ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es21 ojú ìwé 58-67
  • June

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • June
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Tuesday, June 1
  • Wednesday, June 2
  • Thursday, June 3
  • Friday, June 4
  • Saturday, June 5
  • Sunday, June 6
  • Monday, June 7
  • Tuesday, June 8
  • Wednesday, June 9
  • Thursday, June 10
  • Friday, June 11
  • Saturday, June 12
  • Sunday, June 13
  • Monday, June 14
  • Tuesday, June 15
  • Wednesday, June 16
  • Thursday, June 17
  • Friday, June 18
  • Saturday, June 19
  • Sunday, June 20
  • Monday, June 21
  • Tuesday, June 22
  • Wednesday, June 23
  • Thursday, June 24
  • Friday, June 25
  • Saturday, June 26
  • Sunday, June 27
  • Monday, June 28
  • Tuesday, June 29
  • Wednesday, June 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2021
es21 ojú ìwé 58-67

June

Tuesday, June 1

Orogún rẹ̀ ń pẹ̀gàn rẹ̀ ṣáá kó lè múnú bí i.​—1 Sám. 1:6.

Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni Hánà tó wá di ìyá wòlíì Sámúẹ́lì kojú. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni kò fi rọ́mọ bí. (1 Sám. 1:2) Bẹ́ẹ̀ sì rèé nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ojú ẹni ègún ni wọ́n fi máa ń wo obìnrin tí kò bá rọ́mọ bí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìtìjú bá Hánà. (Jẹ́n. 30:​1, 2) Ìṣòro yìí tún légbá kan fún Hánà torí pé ọkọ rẹ̀ ní ìyàwó míì tó ń jẹ́ Pẹ̀nínà, tó láwọn ọmọ, tó sì máa ń torí ìyẹn pẹ̀gàn Hánà. Hánà ò mọ ohun tó lè ṣe sí ìṣòro yẹn, ó sì ń kó ìdààmú ọkàn bá a. Ọ̀rọ̀ yìí dùn ún débi pé “ńṣe ló máa ń sunkún, tí kò sì ní jẹun.” Bíbélì sọ pé “inú Hánà bà jẹ́ gan-an.” (1 Sám. 1:​7, 10) Àmọ́ báwo ni Hánà ṣe rí ìtùnú? Hánà sọ gbogbo ìṣòro tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a fún Jèhófà. Lẹ́yìn tó gbàdúrà tán, ó sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ fún Élì àlùfáà àgbà. Élì wá sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fún ọ ní ohun tí o béèrè.” Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára obìnrin náà? Bíbélì ròyìn pé Hánà “bá tirẹ̀ lọ, ó jẹun, kò sì kárí sọ mọ́.” (1 Sám. 1:​17, 18) Ó ṣe kedere pé àdúrà tí Hánà gbà yẹn mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀. w20.02 21 ¶4-5

Wednesday, June 2

Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bó ṣe yẹ kí ẹ dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.​—Kól. 4:6.

Láìpẹ́, Jèhófà máa pa ètò búburú yìí run. Kìkì “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” nìkan ló sì máa là á já. (Ìṣe 13:48) Ó yẹ kó túbọ̀ máa wù wá pé káwọn mọ̀lẹ́bí wa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣe tán, Jèhófà Baba wa ọ̀run “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé a lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́, a sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́. Ó ṣe tán, wọ́n máa ń sọ pé pẹ̀lẹ́ lákọ ó sì lábo. Tá a bá ń wàásù fáwọn tá ò mọ̀ rí, a máa ń fi pẹ̀lẹ́tù bá wọn sọ̀rọ̀, àmọ́ a kì í sábà ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí wa sọ̀rọ̀. Nígbà míì, tá a bá ronú nípa ìgbà tá a kọ́kọ́ wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa, a lè rí i pé ọ̀nà tá a gbà bá wọn sọ̀rọ̀ ò dáa tó. Ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sílò nígbàkigbà tá a bá fẹ́ wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa. Torí tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe la máa lé wọn sá dípò ká fà wọ́n wá sínú òtítọ́. w19.08 14-15 ¶3-5

Thursday, June 3

Kristi . . . fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.​—1 Pét. 2:21.

Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o mọ òtítọ́ nípa ẹni tí Ọmọ jẹ́? O kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù lẹnì kejì tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àti lọ́run. Òun ni Olùràpadà wa torí ó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Tá a bá fi hàn nínú ìwà àti ìṣe wa pé a nígbàgbọ́ nínú ìràpadà Kristi, Ọlọ́run máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, àá sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16) Jésù ni Àlùfáà Àgbà wa. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè jàǹfààní nínú ìràpadà náà, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Héb. 4:15; 7:​24, 25) Torí pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, òun ni Jèhófà máa lò láti ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́, á pa gbogbo ẹni ibi run, á sì mú kí aráyé gbádùn ìbùkún ayérayé nínú Párádísè. (Mát. 6:​9, 10; Ìfi. 11:15) Jésù ni àwòkọ́ṣe wa. Ó ṣe tán, ìfẹ́ Ọlọ́run ló fi gbogbo ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 4:34) Tó o bá gba òtítọ́ tí Bíbélì sọ nípa Jésù gbọ́, wàá nífẹ̀ẹ́ Ọmọ tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ gan-an. Èyí á mú kó o fayé rẹ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bíi ti Jésù. w20.03 10 ¶12-13

