January
Wednesday, January 1
Wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, òun nìkan ṣoṣo ni ìyá rẹ̀ bí. Yàtọ̀ síyẹn, opó ni obìnrin náà.—Lúùkù 7:12.
Lẹ́yìn tí Jésù ‘tajú kán rí’ ìyá ọmọ tó kú náà, “àánú rẹ̀ ṣe é.” (Lúùkù 7:13) Jésù ò kàn káàánú ìyá ọmọ náà, àmọ́ ó ṣe ohun kan tó fi hàn pé àánú ẹ̀ ṣe é. Ó wá sọ ohun tó fi ìyá ọmọ náà lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Má sunkún mọ́.” Lẹ́yìn náà, ó ṣe ohun kan láti ràn án lọ́wọ́. Ó jí ọmọ ẹ̀ dìde, ó sì ‘fà á lé e lọ́wọ́.’ (Lúùkù 7:14, 15) Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe jí ọmọ obìnrin opó náà dìde? Ohun tá a rí kọ́ ni pé ká máa fàánú hàn sáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Tá a bá lákìíyèsí bíi ti Jésù, àwa náà á máa fàánú hàn sáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká sọ ohun tó máa tù wọ́n nínú tàbí ká ṣe ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 17:17; 2 Kọ́r. 1:3, 4; 1 Pét. 3:8) Kódà, tí ohun tá a ṣe fún wọn ò bá tó nǹkan, ó máa tù wọ́n nínú gan-an. w23.04 5-6 ¶13-15
Thursday, January 2
Ikú kọ́ ló máa gbẹ̀yìn àìsàn yìí, àmọ́ ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run.—Jòh. 11:4.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé ọ̀rẹ́ òun ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, ó ṣì lo ọjọ́ méjì ní òdìkejì Jọ́dánì kó tó wá sí Bẹ́tánì. Nígbà tí Jésù máa dé, ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú. Torí náà, ó wu Jésù kó ṣe nǹkan tó máa ṣe àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ láǹfààní, táá sì jẹ́ káwọn èèyàn yin Ọlọ́run lógo. (Jòh. 11:6, 11, 17) Àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú ìtàn yìí. Ẹ kíyè sí i pé nígbà tí Màríà àti Màtá ránṣẹ́ sí Jésù, wọn ò sọ pé kó wá sí Bẹ́tánì. Wọ́n kàn ránṣẹ́ sí i pé ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ ń ṣàìsàn ni. (Jòh. 11:3) Lóòótọ́, nígbà tí Jésù wà ní òdìkejì Jọ́dánì, ó lè jí Lásárù tó ti kú ní Bẹ́tánì dìde, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbéra lọ sí Bẹ́tánì níbi tí Màríà àti Màtá tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń gbé. Ṣé ìwọ náà ní ọ̀rẹ́ kan tó ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà ìṣòro tó ò bá tiẹ̀ sọ fún un? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lẹ́ni tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní “ìgbà wàhálà” nìyẹn. (Òwe 17:17) Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà. w23.04 10 ¶10-11
Friday, January 3
Olóòótọ́ ni ẹni tó ṣèlérí.—Héb. 10:23.
Tá a bá níṣòro, a lè máa rò pé ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí ò ní dé láé. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò nígbàgbọ́ tó lágbára? Ó lè má jẹ́ bẹ́ẹ̀. Wo àpèjúwe yìí ná. Ká sọ pé òjò ti ń rọ̀ láti nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan, a lè rò pé oòrùn ò ní ràn mọ́. Lọ́nà kan náà, tí ìṣòro bá dorí wa kodò, a lè rò pé ayé tuntun ò ní dé mọ́. Torí náà, tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára, á dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. (Sm. 94:3, 14, 15; Héb. 6:17-19) Ohun tó dá wa lójú yìí máa ń jẹ́ ká fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Ẹ jẹ́ ká tún wo nǹkan míì tó gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé àlá tí ò lè ṣẹ ni “ìhìn rere” nípa ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Mát. 24:14; Ìsík. 33:32) Ó yẹ ká ṣọ́ra, ká má ṣiyèméjì bíi tiwọn. Torí náà, tá ò bá fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. w23.04 27 ¶6-7; 28 ¶14
Saturday, January 4
A mọ̀ pé a máa rí àwọn ohun tí a béèrè gbà, torí pé a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.—1 Jòh. 5:15.
Ṣé o ti bi ara ẹ rí pé ṣé Jèhófà tiẹ̀ ń dáhùn àdúrà mi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lò ń béèrè irú ìbéèrè yẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ti béèrè irú ìbéèrè yìí, pàápàá nígbà tí wọ́n níṣòro tó le gan-an. Táwa náà bá níṣòro, ó lè má rọrùn láti rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa. Kí ló máa mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àwọn tó ń sìn ín? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, a sì ṣeyebíye lójú ẹ̀. (Hág. 2:7; 1 Jòh. 4:10) Ìdí nìyẹn tó fi ní ká máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí òun, ká sì máa béèrè ohun tá a fẹ́. (1 Pét. 5:6, 7) Ó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè sún mọ́ òun, ká sì borí àwọn ìṣòro tá a ní. Nínú Bíbélì, a sábà máa ń kà nípa bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. Ṣé o rántí àpẹẹrẹ kan? w23.05 8 ¶1-4
Sunday, January 5
Màríà sọ pé: “Ọkàn mi gbé Jèhófà ga.”—Lúùkù 1:46.
