February
Saturday, February 1
Màá fetí sí yín.—Jer. 29:12.
Nígbà tí Ọba Hẹsikáyà ń ṣàìsàn tó le gan-an, ó bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kára òun yá. Jèhófà sì wò ó sàn. (2 Ọba 20:1-6) Àmọ́ nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bẹ Jèhófà pé kó yọ “ẹ̀gún kan” tó wà nínú ara òun kúrò, Jèhófà ò mú un kúrò. (2 Kọ́r. 12:7-9) Nígbà tí Ọba Hẹ́rọ́dù fẹ́ pa àpọ́sítélì Jémíìsì àti àpọ́sítélì Pétérù, wọ́n pa Jémíìsì, àmọ́ Jèhófà dá Pétérù sílẹ̀ lọ́nà ìyanu. (Ìṣe 12:1-11) A lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi gba Pétérù sílẹ̀ àmọ́ tí ò gba Jémíìsì sílẹ̀?’ Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà “kì í ṣe ojúsàájú.” (Diu. 32:4) Nígbà míì, ó lè jẹ́ ohun tá ò lérò ni Jèhófà máa fi dáhùn àdúrà wa. Àmọ́, a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa dáhùn àdúrà wa lọ́nà tó tọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé a kì í ráhùn nípa ọ̀nà tó gbà dáhùn àdúrà wa.—Jóòbù 33:13. w23.11 21 ¶6
Sunday, February 2
Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . ṣe tán láti ṣègbọràn.—Jém. 3:17.
Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Jémíìsì láti sọ pé àwọn tó gbọ́n máa ń “ṣe tán láti ṣègbọràn.” Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ? Ohun tó ń sọ ni pé ó yẹ kó yá wa lára, kó sì máa wù wá láti ṣègbọràn sáwọn tí Jèhófà fún láǹfààní láti wà nípò àṣẹ. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ò retí pé ká ṣègbọràn sẹ́nikẹ́ni tó bá sọ pé ká ṣe ohun tó ta ko ìlànà ẹ̀. (Ìṣe 4:18-20) Ó túbọ̀ máa ń rọrùn fún wa láti ṣègbọràn sí Jèhófà ju èèyàn lọ. Ìdí sì ni pé ìtọ́sọ́nà Jèhófà pé. (Sm. 19:7) Àmọ́, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá torí aláìpé ni wọ́n. Síbẹ̀, Bàbá wa ọ̀run fún àwọn òbí, àwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn alàgbà nínú ìjọ láṣẹ dé àyè kan. (Òwe 6:20; 1 Tẹs. 5:12; 1 Pét. 2:13, 14) Tá a bá ń ṣègbọràn sí wọn, Jèhófà là ń ṣègbọràn sí yẹn. w23.10 6 ¶2-3
Monday, February 3
Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni.—Ìfi. 21:5.
Ọ̀nà kan tá a lè gbà mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa ronú lórí bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó. Ó lágbára láti mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ó máa ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ torí òun ni Ọlọ́run Olódùmarè. (Jóòbù 42:2; Máàkù 10:27; Éfé. 3:20) Ọlọ́run fi dá Ábúráhámù àti Sérà lójú pé wọ́n máa bí ọmọkùnrin kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti darúgbó. (Jẹ́n. 17:15-17) Ó tún sọ fún Ábúráhámù pé òun máa fún àwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù fi ṣẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, lásìkò yẹn, ó lè dà bíi pé ìlérí tí Jèhófà ṣe ò ní ṣẹ láé. Àmọ́ ìlérí náà ṣẹ. Ó sọ fún Màríà wúńdíá pé ó máa bí Ọmọ òun, ìyẹn ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nínú ọgbà Édẹ́nì pé wọ́n máa bí. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ṣẹ! (Jẹ́n. 3:15) Tá a bá ń ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe tó mú ṣẹ, á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, á sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ayé tuntun máa dé.—Jóṣ. 23:14; Àìsá. 55:10, 11. w23.04 28 ¶10-12.
Tuesday, February 4
Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi; gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.—Sm. 143:1.
Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà Dáfídì, ó sì gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ẹ̀. (1 Sám. 19:10, 18-20; 2 Sám. 5:17-25) Ọkàn tiwa náà balẹ̀ pé Jèhófà máa dáhùn àwọn àdúrà wa. (Sm. 145:18) Jèhófà lè má dáhùn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́. Pọ́ọ̀lù bẹ Ọlọ́run pé kó mú “ẹ̀gún kan” kúrò nínú ara òun. Kódà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù dìídì gbàdúrà nípa ìṣòro ńlá yìí. Ṣé Jèhófà wá dáhùn àwọn àdúrà yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ kì í ṣe bí Pọ́ọ̀lù ṣe fẹ́. Dípò kí Jèhófà mú ìṣòro náà kúrò, ṣe ni Jèhófà fún un lókun kó lè máa jọ́sìn òun nìṣó. (2 Kọ́r. 12:7-10) Nígbà míì, Jèhófà lè má dáhùn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́. Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà mọ ọ̀nà tó dáa jù láti gbà ràn wá lọ́wọ́. Kódà, ó máa ń “ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn.” (Éfé. 3:20) Torí náà, ó lè má jẹ́ àsìkò tá a retí ni Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa, ó sì lè má jẹ́ bá a ṣe fẹ́. w23.05 8-9 ¶4-6
Wednesday, February 5
Wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀, tí wọ́n á sì jáde wá.—Jòh. 5:28, 29.
