May
Saturday, May 1
Sọ fún wa ohun tí a máa ṣe nípa ọmọ tí a máa bí.—Oníd. 13:8.
Kí làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe káwọn ọmọ wọn lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Bíi ti Mánóà, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀, àmọ́ ìwà wa gan-an ló máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ jù. Ó dájú pé àpẹẹrẹ rere ni Jósẹ́fù àti Màríà fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn títí kan Jésù. Jósẹ́fù ṣiṣẹ́ kára kó lè bójú tó ìdílé rẹ̀. Bákan náà, ó mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Diu. 4:9, 10) Jósẹ́fù máa ń mú ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù “lọ́dọọdún” láti ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. (Lúùkù 2:41, 42) Àwọn olórí ìdílé kan lè ronú pé kò sídìí káwọn ṣe bẹ́ẹ̀ torí á tán àwọn lókun, á ná àwọn lówó, kò sì ní rọrùn. Àmọ́, ó ṣe kedere pé Jósẹ́fù mọyì nǹkan tẹ̀mí, ó sì kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ẹ̀rí fi hàn pé Màríà mọ Ìwé Mímọ́ gan-an, ó sì dájú pé ó kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́rọ̀ àti níṣe láti nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. w19.12 24-25 ¶9-12
Sunday, May 2
Mo jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.—Róòmù 7:14.
Ohun tí Jèhófà ṣe lẹ́yìn tí Ádámù ṣàìgbọràn tún fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. Nígbà tí Ádámù ṣàìgbọràn sí Baba rẹ̀ ọ̀run, kò sí lára ìdílé Jèhófà mọ́, bó sì ṣe rí fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ náà nìyẹn. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, Jèhófà ò pa wá tì, ó tún ràn wá lọ́wọ́. Jèhófà fìyà tó tọ́ jẹ Ádámù, àmọ́ ó ṣèlérí pé òun máa dá àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ nídè. Kété lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ náà ni Jèhófà ṣèlérí pé àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn lára ọmọ Ádámù máa pa dà sínú ìdílé òun. (Jẹ́n. 3:15; Róòmù 8:20, 21) Jèhófà mú kíyẹn ṣeé ṣe lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Bí Jèhófà ṣe yọ̀ǹda kí Ọmọ rẹ̀ kú fún wa fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Jòh. 3:16) Baba tó ju baba lọ ni. Ó máa ń gbọ́ àdúrà wa, ó sì ń pèsè ohun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ó máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń tì wá lẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ṣètò ọjọ́ iwájú aláyọ̀ fún wa. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an! w20.02 6 ¶16-17; 7 ¶20
Monday, May 3
Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.—Sm. 94:19.
Ǹjẹ́ o ti kojú ìṣòro tó mú kó o ṣàníyàn rí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun táwọn kan sọ tàbí ohun tí wọ́n ṣe ló mú kó o máa ṣàníyàn. Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ ohun tó o sọ tàbí ohun kan tó o ti ṣe sẹ́yìn ló mú kó o máa ṣàníyàn. Bí àpẹẹrẹ, àṣìṣe tó o ti ṣe sẹ́yìn lè mú kó o máa ronú pé bóyá ni Jèhófà lè dárí jì ẹ́. Ibi tọ́rọ̀ tiẹ̀ tún wá burú sí ni pé o lè máa ronú pé torí pé o ò nígbàgbọ́ lo ṣe ń ṣàníyàn tàbí pé o ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan látinú Bíbélì. Obìnrin tó nígbàgbọ́ ni Hánà tó wá di ìyá wòlíì Sámúẹ́lì. Àmọ́, nígbà kan orogún rẹ̀ pẹ̀gàn rẹ̀ débi pé ńṣe ló máa ń sunkún, ìyẹn sì mú kó ní ìdààmú ọkàn. (1 Sám. 1:7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, ìgbà kan wà tóun náà ní “àníyàn lórí gbogbo ìjọ.” (2 Kọ́r. 11:28) Ọba Dáfídì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára débi pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. (Ìṣe 13:22) Síbẹ̀ Dáfídì ṣe àwọn àṣìṣe tó mú kí ìdààmú ọkàn bá a. (Sm. 38:4) Jèhófà tu àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí nínú, ó sì tù wọ́n lára. w20.02 20 ¶1-2
Tuesday, May 4
Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀.—Mát. 16:24.
Tó o bá fẹ́ ya ara ẹ sí mímọ́, wàá gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, wàá sì sọ fún un pé òun lo máa fayé rẹ sìn títí láé. Bíbélì sọ pé ẹni tó bá ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà “sẹ́ ara rẹ̀.” Tó o bá yara ẹ sí mímọ́, ó túmọ̀ sí pé ìwọ kọ́ lo ni ara ẹ mọ́, ti Jèhófà lo jẹ́, àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ sì nìyẹn. (Róòmù 14:8) Ńṣe lò ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ fún Jèhófà pé láti ìsinsìnyí lọ, ìfẹ́ rẹ̀ ni wàá máa ṣe kì í ṣe ìfẹ́ tìrẹ. Ẹ̀jẹ́ tàbí ìlérí pàtàkì ni ìyàsímímọ́ tó o ṣe jẹ́. Jèhófà kì í fipá múni láti jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí. Àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó retí pé ká mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. (Sm. 116:12, 14) Kò sẹ́ni tó mọ̀ nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́, àárín ìwọ àti Jèhófà nìkan lọ̀rọ̀ náà mọ. Àmọ́ ó ṣojú àwọn míì nígbà tó o ṣèrìbọmi, bóyá ní àpéjọ àyíká tàbí ti agbègbè. Nígbà tó o ṣèrìbọmi, ńṣe lò ń jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé o ti yara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Lédè míì, ò ń jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ara rẹ, gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ. Bákan náà, o ti pinnu pé Jèhófà ni wàá fayé rẹ sìn títí láé.—Máàkù 12:30. w20.03 9 ¶4-5
Wednesday, May 5
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan kó yín ṣìnà.—2 Tẹs. 2:3.