Màríà fúnra ẹ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kì í ṣe torí pé Jósẹ́fù ń sin Jèhófà lòun náà ṣe ń sin Jèhófà. Ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń wáyè ronú lórí ohun tó kọ́ nípa Jèhófà. (Lúùkù 2:19, 51) Ó dájú pé àjọṣe tó dáa tí Màríà ní pẹ̀lú Jèhófà mú kó jẹ́ aya rere. Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn aya ló ń sapá láti ṣe bíi ti Màríà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Emiko sọ pé: “Mo máa ń dá gbàdúrà, mo sì máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo ṣègbéyàwó, ọkọ mi ló máa ń gbàdúrà fún wa tó sì máa ń darí ohunkóhun tá a bá fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn wa, ìyẹn ni ò jẹ́ kí n máa ṣe àwọn nǹkan tí mo máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Mo rí i pé àfi kémi fúnra mi ṣiṣẹ́ kára kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà lè lágbára. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ya àkókò sọ́tọ̀ láti dá gbàdúrà sí Jèhófà, kí n máa ka Bíbélì, kí n sì máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí mo bá kà.” (Gál. 6:5) Torí náà tó o bá jẹ́ aya, tó o sì ń mú kí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, ọkọ ẹ á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ, á sì máa yìn ẹ́.—Òwe 31:30. w23.05 21 ¶6
Monday, January 6
Màá kọ́ yín ní ìbẹ̀rù Jèhófà.—Sm. 34:11.
Wọn ò bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run mọ́ wa, ṣe ló yẹ ká kọ́ ọ. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa kíyè sí àwọn nǹkan tó dá. Bá a bá ṣe ń rí ọgbọ́n Ọlọ́run, agbára rẹ̀ àti ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tó ní sí wa lára “àwọn ohun tó dá,” bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. (Róòmù 1:20) Ọ̀nà míì tá a lè gbà kọ́ béèyàn ṣe ń bẹ̀rù Ọlọ́run ni pé ká máa gbàdúrà déédéé. Bá a bá ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa mọ irú ẹni tó jẹ́. Gbogbo ìgbà tá a bá ní kó fún wa lókun láti fara da ìṣòro làá máa rántí bí agbára tó ní ṣe pọ̀ tó. Tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó jẹ́ kí ọmọ ẹ̀ kú nítorí wa, ṣe là ń rán ara wa létí bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣe pọ̀ tó. Bákan náà, tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, ó máa ń jẹ́ ká rántí pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà. Irú àwọn àdúrà yìí máa ń jẹ́ ká túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà. Àwọn àdúrà yẹn tún máa ń jẹ́ ká pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. w23.06 15 ¶6-7
Tuesday, January 7
Jèhófà ni Afúnnilófin wa.—Àìsá. 33:22.
Léraléra ni Jèhófà máa ń fún àwa èèyàn ẹ̀ lófin tí ò lọ́jú pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbìmọ̀ olùdarí ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ sọ nǹkan mẹ́ta tó yẹ ká máa ṣe ká lè jẹ́ adúróṣinṣin: (1) ká sá fún ìbọ̀rìṣà, ká sì máa sin Jèhófà nìkan, (2) ká máa pa òfin Jèhófà mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ àti (3) ká máa sá fún ìṣekúṣe. (Ìṣe 15:28, 29) Báwo làwa Kristẹni ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin nínú nǹkan mẹ́ta yìí? Ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà, ká sì máa jọ́sìn ẹ̀. Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn. (Diu. 5:6-10) Kódà, nígbà tí Èṣù dán Jésù wò, ó sọ fún un pé Jèhófà nìkan la gbọ́dọ̀ jọ́sìn. (Mát. 4:8-10) Torí náà, àwa Kristẹni kì í lo ère nínú ìjọsìn wa. Bákan náà, a kì í sọ àwọn èèyàn di ọlọ́run, bóyá olórí ẹ̀sìn ni wọ́n, olóṣèlú, ìlúmọ̀ọ́ká eléré ìdárayá tàbí gbajúgbajà òṣèré. Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn torí pé òun ló “dá ohun gbogbo.”—Ìfi. 4:11. w23.07 15 ¶3-4
Wednesday, January 8
Ìbẹ̀rù Jèhófà máa ń mú kéèyàn yẹra fún ohun búburú.—Òwe 16:6.
Ìṣekúṣe àti ìwòkuwò ti mọ́ àwọn èèyàn lára nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. (Éfé. 4:19) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run, ká sì máa sá fún ìwà burúkú. Òwe orí kẹsàn-án sọ nípa àwọn obìnrin méjì tá a fi wé ọgbọ́n àti òmùgọ̀. Àwọn obìnrin méjì yìí ń pe àwọn aláìmọ̀kan, ìyẹn “àwọn tí kò ní làákàyè” pé kí wọ́n wá. Kálukú wọn ló ń sọ pé, ‘Wá sílé mi kó o wá jẹun.’ (Òwe 9:1, 4-6) Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ sọ́dọ̀ obìnrin àkọ́kọ́ yàtọ̀ pátápátá sóhun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ sọ́dọ̀ obìnrin kejì. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí “òmùgọ̀ obìnrin” náà ń sọ. (Òwe 9:13-18) Gbogbo ẹnu ló fi ń pe àwọn tí kò ní làákàyè pé ẹ “Wọlé síbí,” kẹ́ ẹ wá jẹun. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ? Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ikú ti pa wà níbẹ̀.” Ó kìlọ̀ fún wa nípa “obìnrin oníwàkiwà” àti “obìnrin oníṣekúṣe.” Bíbélì sọ fún wa pé: “Ilé rẹ̀ ń rini sínú ikú.” (Òwe 2:11-19) Òwe 5:3-10 tún kìlọ̀ fún wa nípa “obìnrin oníwàkiwà” tí “ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ikú.” w23.06 22 ¶6-7
Thursday, January 9
Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.—Fílí. 4:5.
Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fòye báni lò. (1 Tím. 3:2, 3) Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ kí alàgbà kan máa retí pé gbogbo ìgbà ni káwọn alàgbà yòókù gba ohun tóun bá sọ torí òun dàgbà jù wọ́n lọ, òun sì nírìírí jù wọ́n lọ. Ó yẹ kó gbà pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè lo alàgbà èyíkéyìí láti sọ ohun tó máa mú kí wọ́n ṣe ìpinnu tó dáa. Tí ìgbìmọ̀ alàgbà bá ṣe ìpinnu tí ò ta ko ìlànà Bíbélì, táwọn tó pọ̀ jù nínú ìgbìmọ̀ náà sì fọwọ́ sí i, ó yẹ káwọn alàgbà yòókù fòye báni lò, kí wọ́n sì fara mọ́ ọn, kódà tí ìpinnu náà ò bá wù wọ́n. Tá a bá ń fòye báni lò, a máa jàǹfààní tó pọ̀. A máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará wa, àlàáfíà sì máa wà nínú ìjọ. Inú wa á máa dùn torí ìwà tó dáa táwọn ará wa ní àti àṣà ìbílẹ̀ wọn lóríṣiríṣi, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé inú wa á máa dùn torí a mọ̀ pé à ń fara wé Jèhófà Ọlọ́run tó ń fòye báni lò. w23.07 25 ¶16-17
Friday, January 10
Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa lóye.—Dán. 12:10.
Ohun tó tọ́ ló mú kí Dáníẹ́lì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó fẹ́ mọ òtítọ́. Dáníẹ́lì tún nírẹ̀lẹ̀, ó mọ̀ pé Jèhófà máa jẹ́ káwọn tí wọ́n mọ òun, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òun lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀. (Dán. 2:27, 28) Dáníẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ìyẹn sì fi hàn pé ó nírẹ̀lẹ̀. (Dán. 2:18) Dáníẹ́lì tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Ó ṣèwádìí nínú Ìwé Mímọ́ tó wà nígbà ayé rẹ̀. (Jer. 25:11, 12; Dán. 9:2) Báwo lo ṣe lè fara wé Dáníẹ́lì? Ronú nípa ìdí tó o fi fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ṣé torí pé o fẹ́ mọ òtítọ́ ló mú kó o fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Jòh. 4:23, 24; 14:16, 17) Àmọ́, àwọn kan máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n ń wá ẹ̀rí tó máa fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ ni Bíbélì. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n rò pé táwọn bá rí àwọn ẹ̀rí yẹn, àwọn máa lè pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, àwọn á sì máa gbé ìgbé ayé àwọn báwọn ṣe fẹ́. Àmọ́, ìdí tó fi yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ni pé ká lè mọ òtítọ́. w23.08 9-10 ¶7-8
Saturday, January 11
Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì . . . , agbára rẹ ò ní tó nǹkan.—Òwe 24:10.
Tá a bá ń fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì, a lè dẹrù pa ara wa. (Gál. 6:4) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara wọn, ká sì máa bá wọn díje. (Gál. 5:26) Tá a bá ń ṣiṣẹ́ kára torí ká lè ní nǹkan táwọn ẹlòmíì ní, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tágbára wa ò ká. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, “ìrètí pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn.” Tá a bá wá ń retí ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀ láé, ẹ ò rí i pé ìbànújẹ́ yẹn máa pọ̀ gan-an! (Òwe 13:12) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa rẹ̀ wá gan-an, a ò sì ní lè sáré ìyè náà dáadáa. Má rò pé o ò ṣe tó ohun tí Jèhófà retí pé kó o ṣe. Kò retí pé kó o ṣe ohun tó ju agbára ẹ lọ. (2 Kọ́r. 8:12) Mọ̀ dájú pé Jèhófà kì í fi ohun tó o ṣe wé ohun táwọn ẹlòmíì ṣe. (Mát. 25:20-23) Ó mọyì bó o ṣe ń sin òun tọkàntọkàn, bó o ṣe jẹ́ olóòótọ́ àti bó o ṣe ń fara dà á. w23.08 29 ¶10-11
Sunday, January 12
Ṣé kí òùngbẹ wá pa mí ni?—Oníd. 15:18.
Jèhófà dáhùn àdúrà Sámúsìn, ó sì jẹ́ kí omi ṣàn jáde látinú kòtò kan lọ́nà ìyanu. Nígbà tó mu omi náà, “okun rẹ̀ pa dà, ó sì sọ jí.” (Oníd. 15:19) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣeé ṣe kí omi ṣì wà nínú kòtò náà nígbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wòlíì Sámúẹ́lì láti kọ ìwé Àwọn Onídàájọ́. Torí náà, nígbàkigbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá rí kòtò omi tó ń ṣàn náà, wọ́n á máa rántí pé tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Ó yẹ káwa náà máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láìka ẹ̀bùn tá a ní sí àtàwọn nǹkan míì tá a ti gbé ṣe nínú ètò rẹ̀. Ó yẹ ká mọ̀wọ̀n ara wa, ká sì gbà pé ohun tó máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí ni tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí Sámúsìn ṣe pa dà lókun lẹ́yìn tó mu omi tí Jèhófà pèsè fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa máa lágbára tá a bá ń lo gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń pèsè fún wa.—Mát. 11:28. w23.09 4 ¶8-10
Monday, January 13
Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ líle ń ru ìbínú sókè.—Òwe 15:1.
