ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es21 ojú ìwé 68-77
  • July

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Thursday, July 1
  • Friday, July 2
  • Saturday, July 3
  • Sunday, July 4
  • Monday, July 5
  • Tuesday, July 6
  • Wednesday, July 7
  • Thursday, July 8
  • Friday, July 9
  • Saturday, July 10
  • Sunday, July 11
  • Monday, July 12
  • Tuesday, July 13
  • Wednesday, July 14
  • Thursday, July 15
  • Friday, July 16
  • Saturday, July 17
  • Sunday, July 18
  • Monday, July 19
  • Tuesday, July 20
  • Wednesday, July 21
  • Thursday, July 22
  • Friday, July 23
  • Saturday, July 24
  • Sunday, July 25
  • Monday, July 26
  • Tuesday, July 27
  • Wednesday, July 28
  • Thursday, July 29
  • Friday, July 30
  • Saturday, July 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2021
es21 ojú ìwé 68-77

July

Thursday, July 1

Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.​—Fílí. 4:6.

Ìdààmú ọkàn lè bá wa nígbà táwọn míì bá sọ̀rọ̀ tó dùn wá tàbí tí wọ́n bá hùwà àìdáa sí wa. Ó lè dùn wá gan-an tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí ìbátan wa kan ló ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí wa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà nígbà tí orogún rẹ̀ ń pẹ̀gàn ẹ̀. (1 Sám. 1:12) Àwa náà lè ṣe bíi tiẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà ní gbogbo ìgbà nípa ohun tó ń kó ìdààmú ọkàn bá wa àti ohun tó ń bà wá lẹ́rù. Kò dìgbà tá a bá sọ àwọn ọ̀rọ̀ dídùn tàbí tá a to ọ̀rọ̀ wa lẹ́sẹẹsẹ kí Jèhófà tó gbọ́ wa. Nígbà míì, a tiẹ̀ lè sunkún sí Jèhófà lọ́rùn bá a ṣe ń sọ ohun tó ń dùn wá, tá ò sì pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ. Bó ti wù kó rí, Jèhófà kò ní sọ pé ọ̀rọ̀ wa sú òun, kò sì ní ṣàì tẹ́tí sí wa. Láfikún sí pé ká sọ àwọn ìṣòro wa fún Jèhófà, ó tún yẹ ká fi ìmọ̀ràn inú Fílípì 4:​6, 7 sọ́kàn tá a bá ń gbàdúrà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dìídì sọ pé ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ká sì fi ìmọrírì hàn fún ohun tó ṣe fún wa. Ẹ gbọ́ ná, ṣé ìdí wà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àbí kò sí? Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa dúpẹ́ fún àwọn nǹkan tó dá, ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó dá wa, ó ń dá ẹ̀mí wa sí, ó ń fìfẹ́ hàn sí wa, ó sì jẹ́ ká nírètí ìyè àìnípẹ̀kun. w20.02 21 ¶3; 22 ¶6

Friday, July 2

Ohun gbogbo ni àkókò wà fún . . . ìgbà sísọ̀rọ̀.​—Oníw. 3:​1, 7.

Jèhófà ló fún wa lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ. (Ẹ́kís. 4:​10, 11; Ìfi. 4:11) Nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ ká lóye bá a ṣe lè lo ẹ̀bùn náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ìgbà gbogbo ló yẹ ká ṣe tán láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. (Mát. 24:14; Róòmù 10:14) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fara wé Jésù. Ọ̀kan lára ìdí tí Jésù fi wá sáyé ni pé kó lè kọ́ni ní òtítọ́ nípa Baba rẹ̀. (Jòh. 18:37) Àmọ́ ó tún ṣe pàtàkì ká mọ bó ṣe yẹ ká bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Torí náà, tá a bá ń sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn, a gbọ́dọ̀ máa fi “ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀” ṣe bẹ́ẹ̀, ká fi hàn pé a gba tiwọn rò, ká má sì kàn wọ́n lábùkù torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (1 Pét. 3:15) Tá a bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò, wọ́n á gbọ́rọ̀ wa, wọ́n á sì rí ẹ̀kọ́ kọ́. Àwọn alàgbà kì í lọ́ tìkọ̀ láti gba arákùnrin tàbí arábìnrin èyíkéyìí nímọ̀ràn tó bá pọn dandan. Síbẹ̀, wọ́n máa ń wá àkókò tó wọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ kí ojú má bàa ti onítọ̀hún. w20.03 18-19 ¶2-4

Saturday, July 3

Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.​—Mát. 26:41.

Àwọn nǹkan wo la lè gbàdúrà fún? A lè bẹ Jèhófà pé kó “fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Lúùkù 17:5; Jòh. 14:1) Kò sí àní-àní pé a nílò ìgbàgbọ́ torí pé gbogbo ọmọlẹ́yìn Jésù pátá ni Sátánì máa dán wò. (Lúùkù 22:31) Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀? Tá a bá ti ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé láti yanjú ìṣòro kan, ìgbàgbọ́ tá a ní máa mú ká fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé kò síṣòro tó kọjá agbára Jèhófà. (1 Pét. 5:​6, 7) Láìka àdánwò yòówù ká máa kojú sí, àdúrà máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alàgbà kan tó ń jẹ́ Robert tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún. Ó sọ pé: “Ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 4:​6, 7 ló mú kí n lè fara da gbogbo ìṣòro tí mo ní. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbà kan wà tí mi ò lówó lọ́wọ́. Ìgbà kan sì wà tí mi ò sí nípò alàgbà mọ́.” Kí ló jẹ́ kọ́kàn Robert balẹ̀ láìka àwọn ìṣòro yìí sí? Ó sọ pé: “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí àníyàn bá ti ń gbà mí lọ́kàn ni mo máa ń gbàdúrà. Mo gbà pé bí mo ṣe ń tẹra mọ́ àdúrà gbígbà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi túbọ̀ ń balẹ̀ sí i.” w19.04 9-10 ¶5-7

Sunday, July 4

Ìwọ gan-an ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí.​—Sm. 51:4.

Ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe jẹ́ lójú Ọlọ́run. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ sí ẹlòmíì, ó tún ṣẹ̀ sí Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Òfin yẹn sọ pé tí ẹnì kan bá ja ọmọnìkejì rẹ̀ lólè tàbí tó lù ú ní jìbìtì, ńṣe lonítọ̀hún “hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà.” (Léf. 6:​2-4) Ó ṣe kedere nígbà náà pé tí ẹnì kan nínú ìjọ bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, ńṣe lonítọ̀hún hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà torí pé ṣe ló dà bí ìgbà tó ba ayé ọmọ náà jẹ́. Tẹ́nì kan tó pe ara rẹ̀ ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, lédè míì tó yan ọmọ náà jẹ, tó fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, ìwà àìṣòótọ́ lonítọ̀hún hù sí Jèhófà. Ó sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Jèhófà. Torí náà, ìwà burúkú gbáà ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, kò lórúkọ míì, ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ló sì jẹ́ lójú Ọlọ́run. Àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ṣàlàyé ohun táwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lè ṣe láti borí ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n ní. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n sọ ohun táwọn míì lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n sì gbé wọn ró, àtohun táwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Bákan náà, ètò Ọlọ́run ti fi Ìwé Mímọ́ dá àwọn alàgbà lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Léraléra ni ètò Ọlọ́run ń pèsè àwọn ìsọfúnni tuntun nípa báwọn alàgbà ṣe lè bójú tó ọ̀rọ̀ náà. w19.05 9 ¶8-9

Monday, July 5

Ṣé ó yẹ kí wọ́n lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú nítorí alààyè?​—Àìsá. 8:19.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí idà tó mú, ó sì lágbára láti já irọ́ Sátánì. (Éfé. 6:17) Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló jẹ́ ká mọ̀ pé kò ṣeé ṣe fún ẹni tó wà láàyè láti bá òkú sọ̀rọ̀. (Sm. 146:4) Ó tún jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà nìkan ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tí kò sì ní tàsé. (Àìsá. 45:21; 46:10) Torí náà, tá a bá ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀ déédéé, a ò ní gba Sátánì gbọ́, kódà àá kórìíra gbogbo irọ́ táwọn ẹ̀mí èṣù ń pa. Torí náà, má ṣe lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. Torí pé Kristẹni tòótọ́ ni wá, a kì í lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. Bí àpẹẹrẹ, a kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn abẹ́mìílò èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ la ò kì í wá bá a ṣe máa bá òkú sọ̀rọ̀ lọ́nàkọnà. A kì í lọ́wọ́ nínú àṣà ìsìnkú tó ń fi hàn pé àwọn òkú ṣì wà láàyè níbì kan. Bákan náà, a kì í jẹ́ káwọn awòràwọ̀ àtàwọn woṣẹ́woṣẹ́ sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la fún wa. A mọ̀ dáadáa pé gbogbo àwọn àṣà yìí léwu gan-an, wọ́n sì lè mú kéèyàn ní àjọṣe pẹ̀lú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. w19.04 21-22 ¶8-9

Tuesday, July 6

Ọlọ́run fi wọ́n sílẹ̀ fún ìwà àìmọ́, kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn.​—Róòmù 1:24.

Àwọn tó fara mọ́ èrò ayé máa ń bẹnu àtẹ́ lu ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀, wọ́n sì gbà pé kò bọ́gbọ́n mu. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè ronú pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run dá wa lọ́nà táá mú kó máa wù wá láti ní ìbálòpọ̀, táá tún wá fún wa lófin nípa ẹ̀?’ Ìṣòro táwọn tó nírú èrò bẹ́ẹ̀ ní ni pé, wọ́n gbà pé gbogbo ohun tó bá ti wu èèyàn ló gbọ́dọ̀ ṣe. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a lè kó ara wa níjàánu, ká sì pinnu pé a ò ní lọ́wọ́ sí ìwàkiwà. (Kól. 3:5) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti fi ẹ̀bùn ìgbéyàwó jíǹkí wa ká lè gbádùn ìbálòpọ̀ lọ́nà tó tọ́. (1 Kọ́r. 7:​8, 9) Kò sí àní-àní pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ bọ́gbọ́n mu, gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló sì fi sàn ju ohun táyé ń gbé lárugẹ lọ. Bíbélì tiẹ̀ tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìbálòpọ̀ máa ń gbádùn mọ́ni. (Òwe 5:​18, 19) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mọ bó ṣe máa kó ara rẹ̀ níjàánu nínú jíjẹ́ mímọ́ àti nínú iyì, kì í ṣe nínú ojúkòkòrò ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu.”​—1 Tẹs. 4:​4, 5. w19.05 22-23 ¶7-9

Wednesday, July 7

Ìwọ yóò ya bò wọ́n bí ìjì, . . . ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ.​—Ìsík. 38:9.

Jèhófà kò ní jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè pa àwa èèyàn rẹ̀ run. Kí nìdí? Àwa là ń jẹ́ kí aráyé mọ orúkọ Jèhófà, a sì ti pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ pé ká jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá. (Ìṣe 15:​16, 17; Ìfi. 18:4) Yàtọ̀ síyẹn, à ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti kúrò nínú rẹ̀. Torí náà, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà kò ní “gbà lára àwọn ìyọnu rẹ̀.” Bó ti wù kó rí, àwọn nǹkan kan ṣì máa dán ìgbàgbọ́ wa wò. (Ìsík. 38:​2, 8) Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pa gbogbo ẹ̀sìn èké run, àwa èèyàn Jèhófà máa dà bí igi tó dá dúró lẹ́yìn tí ìjì ti ya gbogbo igi inú igbó lulẹ̀. Ìyẹn máa bí Sátánì nínú gan-an, ṣe lá tu itọ́ sókè, táá sì fojú gbà á. Á wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ‘àwọn ọ̀rọ̀ àìmọ́ tó ní ìmísí,’ ìyẹn àwọn ìpolongo ẹ̀tàn láti mú káwọn orílẹ̀-èdè gbìmọ̀ pọ̀ kí wọ́n sì gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà. (Ìfi. 16:​13, 14) Ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ni Bíbélì pè ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” Tí àwọn orílẹ̀-èdè bá ti kọjú ìjà sáwa èèyàn Jèhófà, ogun Amágẹ́dọ́nì bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.​—Ìfi. 16:16. w19.09 11 ¶12-13

Thursday, July 8

Èrò àwọn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.​—1 Kọ́r. 3:20.

