ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 3-5
  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 3-5

Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀

Ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́ máa jẹ́ kó o tètè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn ìtàn inú Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá níṣòro. Ó tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o lè fi fúnni níṣìírí àtèyí tó o lè fi fúnni nímọ̀ràn kẹ́ni náà lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn. Lọ sí àkòrí tó o fẹ́, wàá rí àwọn ìbéèrè tó ṣe tààràtà àti àlàyé ṣókí nípa àwọn ìtàn Bíbélì tá a tọ́ka sí níbẹ̀. (Wo àpótí tá a pè ní “Bó O Ṣe Lè Lo Ìwé Yìí.”) Ìwé yìí máa jẹ́ kó o rí ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn àti ìsọfúnni tó wúlò, tó sì ń tuni nínú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wàá tún rí àwọn ìlànà Bíbélì tó o lè fi fúnni níṣìírí àtèyí tó o lè fi gbani nímọ̀ràn.

Bó O Ṣe Lè Lo Ìwé Yìí 

Tó o bá ń wá àkòrí kan, o lè tẹ̀ ẹ́ sínú àpótí tá a ti lè wá ọ̀rọ̀ tàbí kó o wo àwọn ìsọ̀rí tá a pín ìwé yìí sí. Ìsọ̀rí méje tí ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́ pín sí ni: Ìṣòro, Ohun Téèyàn Ń Ṣe, Ìjọ, Ìgbésí Ayé, Ìdílé, Àjọṣe Pẹ̀lú Jèhófà, àti Irú Ẹni Téèyàn Jẹ́. Wàá rí àkòrí ọ̀rọ̀ tó ò ń wá nínú ọ̀kan lára àwọn ìsọ̀rí yìí. Mú ìsọ̀rí tó o fẹ́, kó o sì lọ sí èyí tó wù ẹ́ lára àwọn àkòrí tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí náà. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé o ò mọ ìsọ̀rí tó o ti lè rí àkòrí tó ò ń wá, tẹ Gbogbo ẹ̀, kó o wá fara balẹ̀ wá èyí tó wù ẹ́ lára gbogbo àwọn àkòrí tó wà níbẹ̀. Lábẹ́ àkòrí kọ̀ọ̀kan, wàá rí àwọn kókó tá a kọ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀. Gbólóhùn tó ṣe tààràtà làwọn kan, àwọn míì sì jẹ́ ìbéèrè. Lẹ́yìn tó o bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà lábẹ́ kókó kọ̀ọ̀kan, ronú nípa báwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe ti ọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn tàbí bó ṣe dáhùn ìbéèrè tó wà níbẹ̀. A pín àwọn àkòrí kan sí kéékèèké kó lè rọrùn fún ẹ láti tètè rí ohun tó ò ń wá. Bákan náà, tá a bá tọ́ka sí àfikún ẹsẹ Bíbélì, wàá rí ọ̀rọ̀ náà “Tún wo.” Èyí á jẹ́ kó o rí àwọn kókó míì tó tan mọ́ àkòrí tó ò ń ṣèwádìí nípa ẹ̀. Wàá tún rí apá tá a pè ní “Àpẹẹrẹ inú Bíbélì.” Nínú apá yìí, a kọ ẹsẹ Bíbélì kan, a sì ṣe àlàyé ṣókí nípa kókó pàtàkì tó wà nínú ẹsẹ náà. Àlàyé yìí á jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn tó o bá ka ẹsẹ Bíbélì náà.

Kì í ṣe gbogbo ẹsẹ Bíbélì tó bá àkòrí kọ̀ọ̀kan mu lo máa rí nínú ìwé yìí. Àmọ́, wàá rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣe pàtàkì, èyí á sì mú kó rọrùn fún ẹ láti ṣèwádìí sí i. (Owe 2:1-6) Kó o lè ṣèwádìí sí i, lo àwọn atọ́ka ẹsẹ Bíbélì tó wà láàárín ojú ìwé Bíbélì àtàwọn àlàyé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bákan náà, o lè lo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí Watch Tower Publications Index láti ṣèwádìí síwájú sí i nípa ohun tí ẹsẹ Bíbélì kan túmọ̀ sí àti bá a ṣe lè lò ó. Àwọn ìtẹ̀jáde tó dé kẹ́yìn ni kó o máa lò, kó o lè rí òye tá a ní báyìí nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Àdúrà wa ni pé bó o ṣe ń lo ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́, kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Tó o bá ń lo ìwé yìí, ìwọ náà á jẹ́rìí sí i pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára.”—Heb 4:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́