Kí la lè ṣe tí wọ́n bá múnú bí wa, irú bíi kẹ́nì kan sọ ohun tí ò dáa nípa Jèhófà àbí Bíbélì? Ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè fọgbọ́n dá ẹni náà lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Àmọ́, tá a bá rí i pé ọ̀nà tá a gbà dá ẹni náà lóhùn ò dáa tó ńkọ́? A lè gbàdúrà nípa ẹ̀, ká sì ronú nípa bá a ṣe máa dáhùn dáadáa nígbà míì. Jèhófà máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè kó ara wa níjàánu, ká sì níwà tútù. Tẹ́nì kan bá múnú bí wa, àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà tí ò ní jẹ́ ká gbaná jẹ. Ẹ̀mí Ọlọ́run lè jẹ́ ká rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà. (Jòh. 14:26) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlànà tó wà nínú ìwé Òwe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ oníwà tútù. (Òwe 15:18) Ìwé Bíbélì yẹn tún jẹ́ ká mọ àǹfààní tá a máa rí tá ò bá gbaná jẹ nígbà tí wọ́n bá múnú bí wa.—Òwe 10:19; 17:27; 21:23; 25:15. w23.09 15 ¶6-7
Tuesday, January 14
Ó wù mí kí n máa rán yín létí àwọn nǹkan yìí nígbà gbogbo.—2 Pét. 1:12.
Àpọ́sítélì Pétérù mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi sin Jèhófà tọkàntọkàn. Láwọn àsìkò yẹn, ó wà pẹ̀lú Jésù nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, òun ló kọ́kọ́ wàásù fáwọn tí kì í ṣe Júù, nígbà tó sì yá, ó di ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ olùdarí. Àmọ́ kó tó kú, Jèhófà gbé àwọn iṣẹ́ míì fún un. Ní nǹkan bí ọdún 62-64 S.K., Jèhófà fẹ̀mí ẹ̀ darí Pétérù láti kọ ìwé Pétérù kìíní àti ìkejì. (2 Pét. 1:13-15) Àsìkò tí “oríṣiríṣi àdánwò kó ìdààmú” bá àwọn Kristẹni ni Pétérù kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀. (1 Pét. 1:6) Àwọn èèyàn burúkú ń dọ́gbọ́n mú ẹ̀kọ́ èké àti ìwà àìmọ́ wọnú ìjọ. (2 Pét. 2:1, 2, 14) Àwọn Kristẹni tó ń gbé Jerúsálẹ́mù máa tó rí “òpin ohun gbogbo,” ìyẹn ìgbà táwọn ọmọ ogun Róòmù máa pa ìlú yẹn àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. (1 Pét. 4:7) Kò sí iyè méjì pé àwọn lẹ́tà tí Pétérù kọ máa ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tó bá yọjú, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tó lè yọjú lọ́jọ́ iwájú. w23.09 26 ¶1-2
Wednesday, January 15
[Kristi] kọ́ ìgbọràn látinú ìyà tó jẹ.—Héb. 5:8.
Bíi ti Jésù, àwa náà máa ń kọ́ ìgbọràn tí nǹkan ò bá fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àrùn kòrónà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ètò Ọlọ́run sọ pé a ò ní ṣèpàdé ní Ilé Ìpàdé wa mọ́, a ò sì ní wàásù láti ilé dé ilé mọ́. Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti ṣe ohun tí wọ́n sọ yẹn? Ìgbọràn tó o ṣe dáàbò bò ẹ́, ó jẹ́ kí ìwọ àtàwọn ará ìjọ wà níṣọ̀kan, ó sì múnú Jèhófà dùn. Ní báyìí, gbogbo wa ti ṣe tán láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ fún wa nígbà ìpọ́njú ńlá torí ó lè jẹ́ ìyẹn ló máa gba ẹ̀mí wa là! (Jóòbù 36:11) Ìdí tá a fi pinnu pé àá máa ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, a sì fẹ́ ṣe ohun tó fẹ́. (1 Jòh. 5:3) Kò sóhun tá a lè fi san gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún wa. (Sm. 116:12) Torí náà, ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tó fún láǹfààní láti wà nípò àṣẹ. Tá a bá ń ṣègbọràn, á fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni wá. A sì mọ̀ pé àwọn ọlọ́gbọ́n ló máa ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀.—Òwe 27:11. w23.10 11 ¶18-19
Thursday, January 16
Ẹ jọ́sìn Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé.—Ìfi. 14:7.