Láyé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Sátánì lo ẹ̀sìn èké láti gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Ohun tó sì ń ṣe lónìí náà nìyẹn. Ẹ̀sìn èké fàyè gba onírúurú ìṣekúṣe, kódà ohun tí wọ́n fi ń ṣayọ̀ nìyẹn. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni máa lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ ohun tí ìwà yìí ti yọrí sí. (Róòmù 1:​28-31) Lára “àwọn ohun tí kò yẹ” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn ni gbogbo onírúurú ìṣekúṣe títí kan kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ àti kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀. (Róòmù 1:​24-27, 32; Ìfi. 2:20) Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà tó wà nínú Bíbélì! Ọgbọ́n táwọn èèyàn ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ ta ko àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. “Àwọn iṣẹ́ ti ara” ni ọgbọ́n ayé yìí ń gbé lárugẹ, kì í jẹ́ káwọn èèyàn mú èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run dàgbà. (Gál. 5:​19-23) Ó máa ń sọ àwọn èèyàn di agbéraga, wọ́n máa ń ro ara wọn ju bó ti yẹ lọ, ó sì ń mú kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan.” (2 Tím. 3:​2-4) Àwọn ìwà yìí yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ànímọ́ bí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù tí Bíbélì gba àwa ìránṣẹ́ Jèhófà níyànjú pé ká ní.​—2 Sám. 22:28. w19.06 5-6 ¶12-14

Friday, July 9

Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.​—Òwe 17:17.

Àsìkò tí nǹkan ò rọgbọ rárá ni Èlíjà ṣiṣẹ́ wòlíì nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Jèhófà sọ fún Èlíjà pé kó yan Èlíṣà láti máa bá a ṣiṣẹ́. Ohun tí Jèhófà ṣe yìí jẹ́ kí Èlíjà rí ẹni táá ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí nǹkan bá tojú sú u. Lọ́nà kan náà, táwa náà bá ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún ọ̀rẹ́ tó ṣe é finú hàn, irú ẹni bẹ́ẹ̀ á dúró tì wá nígbà ìṣòro, á sì jẹ́ ká lè fara dà á. (2 Ọba 2:2) Tó bá dà bíi pé kò sẹ́ni tó o lè finú hàn, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ táá fún ẹ níṣìírí, táá sì dúró tì ẹ́. Jèhófà ran Èlíjà lọ́wọ́ láti fara da ìdààmú ọkàn tó ní, ìyẹn sì mú kó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àpẹẹrẹ Èlíjà fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ ká nírètí. Nígbà míì, a lè kojú ìṣòro tó le gan-an, tó ń kó ìdààmú ọkàn bá wa, tó sì ń tán wa lókun. Síbẹ̀, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, á fún wa lókun ká lè máa sìn ín nìṣó.​—Àìsá. 40:​28, 29. w19.06 15 ¶4; 16 ¶9-10

Saturday, July 10

Ìbẹ̀rù èèyàn jẹ́ ìdẹkùn, àmọ́ ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò rí ààbò.​—Òwe 29:25.

A lè túbọ̀ nígboyà nísinsìnyí tá a bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì bẹ̀rù èèyàn. Bó ṣe jẹ́ pé àá túbọ̀ lágbára tá a bá ń ṣe eré ìmárale, bẹ́ẹ̀ náà làá túbọ̀ nígboyà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, níbi térò pọ̀ sí, lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà àti níbi táwọn èèyàn ti ń tajà. Tá a bá ń fìgboyà wàásù nísinsìnyí, ẹ̀rù ò ní bà wá láti wàásù nígbà tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa. (1 Tẹs. 2:​1, 2) A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára arábìnrin kan tó lo ìgboyà nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí i. Arábìnrin Nancy Yuen ò ga ju ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún (1.5 m) lọ, síbẹ̀ kì í bẹ̀rù. Nígbà táwọn alátakò halẹ̀ mọ́ ọn pé kò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, ó kọ̀ jálẹ̀, ó sì ń wàásù nìṣó. Torí náà, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n fún nǹkan bí ogún (20) ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àwọn Kọ́múníìsì ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà. Àwọn ọlọ́pàá tó fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò sọ pé “òun ló lágídí jù” lórílẹ̀-èdè wọn. w19.07 5 ¶13-14

Sunday, July 11

Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.​—Mát. 28:19.

Ó máa ń yá àwọn kan lára láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn tá à ń bá pàdé lè kọ́kọ́ ṣe bíi pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa. Ó lè gba pé ká ṣe ohun táá mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Torí náà, tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ̀ wọ́n lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ múra ohun tá a máa sọ àti ọ̀nà tá a máa gbà sọ ọ́. Yan àwọn àkòrí tó o mọ̀ pé àwọn tó ò ń wàásù fún máa nífẹ̀ẹ́ sí. Lẹ́yìn ìyẹn, múra bó o ṣe máa gbé e kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi onílé pé: “Ṣé mo lè mọ èrò yín lórí ọ̀rọ̀ yìí? Tó bá jẹ́ pé ìjọba kan ṣoṣo ló ń ṣàkóso ayé, ṣé ẹ rò pé á lè yanjú gbogbo ìṣòro táwa èèyàn ń kojú?” Lẹ́yìn ìyẹn, o lè ka Dáníẹ́lì 2:​44, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ẹ̀. O sì lè bi òbí kan pé: “Kí lẹ rò pé èèyàn lè ṣe tó bá fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ yanjú? Màá fẹ́ mọ èrò yín lórí ọ̀rọ̀ yìí.” Lẹ́yìn ìyẹn, o lè ka Diutarónómì 6:​6, 7, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ẹ̀. Ó ṣe kedere pé a máa ń láyọ̀ gan-an tá a bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn Kristi. w19.07 15 ¶4, 6-7

Monday, July 12

Ǹjẹ́ èèyàn lè ṣe àwọn ọlọ́run fún ara rẹ̀ nígbà tí wọn kì í ṣe ọlọ́run ní ti gidi?​—Jer. 16:20.