Sátánì ń mú káwọn èèyàn gbàgbé Jèhófà. Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì Jésù, àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ẹ̀kọ́ èké kọ́ni. (Ìṣe 20:29, 30) Àwọn apẹ̀yìndà yìí bẹ̀rẹ̀ sí í mú káwọn èèyàn gbàgbé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn, wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ bí “Olúwa” rọ́pò rẹ̀. Bí wọ́n ṣe fi “Olúwa” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run mú kó ṣòro fáwọn tó ń ka Bíbélì láti rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn “olúwa” míì tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn. (1 Kọ́r. 8:5) Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “Olúwa” fún Jèhófà àti Jésù mú kó ṣòro láti mọ̀ pé àwọn méjèèjì kì í ṣe ẹnì kan náà àti pé ipò wọn yàtọ̀ síra. (Jòh. 17:3) Ìdàrúdàpọ̀ yìí wà lára ohun tó mú kí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tó jẹ́ ẹ̀kọ́ èké gbilẹ̀, ó sì tún mú kí ọ̀pọ̀ máa ronú pé àdììtú ni Ọlọ́run, a ò sì lè mọ irú ẹni tó jẹ́. Ẹ ò rí i pé ìtànjẹ gbáà nìyẹn!—Ìṣe 17:27. w19.06 5 ¶11
Thursday, May 6
Ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láìkù síbì kan.—2 Tím. 4:5.
Ọ̀kan lára ohun táá mú ká ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyanjú ni pé ká túbọ̀ máa sunwọ̀n sí i nínú bá a ṣe ń wàásù. (Òwe 1:5; 1 Tím. 4:13, 15) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà fún wa láǹfààní pé ká jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́” òun! (1 Kọ́r. 3:9) Tó o bá “wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” tó o sì jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbawájú nígbèésí ayé rẹ, ó dájú pé wàá máa “fi ayọ̀ sin Jèhófà.” (Fílí. 1:10; Sm. 100:2) Láìka ipò rẹ sí, torí pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ẹ́, o ò ní ṣiyèméjì pé Jèhófà máa fún ẹ lágbára tó o nílò láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyanjú. (2 Kọ́r. 4:1, 7; 6:4) Yálà ipò rẹ fún ẹ láyè láti ṣe púpọ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, wàá “láyọ̀” tó o bá ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ yìí. (Gál. 6:4) Tó o bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyanjú tàbí láìkù síbì kan, ṣe lò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, “wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.”—1 Tím. 4:16. w19.04 6 ¶15; 7 ¶17
Friday, May 7
Sátánì . . . ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà.—Ìfi. 12:9.
Ọ̀nà kan gbòógì tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ni ìbẹ́mìílò. Àwọn abẹ́mìílò gbà pé àwọn mọ ohun táwọn míì ò mọ̀, àwọn sì lágbára àrà ọ̀tọ̀ láti darí àwọn nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ àtàwọn awòràwọ̀ gbà pé àwọn lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àwọn míì máa ń ṣe bíi pé àwọn ń bá òkú sọ̀rọ̀. Àwọn kan gbà pé àjẹ́ làwọn, àwọn míì sì ń pidán, wọ́n máa ń gbìyànjú láti fi èèdì di àwọn èèyàn tàbí láti tú wọn sílẹ̀. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè méjìdínlógún (18) ní Latin America àtàwọn erékùṣù Caribbean, wọ́n rí i pé ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn ibẹ̀ ló gbà gbọ́ nínú idán pípa, iṣẹ́ àjẹ́ tàbí iṣẹ́ oṣó, wọ́n sì tún gbà pé ó ṣeé ṣe láti bá òkú sọ̀rọ̀. Wọ́n tún ṣe irú ìwádìí kan náà láwọn orílẹ̀-èdè méjìdínlógún (18) nílẹ̀ Áfíríkà. Ìwádìí náà fi hàn pé àwọn tó ju ìdajì ló gbà gbọ́ pé àwọn àjẹ́ wà. Kókó ibẹ̀ ni pé, ibi yòówù ká máa gbé, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò. w19.04 20-21 ¶3-4
Saturday, May 8
Ẹ . . . máa kíyè sára, kó má bàa sí ẹnì kankan láàárín yín tó jẹ́ oníṣekúṣe.—Héb. 12:16.
Jèhófà Ọlọ́run kórìíra gbogbo ìwà ìkà. (Sm. 5:4-6) Ẹ wo bó ṣe máa kó o ní ìríra tó pé ẹnì kan ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe torí pé ìwà ìkà tí ò ṣeé gbọ́ sétí ni! Ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwà ìkà yìí làwa èèyàn rẹ̀ náà fi ń wò ó. A kórìíra ìwà burúkú yìí tẹ̀gbintẹ̀gbin, a ò fàyè gba irú ẹ̀ rárá láàárín wa, a kì í sì í gbójú fò ó tí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ bá dán irú ẹ̀ wò. (Róòmù 12:9) Ńṣe lẹni tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ń tẹ “òfin Kristi” lójú! (Gál. 6:2) Orí ìfẹ́ la gbé gbogbo ohun tí Jésù fi kọ́ni àtohun tó ṣe kà, ó sì gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ. Torí pé òfin yìí làwa Kristẹni ń tẹ̀ lé, a máa ń ṣe ohun táá fi àwọn ọmọdé lọ́kàn balẹ̀, táá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ojúlówó ìfẹ́ la ní sí àwọn. Àmọ́ ìwà burúkú gbáà ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe jẹ́, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan sì ni. Ìwà yìí máa ń mú kẹ́rù ba àwọn ọmọdé, kì í jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò fìfẹ́ hàn. Ohun tó bani nínú jẹ́ ni pé ìwà burúkú yìí ti ń yọ́ wọnú ìjọ. Ìdí sì ni pé “àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà” ti gbòde kan, lára wọn sì ti ń yọ́ wọnú ìjọ. (2 Tím. 3:13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fàyè gba èròkerò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìyẹn sì ti mú kí wọ́n bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe. w19.05 8 ¶1-3
Sunday, May 9
Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.—Jém. 5:16.