Ká ní áńgẹ́lì kan fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀, ṣé wàá gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ fún ẹ? Lónìí, áńgẹ́lì kan ń bá “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn” sọ̀rọ̀. Kí ni áńgẹ́lì náà ń sọ? Ó ní: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un . . . Ẹ jọ́sìn Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé.” (Ìfi. 14:6, 7) Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ tí gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn. A mà dúpẹ́ o pé a láǹfààní láti máa jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀ tẹ̀mí! Kí ni tẹ́ńpìlì náà, ibo sì la ti lè rí àlàyé nípa ẹ̀? Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí kì í ṣe ilé tá a ti ń jọ́sìn. Ó jẹ́ ètò tí Jèhófà ṣe ká lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ètò tí Jèhófà ṣe yìí nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó jẹ́ Hébérù tó ń gbé ní Jùdíà. w23.10 24 ¶1-2
Friday, January 17
“Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,” ni Jèhófà wí.—Sek. 4:6.
Nígbà tó dọdún 522 Ṣ.S.K., àwọn ọ̀tá àwọn Júù mú kí ìjọba Páṣíà dá iṣẹ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà tí wọ́n ń kọ́ dúró. Àmọ́ Sekaráyà fi dá àwọn Júù yẹn lójú pé Jèhófà máa fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó láìka àtakò èyíkéyìí sí. Nígbà tó dọdún 520 Ṣ.S.K., Ọba Dáríúsì pàṣẹ pé kí wọ́n máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà nìṣó. Kódà, ó fún wọn lówó, ó sì tún ní káwọn gómìnà tó wà lágbègbè wọn ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ẹ́sírà 6:1, 6-10) Jèhófà ṣèlérí fáwọn èèyàn ẹ̀ pé òun máa ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá gbájú mọ́ iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń tún kọ́. (Hág. 1:8, 13, 14; Sek. 1:3, 16) Ohun táwọn wòlíì yẹn sọ fáwọn Júù fún wọn níṣìírí gan-an, wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń tún kọ́ lọ́dún 520 Ṣ.S.K., wọ́n sì parí ẹ̀ kí ọdún márùn-ún tó pé. Torí pé àwọn Júù yẹn fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n níṣòro, Jèhófà pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Ohun tí Jèhófà ṣe yìí jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn ẹ̀.—Ẹ́sírà 6:14-16, 22. w23.11 15 ¶6-7
Saturday, January 18
Ẹ máa rìn létòlétò nínú ìgbàgbọ́ tí baba wa Ábúráhámù ní.—Róòmù 4:12.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gbọ́ nípa Ábúráhámù, ọ̀pọ̀ lára wọn ni ò mọ̀ ọ́n dáadáa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan nìwọ́ mọ̀ nípa Ábúráhámù. Bí àpẹẹrẹ, o mọ̀ pé Bíbélì pè é ní “baba gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́.” (Róòmù 4:11) Torí náà, o lè máa ronú pé, ‘Ṣé mo lè tọ ipasẹ̀ Ábúráhámù, kí n sì nírú ìgbàgbọ́ tó ní?’ Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá fẹ́ nígbàgbọ́ bíi ti Ábúráhámù, ọ̀kan lára ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé kó lọ sí ilẹ̀ kan tó jìnnà, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi gbé inú àgọ́, ó sì ṣe tán láti fi Ísákì ọmọ ẹ̀ tó fẹ́ràn gan-an rúbọ sí Ọlọ́run. Àwọn nǹkan tó ṣe yẹn fi hàn pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára. Torí pé Ábúráhámù nígbàgbọ́ tó sì ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn bẹ́ẹ̀, ó rí ojúure Ọlọ́run, ó sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jém. 2:22, 23) Jèhófà fẹ́ kí ìwọ náà rí ojúure òun, kó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀ bíi ti Ábúráhámù. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí ẹ̀ darí Pọ́ọ̀lù àti Jémíìsì pé kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù nínú Bíbélì. w23.12 2 ¶1-2
Sunday, January 19
Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀.—Jém. 1:19.
Ẹ̀yin arábìnrin, ẹ kọ́ bá a ṣe ń béèyàn sọ̀rọ̀ àti bá a ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀. Ó ṣe pàtàkì káwa Kristẹni kọ́ bá a ṣe máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dáa. Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi gbà wá nímọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Tó o bá ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀, á jẹ́ kó o fọ̀rọ̀ ẹni náà ro ara ẹ wò tàbí kó o bá a “kẹ́dùn.” (1 Pét. 3:8) Tó o bá rí i pé ohun tẹ́ni náà ń sọ ò yé ẹ tàbí tó ò mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀, bi í láwọn ìbéèrè tó yẹ. Lẹ́yìn náà, ronú dáadáa kó o tó sọ̀rọ̀. (Òwe 15:28, àlàyé ìsàlẹ̀) Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé òótọ́ ni mo fẹ́ sọ, ṣé ó sì máa gbé ẹni náà ró? Ṣé ohun tí mo fẹ́ sọ ò ní kó ìtìjú bá a, táá sì fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀?’ Máa kíyè sí àwọn arábìnrin tó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. (Òwe 31:26) Máa kíyè sí ohun tí wọ́n ń sọ àti bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́. Bó o bá ṣe mọ bá a ṣe ń béèyàn sọ̀rọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àárín ìwọ àtàwọn èèyàn á ṣe gún régé tó. w23.12 21 ¶12
Monday, January 20
Ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ . . . gbogbo ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ni yóò máa kọ̀.—Òwe 18:1.