Friday, June 4

Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.​—1 Tẹs. 5:17.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù gbàdúrà lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó fi ìrántí ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀, ó gbàdúrà sórí búrẹ́dì àti wáìnì tó lò. (1 Kọ́r. 11:​23-25) Yàtọ̀ síyẹn, kí òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó kúrò nínú yàrá tí wọ́n ti ṣe Ìrékọjá, ó gbàdúrà pẹ̀lú wọn. (Jòh. 17:​1-26) Nígbà tóun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé Òkè Ólífì, ó tún gbàdúrà léraléra. (Mát. 26:​36-39, 42, 44) Kódà, àdúrà ni gbólóhùn tó kẹ́yìn tí Jésù sọ lórí òpó igi oró. (Lúùkù 23:46) Ó ṣe kedere pé Jésù gbàdúrà sí Jèhófà nípa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ohun kan tó mú kí Jésù fara da àwọn àdánwò tó kojú ni pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kò sì dákẹ́ àdúrà. Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì ò tẹra mọ́ àdúrà gbígbà lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Torí náà, ṣe ni wọ́n sá lọ nígbà tí wọ́n kojú àdánwò. (Mát. 26:​40, 41, 43, 45, 56) Táwa náà bá kojú àdánwò, ohun kan ṣoṣo tó lè mú ká borí ni pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo” bíi ti Jésù. w19.04 9 ¶4-5

Saturday, June 5

Èmi ni Jèhófà; èmi kì í yí pa dà.​—Mál. 3:6.

Jèhófà kórìíra ìbẹ́mìílò tẹ̀gàntẹ̀gàn! Ó pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹnì kankan láàárín yín ò gbọ́dọ̀ sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná, kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́, kò gbọ́dọ̀ pidán, kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, kò gbọ́dọ̀ di oṣó, kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí woṣẹ́woṣẹ́, kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú. Torí Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.” (Diu. 18:​10-12) Òótọ́ ni pé àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè. Síbẹ̀, ohun tó dájú ni pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìbẹ́mìílò kò yí pa dà. Jèhófà kìlọ̀ pé ká má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò torí pé ó máa ń fa àkóbá. Sátánì ń tipasẹ̀ ìbẹ́mìílò tan irọ́ kálẹ̀ pé àwọn òkú máa ń lọ gbé níbòmíì. (Oníw. 9:5) Ó tún máa ń lo ìbẹ́mìílò láti dẹ́rù ba àwọn èèyàn kí wọ́n má bàa sin Jèhófà. Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé káwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò máa wá ìrànwọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù dípò Jèhófà. w19.04 21 ¶5-6

Sunday, June 6

Tí o bá ń ṣe ohun búburú, máa bẹ̀rù.​—Róòmù 13:4.

Ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára gan-an, tó sì wúwo rinlẹ̀ ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Ńṣe lẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe fa ìrora tó kọjá àfẹnusọ fún ọmọ náà, ó sì fìyà jẹ ẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó yan ọmọ náà jẹ, ó fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, ó sì mú kó ṣòro fún un láti fọkàn tán ẹnikẹ́ni. Torí náà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a dáàbò bo àwọn ọmọdé lọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn yìí, ká sì rí i dájú pé a pèsè ìtùnú àti ìrànwọ́ fáwọn tí wọ́n hùwà ìkà yìí sí. (1 Tẹs. 5:14) Tí ẹnì kan nínú ìjọ bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, ńṣe ló kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọ́run. (Mát. 5:16; 1 Pét. 2:12) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fàyè gba àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, tí wọn ò ronú pìwà dà, tí wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ rere tí ìjọ ní. Tẹ́nì kan nínú ìjọ bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe tàbí tó hùwà ọ̀daràn míì, ó ti rú òfin ìjọba nìyẹn. (Fi wé Ìṣe 25:8.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ojúṣe àwọn alàgbà láti fìyà jẹ ẹ́ lábẹ́ òfin ìjọba, wọn kì í bo ohun tó ṣe mọ́lẹ̀ kí ìjọba má bàa fìyà tó tọ́ jẹ ẹ́. w19.05 9 ¶4-7

Monday, June 7

Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.​—1 Kọ́r. 3:19.

Jèhófà ni Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá, torí náà ọkàn wa balẹ̀ pé kò sí ìṣòro tá ò ní lè borí. (Àìsá. 30:​20, 21) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń kọ́ wa ní gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ ká lè “kúnjú ìwọ̀n dáadáa,” ká sì “gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.” (2 Tím. 3:17) Tá a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa, a máa di ọlọgbọ́n, ìgbésí ayé wa sì máa nítumọ̀ ju tàwọn tó ń gbé “ọgbọ́n ayé” yìí lárugẹ. (Sm. 119:​97-100) Ó bani nínú jẹ́ pé kì í rọrùn láti dá yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé. Torí pé a jẹ́ aláìpé, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú tàbí ká máa hùwà bíi tàwọn tó ń fi ọgbọ́n ayé yìí ṣèwà hù. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má fi ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán mú yín lẹ́rú látinú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn.” (Kól. 2:8) Gbogbo èyí ò yani lẹ́nu torí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn máa “fẹ́ràn ìgbádùn” gan-an. (2 Tím. 3:4) Yàtọ̀ síyẹn, báwọn àrùn ìbálòpọ̀ bí AIDS ṣe ń jà ràn-ìn jẹ́ kó hàn gbangba pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ni ọgbọ́n táyé ń gbé lárugẹ.​—2 Pét. 2:19. w19.05 21 ¶1-2; 22 ¶4-5

Tuesday, June 8

Ẹ . . . dúró gbọn-in láti dojú kọ àwọn àrékérekè Èṣù.​—Éfé. 6:11.

