyíkéyìí fún àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ láti fi ara wọn pa mọ́ níbẹ̀.” (Jóòbù 34:​21, 22) Kò síbi tẹ́nì kan lè sá pa mọ́ sí tí Ọlọ́run kò ní rí i. Kò sí afàwọ̀rajà tó lè tan Ọlọ́run jẹ, kò sí bí òkùnkùn ṣe kùn tó tàbí bí òjìji kan ṣe dúdú tó tí ojú Ọlọ́run kò ní rí. Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, ó lè wù wá láti wá àwọn èèyàn burúkú yẹn, àmọ́ a ò ní rí wọn. Wọn ò ní sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni, a ò ní rí wọn mọ́ títí láé!​—Sm. 37:​12-15. w17.04 10 ¶5

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́