Arákùnrin kan tó mọ béèyàn ṣe ń bá àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan sọ̀rọ̀ láwọn ilẹ̀ tó wà ní Ìlà Oòrùn ayé sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, tẹ́nì kan lórílẹ̀-èdè yìí bá sọ pé, ‘Mi ò gba Ọlọ́run gbọ́,’ ohun tó ní lọ́kàn ni pé òun ò gbà gbọ́ nínú kéèyàn máa jọ́sìn àwọn òòṣà táwọn èèyàn ń bọ. Mo sábà máa ń sọ pé àtọwọ́dá làwọn òòṣà yẹn àti pé wọn ò lágbára kankan. Màá wá ka Jeremáyà 16:​20, lẹ́yìn náà màá béèrè pé: ‘Báwo la ṣe lè dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀?’ Mo máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, màá sì ka ohun tó wà nínú Àìsáyà 41:​23, tó sọ pé: ‘Ẹ sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa, ká lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.’ Ẹ̀yìn náà ni màá wá tọ́ka sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà ti sọ tó sì ní ìmúṣẹ nínú Bíbélì.” Arákùnrin míì sọ pé: “Mo máa ń tọ́ka sí àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ àtàwọn òfin ìṣẹ̀dá tó ń darí nǹkan láyé àti lọ́run. Lẹ́yìn náà ni màá wá jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo nǹkan yìí fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà, ó sì jẹ́ orísun ọgbọ́n. Tẹ́ni náà bá ti gbà pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà, màá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà hàn án.” w19.07 23-24 ¶14-15

Tuesday, July 13

Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.​—Fílí. 1:10.

Lára ohun tó ṣe pàtàkì jù náà ni bí Jèhófà ṣe máa ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́, bí ohun tó ní lọ́kàn ṣe máa ṣẹ àti bí ìjọ ṣe máa wà níṣọ̀kan tí àlàáfíà sì máa jọba. (Mát. 6:​9, 10; Jòh. 13:35) Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù yìí ló gbà wá lọ́kàn, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ká “jẹ́ aláìní àbààwọ́n.” Èyí ò túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni pípé. Jèhófà máa kà wá sí aláìní àbààwọ́n tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ tá a ní túbọ̀ jinlẹ̀, tá a sì ń ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn ni pé ká rí i dájú pé a ò mú àwọn míì kọsẹ̀. Ìkìlọ̀ tó lágbára lohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ká má ṣe mú àwọn míì kọsẹ̀. Báwo la ṣe lè mú àwọn míì kọsẹ̀? A lè fa ìkọ̀sẹ̀ fáwọn míì nípasẹ̀ eré ìnàjú tá a yàn láàyò, ìmúra wa àti iṣẹ́ tá à ń ṣe. Àwọn nǹkan tá à ń ṣe lè má burú láyè ara wọn. Àmọ́, tó bá ń da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú débi tí wọ́n fi kọsẹ̀, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà kọjá bẹ́ẹ̀.​—Mát. 18:6. w19.08 10 ¶9-11

Wednesday, July 14

Àwọn yìí ni àwọn tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.​—Ìfi. 7:14.

Àtọdún 1935 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lóye pé àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n nírètí àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí Jòhánù rí nínú ìran. (Ìfi. 7:​9, 10) Kí ogunlọ́gọ̀ náà tó lè la ìpọ́njú ńlá já, wọ́n gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀ kí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi tó bẹ̀rẹ̀. Wọ́n gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ tó lágbára, ìyẹn ló máa jẹ́ kí wọ́n lè “bọ́ nínú gbogbo nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀” ṣáájú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Lúùkù 21:​34-36) Ìrètí tí ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà ní ń múnú wọn dùn. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló ń pinnu ibi táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ti máa gba èrè wọn, yálà ní ọ̀run tàbí láyé. Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ogunlọ́gọ̀ náà gbà pé èrè yòówù káwọn ní, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà nípasẹ̀ ìràpadà Jésù Kristi ló mú kó ṣeé ṣe.​—Róòmù 3:24. w19.09 28 ¶10; 29 ¶12-13

Thursday, July 15

Ìdùnnú Jèhófà ni agbára yín.​—Neh. 8:​10, àlàyé ìsàlẹ̀.

Bí iṣẹ́ ìsìn rẹ bá tiẹ̀ yí pa dà, pinnu pé wàá ṣàṣeyọrí bó ti wù kó rí. Má ṣe wo ara rẹ bí aláìmọ̀-ọ́n-ṣe. Máa fiyè sí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, má sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Fara wé àwọn Kristẹni tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà lọ́gọ́rùn-ún ọdún kìíní. Bíbélì ròyìn pé “wọ́n ń kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà” ní gbogbo ibi tí wọ́n lọ. (Ìṣe 8:​1, 4) Tó ò bá dẹwọ́, wàá rẹ́ni tó máa gbọ́rọ̀ rẹ, tí wàá sì máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lé àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan kúrò lórílẹ̀-èdè kan, wọ́n sì lọ sórílẹ̀-èdè míì láti wàásù fáwọn tó ń sọ èdè wọn níbẹ̀ torí àìní wà lágbègbè yẹn. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Jèhófà bù kún iṣẹ́ wọn, wọ́n sì dá àwùjọ mélòó kan sílẹ̀. Àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà ló ń fún wa láyọ̀. Torí náà, túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, máa bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n, kó máa tọ́ ẹ sọ́nà, kó sì máa tì ẹ́ lẹ́yìn. Rántí pé ohun tó jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ ibi tó o wà tẹ́lẹ̀ ni pé gbogbo ọkàn lo fi ṣe iṣẹ́ náà. Torí náà, fi gbogbo ọkàn ẹ sí iṣẹ́ ìsìn tó ò ń ṣe báyìí, wàá sì rí bí Jèhófà ṣe máa mú kó o nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ náà.​—Oníw. 7:10. w19.08 24-25 ¶15-16

Friday, July 16

Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba?​—Héb. 12:9.