Sátánì tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti gbà pé kí òjò tó lè rọ̀ dáadáa, àfi kí wọ́n máa bọ àwọn òrìṣà táwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń bọ. Àwọn tó yí wọn ká gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ètùtù kan káwọn òòṣà tó lè mú kí òjò rọ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà sì ronú pé bíbọ òòṣà yẹn ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí òjò á fi tètè rọ̀, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà Báálì. Sátánì tún kíyè sí i pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà lọ́kàn wọn, ó sì fi dẹkùn mú wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká máa ń ṣèṣekúṣe tó burú jáì tí wọ́n bá ń bọ àwọn òrìṣà wọn. Bí àpẹẹrẹ, àtọkùnrin àtobìnrin wọn ló máa ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó nínú tẹ́ńpìlì. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò rí ohun tó burú nínú kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀, kódà ohun tí wọ́n fi ń ṣayọ̀ nìyẹn! (Diu. 23:​17, 18; 1 Ọba 14:24) Àwọn abọ̀rìṣà yẹn gbà pé ohun táwọn ń ṣe ló máa mú kí àwọn òrìṣà wọn bù kún ilẹ̀ náà, kí irúgbìn wọn sì so dáadáa. Ìṣekúṣe táwọn abọ̀rìṣà náà ń ṣe fa ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ra, èyí sì mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà. w19.06 2 ¶3; 4 ¶7-8

Wednesday, June 9

Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.​—Héb. 6:10.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míì ni iṣẹ́ ìsìn wọn ti yí pa dà. Kò rọrùn rárá fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin olóòótọ́ yìí láti fi iṣẹ́ tí wọ́n gbádùn gan-an sílẹ̀. Tó o bá wà lára wọn, kí lá jẹ́ kó rọrùn fún ẹ nínú ipò tuntun tó o bára ẹ? Rí i pé o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. Bákan náà, máa wàásù déédéé ní ìjọ tuntun tó o wà. Fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í gbàgbé àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín láìka ìyípadà tó dé bá wọn bí wọn ò bá tiẹ̀ lè ṣe tó bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ṣe bó o ti mọ. Má ṣe jẹ́ kí àníyàn ayé Sátánì yìí paná ìtara tó o ní fún ìjọsìn Jèhófà. (Mát. 13:22) Má ṣe jẹ́ kí ohun táyé Sátánì ń gbé lárugẹ àtohun táwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí ń sọ mú kó o máa lé owó. (1 Jòh. 2:​15-17) Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó ṣèlérí pé òun máa fún ẹ lókun, òun máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, òun á sì pèsè ohun tó o nílò “ní àkókò tó tọ́.”​—Héb. 4:16; 13:​5, 6. w19.08 20 ¶4; 21-22 ¶7-8

Thursday, June 10

Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró.​—Sm. 55:22.

Ṣé àwọn ìṣòro kan wà tó ń bá ẹ fínra? Ọkàn wa máa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọ àwọn ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè. Ó mọ ibi tágbára wa kù sí, ó mọ ohun tá à ń rò lọ́kàn àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. (Sm. 103:14; 139:​3, 4) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tó ń kó ìdààmú ọkàn bá wa. Ìdààmú lè mú kéèyàn ṣinú rò, ó sì lè mú kéèyàn rẹ̀wẹ̀sì. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, rántí pé Jèhófà ò ní dá ẹ dá a, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Jèhófà rọ̀ ẹ́ pé kó o sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún òun, òun sì máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ fún ìrànlọ́wọ́. (Sm. 5:3; 1 Pét. 5:7) Torí náà, máa gbàdúrà lemọ́lemọ́ sí Jèhófà nípa àwọn ìṣòro tó o ní. Òótọ́ ni pé Jèhófà ò ní bá ẹ sọ̀rọ̀ ní tààràtà, àmọ́ á bá ẹ sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì á tù ẹ́ nínú wọ́n á sì mú kó o nírètí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ máa fún ẹ níṣìírí.​—Róòmù 15:4; Héb. 10:​24, 25. w19.06 16 ¶7-8

Friday, June 11

Gbogbo orílẹ̀-èdè sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.​—Mát. 24:9.

Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí ẹ, bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, máa “tú ọkàn rẹ jáde bí omi,” kó o sì jẹ́ kó mọ gbogbo ohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè àtohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù. (Ìdárò 2:19) Bó o ṣe túbọ̀ ń gbàdúrà lọ́nà yìí, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà. (Róòmù 8:​38, 39) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣẹ. (Nọ́ń. 23:19) Tó o bá ń ṣiyèméjì pé bóyá làwọn ìlérí yẹn máa ṣẹ, wẹ́rẹ́ ni Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ máa rí ẹ mú. (Òwe 24:10; Héb. 2:15) Àbá kan rèé: Walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o lè mọ àwọn ohun tí Jèhófà máa ṣe nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ àti ìdí tó fi yẹ kó dá ẹ lójú pé á mú àwọn ìlérí náà ṣẹ. Báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Stanley Jones tó lo ọdún méje lẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á láìbọ́hùn? Ó sọ pé: “Ìgbàgbọ́ mi lágbára gan-an torí mo mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àtohun tó máa ṣe, mi ò sì ṣiyèméjì nípa ẹ̀ rárá. Ìyẹn ni ò jẹ́ kí n bọ́hùn.” Tó bá dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ láìsí tàbí ṣùgbọ́n, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kò sì sóhun tó máa dẹ́rù bà ẹ́ débi tí wàá fi bọ́hùn.​—Òwe 3:​25, 26. w19.07 2 ¶1; 3 ¶6-7

Saturday, June 12

Tí ẹ bá wọ ìlú tàbí abúlé èyíkéyìí, ẹ wá ẹni yíyẹ kàn níbẹ̀, kí ẹ sì dúró síbẹ̀ títí ẹ fi máa kúrò.​—Mát. 10:11.