Látìgbàdégbà, ó yẹ kí gbogbo wa máa ronú nípa àjíǹde àwọn òkú tí Bíbélì sọ pé ó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ò mọ ìgbà tí àìsàn tó le gan-an lè ṣe wá tàbí ìgbà tí èèyàn wa kan lè kú lójijì. (Oníw. 9:11; Jém. 4:13, 14) Ìrètí tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde máa jẹ́ ká fara da irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀. (1 Tẹs. 4:13) Ìwé Mímọ́ fi dá wa lójú pé Bàbá wa ọ̀run mọ̀ wá dáadáa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Lúùkù 12:7) Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa débi pé tó bá máa jí àwọn tó kú dìde, irú ẹni tí wọ́n jẹ́ ò ní yí pa dà, wọ́n á sì rántí gbogbo ohun tí wọ́n mọ̀ kí wọ́n tó kú. Ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an torí ó fún wa láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Kódà tá a bá kú, ó máa jí wa dìde! Kí ló mú ká gbà pé àjíǹde tí Ọlọ́run ṣèlérí máa wáyé? Torí ó dá wa lójú pé ẹni tó ṣèlérí náà ní agbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ó sì wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. w23.04 8-9 ¶2-4
Thursday, February 6
Ó jẹ́ àṣà [Jósẹ́fù àti Màríà] láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún kí wọ́n lè lọ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.—Lúùkù 2:41.
Jósẹ́fù àti Màríà ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà lè túbọ̀ lágbára. Wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn máa jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ nínú ìdílé. (Lúùkù 2:22-24; 4:16) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa ni wọ́n jẹ́ fún ẹ̀yin tọkọtaya òde òní! Tẹ́ ẹ bá láwọn ọmọ bíi ti Jósẹ́fù àti Màríà, ó lè má rọrùn fún yín láti máa lọ sípàdé tàbí láti máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé. Kódà, ó lè nira gan-an fún ẹ̀yin tọkọtaya láti máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀, kẹ́ ẹ sì jọ máa gbàdúrà. Síbẹ̀, ẹ rántí pé tí ẹ bá ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀, ẹ máa túbọ̀ sún mọ́ ọn, ẹ̀ẹ́ sì túbọ̀ sún mọ́ra yín. Torí náà, ẹ rí i dájú pé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú nínú ìdílé yín. Tí ìfẹ́ tó wà láàárín ẹ̀yin tọkọtaya bá ti ń di tútù, ó lè má rọrùn láti jọ jókòó pé ẹ fẹ́ ṣe ìjọsìn ìdílé. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí ohun tẹ́ ẹ máa jíròrò pọ̀ jù kẹ́ ẹ lè gbádùn ẹ̀. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín, á sì máa wù yín láti jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀. w23.05 22 ¶7-8
Friday, February 7
Ọbadáyà bẹ̀rù Jèhófà gidigidi.—1 Ọba 18:3.
Báwo ni ìbẹ̀rù tó tọ́ ṣe ran Ọbadáyà lọ́wọ́? Ó ràn án lọ́wọ́ torí ó mú kó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó sì ṣeé fọkàn tán. Ìyẹn ló mú kí ọba fi ṣe alábòójútó agbo ilé rẹ̀. (Fi wé Nehemáyà 7:2.) Torí pé Ọbadáyà bẹ̀rù Jèhófà, ìyẹn tún jẹ́ kó nígboyà gan-an, ó sì dájú pé ó nílò ànímọ́ yìí. Ó gbé ayé nígbà ìṣàkóso Ọba Áhábù tó burú gan-an. (1 Ọba 16:30) Bákan náà, Jésíbẹ́lì ìyàwó Áhábù tó ń sin Báálì kórìíra Jèhófà gan-an débi pé kò fẹ́ kí ọmọ Ísírẹ́lì èyíkéyìí tó wà ní ìjọba àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì máa sin Jèhófà. Kódà, ó pa ọ̀pọ̀ lára àwọn wòlíì Ọlọ́run. (1 Ọba 18:4) Nígbà tí Jésíbẹ́lì ń wá àwọn wòlíì Ọlọ́run káàkiri kó lè pa wọ́n, Ọbadáyà kó ọgọ́rùn-ún (100) lára wọn, ó fi wọ́n pa mọ́ ‘ní àádọ́ta-àádọ́ta sínú ihò, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ àti omi.’ (1 Ọba 18:13, 14) Ohun tí Ọbadáyà ṣe yìí gba ìgboyà, àmọ́ ká sọ pé Jésíbẹ́lì gbọ́ nípa ẹ̀ ni, ṣe ló máa pa á. Ká sòótọ́, ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba Ọbadáyà torí pé kò fẹ́ kú. Àmọ́ Ọbadáyà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn tó ń sìn ín ju ẹ̀mí ara ẹ̀ lọ. w23.06 16 ¶9-10
Saturday, February 8
Èmi, Jèhófà, ni . . . Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.—Àìsá. 48:17.