Ó yẹ ká fi ara wa sábẹ́ Jèhófà torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. Torí náà, ó láṣẹ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fún gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀ láyé àti lọ́run. (Ìfi. 4:11) Àmọ́, ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ ká ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso ló dáa jù. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ṣàkóso tí wọ́n sì ń darí àwọn míì. Àmọ́ tá a bá fi àkóso wọn wé ti Jèhófà, àá rí i pé Jèhófà ni Alákòóso tó gbọ́n jù. Yàtọ̀ síyẹn, òun ló nífẹ̀ẹ́ wa jù, ó ń ṣàánú wa, ó sì ń gba tiwa rò. (Ẹ́kís. 34:6; Róòmù 16:27; 1 Jòh. 4:8) A lè fi hàn pé à ń fi ara wa sábẹ́ Jèhófà tá a bá ń sapá láti máa ṣègbọràn sí i lójoojúmọ́, tá a sì yẹra fún ṣíṣe tinú wa. (Òwe 3:5) Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ànímọ́ tó ta yọ tí Jèhófà ní, bẹ́ẹ̀ lá máa rọrùn fún wa láti fi ara wa sábẹ́ rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ àtàwọn ànímọ́ míì tó ní ń hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe. (Sm. 145:9) Bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i. Tá a bá sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò nílò òfin jàn-ànràn-jan-anran ká tó mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. w19.09 14 ¶1, 3

Saturday, July 17

Àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ.​—Mát. 11:30.

Ẹrù tó ń wọni lọ́rùn ni Sátánì gbé ka àwọn èèyàn lórí, ó sì ń fayé ni wọ́n lára. Bí àpẹẹrẹ, ó fẹ́ ká gbà gbọ́ pé Jèhófà ò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá àti pé kò nífẹ̀ẹ́ wa. Ká ní bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ohun ìbànújẹ́ gbáà ni ì bá jẹ́! (Jòh. 8:44) Àmọ́ kò sóhun tó jọ ọ́ torí pé irọ́ funfun báláú ni. Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó wá “sọ́dọ̀” Jésù. (Mát. 11:28) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo wa gan-an, kò sì fọ̀rọ̀ wa ṣeré rárá. (Róòmù 8:​32, 38, 39) Iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa yàtọ̀ sí iṣẹ́ tara wa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀pọ̀ wa bá fi máa délé lẹ́yìn iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, á ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, iṣẹ́ tá a ṣe lọ́jọ́ náà sì lè má fi bẹ́ẹ̀ wú wa lórí. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá lo ara wa dé góńgó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà àti ti Jésù, inú wa máa ń dùn gan-an. Ó lè rẹ̀ wá tẹnutẹnu lóòótọ́, kódà ó lè jẹ́ pé ńṣe la tiraka lọ sípàdé lọ́jọ́ náà. Àmọ́ nígbà tá a bá fi máa pa dà sílé, ṣe ni inú wa máa ń dùn tí ara wa sì máa ń yá gágá. Bó sì ṣe máa ń rí náà nìyẹn tá a bá sapá láti lọ sóde ẹ̀rí tá a sì ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́. Àǹfààní tá a máa ń rí kọjá ohun tó ń ná wa lọ! w19.09 20 ¶1; 23-24 ¶15-16

Sunday, July 18

Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ bí olè ní òru.​—1 Tẹs. 5:2.

Níwọ̀nba àkókò díẹ̀ tó kù kí “ọjọ́ Jèhófà” bẹ̀rẹ̀, Jèhófà fẹ́ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ká sì jẹ́ kọ́wọ́ wa dí. A gbọ́dọ̀ rí i pé à ń “ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Kódà, Jésù sọ àwọn nǹkan táá ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó tún jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe, ó ní: “Bákan náà, a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:​4, 8, 10; Mát. 24:14) Wò ó ná: Nígbàkigbà tó o bá ń wàásù, ṣe lò ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yẹn ṣẹ! Ọdọọdún ni iṣẹ́ ìwàásù ń tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń pọ̀ sí i kárí ayé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Lọ́dún 1914, díẹ̀ làwọn akéde fi lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,155), ilẹ̀ mẹ́tàlélógójì (43) péré ni wọ́n sì wà. Àmọ́ lónìí, mílíọ̀nù mẹ́jọ àtààbọ̀ ni wá, a sì ń wàásù ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì (240) ilẹ̀! Síbẹ̀, iṣẹ́ ò tíì parí o. Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn púpọ̀ sí i mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé.​—Sm. 145:​11-13. w19.10 8 ¶3; 9-10 ¶7-8

Monday, July 19

Ọlọ́run ti bù kún yín ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ lè máa fúnni lóríṣiríṣi ọ̀nà, èyí sì ń mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.​—2 Kọ́r. 9:11.

Jèhófà lo Básíláì láti ran Ọba Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́. “Ebi ń pa àwọn èèyàn náà, ó ti rẹ̀ wọ́n, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n” nígbà tí wọ́n sá kúrò nílùú torí Ábúsálómù ọmọ Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Básíláì ti darúgbó, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, òun àtàwọn míì sì lọ pèsè fún Dáfídì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Básíláì ò ronú pé òun ò lè wúlò fún Jèhófà mọ́ torí pé òun ti dàgbà. Dípò bẹ́ẹ̀, tinútinú ló fi yọ̀ǹda àwọn nǹkan ìní rẹ̀ kó lè pèsè ohun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nílò. (2 Sám. 17:​27-29) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ yìí? Yálà ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, Jèhófà lè lò wá láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa tó ṣaláìní bóyá lórílẹ̀-èdè wa tàbí lórílẹ̀-èdè míì. (Òwe 3:​27, 28; 19:17) Tá ò bá tiẹ̀ lè ṣèrànwọ́ fún wọn ní tààràtà, a lè fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé kí ètò Ọlọ́run lè rí owó tí wọ́n á fi ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá.​—2 Kọ́r. 8:​14, 15. w19.10 21 ¶6

Tuesday, July 20

Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tí wọ́n ṣe tán láti ṣe ara wọn níkà, àmọ́ ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.​—Òwe 18:24.