Kí nìdí tí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fi ṣe pàtàkì gan-an? Ìdí ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi nìkan ló lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbésí ayé àwọn tó bá ń tẹ̀ lé Kristi máa ń nítumọ̀, wọ́n sì nírètí àtigbé títí láé lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 14:6; 17:3) Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ńlá ni Jésù gbé fún wa yìí, àmọ́ a ò lè dá iṣẹ́ náà ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan nípa ara rẹ̀ àtàwọn Kristẹni bíi tiẹ̀, ó ní: “Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.” (1 Kọ́r. 3:9) Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni Jèhófà àti Jésù fún wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá! Iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn máa ń fún wa láyọ̀. Ohun àkọ́kọ́ tá a máa ṣe tá a bá fẹ́ sọni di ọmọ ẹ̀yìn ni pé ká “wá” àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kàn. Ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá lóòótọ́ ni pé ká máa wàásù fún gbogbo àwọn tá a bá pàdé. Bẹ́ẹ̀ ni, tá a bá ń pa àṣẹ Kristi mọ́ pé ká wàásù, ṣe là ń fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá. w19.07 15 ¶3-5

Sunday, June 13

Ọgbọ́n jẹ́ ààbò bí owó ṣe jẹ́ ààbò, àmọ́ àǹfààní ìmọ̀ ni pé: Ọgbọ́n máa ń dá ẹ̀mí àwọn tó ní in sí.​—Oníw. 7:12.

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ló kọ́kọ́ máa ń fa ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́ra. Nílùú New York, arábìnrin kan tó máa ń wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Mandarin sọ pé: “Mo máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, mo sì máa ń tẹ́tí sí wọn. Tí mo bá gbọ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá síbẹ̀, mo lè bi wọ́n pé: ‘Báwo ni nǹkan, ṣé ara ti ń mọlé? Ṣé o ti ríṣẹ́? Báwo làwọn ará ìlú yìí ṣe ń ṣe sí ẹ?’ ” Nígbà míì, àwọn ìbéèrè yìí máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún un láti wàásù. Tó bá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu, arábìnrin náà tún máa ń béèrè pé: “Kí lo rò pé ó lè mú kí àárín àwọn èèyàn gún? Jẹ́ kí n fi òwe inú Bíbélì kan hàn ẹ́. Ó ní: ‘Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dà bí ìgbà téèyàn ṣí ibú omi sílẹ̀; kí ìjà tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.’ Ṣé o rò pé ìmọ̀ràn yìí lè mú kí àárín àwa èèyàn gún régé?” (Òwe 17:14) Irú ìjíròrò yìí lè jẹ́ ká mọ àwọn táá fẹ́ ká pa dà wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. w19.07 23 ¶13

Monday, June 14

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó ṣubú tí kò sí ẹni tó máa gbé e dìde?​—Oníw. 4:10.

Ohun tá a lè ṣe fáwọn tí iṣẹ́ ìsìn wọn yí pa dà ni pé ká lóye wọn, ká sì gba tiwọn rò, kì í ṣe pé ká kàn máa káàánú wọn lásán. Ó ṣeé ṣe kí àwọn fúnra wọn máa ṣàìsàn tàbí kí wọ́n máa tọ́jú mọ̀lẹ́bí wọn kan tó ń ṣàìsàn. Wọ́n sì lè máa ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó kú. Bákan náà, wọ́n lè máa ṣàárò àwọn ará tí wọ́n fi sílẹ̀ níbi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, bí ò tiẹ̀ hàn lójú wọn. Ó máa ń pẹ́ kéèyàn tó lè gbọ́kàn kúrò nínú àwọn nǹkan yìí. Ní báyìí ná, àpẹẹrẹ yín àti bẹ́ ẹ ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ máa mú kára wọn mọlé. Arábìnrin kan tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn nílẹ̀ òkèèrè sọ pé: “Níbi tí mo ti ń sìn tẹ́lẹ̀, ojoojúmọ́ ni mo máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ látìgbà tí mo ti débí, mi ò réèyàn bá sọ̀rọ̀ ká má tíì sọ pé màá ka Bíbélì tàbí fi fídíò hàn wọ́n. Bó ti wù kó rí, àwọn akéde ìjọ náà máa ń mú mi lọ sí ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn. Èyí mú kó dá mi lójú pé èmi náà ṣì máa ní ìkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, mo mọ bí mo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò níbi tí mo wà báyìí. Èyí sì mú kí n pa dà láyọ̀.” w19.08 22 ¶10; 24 ¶13-14

Tuesday, June 15

Mo rọ Yúódíà, mo sì rọ Síńtíkè pé kí wọ́n ní èrò kan náà nínú Olúwa.​—Fílí. 4:2.

Bíi ti Yúódíà àti Síńtíkè, ohun kan wà tó lè mú kó ṣòro fáwa náà láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, ìyẹn tó bá jẹ́ pé ibi tí wọ́n kù sí nìkan la gbájú mọ́. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe lójoojúmọ́. Tó bá jẹ́ pé àṣìṣe àwọn míì là ń wò ṣáá, a ò ní lè nífẹ̀ẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan ò bá dara pọ̀ mọ́ wa nígbà tá à ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, inú lè bí wa. Tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn àṣìṣe tí arákùnrin náà ti ṣe sẹ́yìn, ṣe ni inú ẹ̀ á túbọ̀ máa bí wa, a ò sì ní fẹ́ bá a da nǹkan pọ̀ mọ́. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, á dáa kó o ronú lórí kókó yìí: Jèhófà mọ ibi tí àwa àti arákùnrin náà kù sí. Síbẹ̀, bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa náà ló ṣe nífẹ̀ẹ́ arákùnrin yẹn. Nítorí náà, ó yẹ ká fara wé Jèhófà, ká sì rí i pé ibi táwọn ará wa dáa sí là ń gbájú mọ́. Tá a bá ń sapá láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, okùn ìfẹ́ wa á túbọ̀ lágbára, àárín wa á sì túbọ̀ gún.​—Fílí. 2:​1, 2. w19.08 9-10 ¶7-8

Wednesday, June 16

Jèhófà . . . ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.​—Sm. 138:6.