Jèhófà ló ṣì ń tọ́ àwa èèyàn ẹ̀ sọ́nà lónìí, bó ṣe ṣe nígbà àtijọ́. Ó máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń lo Jésù Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ orí ìjọ láti darí wa. Ṣé ẹ̀rí wà pé Jèhófà ṣì ń lo àwọn èèyàn láti darí wa? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọdún tó tẹ̀ lé ọdún 1870. Arákùnrin Charles Taze Russell àtàwọn tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fòye mọ̀ pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run. (Dán. 4:25, 26) Ohun tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ṣèwádìí nínú Bíbélì, wọ́n sì gbà pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ẹ̀ máa ṣẹ. Ṣé Jèhófà ń tọ́ wọn sọ́nà bí wọ́n ṣe ń ṣèwádìí nínú Bíbélì? Ó dájú pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láyé lọ́dún 1914 jẹ́ kó hàn gbangba pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run. Ọdún yẹn ni wọ́n ja Ogun Àgbáyé Kìíní, lẹ́yìn náà àjàkálẹ̀ àrùn, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àìtó oúnjẹ wáyé. (Lúùkù 21:10, 11) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lo àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí láti tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. w24.02 22 ¶11
Sunday, February 9
Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.—Sm. 34:19.
Ó dá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká gbádùn ayé wa dáadáa. (Róòmù 8:35-39) Ó tún dá wa lójú pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣe wá láǹfààní tá a bá ń tẹ̀ lé wọn. (Àìsá. 48:17, 18) Àmọ́ tí ìṣòro bá dé bá wa ńkọ́, kí la máa ṣe? Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan nínú ìdílé wa lè ṣe ohun tó dùn wá. A lè ní àìsàn kan tó lè má jẹ́ ká ṣe tó bá a ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àjálù lè ṣẹlẹ̀ sí wa, irú bí omíyalé àti ìmìtìtì ilẹ̀, wọ́n sì lè ṣenúnibíni sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́. Táwọn ìṣòro yìí bá dé bá wa, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wa pé: ‘Kí ló dé tírú èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi? Àbí mo ti ṣe ohun tí ò dáa ni? Àbí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí fi hàn pé inú Jèhófà ò dùn sí mi mọ́ ni?’ Ṣé o ti nírú èrò yìí rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má rẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti nírú èrò tó o ní yìí rí.—Sm. 22:1, 2; Háb. 1:2, 3. w23.04 14 ¶1-2
Monday, February 10
Mo ti pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ nígbà gbogbo.—Sm. 119:112.
Tí ọkàn wa bá ń fà sí nǹkan burúkú, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló yẹ ká gbé èrò náà kúrò lọ́kàn, ká má bàa ṣe ohun tó máa ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. Jèhófà retí pé ká “ṣègbọràn látọkàn wá.” (Róòmù 6:17) Ó máa ń tọ́ wa sọ́nà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ pa àwọn òfin ẹ̀ kan mọ́ ká wá pa àwọn kan tì, gbogbo ẹ̀ la gbọ́dọ̀ pa mọ́. (Àìsá. 48:17, 18; 1 Kọ́r. 6:9, 10) Èṣù máa ń lo àwọn èèyàn láti fìyà jẹ wá, kí wọ́n sì fúngun mọ́ wa ká lè ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Ohun tó ń wá ni bó ṣe máa ‘pa wá jẹ,’ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà lè bà jẹ́. (1 Pét. 5:8) Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pa àwọn kan lára wọn torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Ìṣe 5:27, 28, 40; 7:54-60) Sátánì ṣì ń lo inúnibíni lónìí. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alátakò tún máa ń ṣenúnibíni sáwọn ará wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Sátánì tún máa ń lo “àrékérekè” láti mú ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́.—Éfé. 6:11. w23.07 15-16 ¶6-9
Tuesday, February 11
Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo.—Éfé. 4:15.
Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á máa pọ̀ sí i. Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ló ń jẹ́ kó o máa ṣe ohun tó fẹ́. Àwọn ìlànà Bíbélì tó o kọ́ ló ń jẹ́ kó o ṣèpinnu tó tọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìwà ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í dáa sí i torí pé o fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bí ọmọ kan ṣe máa ń fara wé òbí ẹ̀, bẹ́ẹ̀ nìwọ náà ń fara wé Baba rẹ ọ̀run. (Éfé. 5:1, 2) Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà ń lágbára sí i ju ti ìgbà tí mo ṣèrìbọmi? Látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi, ṣé ìwà àti èrò mi jọ ti Jèhófà, pàápàá tó bá dọ̀rọ̀ kí n fìfẹ́ hàn sáwọn ará?’ Tó o bá rí i pé “ìfẹ́ tí o ní níbẹ̀rẹ̀” fún Jèhófà àtàwọn ará ti ń di tútù, má jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà. Jésù ò pa wọ́n tì, ó sì dájú pé kò ní pa àwa náà tì. (Ìfi. 2:4, 7) Ó mọ̀ pé ìfẹ́ wa ṣì lè pa dà lágbára bíi tìgbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. w23.07 8 ¶2-3
Wednesday, February 12
Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.—Sm. 86:5.
Àpọ́sítélì Pétérù ṣe àwọn àṣìṣe kan. Ohun àkọ́kọ́ ni pé ó dá ara ẹ̀ lójú jù, ó sì fọ́nnu pé òun máa jẹ́ olóòótọ́ kódà tí gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù bá pa Jésù tì. (Máàkù 14:27-29) Lẹ́yìn ìyẹn, léraléra ni Pétérù sùn lọ, kò sì ṣọ́nà bí Jésù ṣe ní kí wọ́n ṣe. (Máàkù 14:32, 37-41) Kò tán síbẹ̀ o, Pétérù sá fi Jésù sílẹ̀ nígbà táwọn jàǹdùkú dé. (Máàkù 14:50) Paríparí ẹ̀, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rí, kódà ó búra pé òótọ́ lòun sọ. (Máàkù 14:66-71) Kí ni Pétérù wá ṣe nígbà tó rí i pé òun ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá? Ó bara jẹ́, ó sì sunkún kíkankíkan. (Máàkù 14:72) Dípò tí Jésù fi máa bá Pétérù wí torí àṣìṣe tó ṣe, ńṣe ló tún bá a sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, ó sì gbé iṣẹ́ pàtàkì míì fún un. (Jòh. 21:15-17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù mọ̀ pé òun ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, kò ronú pé ó ti tán fún òun. Torí ó dá a lójú pé Jésù Ọ̀gá òun ṣì nífẹ̀ẹ́ òun àti pé ó ti dárí ji òun. Kí la rí kọ́? Jèhófà fi dá wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, òun sì ṣe tán láti dárí jì wá tá a bá dẹ́ṣẹ̀.—Róòmù 8:38, 39. w24.03 18 ¶13-15
Thursday, February 13
Àwọn tó ti pa pọ̀ gan-an.—Òwe 7:26.
Tó o bá ṣèṣekúṣe, ó lè kó ìtìjú bá ẹ. O ò ní níyì lójú ara ẹ mọ́. Ó lè jẹ́ kó o gboyún àpàpàǹdodo, ó sì lè tú ìdílé ká. Ká sòótọ́, ìwà ọgbọ́n ni tá ò bá lọ sí “ilé” òmùgọ̀ obìnrin. Yàtọ̀ sí pé àwọn tó ń ṣèṣekúṣe máa ń pàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n tún máa ń kó àrùn tó lè mú kí wọ́n kú láìtọ́jọ́. (Òwe 7:23) Ọ̀rọ̀ tó parí Òwe orí 9 ẹsẹ 18 sọ pé: “Àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ Isà Òkú.” Àmọ́, kí wá nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń lọ sílé obìnrin náà, tí wọ́n sì ń kàgbákò? (Òwe 9:13-18) Lónìí, fíìmù àti àwòrán ìṣekúṣe gbòde kan, ó sì yẹ ká sá fún un. Èrò àwọn kan ni pé téèyàn bá ń wò wọ́n, kò lè ṣe ìpalára kankan. Àmọ́ irọ́ gbáà nìyẹn torí ó máa ń pani lára, kì í jẹ́ kéèyàn níyì, ó sì máa ń ṣòro láti jáwọ́ níbẹ̀. Téèyàn bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe, ó máa ń pẹ́ gan-an kí onítọ̀hún tó gbàgbé ẹ̀. Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé ó máa ń jẹ́ kó wu èèyàn láti ṣèṣekúṣe. (Kól. 3:5; Jém. 1:14, 15) Òótọ́ kan ni pé àwọn tó bá ń wo ìwòkuwò máa ń ṣèṣekúṣe tó bá yá. w23.06 23 ¶10-11
Friday, February 14
Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.—Dán. 2:44.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì, àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń dojú ìjà kọ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà, wọn ò ní lè gba ipò ẹ̀. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé “òkúta” tó ṣàpẹẹrẹ Ìjọba Ọlọ́run máa fọ́ ẹsẹ̀ ère yẹn, ìyẹn ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. (Dán. 2:34, 35, 44, 45) Ṣé ó dá ẹ lójú pé òótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Dáníẹ́lì sọ nípa ẹsẹ̀ irin àti amọ̀? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kò ní jẹ́ kó o máa lépa owó torí ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ pa run. (Lúùkù 12:16-21; 1 Jòh. 2:15-17) Tó o bá gbà pé òótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí, á jẹ́ kó o tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Mát. 6:33; 28:18-20) Ní báyìí tá a ti sọ̀rọ̀ ṣókí nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, o ò ṣe bi ara ẹ ní ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé ó dá mi lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó pa gbogbo ìjọba èèyàn run?’ w23.08 11 ¶13-14
Saturday, February 15
Kálukú wa ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.—Róòmù 14:12.