Ó lè ṣòro fún wa láti sọ tinú wa fún àwọn ẹlòmíì bóyá torí pé ẹnì kan ti ṣe ohun tó dùn wá nígbà kan rí. (Òwe 18:19) Ó sì lè máa ṣe wá bíi pé a ò ráyè, a ò sì lè ṣe wàhálà àtimáa wá àwọn ọ̀rẹ́ kan kiri. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ má jẹ́ kó sú wa. Tá a bá fẹ́ káwọn ará wa dúró tì wá nígbà ìṣòro, ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká kọ́ bá a ṣe lè máa sọ tinú wa fún wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ wa á túbọ̀ le sí i. (1 Pét. 1:22) Jésù máa ń báwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn rẹ̀, ìyẹn sì fi hàn pé ó fọkàn tán wọn. (Jòh. 15:15) Àwa náà lè fara wé Jésù tá a bá ń sọ àwọn nǹkan tó ń múnú wa dùn àtàwọn nǹkan tó ń bà wá nínú jẹ́ fáwọn míì. Tẹ́nì kan bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀, fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ fi jọra. Tí ìwọ náà bá ń gbìyànjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láìfi ohunkóhun pa mọ́, ó dájú pé wàá túbọ̀ láwọn ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ jọ máa sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí.​—Òwe 27:9. w19.11 4 ¶8-9

Wednesday, July 21

Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.​—Ìsík. 2:4.

Nígbà ìpọ́njú ńlá, ó ṣeé ṣe kí ohun tá à ń wàásù yí pa dà. Ní báyìí, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run là ń kéde, a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ tó bá dìgbà yẹn, ìkéde gbankọgbì tó dà bí òkúta yìnyín làá máa kéde. (Ìfi. 16:21) Àá máa kéde pé ayé Sátánì yìí máa tó pa run. Kí làá máa wàásù gan-an, ọ̀nà wo la sì máa gbà ṣe é? Àfi ká dúró dìgbà yẹn. A lè wá béèrè pé, ṣé ọ̀nà tá a gbà ń wàásù náà làá máa lò àbí ọ̀nà míì la máa gbé e gbà? Ó dìgbà yẹn ká tó mọ̀. Ọ̀nà yòówù kó jẹ́, àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ láti fìgboyà kéde ìdájọ́ Jèhófà! (Ìsík. 2:​3-5) Ó ṣeé ṣe kí ìkéde wa bí àwọn orílẹ̀-èdè nínú, kí wọ́n sì gbìyànjú láti pa wá lẹ́nu mọ́ pátápátá. Ní báyìí, Jèhófà ló ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, òun náà ló sì máa ràn wá lọ́wọ́ tó bá dìgbà yẹn. Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa fún wa lágbára láti ṣe iṣẹ́ náà láṣeyanjú.​—Míkà 3:8. w19.10 16 ¶8-9

Thursday, July 22

Àwọn kan . . . ti ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́.​—1 Tím. 6:10.

Ọ̀rọ̀ náà “ṣìnà kúrò” fi hàn pé a lè ní ìpínyà ọkàn torí pé à ń wá bá a ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, a máa dẹni tó ní “ọ̀pọ̀ ìfẹ́ ọkàn tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì lè pani lára.” (1 Tím. 6:9) Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn nǹkan yìí wà lára ohun tí Sátánì ń lò láti gbéjà kò wá, torí náà ká kíyè sára kí wọ́n má bàa jọba lọ́kàn wa. Ẹ jẹ́ ká sọ pé a lówó láti ra ohunkóhun tá a bá fẹ́. Ṣó burú tá a bá ra àwọn nǹkan tá a fẹ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nílò wọn? Ó lè má rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí: Tá a bá tiẹ̀ lówó láti ra nǹkan kan, tá a bá rà á tán, ṣé a máa ráyè lò ó? Tó bá nílò àtúnṣe ńkọ́? Yàtọ̀ síyẹn, ṣé ó ṣeé ṣe ká bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tara? Ṣé ìfẹ́ tá a ní fáwọn ohun ìní tara ò ní jẹ́ ká hùwà bíi ti ọ̀dọ́kùnrin tí kò gbà láti tẹ̀ lé Jésù torí àwọn nǹkan tó ní? (Máàkù 10:​17-22) Ẹ wo bó ṣe máa bọ́gbọ́n mu tó tá a bá jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ká lè fi àkókò àti okun wa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run! w19.11 17-18 ¶15-16

Friday, July 23

Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.​—Òwe 21:5.

Tó o bá ti pinnu láti ṣe nǹkan kan, Ọlọ́run lè fún ẹ ní “agbára láti ṣe é.” (Fílí. 2:13) Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lágbára. Bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó bá jọ pé o ò tíì rí ìdáhùn sí àdúrà ẹ, má jẹ́ kó sú ẹ, túbọ̀ máa gbàdúrà. Jésù náà sọ pé: “Ẹ máa béèrè [fún ẹ̀mí mímọ́], a sì máa fún yín.” (Lúùkù 11:​9, 13) Yàtọ̀ síyẹn, ṣètò bó o ṣe fẹ́ ṣe é. Tó o bá fẹ́ parí ohun tó o dáwọ́ lé, o gbọ́dọ̀ ṣètò ohun tó o fẹ́ ṣe, kó o sì máa tẹ̀ lé ìṣètò náà. Torí náà, tó o bá ti pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe, kọ gbogbo ìgbésẹ̀ tó o fẹ́ gbé lórí ẹ̀ sílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Tó o bá pín àwọn nǹkan náà sí kéékèèké, á rọrùn fún ẹ láti rí ibi tó o báṣẹ́ dé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì níyànjú pé kí wọ́n máa ya owó tí wọ́n fẹ́ fi ṣètìlẹ́yìn sọ́tọ̀ “ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀,” kó má bàa di pé tóun bá dé ni wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kówó náà jọ. (1 Kọ́r. 16:2) Tíwọ náà bá ní nǹkan púpọ̀ láti ṣe, pín in sí kéékèèké kẹ́rù yẹn má bàa wọ̀ ẹ́ lọ́rùn. w19.11 29 ¶13-14

Saturday, July 24

Àwọn tó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀ lé ọ; Jèhófà, ìwọ kì yóò pa àwọn tó ń wá ọ tì láé.​—Sm. 9:10.