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nìkan ló lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì rí ojú rere rẹ̀. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Bíbélì sọ pé Jèhófà “jìnnà sí àwọn agbéraga.” Kò sí àní-àní pé gbogbo wa la fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a sì fẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ wa. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká sapá láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í gbéra ga, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í jọra ẹ̀ lójú. Bíbélì fi hàn pé ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń bẹ̀rù Ọlọ́run, kì í sì í fojú pa àwọn míì rẹ́. Bákan náà, ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé àwọn míì sàn ju òun lọ. (Fílí. 2:​3, 4) Ìwà àwọn kan máa ń jẹ́ kó dà bíi pé wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Wọ́n lè máa ṣe jẹ́jẹ́, àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà sì lè mú kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn míì. Síbẹ̀ kó jẹ́ pé nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún, agbéraga ni wọ́n. Àmọ́ bópẹ́ bóyá, irú ẹni tí wọ́n jẹ́ máa hàn sójú táyé.​—Lúùkù 6:45. w19.09 2 ¶1, 3-4

Thursday, June 17

[Ó] ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn . . . tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.​—2 Tẹs. 1:8.

Gbogbo òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Jésù fi kọ́ni ni Bíbélì pè ní “ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” À ń ṣègbọràn sí ìhìn rere tá a bá ń jẹ́ kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí wa. Lédè míì, ká máa fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wa, ká máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run, ká sì máa fìtara kéde Ìjọba rẹ̀. (Mát. 6:33; 24:14) Ó tún yẹ ká máa ti àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Jésù lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń bójú tó ojúṣe pàtàkì tí wọ́n ní nínú ètò Ọlọ́run. (Mát. 25:​31-40) Láìpẹ́ àwọn ẹni àmì òróró máa fi hàn pé àwọn mọrírì ìtìlẹ́yìn tí “àwọn àgùntàn mìíràn” fún wọn. (Jòh. 10:16) Báwo ni wọ́n á ṣe fi hàn pé àwọn mọrírì wọn? Kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ti máa wà lọ́run, wọ́n á sì ti di ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́. Wọ́n máa wà lára ẹgbẹ́ ogun ọ̀run táá pa Gọ́ọ̀gù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run, wọ́n á sì dáàbò bo “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ìfi. 2:​26, 27; 7:​9, 10) Ó dájú pé inú ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí máa dùn gan-an pé àwọn ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹni àmì òróró nígbà tí wọ́n wà láyé! w19.09 12-13 ¶16-18

Friday, June 18

Ara sì máa tù yín.​—Mát. 11:29.

Kí nìdí tí ara fi máa ń tù wá bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa? Ìdí ni pé àwọn alábòójútó tó dáa jù la ní. Jèhófà tó jẹ́ Alábòójútó wa Tó Ga Jù Lọ kì í ṣe abaraámóorejẹ, ó sì máa ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Ó mọyì iṣẹ́ tá à ń ṣe fún un. (Héb. 6:10) Ó sì máa ń fún wa lágbára ká lè ṣe ojúṣe wa láṣeyanjú. (2 Kọ́r. 4:7; Gál. 6:​5, àlàyé ìsàlẹ̀) Jésù Ọba wa náà ò kẹ̀rẹ̀, àpẹẹrẹ tó dáa ló fi lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 13:15) Àwọn alàgbà tó ń bójú tó wa ńkọ́? Àwọn náà ń sa gbogbo ipá wọn láti máa fara wé Jésù “olùṣọ́ àgùntàn ńlá.” (Héb. 13:20; 1 Pét. 5:2) Wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti jẹ́ onínúure, bí wọ́n ṣe ń kọ́ wa, tí wọ́n ń dáàbò bò wá tí wọ́n sì ń fún wa níṣìírí. Bákan náà, àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa jù la ní. Àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán la ní, iṣẹ́ tá a jọ ń ṣe sì ń múnú wa dùn, kò sí ẹlẹ́gbẹ́ ẹ̀ níbòmíì. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó ná: Àǹfààní ńlá la ní pé àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run là ń bá ṣiṣẹ́, ìlànà gíga ni wọ́n sì ń tẹ̀ lé, síbẹ̀ wọn ò jọ ara wọn lójú. Wọ́n ní ẹ̀bùn lóríṣiríṣi, síbẹ̀ wọn kì í gbéra ga, wọ́n gbà pé àwọn míì sàn ju àwọn lọ. Torí pé wọ́n mú wa lọ́rẹ̀ẹ́, wọn kì í fojú alábàáṣiṣẹ́ lásán wò wá. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa débi pé wọ́n lè yọ ojú wọn fún wa, àní sẹ́ wọ́n ṣe tán àtifi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí wa! w19.09 20 ¶1; 23 ¶12-14

Saturday, June 19

Ẹ ò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn á fi dé bá yín lójijì bí ìgbà tí ilẹ̀ mọ́ bá olè.​—1 Tẹs. 5:4.

Nínu ọ̀rọ̀ ìyànjú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, ó mẹ́nu kan “ọjọ́ Jèhófà.” (1 Tẹs. 5:​1-6) Bó ṣe wà níbi tá a kà yìí, ọjọ́ Jèhófà ni àkókò kan tó máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìparun “Bábílónì Ńlá” tó sì máa dópin nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:​14, 16; 17:5) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ ká rí ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe àtohun tó yẹ ká ṣọ́ra fún ká lè múra sílẹ̀ de “ọjọ́ Jèhófà.” Ó rọ̀ wá pé ká má ṣe “máa sùn bí àwọn yòókù ti ń ṣe.” Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ “wà lójúfò” ká sì máa ronú lọ́nà tó tọ́. A gbọ́dọ̀ kíyè sára kó má bàa di pé à ń dá sọ́rọ̀ òṣèlú ká má sì ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ẹ̀. Tá a bá lọ dá sọ́rọ̀ òṣèlú pẹ́nrẹ́n, á jẹ́ pé a ti ń di “apá kan ayé” nìyẹn. (Jòh. 15:19) A sì mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú kí àlàáfíà jọba níbi gbogbo láyé. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, kò ní ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sin Jèhófà. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìwàásù kọjá ohun téèyàn ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú, ó sì jẹ́ kánjúkánjú! w19.10 8 ¶3; 9 ¶5-6

Sunday, June 20

Mú àkájọ ìwé kan, kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo bá ọ sọ sínú rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ sí Ísírẹ́lì àti Júdà.​—Jer. 36:2.