Ó yẹ kó o mọ̀wọ̀n ara ẹ, kó o sì gbà pé ọjọ́ orí ẹ, àìsàn àtàwọn nǹkan míì lè má jẹ́ kó o ṣe tó bó o ṣe fẹ́. Ìwọ náà lè ṣe bíi ti Básíláì. Tó o bá rí i pé àìsàn tàbí ọjọ́ orí ẹ ò ní lè jẹ́ kó o ṣe iṣẹ́ kan, o lè ní kí wọ́n gbé e fún ẹlòmíì. (2 Sám. 19:35, 36) Bíi ti Mósè, jẹ́ káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì gbéṣẹ́ fún wọn. (Ẹ́kís. 18:21, 22) Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, kò ní jẹ́ kó o máa lé àwọn nǹkan tó ju agbára ẹ lọ. Kò tún yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi nítorí ìpinnu tí ò dáa táwọn ẹlòmíì ṣe. A ò lè ṣèpinnu fáwọn ẹlòmíì, a ò sì lè dáàbò bò wọ́n kí wọ́n má jìyà ìpinnu tí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kan lè sọ pé òun ò sin Jèhófà mọ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè kó ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ bá àwọn òbí ọmọ náà. Àmọ́, tírú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ bá ń dá ara wọn lẹ́bi nítorí ìpinnu tí ò dáa tọ́mọ wọn ṣe, ńṣe lẹ̀dùn ọkàn wọn á máa pọ̀ sí i. Ìyẹn ò sí lára ẹrù tí Jèhófà retí pé kí wọ́n gbé. w23.08 29 ¶11-12
Sunday, February 16
[Sámúsìn] nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dẹ̀lílà.—Oníd. 16:4.
Aláìpé bíi tiwa ni Sámúsìn, torí náà láwọn ìgbà kan, ó ṣe àwọn ìpinnu tí ò dáa. Kódà, ó ṣe ìpinnu kan tí ìgbẹ̀yìn ẹ̀ ò dáa rárá. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tí Sámúsìn di onídàájọ́, “ó nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dẹ̀lílà ní Àfonífojì Sórékì.” Ṣáájú ìgbà yẹn, Sámúsìn ti fẹ́ obìnrin ará Filísínì kan, àmọ́ “Jèhófà ló fẹ́ kó” fẹ́ ẹ kó lè lo àǹfààní yẹn láti “gbógun ja àwọn Filísínì.” Nígbà tó yá, Sámúsìn lọ sílùú Gásà ní Filísínì, ó sì dé sílé obìnrin aṣẹ́wó kan. Ìgbà yẹn ni Jèhófà fún un lágbára láti yọ àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè ìlú náà kúrò, ìyẹn á sì mú kó rọrùn fáwọn ọ̀tá láti wọlé. (Oníd. 14:1-4; 16:1-3) Àmọ́, ọ̀rọ̀ Dẹ̀lílà yàtọ̀ ní tiẹ̀ torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, bí Sámúsìn ṣe fẹ́ Dẹ̀lílà ò ní lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti gbéjà ko àwọn Filísínì. Ńṣe ni Dẹ̀lílà gba owó gọbọi táwọn Filísínì fún un kó lè dalẹ̀ Sámúsìn. w23.09 5 ¶12-13
Monday, February 17
Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀.—Òwe 19:11.