Ó lè má rọrùn fún ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn láti gbàdúrà. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè máa ronú pé Jèhófà ò lè tẹ́tí sí èèyàn bíi tòun. Tá a bá wà pẹ̀lú ẹni náà, a lè gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀, ká sì dárúkọ rẹ̀ nínú àdúrà náà, ìyẹn á sì jẹ́ kára tù ú. Nínú àdúrà náà, a lè sọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó àti bí gbogbo àwọn ará ìjọ ṣe fẹ́ràn rẹ̀. A tún lè bẹ Jèhófà pé kó tu àgùntàn rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí nínú, kọ́kàn rẹ̀ lè balẹ̀. Ó dájú pé irú àdúrà bẹ́ẹ̀ máa tu ẹni náà nínú gan-an. Ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Téèyàn bá sọ̀rọ̀ láìronú, ó lè dá kún ọgbẹ́ ọkàn ẹni náà, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mára tuni. (Òwe 12:18) Torí náà bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ ọ̀rọ̀ tó o lè lò táá mára tù ú, táá fi í lọ́kàn balẹ̀, táá sì múnú rẹ̀ dùn. Tún fi sọ́kàn pé kò sí ọ̀rọ̀ tó lè tuni nínú bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì. (Héb. 4:12) Tá a bá ń tu àwọn míì nínú, ṣe là ń rán wọn létí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Ká má sì gbàgbé pé Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà. Kò sí ìwà burúkú tẹ́nì kan hù tó bò. Gbogbo ẹ̀ ni Jèhófà ń rí, kò sì ní ṣàìfi ìyà jẹ oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà.—Nọ́ń. 14:18. w19.05 18 ¶18; 19 ¶19, 21
Monday, May 10
Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má fi ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán mú yín lẹ́rú látinú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn.—Kól. 2:8.
Ohun tí Sátánì ń fẹ́ ni pé ká kẹ̀yìn sí Jèhófà. Kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ ohun tó ń fẹ́, ó máa ń sapá láti yí èrò wa pa dà. Lédè míì, Sátánì fẹ́ ká máa ronú bíi tòun, ká sì máa ṣe ohun tó fẹ́. Ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí ló sì máa ń lò láti tàn wá jẹ. (Kól. 2:4) Ṣé òótọ́ ni pé Sátánì lè tàn wá jẹ? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ẹ rántí pé àwọn Kristẹni ni ìkìlọ̀ tó wà nínú Kólósè 2:8 wà fún. Kódà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yẹn sí. (Kól. 1:2, 5) Tí Sátánì bá lè tan àwọn Kristẹni kan jẹ nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ó dájú pé ó lè tan àwa náà jẹ lónìí. (1 Kọ́r. 10:12) Kí nìdí? Ìdí ni pé a ti fi Sátánì sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé. Torí náà, bó ṣe máa ṣi àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́nà ló gbájú mọ́. (Ìfi. 12:9, 12, 17) Yàtọ̀ síyẹn, àsìkò táwọn èèyàn burúkú àtàwọn afàwọ̀rajà túbọ̀ ń “burú sí i” là ń gbé yìí.—2 Tím. 3:1, 13. w19.06 2 ¶1-2
Tuesday, May 11
Ó tó gẹ́ẹ́! Jèhófà, gba ẹ̀mí mi.—1 Ọba 19:4.
Ẹ̀rù ba Èlíjà nígbà tí Ayaba Jésíbẹ́lì sọ pé òun máa gbẹ̀mí ẹ̀. Torí náà, Èlíjà sá lọ sí agbègbè Bíá-ṣébà. Ìdààmú ọkàn bá a débi pé ó sọ fún Jèhófà pé ó sàn “kí òun kú.” Kí ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀? Ohun kan ni pé Èlíjà kì í ṣe ẹni pípé, “ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa” lòun náà. (Jém. 5:17) Yàtọ̀ síyẹn, ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn tó rìn ti mú kó rẹ̀ ẹ́, kò sì lókun mọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó máa ronú pé gbogbo ìsapá òun láti mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn Jèhófà ti já sásán àti pé òun nìkan lòun ń sin Jèhófà. (1 Ọba 18:3, 4, 13; 19:10, 14) Ọ̀rọ̀ ẹ̀ yé Jèhófà, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Jèhófà ò bá a wí torí pé ó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fún un lókun. (1 Ọba 19:5-7) Nígbà tó yá, Jèhófà fìfẹ́ tún èrò Èlíjà ṣe, ó sì jẹ́ kó rí bí agbára òun ṣe pọ̀ tó. Jèhófà wá sọ fún un pé àwọn ẹgbẹ̀rún méje (7,000) míì ṣì wà ní Ísírẹ́lì tí wọn ò jọ́sìn Báálì. (1 Ọba 19:11-18) Àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe yìí mú kí Èlíjà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. w19.06 15-16 ¶5-6
Wednesday, May 12
[Ẹ] máa tẹrí ba fún àwọn àgbà ọkùnrin. . . . [Ẹ] gbé ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀ nínú àjọṣe yín, torí Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga.—1 Pét. 5:5.