Lónìí, Jèhófà lè lo ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa tàbí àwọn alàgbà láti ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká yẹra fáwọn èèyàn. Ó lè wù wá pé ká dá wà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò burú, àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe kí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́? Rí i dájú pé o ò yẹra fáwọn èèyàn. Tá a bá yẹra fáwọn èèyàn, ó lè jẹ́ ká máa ronú nípa ara wa nìkan àti ìṣòro tá a ní. Ìyẹn sì lè jẹ́ kó nira fún wa láti ṣe ìpinnu tó tọ́. Ká sòótọ́, àwọn ìgbà míì lè wà tó máa gba pé ká dá wà, pàápàá tó bá jẹ́ pé àjálù ńlá ló ṣẹlẹ̀ sí wa. Àmọ́ tó bá ti ń pẹ́ jù tá a ti dá wà, a lè má rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí Jèhófà fẹ́ lò láti ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ káwọn ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́. Gbà pé àwọn ni Jèhófà ń lò láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Òwe 17:17; Àìsá. 32:1, 2. w24.01 24 ¶12-13
Tuesday, January 21
Kò gbọ́dọ̀ fi abẹ kan orí rẹ̀.—Nọ́ń. 6:5.
Àwọn Násírì máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn ò ní gé irun àwọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa ń fi hàn pé wọ́n fẹ́ mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ délẹ̀délẹ̀. Ó ṣeni láàánú pé àwọn ìgbà kan wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ò mọyì àwọn Násírì, wọn ò sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà míì, ó máa ń gba pé kí Násírì kan nígboyà kó tó lè dúró lórí ìpinnu tó ṣe, kó sì lè yàtọ̀ sáwọn tí kì í ṣe Násírì. (Émọ́sì 2:12) Torí a ti pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà la fẹ́ ṣe, àwa náà máa ń dá yàtọ̀ sáwọn tó wà láyìíká wa. Ó gba ìgboyà ká tó lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá nílé ìwé tàbí níbi iṣẹ́. Bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé, táwọn èèyàn sì ń hùwà ìbàjẹ́, ó máa túbọ̀ ṣòro fún wa láti fi ìlànà Bíbélì sílò, ká sì máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. (2 Tím. 1:8; 3:13) Torí náà ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ máa rántí pé a máa “mú ọkàn [Jèhófà] yọ̀” tá a bá ń fìgboyà ṣe ohun tó jẹ́ ká dá yàtọ̀ sáwọn tí ò sin Jèhófà.—Òwe 27:11; Mál. 3:18. w24.02 16 ¶7; 17 ¶9
Wednesday, January 22
Ẹ tẹ́wọ́ gba ara yín.—Róòmù 15:7.
Ẹ jẹ́ ká wo irú àwọn èèyàn tó wà nínú ìjọ Róòmù. Báwọn Júù tó mọ Òfin Mósè láti kékeré ṣe wà níbẹ̀ náà ni àwọn Kèfèrí tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tàwọn Júù wà níbẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni kan jẹ́ ẹrú, àwọn Kristẹni míì kì í sì í ṣe ẹrú. Kódà, àwọn Kristẹni kan láwọn ẹrú tó ń ṣiṣẹ́ fún wọn. Torí náà, báwo làwọn Kristẹni yẹn á ṣe máa fìfẹ́ hàn síra wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lówó ju ara wọn lọ, tí àṣà wọn sì yàtọ̀ síra? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ tẹ́wọ́ gba ara yín.” Kí ló ní lọ́kàn? Ọ̀rọ̀ tá a tú sí ‘tẹ́wọ́ gbà’ túmọ̀ sí pé ká gba ẹnì kan sílé wa, ká fún un lóúnjẹ tàbí ká máa bá a ṣọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ fún Fílémónì pé kó “fi ìfẹ́ gba” Ónísímù ìránṣẹ́ ẹ̀ tó sá kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀. (Fílém. 17) Pírísílà àti Ákúílà náà gba Àpólò tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì “mú un wọ àwùjọ wọn” bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan tó mọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristẹni ò tó nǹkan. (Ìṣe 18:26) Àwọn Kristẹni yẹn ò jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ wọn àtàwọn nǹkan míì fa ìpínyà láàárín wọn, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n fìfẹ́ gba ara wọn tọwọ́tẹsẹ̀. w23.07 6 ¶13
Thursday, January 23
Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà.—Sm. 116:14.
Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó o fi ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà ni pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Kì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n lásán lo ní fún Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ torí pé o ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ tó péye” àti “òye tẹ̀mí” nípa àwọn nǹkan tó o kọ́ nípa Jèhófà, ìyẹn ló sì jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Kól. 1:9) Àwọn nǹkan tó o kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ kó o mọ̀ pé (1) Jèhófà wà lóòótọ́, (2) òun ló darí àwọn tó kọ Bíbélì àti pé (3) ètò ẹ̀ ló ń lò láti jẹ́ kí ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Ó yẹ káwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà mọ àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ inú Bíbélì, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ kí wọ́n máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn ní gbogbo àsìkò tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. (Mát. 28:19, 20) Wọ́n ti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ti pinnu pé òun nìkan làwọn á máa sìn. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? w24.03 4-5 ¶6-8
Friday, January 24
Wọ́n á sì di ara kan.—Jẹ́n. 2:24.