Ìjìnlẹ̀ òye máa jẹ́ ká níwà tútù. Ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye ò ní bínú tí wọ́n bá ní kó ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, táwọn èèyàn bá bi wá ní ìbéèrè, wọn kì í sọ ìdí tí wọ́n fi béèrè ìbéèrè náà. Ìyẹn fi hàn pé a lè má mọ ìdí tí ẹni náà fi béèrè ìbéèrè yẹn. Ó lè jẹ́ pé ó fẹ́ ta kò wá tàbí kó jẹ́ pé nǹkan kan ń jẹ ẹ́ lọ́kàn ló fi béèrè ìbéèrè náà. Torí náà, á dáa ká fara balẹ̀ wádìí ká tó dáhùn. (Òwe 16:23) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Gídíónì ṣe nígbà táwọn ọkùnrin Éfúrémù wá bá a. Wọ́n fìbínú béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé kí nìdí tí ò fi pe àwọn nígbà tó kọ́kọ́ fẹ́ lọ bá àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì jà. Àmọ́ kí nìdí tí wọ́n fi ń bínú? Ṣé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbéraga ló wọ̀ wọ́n lẹ́wù? Èyí ó wù ó jẹ́, Gídíónì fi hàn pé òun ní ìjìnlẹ̀ òye. Ó mọ ohun tó ń bí wọn nínú, ó sì dá wọn lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Kí ni wọ́n wá ṣe? Ìbínú wọn rọlẹ̀, “ara wọn [sì] balẹ̀.”—Oníd. 8:1-3. w23.09 16 ¶8-9
Tuesday, February 18
Èmi ni àrídunnú rẹ̀ lójoojúmọ́.—Òwe 8:30.
Bí àárín bàbá àti ọmọ tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn ṣe máa ń gún régé, bẹ́ẹ̀ náà ni àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti Jésù ṣe rí. Kò sí àní-àní pé ó dun Jèhófà gan-an bó ṣe ń rí i tí wọ́n hùwà ìkà sí Ọmọ ẹ̀, bí wọn ò ṣe gbà pé òun ni Mèsáyà, tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́. Àwọn òbí tọ́mọ wọn kú máa ń mọ ẹ̀dùn ọkàn burúkú tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń fà. Ó dá wa lójú háún pé àjíǹde máa wáyé, àmọ́ ìyẹn ò sọ pé a ò ní lẹ́dùn ọkàn tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ohun tá a sọ yìí jẹ́ ká rí bó ṣe rí lára Jèhófà bó ṣe ń wo Ọmọ ẹ̀ tó ń jìyà lọ́jọ́ tí wọ́n pa á lọ́dún 33 S.K. (Mát. 3:17) Láti ìsinsìnyí títí dìgbà tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, o ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín? Tó bá sì dọjọ́ yẹn, má gbàgbé láti wo fídíò àkànṣe Ìjọsìn Òwúrọ̀ tá a ṣe fún Ìrántí Ikú Kristi. Torí náà, tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa, á jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní Ìrántí Ikú Kristi.—Ẹ́sírà 7:10. w24.01 11 ¶10-12
Wednesday, February 19
Ó máa sọ yín di alágbára.—1 Pét. 5:10.
Ọ̀kan lára ohun tó máa ń jẹ́ ká rí okun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà ni pé ká máa gbàdúrà sí i. Tí Jèhófà bá fẹ́ dáhùn àdúrà wa, ó máa ń fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) A tún lè rí okun gbà tá a bá ń ka Bíbélì, tá a sì ń ronú nípa ohun tá a kà. (Sm. 86:11) Bákan náà, ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì máa ń fún wa “ní agbára.” (Héb. 4:12) Torí náà, tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, tó ò ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, wàá rí okun tó o nílò láti fara dà á, o ò ní pàdánù ayọ̀ rẹ, wàá sì lè ṣe iṣẹ́ tí ò rọrùn láṣeyọrí. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fún wòlíì Jónà lókun. Ó sá fún iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Nítorí ẹ̀, ìjì líle kan fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí òun àtàwọn tó wà pẹ̀lú ẹ̀ nínú ọkọ̀. Nígbà tí wọ́n jù ú sínú òkun, inú ikùn ẹja ńlá kan ló ti bá ara ẹ̀. Kí ni Jónà ṣe kó lè rí okun gbà nígbà tó wà nínú ikùn ẹja? Ó gbàdúrà sí Jèhófà.—Jónà 2:1, 2, 7. w23.10 13 ¶4-6
Thursday, February 20
Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.—1 Pét. 4:7.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ni àpọ́sítélì Pétérù dìídì kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀ sí, Jèhófà jẹ́ káwọn àkọsílẹ̀ náà wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Torí náà, àwa náà lè jàǹfààní gan-an nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀. (Róòmù 15:4) Àwọn tí ò gba àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì gbọ́ pọ̀ láyé yìí. Àwọn alátakò lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ọ̀pọ̀ ọdún la ti ń sọ pé òpin máa dé. Àwọn kan tó ń ṣàríwísí sọ pé òpin ò lè dé láé. (2 Pét. 3:3, 4) Tá a bá gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lẹ́nu ẹni tá à ń wàásù fún, ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa kan, ìgbàgbọ́ wa lè má lágbára mọ́. Àmọ́ Pétérù sọ ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́. Lójú àwọn kan, ó jọ pé Jèhófà ń fi nǹkan falẹ̀ torí kò pa ayé burúkú yìí run. Ohun tí Pétérù sọ máa jẹ́ ká fojú tó tọ́ wo nǹkan, ó sì máa rán wa létí pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àkókò yàtọ̀ pátápátá sí tàwa èèyàn. (2 Pét. 3:8, 9) Torí lójú Jèhófà, ẹgbẹ̀rún ọdún (1,000) dà bí ọjọ́ kan. Jèhófà ní sùúrù gan-an, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run. Àmọ́ tí ọjọ́ Jèhófà bá dé, ayé burúkú yìí máa dópin. w23.09 26-27 ¶2-5
Friday, February 21
[Ó] yẹ ká túbọ̀ máa fiyè sí àwọn ohun tí a gbọ́, ká má bàa sú lọ láé.—Héb. 2:1.