Mọ̀wọ̀n ara rẹ, má ṣe kọjá àyè rẹ. Ó ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn arákùnrin tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n ń múpò iwájú. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní fa ìṣòro fún ara wa tàbí fún àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn tó ń múpò iwájú sọ fún àwọn akéde pé kí wọ́n má ṣe fún àwọn èèyàn ní ìtẹ̀jáde wa tí wọ́n bá wàásù fún wọn. Síbẹ̀, arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan gbà pé òun gbọ́n jùyẹn lọ, kò sì fi ìtọ́ni náà sílò, ṣe ló ń fún àwọn èèyàn ní ìwé wa. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Kò pẹ́ tí òun àtàwọn míì parí wíwàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà làwọn ọlọ́pàá mú wọn tí wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Ó ṣeé ṣe káwọn aṣojú ìjọba ti máa ṣọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan síbòmíì, wọ́n sì gba gbogbo ìwé yẹn lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fún. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni, ká má ṣe ronú pé a gbọ́n ju àwọn tó ń múpò iwájú. Inú Jèhófà máa ń dùn bá a ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó yàn sípò.—Héb. 13:7, 17. w19.07 12 ¶17
Thursday, May 13
Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.—2 Tím. 3:12.
Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n máa pa Jésù Olúwa wa, ó sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Jòh. 17:14) Àtìgbà yẹn làwọn tó kórìíra ìjọsìn tòótọ́ ti ń ṣe inúnibíni sáwa ìránṣẹ́ Jèhófà, wọn ò sì jáwọ́ títí di àsìkò wa yìí. Torí náà, bí òpin ayé búburú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé bẹ́ẹ̀ làwọn ọ̀tá wa á túbọ̀ máa koná mọ́ àtakò tí wọ́n ń ṣe sí wa. (Mát. 24:9) Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni? Kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká máa ronú nípa onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe inúnibíni sí wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù á máa bà wá, àá sì máa ṣàníyàn. Àmọ́ kò yẹ ká kú sílẹ̀ de ikú báwọn èèyàn ṣe máa ń sọ. (Òwe 12:25; 17:22) Ìbẹ̀rù wà lára àwọn ohun ìjà tí ‘Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá wa’ máa ń lò láti bá wa jà. (1 Pét. 5:8, 9) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká mú kí àjọṣe tó wà láàárín àwa àti Jèhófà túbọ̀ gún régé nísinsìnyí. w19.07 2 ¶1-3
Friday, May 14
Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19.
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ṣètò ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lórí òkè kan ní Gálílì. Ó dájú pé ara wọn á ti wà lọ́nà láti rí Jésù, kí wọ́n sì gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ. (Mát. 28:16) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibẹ̀ ló ti “fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (1 Kọ́r. 15:6) Kí nìdí tí Jésù fi ṣètò ìpàdé yìí? Ìdí ni pé ó fẹ́ gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé wọn lọ́wọ́. Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:18-20) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù lọ́jọ́ yẹn ló wá di ara ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù gbé fún wọn ni pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn òun. Lónìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìjọ Kristẹni tòótọ́ ló wà kárí ayé, iṣẹ́ yìí làwọn náà sì ń ṣe. w19.07 14 ¶1-2
Saturday, May 15
Ayé wà títí láé.—Oníw. 1:4.
Alábòójútó arìnrìn àjò kan lórílẹ̀-èdè Nọ́wè sọ pé lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Lẹ́yìn tó bá ti kí àwọn èèyàn, ó máa ń sọ pé: “Báwo lẹ ṣe rò pé ọjọ́ ọ̀la wa máa rí? Ṣé ẹ rò pé àwọn olóṣèlú tàbí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló máa yanjú gbogbo ìṣòro wa àbí ẹlòmíì ló máa ṣe é?” Tó bá ti tẹ́tí sí wọn dáadáa, á ka ẹsẹ Bíbélì kan tó sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ fún wọn tàbí kó tọ́ka sí i. Inú àwọn kan máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá mọ̀ pé ayé yìí ò ní pa run àti pé àwọn èèyàn rere lá máa gbé inú rẹ̀ títí láé. (Sm. 37:29) Oríṣiríṣi ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ló yẹ ká máa lò bá a ṣe ń bá onírúurú èèyàn pàdé. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn èèyàn yàtọ̀ síra. Tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ sí kókó ọ̀rọ̀ kan, ẹlòmíì lè má fẹ́ gbọ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn kan lè tẹ́tí sí wa tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tàbí Bíbélì, síbẹ̀ ara àwọn kan kì í yá láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àfi kéèyàn fọgbọ́n sọ ọ́. Èyí ó wù kó jẹ́, ẹ jẹ́ ká lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti wàásù fún onírúurú èèyàn. (Róòmù 1:14-16) Síbẹ̀, a ò ní gbàgbé pé Jèhófà ló ń mú kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ọkàn àwọn ẹni yíyẹ.—1 Kọ́r. 3:6, 7. w19.07 22-23 ¶10-11
Sunday, May 16
Tó bá jẹ́ pé bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa nìyí, àwa náà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa.—1 Jòh. 4:11.
Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló ń mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (1 Jòh. 4:20, 21) A lè ronú pé ó rọrùn gan-an láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, àbí ta lèèyàn ì bá tún nífẹ̀ẹ́ bí kò ṣe àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà? Ó ṣe tán, gbogbo wa là ń sapá ká lè fìwà jọ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, a sì mọyì bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Àmọ́ ká sòótọ́, àwọn ìgbà kan lè wà tó máa ń ṣòro láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pa láṣẹ. Yúódíà àti Síńtíkè nítara gan-an, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Síbẹ̀, èdèkòyédè wáyé láàárín àwọn obìnrin méjèèjì yìí. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ yẹn, ó dìídì dárúkọ Yúódíà àti Síńtíkè, ó sì gbà wọ́n níyànjú láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé “kí wọ́n ní èrò kan náà.” (Fílí. 4:2, 3) Pọ́ọ̀lù tún sọ fáwọn ará ìjọ yẹn lápapọ̀ pé: “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn.”—Fílí. 2:14. w19.08 9 ¶6-7
Monday, May 17
Ẹ máa bá ara yín gbé ẹrù tó wúwo.—Gál. 6:2.
Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ìjọ àtàwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń ṣe bẹbẹ tó bá di pé kí wọ́n ran àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n má fiṣẹ́ náà sílẹ̀, wọ́n sì máa ń fowó àtàwọn nǹkan míì ránṣẹ́ sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan máa ń bá wọn bójú tó òbí wọn tó wà nílé. Tí nǹkan bá yí pa dà fáwọn tó wà nínú iṣẹ́ alákòókò kíkún tí wọ́n sì kó wá sí ìjọ yín, ẹ má ṣe fojú burúkú wò wọ́n bíi pé ṣe ni ètò Ọlọ́run bá wọn wí tàbí pé wọ́n gbaṣẹ́ lọ́wọ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti mú kára tù wọ́n. Ẹ gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, ẹ gbóríyìn fún wọn torí iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ti ṣe kódà tí àìlera ò bá jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ẹ sún mọ́ wọn kẹ́ ẹ lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n. Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn torí pé ọ̀pọ̀ ìrírí ni wọ́n ní, ètò Ọlọ́run sì ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ gan-an. Níbẹ̀rẹ̀, ó máa gba pé kẹ́ ẹ ṣèrànwọ́ fáwọn tí iṣẹ́ ìsìn wọn yí pa dà, bóyá kẹ́ ẹ bá wọn wá ilé tàbí iṣẹ́. Ó sì lè gba pé kẹ́ ẹ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń wọkọ̀ ládùúgbò yín àti bí wọ́n ṣe ń ra nǹkan. w19.08 23-24 ¶12-13
Tuesday, May 18
[Màá jẹ́ kí wọ́n] mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí mo ṣe sí ọ, ìwọ Gọ́ọ̀gù.—Ìsík. 38:16.
Gọ́ọ̀gù máa gbára lé “agbára èèyàn,” ìyẹn àwọn ọmọ ogun rẹ̀. (2 Kíró. 32:8) Àmọ́ ní tiwa, Jèhófà Ọlọ́run wa la máa gbẹ́kẹ̀ lé, ìyẹn sì máa dà bí ìwà òmùgọ̀ lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n á ronú pé bí ọlọ́run àwọn ẹ̀sìn Bábílónì Ńlá kò bá lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ “ẹranko náà” àti “ìwo mẹ́wàá” rẹ̀, mélòómélòó àwa! (Ìfi. 17:16) Torí náà, Gọ́ọ̀gù máa ronú pé wẹ́rẹ́ báyìí lòun máa pa wá run. Nípa bẹ́ẹ̀, á gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà “bí ìgbà tí ìkùukùu bo ilẹ̀.” Àmọ́ ńṣe ni Gọ́ọ̀gù máa kàgbákò. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ á dà bíi ti Fáráò nínú Òkun Pupa tó gbà níkẹyìn pé Jèhófà lòun ń bá jà. (Ẹ́kís. 14:1-4; Ìsík. 38:3, 4, 18, 21- 23) Kristi àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run máa gbèjà àwa èèyàn Jèhófà, wọ́n á sì pa Gọ́ọ̀gù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run pátápátá. (Ìfi. 19:11, 14, 15) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí olórí ọ̀tá Jèhófà, ìyẹn Sátánì tó lo ìpolongo ẹ̀tàn láti mú káwọn orílẹ̀-èdè bá Ọlọ́run jà ní Amágẹ́dọ́nì? Jésù máa ju òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, ibẹ̀ sì ni wọ́n máa wà fún odindi ẹgbẹ̀rún ọdún kan.—Ìfi. 20:1-3. w19.09 11-12 ¶14- 15
Wednesday, May 19
Ṣáà máa retí rẹ̀! Torí yóò ṣẹ láìkùnà.—Háb. 2:3.
Ó máa ń wù wá pé káwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣèlérí ti ṣẹ. Àmọ́, tó bá dà bíi pé àwọn nǹkan tá à ń retí ò dé lásìkò tá a fẹ́, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, kí iná ìtara wa sì kú. (Òwe 13:12) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 1914. Lásìkò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ronú pé ọdún 1914 làwọn máa lọ sọ́run. Àmọ́ ìyẹn ò ṣẹlẹ̀. Kí wá làwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe? Wọn ò juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí wọn ò lọ sọ́run lọ́dún 1914 torí pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún, kì í ṣe èrè tí wọ́n fẹ́ gbà. Wọ́n pinnu pé àwọn á fi ìfaradà sá eré ìje náà dópin. Kò sí àní-àní pé ó wu ìwọ náà pé kí Jèhófà mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ, kó dá orúkọ mímọ́ rẹ̀ láre, kó sì mú káwọn èèyàn gbà pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé gbogbo nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀ lásìkò tí Jèhófà yàn. Títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, ká má sì rẹ̀wẹ̀sì kódà táwọn nǹkan tá à ń retí ò bá tíì tẹ̀ wá lọ́wọ́. w19.08 4-5 ¶9-10
Thursday, May 20
Oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí.—Mát. 11:29.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni pẹ̀lẹ́ àti onírẹ̀lẹ̀? Ṣé ó máa ń yá mi lára láti ṣiṣẹ́ sin àwọn mí ì? Ṣé mo máa ń fi inúure hàn sáwọn mí ì?’ Jésù mú kára tu àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, inú ẹ̀ sì máa ń dùn láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Lúùkù 10:1, 19-21) Ó máa ń mú kó rọrùn fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti bi í ní ìbéèrè, òun náà sì máa ń tẹ́tí sí èrò wọn. (Mát. 16:13-16) Ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dà bí irúgbìn tó wà lórí ilẹ̀ rere. Wọ́n mọyì ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn, wọ́n fi í sílò, wọ́n sì ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn. Ṣé olórí ìdílé ni ẹ́ tàbí ẹni tó ń múpò iwájú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa ń ṣe sáwọn ará ilé mi àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́? Ṣé mo máa ń mára tù wọ́n? Ṣé mo máa ń jẹ́ kí wọ́n sọ tinú wọn tàbí bi mí ní ìbéèrè? Ṣé mo sì máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn?’ Ó dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí àwọn Farisí tó máa ń gbaná jẹ mọ́ àwọn tó bá ń bi wọ́n ní ìbéèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì máa ń ṣenúnibíni sáwọn tí èrò wọn yàtọ̀ sí tiwọn.—Máàkù 3:1-6; Jòh. 9:29-34. w19.09 20 ¶1; 23 ¶9-11
Friday, May 21
Nígbàkigbà tí wọ́n bá ń sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” ìgbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.—1 Tẹs. 5:3.
Àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè sábà máa ń lo gbólóhùn yìí tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí àjọṣe tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ṣe lè túbọ̀ gún régé. Bó ti wù kó rí, ìkéde “àlàáfíà àti ààbò” tí Bíbélì ń sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nígbà tí wọ́n bá ṣe ìkéde yìí, àwọn èèyàn ayé máa ronú pé àwọn aṣáájú yẹn ti mú kí àlàáfíà jọba níbi gbogbo láyé, pé ayé ti dùn ún gbé àti pé kò séwu mọ́. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, “ìparun òjijì” ló máa dé bá wọn torí pé ìgbà yẹn ni “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀. (Mát. 24:21) Àwọn nǹkan kan wà tí a kò mọ̀. A ò mọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ táá mú kí wọ́n ṣe ìkéde náà, a ò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbà ṣe é. A ò mọ̀ bóyá ìkéde kan ṣoṣo ló máa jẹ́ tàbí ó máa jẹ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ọ̀nà yòówù kó jẹ́, ohun kan dá wa lójú: Àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè ò lè mú kí àlàáfíà jọba láyé, torí náà a ò ní jẹ́ kí ìkéde yẹn tàn wá jẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ àmì pé “ọjọ́ Jèhófà” ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀!—1 Tẹs. 5:2. w19.10 8-9 ¶3-4
Saturday, May 22
Ní àkókò yẹn, àwọn èèyàn rẹ máa yè bọ́.—Dán. 12:1.
Ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa rẹ́yìn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Síbẹ̀, kò sídìí tó fi yẹ ká bẹ̀rù. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìjà Ọlọ́run ni. (Òwe 1:33; Ìsík. 38:18-20; Sek. 14:3) Tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, ó máa fún Jésù láṣẹ láti ṣáájú àwọn ọmọ ogun ọ̀run lọ sójú ogun náà. Òun àtàwọn ẹni àmì òróró tó ti jíǹde sọ́run àti ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì ló máa ja ìjà náà. Gbogbo wọn ló máa gbógun ti Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀. (Ìfi. 6:2; 17:14) Jèhófà fi dá wa lójú pé: “Ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí [wa] kò ní ṣàṣeyọrí.” (Àìsá. 54:17) “Ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà máa la “ìpọ́njú ńlá náà” já, wọ́n á sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà. (Ìfi. 7:9, 13-17) Ẹ ò rí bí Bíbélì ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ká má bẹ̀rù àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú torí a mọ̀ pé “Jèhófà ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́.” (Sm. 31:23) Inú gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń yìn ín máa dùn nígbà tó bá sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.—Ìsík. 38:23. w19.10 18-19 ¶17-18
Sunday, May 23
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.—Òwe 17:17.
Bá a ṣe túbọ̀ ń wọnú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, ṣe ni ìṣòro ń peléke sí i. (2 Tím. 3:1) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn ètò ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀-èdè kan ní apá ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, gbogbo nǹkan sì dojú rú. Ohun tó lé lóṣù mẹ́fà làwọn ará wa ò fi lè rìn kiri bó ṣe wù wọ́n torí pé wàhálà yẹn pọ̀ gan-an. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro yẹn? Ṣe làwọn kan sá lọ sílé àwọn ará tó wà ní àdúgbò tí nǹkan ti dẹrùn díẹ̀. Arákùnrin kan tiẹ̀ sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé mo wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nígbà ìṣòro yẹn. Ṣe ni gbogbo wa ń fún ara wa níṣìírí.” Nígbà tí “ìpọ́njú ńlá” bá dé, inú wa máa dùn gan-an tá a bá ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi tó nífẹ̀ẹ́ wa. (Ìfi. 7:14) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká tètè mú kí okùn ọ̀rẹ́ wa pẹ̀lú àwọn ará túbọ̀ le gan-an nísinsìnyí. (1 Pét. 4:7, 8) Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ọ̀tá máa wá gbogbo ọ̀nà láti ba àárín wa jẹ́, kódà wọ́n tiẹ̀ máa parọ́ mọ́ wa. Wọ́n á fẹ́ kẹ̀yìn wa síra wa. Àmọ́ pàbó ni ìsapá wọn máa já sí. Bó ti wù kí wọ́n gbìyànjú tó, wọn ò ní lè paná ìfẹ́ wa. w19.11 2 ¶1-2; 7 ¶19
Monday, May 24
Ẹ ó . . . lè paná gbogbo ọfà oníná ti ẹni burúkú náà.—Éfé. 6:16.