Bíbélì sọ pé èèyàn tó le, tó sì burú gan-an ni Nábálì ọkọ Ábígẹ́lì. (1 Sám. 25:3) Torí náà, ó dájú pé ó máa nira fún Ábígẹ́lì láti máa gbé pẹ̀lú irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ṣé àǹfààní wà fún Ábígẹ́lì láti fi ọkọ ẹ̀ sílẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Àǹfààní yẹn yọ nígbà tí Dáfídì tó máa tó di ọba Ísírẹ́lì fẹ́ pa Nábálì ọkọ ẹ̀ torí pé ó kan òun àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lábùkù. (1 Sám. 25:9-13) Ábígẹ́lì lè sá lọ, kí Dáfídì lè pa Nábálì. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà. Ó bẹ Dáfídì pé kó dá ẹ̀mí Nábálì sí. (1 Sám. 25:23-27) Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ábígẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ojú tí Jèhófà fi wo ìgbéyàwó lòun náà sì fi wò ó. Ó mọ̀ pé ìgbéyàwó jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. Torí náà, Ábígẹ́lì fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, ìdí nìyẹn tó fi ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ará ilé ẹ̀ títí kan ọkọ ẹ̀. Ó gbé ìgbésẹ̀ ní kíá, kí Dáfídì má bàa pa Nábálì ọkọ ẹ̀. w24.03 16 ¶9-10
Saturday, January 25
Màá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fún yín lókun.—Jóòbù 16:5.
Ṣé àwọn kan wà nínú ìjọ ẹ tí wọ́n ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ṣé o mọ àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ń fìgboyà ṣe ohun tó mú kí wọ́n yàtọ̀ sáwọn ọmọ ilé ìwé wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn rárá? Ṣé o mọ àwọn míì tí ò rọrùn fún láti máa sin Jèhófà torí pé ìdílé wọn ń ta kò wọ́n? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká lo gbogbo àǹfààní tá a ní láti fi irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì ìgboyà tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan. (Fílém. 4, 5, 7) Jèhófà mọ̀ pé tọkàntọkàn la fi ń ṣe ohun tóun fẹ́ àti pé a ṣe tán láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan ká lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ. Ó tún buyì kún wa torí ó fún wa láǹfààní láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òun. (Òwe 23: 15, 16) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa sin Jèhófà nìṣó, àá sì máa fi tọkàntọkàn yááfì gbogbo ohun tó bá gbà ká lè máa jọ́sìn ẹ̀. w24.02 18 ¶14; 19 ¶16
Sunday, January 26
Ó lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ó ń ṣe rere, ó sì ń wo àwọn èèyàn sàn.—Ìṣe 10:38.
Fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ bí ọdún 29 S.K. ṣe ń parí lọ. Wọ́n pe Jésù àti Màríà ìyá rẹ̀ wá síbi ìgbéyàwó kan ní abúlé kan tó ń jẹ́ Kánà. Màríà ń ran ìdílé tó ń ṣègbéyàwó náà lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn àlejò wọn. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń jẹun lọ́wọ́ níbi ìgbéyàwó náà, wáìnì tí wọ́n ń mu tán. Ni Màríà bá tètè lọ bá Jésù, ó sì sọ pé: “Wọn ò ní wáìnì kankan.” (Jòh. 2:1-3) Kí ni Jésù ṣe? Ó ṣiṣẹ́ ìyanu kan tó jọni lójú gan-an, ó sọ omi di “wáìnì tó dáa.” (Jòh. 2:9, 10) Nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu míì. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu láti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, méjì lára iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ni pé ó bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, lẹ́yìn ìgbà yẹn ó bọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin. Ó sì ṣeé ṣe kí gbogbo àwọn tí Jésù bọ́ ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27,000) lọ tá a bá ka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ mọ́ wọn. (Mát. 14:15-21; 15:32-38) Láwọn ìgbà tó ṣiṣẹ́ ìyanu yẹn, ó tún wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn.—Mát. 14:14; 15:30, 31. w23.04 2 ¶1-2
Monday, January 27
Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, “Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.”—Àìsá. 41:13.
Lẹ́yìn tí ìṣòro tó le bá dé bá wa, àwọn ìgbà kan wà tí nǹkan lè tojú sú wa, tá ò sì ní lè ronú lọ́nà tó tọ́. Bíi ti Èlíjà, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká ṣáà máa sùn, ká má sì dìde lójú oorun. (1 Ọba 19:5-7) A nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ká lè máa tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Nírú àkókò yẹn, Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa ràn wá lọ́wọ́ bí ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní ṣe sọ. Ọba Dáfídì rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà. Nígbà tó níṣòro táwọn ọ̀tá sì gbógun tì í, ó sọ fún Jèhófà pé: “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń tì mí lẹ́yìn.” (Sm. 18:35) Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà máa ń lo àwọn èèyàn láti ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Dáfídì rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ Jónátánì ọ̀rẹ́ ẹ̀ wá a lọ kó lè tù ú nínú, kó sì fún un níṣìírí. (1 Sám. 23:16, 17) Bákan náà, Jèhófà lo Èlíṣà láti ran Èlíjà lọ́wọ́.—1 Ọba 19:16, 21; 2 Ọba 2:2. w24.01 23-24 ¶10-12
Tuesday, January 28
Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n; ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.—Òwe 2:6.