Ẹni tó mọ orúkọ Ọlọ́run, tó sì mọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ṣe àtohun tó sọ lè ronú pé òun mọ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ló mọ Jèhófà? Kí lẹni tó mọ Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe? Ó gbọ́dọ̀ wáyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, àwọn ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. Ìgbà yẹn lá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ìdí tí Jèhófà fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan àti ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan. Èyí á mú kó mọ̀ bóyá èrò òun, ọ̀rọ̀ òun àti ìṣe òun bá ti Jèhófà mu. Téèyàn bá sì ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe, ohun tó kù ni pé kéèyàn ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Àwọn èèyàn lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tá a bá pinnu pé Jèhófà la máa sìn, kódà wọ́n lè ta kò wá tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà. Àmọ́ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kò ní fi wá sílẹ̀ láé. Tá a bá dúró lórí ìpinnu wa, àá di ọ̀rẹ́ Jèhófà, okùn ọ̀rẹ́ wa ò sì ní já. Ṣó ṣeé ṣe kéèyàn mọ Jèhófà débi téèyàn á fi di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? Ó ṣeé ṣe dáadáa! w19.12 16-17 ¶3-4

Sunday, July 25

Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.​—Sm. 127:3.

Nígbà míì, àwọn ìṣòro tẹ́yin òbí ń kojú lè mú kí nǹkan sú yín, àmọ́ ẹ rántí pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọmọ jẹ́. Ó ṣe tán láti ràn yín lọ́wọ́, inú ẹ̀ sì máa ń dùn láti dáhùn àdúrà yín. Ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Bíbélì, àwọn ìtẹ̀jáde àti nípasẹ̀ àpẹẹrẹ àti ìmọ̀ràn àwọn ará tó ti tọ́ ọmọ yanjú. Àwọn kan sọ pé ó máa ń gba ogún (20) ọdún kéèyàn tó lè tọ́ ọmọ kan yanjú, àmọ́ kókó ibẹ̀ ni pé òbí ni òbí á máa jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́. Lára ohun tó dáa jù tẹ́yin òbí lè fún àwọn ọmọ yín ni ìfẹ́, àkókò yín àti ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ọmọ kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bó ṣe máa fàwọn ẹ̀kọ́ náà sílò. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí òbí Kristẹni tọ́ dàgbà ló sọ òtítọ́ di tiwọn bíi ti arábìnrin kan tó ń jẹ́ Joanna Mae nílẹ̀ Éṣíà. Ó sọ pé: “Ṣe ni mo máa ń dúpẹ́ pé wọ́n kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n sì mú kí n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Òótọ́ ni pé wọ́n bí mi, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe fún mi jùyẹn lọ, wọ́n mú kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀.” (Òwe 23:​24, 25) Ó dájú pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọ̀pọ̀ wa náà nìyẹn. w19.12 27 ¶21-22

Monday, July 26

Kí a . . . fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ tu àwọn míì nínú lábẹ́ àdánwò èyíkéyìí tí wọ́n bá wà.​—2 Kọ́r. 1:4.

Kò dìgbà tá a bá lọ sí ìjọ míì ká tó rí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n nílò ìtùnú, wọ́n wà nínú ìjọ wa náà. Bí ẹ̀rù bá tiẹ̀ ń bà wá, a ṣì lè wọ́nà láti tu àwọn míì nínú. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa ronú pé kí la mọ̀ tá a fẹ́ sọ tàbí kí la lè ṣe fún ẹni tó wà nínú ìṣòro. Àwa náà lè jẹ́ orísun ìtùnú fáwọn tó níṣòro tá a bá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni nǹkan á túbọ̀ máa nira tí ayé náà á sì ṣòro gbé. (2 Tím. 3:13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìṣòro tó ń dé bá wa nítorí àìpé ẹ̀dá àti ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún máa mú kó pọn dandan pé káwọn míì tù wá nínú. Lára ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fara dà á títí dójú ikú ni báwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ ṣe gbárùkù tì í, tí wọ́n sì tù ú nínú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè ran àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìgbàgbọ́ wọn mú bó ti wù kí nǹkan nira tó.​—1 Tẹs. 3:​2, 3. w20.01 12-13 ¶17-19

Tuesday, July 27

O dán àwọn tó pe ara wọn ní àpọ́sítélì wò.​—Ìfi. 2:2.

Awọn ẹni àmì òróró kì í retí pé káwọn èèyàn máa fún àwọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. (Fílí. 2:​2, 3) Wọ́n sì mọ̀ pé nígbà tí Jèhófà fẹ̀mí yan àwọn, kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀. Torí náà, ẹni àmì òróró kan ò ní jẹ́ kó ya òun lẹ́nu táwọn kan ò bá tètè gbà pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan òun. Ó ṣe tán, Bíbélì pàápàá sọ pé ká má ṣe yára gbà gbọ́ tẹ́nì kan bá sọ pé Jèhófà fún òun ní àkànṣe iṣẹ́. Torí pé ẹni àmì òróró kan ò retí pé káwọn èèyàn máa fún òun láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀, kò ní máa sọ fáwọn èèyàn tó bá pàdé pé ẹni àmì òróró lòun. Kò sì ní máa fọ́nnu nípa ẹ̀ (1 Kọ́r. 4:​7, 8) Àwọn ẹni àmì òróró kì í ronú pé àwọn ẹni àmì òróró bíi tiwọn nìkan ló yẹ káwọn máa bá ṣọ̀rẹ́ bí ẹní ń ṣẹgbẹ́ àwa-ara-wa. Wọn kì í wá àwọn ẹni àmì òróró míì kiri bóyá torí kí wọ́n lè jọ máa sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ń rí téèyàn bá di ẹni àmì òróró tàbí kí wọ́n lè jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. (Gál. 1:​15-17) Ìjọ ò ní wà níṣọ̀kan táwọn ẹni àmì òróró bá ń hu irú ìwà yìí. Ìdí sì ni pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ ta ko ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó ń jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.​—Róòmù 16:​17, 18. w20.01 28 ¶6-7

Wednesday, July 28

Tí àwọn nǹkan yìí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ẹ nàró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, torí ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.​—Lúùkù 21:28.

Bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń bá a lọ, àwọn tí ẹ̀sìn wọn ti pa run máa kíyè sí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan la ṣẹ́ kù, ìyẹn sì máa múnú bí wọn. Wọ́n máa jẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ pé inú ń bí àwọn, kódà wọ́n á gbé e sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Inú máa bí àwọn orílẹ̀-èdè àti Sátánì tó ń darí wọn, wọ́n á sì kórìíra wa torí pé ẹ̀sìn tiwa nìkan ló kù. Ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni pé káwọn pa gbogbo ẹ̀sìn run, àmọ́ wọn ò ní ríyẹn ṣe. Torí náà, wọ́n máa dájú sọ wá. Ìgbà táwọn orílẹ̀-èdè bá kóra jọ láti bá wa jà ni Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù. Wọ́n máa fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà. (Ìsík. 38:​2, 14-16) Ìyẹn sì lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn torí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀, pàápàá torí pé a ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí nǹkan ṣe máa rí. Àmọ́ ohun kan dájú, a ò ní bẹ̀rù ìpọ́njú ńlá torí pé Jèhófà máa fún wa láwọn ìtọ́ni táá gbà wá là.​—Sm. 34:19. w19.10 16-17 ¶10-11

Thursday, July 29

Wo bí àwọn ohun tí o ṣe ti pọ̀ tó, Jèhófà Ọlọ́run mi, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti èrò rẹ sí wa.​—Sm. 40:5.

Kì í ṣe ká kàn mọ oore tí Jèhófà ṣe fún wa nìkan ni, ó tún yẹ ká fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Èyí ń jẹ́ ká yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn inú ayé torí pé inú ayé táwọn èèyàn ò ti mọyì nǹkan tí Ọlọ́run ṣe fún wọn là ń gbé. Kódà, ọ̀kan lára ohun tó fi hàn pé “ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé ni pé àwọn èèyàn jẹ́ aláìmoore. (2 Tím. 3:​1, 2) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká ya aláìmoore láé! Jèhófà ò fẹ́ ká máa bára wa jà, ó fẹ́ ká wà ní àlàáfíà. Kódà, ìfẹ́ tá a ní síra wa yìí ló ń fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá. (Jòh. 13:35) A gbà pé òótọ́ lohun tí onísáàmù sọ pé: “Ó mà dára o, ó mà dùn o pé kí àwọn ará máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” (Sm. 133:1) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (1 Jòh. 4:20) Ẹ wo bó ṣe dùn tó pé a wà lára ìdílé tá a ti ń ṣe bí ọmọ ìyá, tá a ‘jẹ́ onínúure, tá a sì ń ṣàánú ara wa!’​—Éfé. 4:32. w20.02 9 ¶6-7

Friday, July 30

Jèhófà ṣíjú àánú wo Hánà.​—1 Sám. 2:21.

Ohun tó fa ẹ̀dùn ọkàn fún Hánà kò yí pa dà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Inú ilé tí Pẹ̀nínà orogún rẹ̀ ń gbé náà ló ń gbé. Bíbélì ò sì sọ pé Pẹ̀nínà ti yíwà pa dà. Èyí túmọ̀ sí pé Hánà á ṣì máa fara da àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí orogún rẹ̀ ń sọ sí i. Síbẹ̀, Hánà kò jẹ́ kóhun tí obìnrin náà ń sọ kó ìbànújẹ́ bá òun mọ́. Lẹ́yìn tó ti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Jèhófà, kò banú jẹ́ mọ́. Ó gbára lé Jèhófà, ara sì tù ú. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín Jèhófà dáhùn àdúrà Hánà, òun náà sì láwọn ọmọ tiẹ̀! (1 Sám. 1:​2, 6, 7, 17-20) A ṣì lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí ìṣòro wa kò bá tiẹ̀ yanjú. A lè gbàdúrà lemọ́lemọ́ ká sì máa lọ sípàdé déédéé, síbẹ̀ káwọn ìṣòro kan má tíì yanjú. Àpẹẹrẹ Hánà jẹ́ ká rí i pé kò sóhun tó lè ní kí Jèhófà má tù wá lára. Òótọ́ kan ni pé Jèhófà kò ní pa wá tì láé, bópẹ́ bóyá á san wá lẹ́san tá ò bá jẹ́ kó sú wa.​—Héb. 11:6. w20.02 22 ¶9-10

Saturday, July 31

Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóò sì gbọ́n sí i.​—Òwe 9:9.

Àwọn alàgbà máa ń rí i dájú pé ìlànà Bíbélì làwọn fi tọ́ ẹnì kan sọ́nà kó lè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ nígbà tó yẹ? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Élì. Élì àlùfáà àgbà ní àwọn ọmọkùnrin méjì kan tó fẹ́ràn gan-an. Àmọ́ àwọn ọmọ náà kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà rárá. Àlùfáà làwọn méjèèjì, wọ́n sì ní ojúṣe pàtàkì tí wọ́n ń bójú tó nínú àgọ́ ìjọsìn. Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń ṣi ipò wọn lò, wọ́n sì ń hùwà ta ló máa mú mi tó bá kan ẹbọ táwọn èèyàn ń rú sí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń bá àwọn obìnrin ṣèṣekúṣe láìbìkítà nípa ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. (1 Sám. 2:​12-17, 22) Bí Òfin Mósè ṣe sọ, ṣe ló yẹ kí wọ́n pa àwọn méjèèjì, àmọ́ dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni bàbá wọn kàn fẹnu lásán bá wọn wí, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n máa bá iṣẹ́ àlùfáà lọ nínú àgọ́ ìjọsìn. (Diu. 21:​18-21) Báwo lohun tí Élì ṣe yẹn ṣe rí lára Jèhófà? Ó sọ fún Élì pé: “Kí ló dé tí ò ń bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ jù mí lọ?” Jèhófà wá pinnu pé òun máa pa àwọn ọmọkùnrin yẹn torí ìwà burúkú wọn.​—1 Sám. 2:​29, 34. w20.03 19 ¶4-5

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́