Nígbà tí àsìkò tó láti ka ohun tó wà nínú àkájọ ìwé náà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Bárúkù ni Jeremáyà ní kó lọ jíṣẹ́ náà. (Jer. 36:​5, 6) Bárúkù fi ìgboyà jíṣẹ́ yìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ náà le gan-an. Ṣé ẹ lè fojú inú wo bí inú Jeremáyà ṣe máa dùn tó nígbà tí Bárúkù lọ sínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tó sì jíṣẹ́ náà? (Jer. 36:​8-10) Nígbà tí àwọn ìjòyè Júdà gbọ́ ohun tí Bárúkù ṣe, wọ́n pàṣẹ pé kó wá ka àkájọ ìwé náà sáwọn létí. (Jer. 36:​14, 15) Wọ́n wá sọ fún un pé àwọn máa sọ fún Ọba Jèhóákímù. Inú bí Ọba Jèhóákímù gan-an nígbà tó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà kọ sílẹ̀, débi pé ó ju àkájọ ìwé náà sínú iná, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Jeremáyà àti Bárúkù. Àmọ́ ṣe ni Jeremáyà mú àkájọ ìwé míì, ó fún Bárúkù, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà fún un. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Bárúkù tún “kọ gbogbo ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé tí Jèhóákímù ọba Júdà sun nínú iná.”​—Jer. 36:26-28, 32. w19.11 3-4 ¶4-6

Monday, June 21

Ọlọ́run ni ẹni tó ń fún yín lágbára . . . ó ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.​—Fílí. 2:13.

Jèhófà máa ń di ohunkóhun tó bá yẹ láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbà kan wà tó di Olùkọ́, Olùtùnú àti Ajíhìnrere. Àwọn yìí sì jẹ́ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ń dì láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Àìsá. 48:17; 2 Kọ́r. 7:6; Gál. 3:8) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń lo àwọn èèyàn láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn. (Mát. 24:14; 28:​19, 20; 2 Kọ́r. 1:​3, 4) Bákan náà, Jèhófà lè fún ẹnikẹ́ni lára wa ní ọgbọ́n àti agbára tá a nílò ká lè di ohunkóhun láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Àwọn àlàyé yìí jẹ́ ká rí díẹ̀ lára ìtúmọ̀ orúkọ Jèhófà, àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sì gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Kò sẹ́ni tí kò wù pé kí Jèhófà lo òun, síbẹ̀ àwọn kan máa ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà lè lo àwọn. Kí nìdí? Wọ́n gbà pé àwọn ò ní lè ṣe púpọ̀ torí ọjọ́ orí wọn, ipò tí wọ́n wà tàbí àwọn ìdí míì. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn míì lè ronú pé ohun táwọn ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti tó, torí náà kò sídìí fún àwọn láti tún tẹ́wọ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì. w19.10 20 ¶1-2

Tuesday, June 22

Ìfẹ́ owó ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú jàǹbá.​—1 Tím. 6:10.

Ìfẹ́ fún ohun ìní tara lè mú ká má ṣe tó bó ṣe yẹ nínú ìjọsìn Jèhófà, ó sì lè jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọmọ ogun tó bá fẹ́ múnú ẹni tó gbà á sí iṣẹ́ ológun dùn, kò ní tara bọ òwò ṣíṣe.” (2 Tím. 2:4) Kódà, wọn ò fàyè gba àwọn ọmọ ogun Róòmù rárá láti ṣe òwò èyíkéyìí. Bíi tàwọn ọmọ ogun tó ti múra sílẹ̀ yẹn, ó yẹ káwa náà wà ní ìmúrasílẹ̀, ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun míì gbà wá lọ́kàn ju iṣẹ́ tí Jèhófà àti Jésù gbé fún wa lọ. Bá a ṣe máa rí ojú rere wọn ṣe pàtàkì ju ohunkóhun míì tá a lè rí nínú ayé Sátánì yìí. Ó ṣe pàtàkì ká máa ya àkókò sọ́tọ̀ ká sì rí i dájú pé a wà ní sẹpẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Bákan náà, a tún gbọ́dọ̀ máa tọ́jú apata ìgbàgbọ́ wa àtàwọn ìhámọ́ra ogun míì tí Jèhófà fún wa. Kò yẹ ká dẹra nù rárá! Kí nìdí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn tó pinnu pé àwọn fẹ́ di ọlọ́rọ̀” máa “ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́.”​—1 Tím. 6:​9, 10. w19.11 17 ¶12, 14-15

Wednesday, June 23

Ìgbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.​—1 Tẹs. 5:3.