Sátánì tí Bíbélì pè ní “baba irọ́” máa ń mú káwọn èèyàn ẹ̀ pa irọ́ mọ́ Jèhófà àtàwọn ará wa. (Jòh. 8:44) Bí àpẹẹrẹ, àwọn apẹ̀yìndà máa ń sọ ohun tí kò jóòótọ́ nípa ètò Jèhófà lórí ìkànnì, tẹlifíṣọ̀n, rédíò àti ìwé ìròyìn, nígbà míì sì rèé wọ́n máa ń yí ọ̀rọ̀ po. Àwọn nǹkan yìí wà lára “ọfà oníná” tí Sátánì máa ń lò. Kí ló yẹ ká ṣe tẹ́nì kan bá pa irú irọ́ yìí lójú wa? Kò yẹ ká fetí sí i rárá! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì fọkàn tán àwọn ará wa. Kókó ibẹ̀ ni pé, a ò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn apẹ̀yìndà. Ká má ṣe tọ pinpin torí pé a fẹ́ gbọ́ tẹnu wọn, ká má sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun sún wa láti bá wọn jiyàn tàbí mú kí ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn. Ṣé ìgbà kan wà tó ṣe ẹ́ bíi pé kó o tẹ́tí sí irọ́ táwọn apẹ̀yìndà ń pa tàbí pé kó o bá wọn jiyàn, àmọ́ tó ò ṣe bẹ́ẹ̀? A gbóríyìn fún ọ. Bó ti wù kó rí, kò yẹ ká dẹra nù torí pé Sátánì ní àwọn nǹkan mí ì tó ń lò láti dán wa wò. w19.11 15 ¶8; 16 ¶11
Tuesday, May 25
Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn.—Òwe 16:2.
Mọ ìdí tó o fi ṣe ìpinnu tó o ṣe. Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, kò ní dáa ká máa tan ara wa tàbí àwọn míì torí pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ṣòro fún wa láti dúró lórí ìpinnu wa. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọ̀dọ́kùnrin kan gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, wákàtí ẹ̀ ò pé mọ́, torí náà kò láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ó lè rò pé ìfẹ́ tóun ní sí Jèhófà ló mú kóun di aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ kó má rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé ó fẹ́ tẹ́ àwọn òbí ẹ̀ tàbí àwọn míì lọ́rùn ló ṣe gba iṣẹ́ náà. Àpẹẹrẹ míì ni ti ẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì fẹ́ jáwọ́ nínú mímu sìgá. Ó gbìyànjú gan-an níbẹ̀rẹ̀ torí pé kò mu sìgá fún ọ̀sẹ̀ kan sí méjì, àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn ó tún pa dà sídìí ẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó jáwọ́ pátápátá. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà àti bó ṣe ń wù ú láti múnú rẹ̀ dùn ló jẹ́ kó ṣàṣeyọrí.—Kól. 1:10; 3:23. w19.11 27 ¶9; 29 ¶10
Wednesday, May 26
Kí ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ lọ́nà tó yẹ ìhìn rere nípa Kristi.—Fílí. 1:27, àlàyé ìsàlẹ̀.
Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé òun máa sá eré ìje ìyè náà dópin, òun sì máa gba èrè ọjọ́ iwájú. Torí pé Kristẹni ẹni àmì òróró ni, ó ń fojú sọ́nà láti gba “èrè ìpè Ọlọ́run sí òkè.” Síbẹ̀, ó mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ máa “sapá” nìṣó kí ọwọ́ òun tó lè tẹ èrè náà. (Fílí. 3:14) Pọ́ọ̀lù wá lo àfiwé kan káwọn ará Fílípì lè rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbájú mọ́ èrè ọjọ́ iwájú yẹn. Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará yẹn létí pé ọ̀run ni ìlú ìbílẹ̀ wọn. (Fílí. 3:20) Kí nìdí tó fi lo àfiwé yìí? Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ohun iyì ni téèyàn bá jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù. Àmọ́ àǹfààní táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yẹn ní kò láfiwé torí pé ọ̀run ni ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ó ṣe kedere pé jíjẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àǹfààní ńlá táwọn Kristẹni yìí ní! Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lónìí náà ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sapá kí wọ́n lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun lọ́run. w19.08 6 ¶14-15
Thursday, May 27
Tí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ máa di òmìnira lóòótọ́.—Jòh. 8:36.
Òmìnira yìí kọjá òmìnira èyíkéyìí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gbà lọ́dún Júbílì. (Léf. 25:8-12) Bí àpẹẹrẹ, béèyàn kan bá gba òmìnira lọ́dún Júbílì, ó sì lè tún pa dà di ẹrú. Yàtọ̀ síyẹn, bópẹ́ bóyá ó ṣì máa kú. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn olóòótọ́ míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ó tipa bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n di ọmọ rẹ̀, tó bá sì tó àkókò, á jí wọn dìde sí ọ̀run kí wọ́n lè bá Jésù ṣàkóso. (Róòmù 8:2, 15-17) Àwọn ló kọ́kọ́ jàǹfààní nínú òmìnira tí Jésù kéde nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì. (Lúùkù 4:16-19, 21) Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àwọn amúnisìn, ìyẹn àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni tí wọ́n sì ń fipá mú àwọn èèyàn láti lọ́wọ́ nínú àṣà tí kò bá òfin Ọlọ́run mu. Bákan náà, wọ́n ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Júbílì ìṣàpẹẹrẹ yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sì máa dópin nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí. w19.12 11 ¶11-12
Friday, May 28
Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.—1 Kọ́r. 15:33.