Jèhófà lawọ́ gan-an torí ó máa ń fún wa lọ́pọ̀ nǹkan. Obìnrin tá a fi “ọgbọ́n tòótọ́” wé nínú ìwé Òwe orí kẹsàn-án jẹ́ ká rí i pé ohun tí Jèhófà máa ń ṣe gan-an nìyẹn. Ẹsẹ kejì sọ pé obìnrin yẹn ti ṣètò gbogbo ẹran rẹ̀, ó ti po wáìnì rẹ̀, ó sì ti tẹ́ tábìlì nínú ilé rẹ̀. (Òwe 9:2) Yàtọ̀ síyẹn, ẹsẹ 4 àti 5 sọ pé: “Ó [ìyẹn ọgbọ́n] sọ fún àwọn tí kò ní làákàyè pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ oúnjẹ mi.’” Kí nìdí tó fi yẹ ká wá sílé ọgbọ́n tòótọ́, ká sì jẹ oúnjẹ ẹ̀? Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀ gbọ́n, ká má bàa kàgbákò. Jèhófà ò fẹ́ kí aburú kankan ṣẹlẹ̀ sí wa ká tó gbọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi “ń to ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣinṣin.” (Òwe 2:7) Tá a bá ń bẹ̀rù Jèhófà tọkàntọkàn, àá máa ṣe ìfẹ́ ẹ̀. Torí náà, a máa ń fetí sí ìmọ̀ràn Jèhófà, inú wa sì máa ń dùn bá a ṣe ń fi sílò.—Jém. 1:25. w23.06 23-24 ¶14-15
Wednesday, January 29
Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín.—Héb. 6:10.
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò lè ṣe tó bá a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tá à ń ṣe tọkàntọkàn, ó sì mọyì ẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Nígbà ayé Sekaráyà, Jèhófà sọ fún un pé kó fi wúrà àti fàdákà táwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì fi ránṣẹ́ ṣe adé kan. (Sek. 6:11) “Adé ńlá” náà á jẹ́ kí wọ́n máa rántí ọrẹ àtinúwá táwọn tó wà ní Bábílónì fi ránṣẹ́. (Sek. 6:14, àlàyé ìsàlẹ̀) Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé gbogbo nǹkan táwa náà ń ṣe tọkàntọkàn bá a ṣe ń jọ́sìn ẹ̀ nígbà ìṣòro. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé yìí, àá ṣì máa níṣòro, kódà ó ṣeé ṣe kó burú ju báyìí lọ lọ́jọ́ iwájú. (2 Tím. 3:1, 13) Àmọ́, kò yẹ ká kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ. Máa rántí ohun tí Jèhófà sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ nígbà ayé Hágáì, ó sọ pé: “Mo wà pẹ̀lú yín . . . Ẹ má bẹ̀rù.” (Hág. 2:4, 5) Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú àwa náà bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣohun tó fẹ́. w23.11 19 ¶20-21
Thursday, January 30
Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.—Lúùkù 5:8.
Jèhófà lè mú kí wọ́n má kọ àwọn àṣìṣe tí àpọ́sítélì Pétérù ṣe sínú Bíbélì, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Dípò ìyẹn, ó jẹ́ káwọn àṣìṣe yẹn wà lákọsílẹ̀ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn. (2 Tím. 3:16, 17) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára ọkùnrin tó jẹ́ aláìpé tó sì mọ nǹkan lára bíi tiwa yìí, àá rí i pé Jèhófà ò retí pé ká jẹ́ ẹni pípé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, tá a sì láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá yí, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, ká má sì jẹ́ kó sú wa. Kí nìdí tí ò fi yẹ kó sú wa? Tá a bá rò pé a ti borí kùdìẹ̀-kudiẹ wa, a lè pa dà ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa kó ara wa níjàánu, ká má bàa pa dà ṣàṣìṣe. Gbogbo wa la máa ń sọ tàbí ṣe ohun tá a máa ń kábàámọ̀ ẹ̀ tó bá yá, àmọ́ tá ò bá jẹ́ kó sú wa, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe, ká sì máa ṣe dáadáa. (1 Pét. 5:10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ṣe àwọn àṣìṣe kan, àánú tí Jésù fi hàn sí i jẹ́ ká rí i pé àwa náà lè máa sin Jèhófà nìṣó bá a tiẹ̀ ṣàṣìṣe. w23.09 20-21 ¶2-3
Friday, January 31
Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.—Jòh. 11:21.
Nígbà tí Lásárù ń ṣàìsàn, Jésù lè wò ó sàn bí Màtá ṣe sọ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Àmọ́ ohun àrà kan wà lọ́kàn Jésù tó fẹ́ ṣe. Jésù wá ṣèlérí fún Màtá pé: “Arákùnrin rẹ máa dìde.” Ó tún sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.” (Jòh. 11:23, 25) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ti fún Jésù lágbára láti jí àwọn òkú dìde. Ṣáájú ìgbà yẹn, ọmọdébìnrin kan kú, kò sì pẹ́ lẹ́yìn tó kú tí Jésù jí i dìde. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù jí ọ̀dọ́kùnrin kan dìde lọ́jọ́ tó kú. (Lúùkù 7:11-15; 8:49-55) Àmọ́, ṣé ó lè jí ẹni tó ti pé ọjọ́ mẹ́rin tó ti kú dìde, tí òkú ẹ̀ á sì ti máa jẹrà? Màríà jáde lọ pàdé Jésù. Ohun tí Màtá sọ lòun náà sọ, ó ní: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” (Jòh. 11:32) Ẹ̀dùn ọkàn bá Màríà àtàwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ ẹ̀. Nígbà tí Jésù rí wọn tí wọ́n ń sunkún, inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Àánú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ṣe é, òun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Jésù mọ̀ pé ó máa ń dun èèyàn gan-an tí èèyàn ẹni bá kú. Ó dájú pé ó wu Jésù gan-an kó ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n sunkún mọ́! w23.04 10-11 ¶12-13