Ìkéde “àlàáfíà àti ààbò” ló máa ṣáájú “ọjọ́ Jèhófà.” (1 Tẹs. 5:​1-6) “Ọjọ́ Jèhófà” tí 1 Tẹsalóníkà 5:2 sọ̀rọ̀ ẹ̀ ni “ìpọ́njú ńlá.” (Ìfi. 7:14) Kí lá jẹ́ ká mọ ìgbà tí ìpọ́njú ńlá náà máa bẹ̀rẹ̀? Bíbélì sọ pé wọ́n máa ṣe ìkéde kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìkéde yẹn lá jẹ́ ká mọ̀ pé ìpọ́njú ńlá máa tó bẹ̀rẹ̀. Ìkéde yẹn ló máa mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ tó sọ pé àwọn alákòóso ayé máa kéde “àlàáfíà àti ààbò.” Ṣé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa dara pọ̀ mọ́ wọn? Ó ṣeé ṣe. Àmọ́, ọ̀kan lára ìtànjẹ àwọn ẹ̀mí èṣù ló máa jẹ́. Irọ́ burúkú ni ìkéde náà, ó sì léwu gan-an torí pé á mú káwọn èèyàn gbà pé àlàáfíà àti ààbò ti dé tó sì jẹ́ pé ìpọ́njú ńlá tírú ẹ̀ ò tíì ṣẹlẹ̀ rí ló rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí aráyé. Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ ọ́ náà ló máa rí, pé “ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn, bí ìgbà tí obìnrin tó lóyún bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí.” Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwa ìránṣẹ́ Jèhófà? Ó lè yà wá lẹ́nu pé wẹ́rẹ́ lọjọ́ Jèhófà bẹ̀rẹ̀, àmọ́ kò ní bá wa lábo. w19.09 9 ¶7-8

Thursday, June 24

Ohun gbogbo ni àkókò wà fún, . . . ìgbà wíwá àti ìgbà gbígbà pé ó ti sọ nù.​—Oníw. 3:​1, 6.

Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu, mọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an. Tó o bá mọ ohun tó o fẹ́ ṣe, á rọrùn fún ẹ láti parí ohun tó o bẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti pinnu pé o fẹ́ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Àmọ́, tí o kò bá ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wàá máa tẹ̀ lé, ọwọ́ ẹ lè má tẹ ohun tó ò ń lé. Àwọn alàgbà ìjọ kan lè pinnu pé àwọn fẹ́ túbọ̀ máa ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn ará, àmọ́ ibi tí wọ́n sọ ọ́ sí yẹn náà ló parí sí, wọn ò ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. Tí wọ́n bá fẹ́ kí ọwọ́ wọn tẹ àfojúsùn yẹn, wọ́n lè bi ara wọn pé: “Àwọn akéde wo gan-an la fẹ́ bẹ̀ wò? Ìgbà wo la sì fẹ́ lọ bẹ̀ wọ́n wò?” Yàtọ̀ síyẹn, má tanra ẹ jẹ. Kì í ṣe gbogbo ohun tó wù wá láti ṣe lagbára wa máa ń gbé, nígbà míì sì rèé, a kì í ní àkókò tó pọ̀ tó láti ṣe àwọn ohun tá a fẹ́ ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká mọ̀wọ̀n ara wa, ká má sì tanra wa jẹ. Nígbà míì, ó lè gba pé ká yí ìpinnu kan tá a ti ṣe pa dà torí pé agbára wa ò gbé e. w19.11 29 ¶11-12

Friday, June 25

Àwọn yìí ni àwọn tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.​—Ìfi. 7:14.

Àsọtẹ́lẹ̀ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun wà nínú Àìsáyà 65:​21-23. Lásìkò yẹn, kò sẹ́ni táá káwọ́ gbera láìṣiṣẹ́ tàbí tó máa jẹ́ ọ̀lẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì fi hàn pé àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà nígbà yẹn á máa ṣe iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀. Tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà bá parí, Ọlọ́run máa “dá ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹrú ìdíbàjẹ́, kí ó sì lè ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Bí Jèhófà ṣe ṣètò pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì máa wáyè sinmi, ó dájú pé bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rí nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. A máa ní àkókò láti jọ́sìn Jèhófà. Ó ṣe tán, ìjọsìn Ọlọ́run ṣe pàtàkì téèyàn bá máa láyọ̀ lónìí, bó sì ṣe máa rí nìyẹn nínú ayé tuntun. Ó ṣe kedere pé gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin máa gbádùn lábẹ́ àkóso Kristi torí pé wọ́n á máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ń jọ́sìn Jèhófà. w19.12 12 ¶15; 13 ¶17-18

Saturday, June 26

Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí . . . sọ́kàn, kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ léraléra.​—Diu. 6:​6, 7.

Tí ẹ̀yin òbí bá fẹ́ “kọ́ àwọn ọmọ” yín ní Ọ̀rọ̀ Jèhófà “léraléra,” ó máa gba pé kẹ́ ẹ máa rán wọn létí ìlànà Ọlọ́run lásọtúnsọ láìjẹ́ kó sú yín. Kó lè ṣeé ṣe, ó ṣe pàtàkì kẹ́ ẹ máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Ó máa ń sú èèyàn tó bá di pé kéèyàn máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà ṣáá. Àmọ́, á dáa kẹ́yin òbí wò ó bí ọ̀nà kan tẹ́ ẹ lè gbà gbin ẹ̀kọ́ òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ yín, táá sì jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀kọ́ náà sílò. Torí náà, ẹ mọ àwọn ọmọ yín dáadáa. Sáàmù kẹtàdínláàádóje (127) fi àwọn ọmọ wé ọfà. (Sm. 127:4) Bó ṣe jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n lè fi ṣe ọfà, tí wọ́n sì máa ń gùn jura wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ yàtọ̀ síra. Fún ìdí yìí, ó yẹ káwọn òbí pinnu bí wọ́n ṣe máa tọ́ ọmọ kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n má sì fi ọ̀kan wé èkejì. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Israel ní ọmọ méjì, àwọn méjèèjì ni wọ́n sì tọ́ yanjú nínú òtítọ́. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Wọ́n ní: “A máa ń bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá wọ́n máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí wọ́n máa ṣe é pa pọ̀. w19.12 26-27 ¶18-20

Sunday, June 27

Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.​—Mát. 7:12.

Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó táwọn èèyàn bá dúró tì wá nígbà ìṣòro tí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́! Arákùnrin Ryan tí bàbá rẹ̀ kú lójijì nínú ìjàǹbá ọkọ̀ kan sọ pé: “Téèyàn bá wà nínú ìṣòro, àwọn nǹkan téèyàn máa ń ṣe lójoojúmọ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn á wá dogun. Torí náà, a máa ń mọyì ẹ̀ gan-an tá a bá rẹ́ni ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan, kódà kó tiẹ̀ jẹ́ àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú.” Torí náà, má ṣe fojú kéré ohun tó o lè ṣe láti tu àwọn tó níṣòro nínú, bó ti wù kó kéré mọ. Ó ṣe kedere pé ọwọ́ Máàkù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dí gan-an. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, Máàkù wáyè láti tu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú, ìyẹn sì mú kó rọrùn fún Pọ́ọ̀lù láti rán an níṣẹ́. Ọgbẹ́ ọkàn tó lágbára ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Angela ní látàrí báwọn ìkà ẹ̀dá ṣe pa ìyá-ìyá rẹ̀ ní ìpakúpa. Nígbà tó ń sọ bó ṣe mọyì àwọn ará tó wá tù ú nínú, ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ tó múra tán láti ṣèrànwọ́ máa ń rọrùn bá sọ̀rọ̀. Ó hàn lójú wọn pé wọ́n bá mi kẹ́dùn, wọn ò sì lọ́ tìkọ̀ rárá láti ràn mí lọ́wọ́.” Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé ó máa ń yá mi lára láti tu àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú, ṣé mo sì máa ń ṣèrànwọ́ fún wọn? Ṣérú ẹni táwọn èèyàn mọ̀ mí sí nìyẹn?’ w20.01 11-12 ¶14-16

Monday, June 28

Ẹni tó bá jẹ búrẹ́dì náà tàbí tó mu ife Olúwa láìyẹ yóò jẹ̀bi.​—1 Kọ́r. 11:27.

Báwo ni ẹni àmì òróró kan ṣe lè jẹ búrẹ́dì kó sì mu wáìnì “láìyẹ” níbi Ìrántí Ikú Kristi? Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá ń tẹ àwọn òfin Jèhófà àti ìlànà rẹ̀ lójú tí kò sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. (Héb. 6:​4-6; 10:​26-29) Àwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn tí wọ́n bá fẹ́ gba “èrè ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 3:​13-16) Ṣe ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ń mú káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì í sọ wọ́n di agbéraga. (Éfé. 4:​1-3; Kól. 3:​10, 12) Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró kì í ronú pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ. Wọ́n mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ tí Jèhófà fún àwọn kò ju èyí tó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó kù lọ. Wọn kì í sì í ronú pé àwọn lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ ju àwọn yòókù lọ. Wọn ò jẹ́ sọ fẹ́nì kan pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn án torí náà kóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ búrẹ́dì kó sì máa mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló ń yan àwọn tó máa lọ sọ́run. w20.01 27-28 ¶4-5

Tuesday, June 29

Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.​—Jém. 4:8.

Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun, ká máa bá òun sọ̀rọ̀, ká sì máa tẹ́tí sí òun. Jèhófà gbà wá níyànjú pé ká “tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,” ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa tẹ́tí sí wa. (Róòmù 12:12) Ọwọ́ rẹ̀ kì í dí láti tẹ́tí sí wa, ọ̀rọ̀ wa kì í sì í sú u. Lọ́wọ́ kejì, àwa náà lè tẹ́tí sí i tá a bá ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tá a sì ń ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé. Àwa náà máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tá a bá ń bá a sọ̀rọ̀, tá a sì ń tẹ́tí sí i. Jèhófà fẹ́ ká sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wa fún òun. (Sm. 62:8) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àdúrà mi kì í ṣe oréfèé bí ọ̀rọ̀ inú ìwé téèyàn dà kọ? Àbí ó máa ń tọkàn mi wá bí ọ̀rọ̀ téèyàn fúnra ẹ̀ kọ sínú lẹ́tà?’ Kò sí àní-àní pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì fẹ́ kí àárín yín túbọ̀ gún régé sí i. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, o gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí Jèhófà kó o sì máa bá a sọ̀rọ̀ déédéé. Sọ àwọn nǹkan tó ò lè sọ fún ẹlòmíì fún un. Sọ àwọn nǹkan tó ń múnú ẹ dùn àtohun tó ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́ fún un. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìgbàkigbà lo lè yíjú sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. w20.02 9 ¶4-5

Wednesday, June 30

Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà níkàáwọ́ yín, kí ẹ máa ṣe alábòójútó.​—1 Pét. 5:2.

Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà gbé fáwọn alàgbà pé kí wọ́n máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn òun. Kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ náà yanjú, á dáa kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú bí Nehemáyà ṣe bá àwọn èèyàn Ọlọ́run lò. Nehemáyà ni gómìnà Júdà, torí náà ó ní ọlá àṣẹ déwọ̀n àyè kan. (Neh. 1:11; 2:​7, 8; 5:14) Àmọ́ àwọn ìṣòro kan wà tí Nehemáyà kojú. Ó rí i pé àwọn èèyàn náà ń ṣe ohun tí kò bójú mu nínú tẹ́ńpìlì, wọn ò sì fún àwọn ọmọ Léfì ní ìpín wọn bí Òfin ṣe sọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Júù ò pa Sábáàtì mọ́, àwọn kan sì fẹ́ obìnrin àjèjì. Kí ni Gómìnà Nehemáyà máa wá ṣe báyìí? (Neh. 13:​4-30) Nehemáyà ò ṣi agbára rẹ̀ lò, kò sì gbé òfin tirẹ̀ kalẹ̀ fáwọn èèyàn náà. Dípò bẹ́ẹ̀, ó bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, ó sì rán àwọn èèyàn náà létí ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ. (Neh. 1:​4-10; 13:​1-3) Yàtọ̀ síyẹn, Nehemáyà dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn náà, wọ́n sì jọ tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́.​—Neh. 4:15. w19.09 16 ¶9-10

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́