Ẹ̀yin òbí, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa. Ó yẹ kí bàbá àti ìyá mọ àwọn táwọn ọmọ wọn ń bá ṣọ̀rẹ́ àtohun tí wọ́n ń ṣe. Ó yẹ kí wọ́n tún mọ àwọn tí wọ́n jọ ń kàn síra lórí ìkànnì àjọlò àtàwọn tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Ìdí ni pé àwọn tí wọ́n ń bá rìn lè nípa lórí bí wọ́n ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń hùwà, ó ṣe tán wọ́n máa ń sọ pé fi ọ̀rẹ́ rẹ hàn mí kí n lè sọ irú èèyàn tó o jẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti sapá kí àwọn ọmọ wọn lè dọ̀rẹ́ àwọn tó ń ṣe dáadáa nínú ètò Jèhófà. Àpẹẹrẹ kan ni ti tọkọtaya kan tó ń jẹ́ N’Déni àti Bomine lórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire, wọ́n sábà máa ń gba alábòójútó àyíká lálejò nílé wọn. Arákùnrin N’Déni sọ pé: “Bá a ṣe ń gbà wọ́n lálejò mú kí ọmọ wa nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn. Bó ṣe di pé ó gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nìyẹn, ní báyìí ó ti di adelé alábòójútó àyíká.” Ó ṣe pàtàkì káwọn òbí tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn kó tó pẹ́ jù. (Òwe 22:6) Ronú nípa àpẹẹrẹ Tímótì. Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé láti “kékeré jòjòló” ni ìyá rẹ̀ Yùníìsì àti Lọ́ìsì ìyá rẹ̀ àgbà ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.—2 Tím. 1:5; 3:15. w19.12 25 ¶14; 26 ¶16-17
Saturday, May 29
Ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.—Òwe 18:24.
Jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán, tó sì ṣeé gbára lé. Bí àpẹẹrẹ, ó dáa ká ṣèlérí fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin pé a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, àmọ́ kò yẹ ká fi mọ ní ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan. Ó tún yẹ ká ṣe àwọn nǹkan pàtó láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Mát. 5:37; Lúùkù 16:10) Táwọn tó nílò ìrànwọ́ bá mọ̀ pé àwọn lè gbára lé wa, ọkàn wọn á balẹ̀, ara á sì tù wọ́n. Ẹ gbọ́ ohun tí arábìnrin kan sọ lórí kókó yìí, ó ní: “Kò sí pé èèyàn ń ṣàníyàn bóyá onítọ̀hún máa wá tàbí kò ní wá, ọkàn wa balẹ̀ pé á dé lásìkò.” Ọkàn àwọn tó níṣòro máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá rẹ́ni fọkàn tán, tí wọ́n á sì sọ tinú wọn fún. Àmọ́ tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi àti ẹni tó ṣeé finú hàn, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onísùúrù. Lẹ́yìn tí ọkọ Arábìnrin Zhanna kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ọkàn ẹ̀ gbọgbẹ́ gan-an. Àmọ́ lẹ́yìn tó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀. Ó sọ pé: “Wọ́n fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi, wọ́n sì mú sùúrù fún mi bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun kan náà ni mò ń sọ lásọtúnsọ.” Ìwọ náà lè fi hàn pé ọ̀rẹ́ gidi ni ẹ́ tó o bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn tó níṣòro, tó o sì ń mú sùúrù fún wọn. w20.01 10-11 ¶9-11
Sunday, May 30
Ẹ̀mí mímọ́ . . . máa kún inú rẹ̀, àní kí wọ́n tó bí i.—Lúùkù 1:15.
Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ èèyàn tí Jèhófà fún ní ẹ̀mí mímọ́ àmọ́ tí wọn ò lọ sọ́run ló wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ darí Dáfídì. (1 Sám. 16:13) Ẹ̀mí mímọ́ mú kó mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Jèhófà, ó sì tún darí rẹ̀ láti kọ àwọn apá kan lára Ìwé Mímọ́. (Máàkù 12:36) Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Dáfídì “kò lọ sí ọ̀run.” (Ìṣe 2:34) Bákan náà, Bíbélì sọ pé ‘ẹ̀mí mímọ́ kún inú’ Jòhánù Arinibọmi. (Lúùkù 1:13-16) Jésù sọ pé kò sí ẹnì kankan tó tóbi ju Jòhánù lọ, àmọ́ ó tún sọ pé Jòhánù ò ní bá òun jọba lọ́run. (Mát. 11:10, 11) Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ran àwọn ọkùnrin yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀, àmọ́ kò fi yàn wọ́n láti lọ sọ́run. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ tó àwọn yẹn ni? Rárá. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jèhófà máa jí wọn dìde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15. w20.01 25 ¶15
Monday, May 31
A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.—1 Jòh. 4:19.
Jèhófà pè wá pé ká wá di ara ìdílé òun. Àwa tá a ti ya ara wa sí mímọ́ tá a sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Ọmọ rẹ̀ la wà nínú ìdílé yìí. Ìdílé aláyọ̀ ni ìdílé wa. Ìgbésí ayé wa nítumọ̀ nísinsìnyí, a sì tún ń retí àtiwà láàyè títí láé yálà ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà fún wa láǹfààní pé ká di ara ìdílé òun bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ná an kò kéré. (Jòh. 3:16) Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé a ti rà wá “ní iye kan.” (1 Kọ́r. 6:20) Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Èyí mú ká lè máa pe Ẹni Gíga Jù Lọ láyé àti lọ́run ní Baba wa. Jèhófà sì ni Baba tó dáa jù. Àwa náà lè béèrè bí onísáàmù kan ṣe béèrè pé: “Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi?” (Sm. 116:12) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sóhun tá a lè fi san oore tí Jèhófà ṣe fún wa. Àmọ́ a lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. w20.02 8 ¶1-3