Kí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tó ń gbé ní Jùdíà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nǹkan méjì ló mú kó kọ ọ́. Ohun àkọ́kọ́ ni pé ó fẹ́ fún wọn níṣìírí. Inú ẹ̀sìn Júù ni ọ̀pọ̀ lára wọn dàgbà sí, ó sì ṣeé ṣe káwọn olórí ẹ̀sìn wọn máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé wọ́n di Kristẹni. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn Kristẹni ò ní tẹ́ńpìlì tí wọ́n ti ń jọ́sìn, wọn ò ní pẹpẹ tí wọ́n ti ń rúbọ sí Ọlọ́run, wọn ò sì ní àwọn àlùfáà tó ń bá wọn rúbọ. Gbogbo nǹkan yìí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi, kí ìgbàgbọ́ wọn má sì lágbára mọ́. (Héb. 3:12, 14) Kódà, àwọn kan lára wọn lè máa ronú láti pa dà sínú ẹ̀sìn Júù. Ìkejì, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù yẹn kò gbìyànjú láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ tuntun tàbí àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀, ìyẹn “oúnjẹ líle” tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Héb. 5:11-14) Ó hàn gbangba pé àwọn kan lára wọn ṣì ń tẹ̀ lé Òfin Mósè. w23.10 25 ¶3-4
Saturday, February 22
[Máa hùwà tó dáa sí] àwọn ọ̀dọ́bìnrin bí ọmọ ìyá, pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.—1 Tím. 5:2.
Àwọn obìnrin kan ti pinnu pé àwọn ò ní lọ́kọ. (Mát. 19:10-12) Mọ̀ dájú pé Jèhófà àti Jésù ò fojú àbùkù wo àwọn Kristẹni tí ò lọ́kọ. Kárí ayé làwọn arábìnrin tí ò lọ́kọ ti ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ìjọ. Bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn, tí wọ́n sì ń jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ wọ́n lógún ti jẹ́ kí wọ́n di arábìnrin àti ìyá ọ̀pọ̀ àwọn ará. (Máàkù 10:29, 30) Àwọn arábìnrin kan ti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn obìnrin Kristẹni ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. (Sm. 68:11) Ṣé o lè ṣètò àkókò ẹ báyìí kó o lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? O lè di aṣáájú-ọ̀nà, o lè yọ̀ǹda ara ẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run tàbí kó o lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Gbàdúrà nípa nǹkan tó o fẹ́ ṣe. Bá àwọn tó ti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sọ̀rọ̀, kó o sì ní kí wọ́n sọ ohun tó o lè ṣe kó o lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lẹ́yìn náà, ṣètò bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀. Tọ́wọ́ ẹ bá tẹ àfojúsùn ẹ, wàá lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. w23.12 22 ¶16-17
Sunday, February 23
A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà.—Máàkù 13:10.
Bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń sún mọ́lé, a mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká túbọ̀ máa wàásù fáwọn èèyàn. Ó lè nira fún wa láti gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, pàápàá tá ò bá lówó lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n bá ń ta kò wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kí lá jẹ́ ká gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run? Ohun tó máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni tá a bá ń rántí pé “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” wà pẹ̀lú wa. Ó máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá gbájú mọ́ ìjọsìn ẹ̀ dípò ọ̀rọ̀ tara wa. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ ṣojo. (Hág. 2:4) Jèhófà fẹ́ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Hágáì rọ àwọn èèyàn Ọlọ́run láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn lákọ̀tun, bí ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà lélẹ̀. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé òun ‘á bù kún wọn.’ (Hág. 2:18, 19) Ó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa bù kún ìsapá wa tá a bá gbájú mọ́ iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́. w23.11 16 ¶8; 17 ¶11
Monday, February 24
Gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀.—Róòmù 3:23.
Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ pé gbogbo èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀. Torí náà kí la lè ṣe, kí Ọlọ́run lè pè wá ní olódodo àti aláìlẹ́bi? Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Ábúráhámù máa jẹ́ káwa Kristẹni tòótọ́ lè dáhùn ìbéèrè yẹn. Jèhófà pe Ábúráhámù ní olódodo nígbà tó ń gbé ilẹ̀ Kénáánì. Kí nìdí tí Jèhófà fi pe Ábúráhámù ní olódodo? Ṣé torí pé Ábúráhámù ń pa Òfin Mósè mọ́ ni? Rárá o. (Róòmù 4:13) Ó ju ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́rin (400) lọ lẹ́yìn tí Jèhófà pe Ábúráhámù ní olódodo kó tó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní Òfin yẹn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí Jèhófà fi pe Ábúráhámù ní olódodo? Ìdí ni pé ó nígbàgbọ́, Jèhófà sì fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí i.—Róòmù 4:2-4. w23.12 3 ¶4-5
Tuesday, February 25
Ṣe ohunkóhun tó wà lọ́kàn rẹ.—1 Kíró. 17:2
Ní alẹ́ ọjọ́ tí wòlíì Nátánì sọ ohun tó wà lókè yẹn fún Ọba Dáfídì, Jèhófà ní kí Nátánì sọ fún Dáfídì pé òun kọ́ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà. (1 Kíró. 17:3, 4, 11, 12) Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tó gbọ́ ìròyìn yìí? Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kó owó àti ohun èlò jọ tí Sólómọ́nì ọmọ ẹ̀ máa fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà. (1 Kíró. 29:1-5) Lẹ́yìn tí Jèhófà ní kí wọ́n sọ fún Dáfídì pé òun kọ́ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló bá a dá májẹ̀mú kan. Jèhófà ṣèlérí fún Dáfídì pé ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ ẹ̀ ló máa ṣàkóso títí láé. (2 Sám. 7:16) Nínú ayé tuntun, ẹ wo bí inú Dáfídì ṣe máa dùn tó nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, tó bá mọ̀ pé Jésù àtọmọdọ́mọ òun ni Ọba tó ń ṣàkóso! Ìtàn Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé tá ò bá tiẹ̀ lè ṣe gbogbo ohun tá a fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó ṣì lè lò wá láwọn apá ibòmíì tá ò lérò. w23.04 15-16 ¶8-10
Wednesday, February 26
Jèhófà ò ní pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì.—Sm. 94:14.
Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, o lè ka àwọn ibì kan nínú Bíbélì, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ wàá rí ìtùnú gbà. Bí àpẹẹrẹ, o lè rí ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìwé Jóòbù, Sáàmù, Òwe àtàwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù orí kẹfà. Torí náà, tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, tó o sì ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ déédéé, ó máa tù ẹ́ nínú. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dúró tì wá nígbà ìṣòro, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 23:4) Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáàbò bò wá, òun máa jẹ́ kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ fún wa, òun máa ràn wá lọ́wọ́, òun sì máa tù wá nínú. Àìsáyà 26:3 sọ nípa Jèhófà pé: “O máa dáàbò bo àwọn tó gbára lé ọ pátápátá; o máa fún wọn ní àlàáfíà tí kò lópin, torí pé ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.” Torí náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó o sì máa lo àwọn nǹkan tó ń pèsè láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá pa dà lókun nígbà ìṣòro. w24.01 25 ¶16-17
Thursday, February 27
Ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí ọ kò ní ṣàṣeyọrí.—Àìsá. 54:17.
Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì tó wà lókè yìí ń ṣẹ lákòókò wa. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tó tẹ̀ lé e yìí náà ti ń ṣẹ lákòókò wa: “Jèhófà máa kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ sì máa pọ̀ gan-an. O máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú òdodo. . . . O ò ní bẹ̀rù ohunkóhun, ohunkóhun ò sì ní já ọ láyà, torí pé kò ní sún mọ́ ọ.” (Àìsá. 54:13, 14) Kódà Sátánì tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” ò lè dá iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe dúró. (2 Kọ́r. 4:4) Ìjọsìn mímọ́ ti pa dà bọ̀ sípò, wọn ò sì ní lè bà á jẹ́ mọ́ láé. Títí láé ló máa wà. Torí náà, kò sí ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí wa tó máa ṣàṣeyọrí! w24.02 4 ¶10
Friday, February 28
Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ bàbá tàbí ìyá jù mí lọ kò yẹ fún mi.—Mát. 10:37.
Àwa Kristẹni máa ń fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Jèhófà. Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ìdílé, a máa ń fi ẹ̀jẹ́ yìí sọ́kàn. A máa ń bójú tó ìdílé wa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ, àmọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ la máa ń fi ṣáájú ohun tí ìdílé wa fẹ́. (Mát. 10:35, 36; 1 Tím. 5:8) Nígbà míì sì rèé, ó lè gba pé ká ṣe àwọn ìpinnu tínú àwọn mọ̀lẹ́bí wa ò ní dùn sí, àmọ́ táá múnú Jèhófà dùn. Òun ló dá ìdílé sílẹ̀, ó sì fẹ́ ká máa láyọ̀. (Éfé. 3:14, 15) Tó bá wù wá pé ká láyọ̀, a gbọ́dọ̀ máa ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì bó o ṣe ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, tí ò ń bójú tó ìdílé ẹ, tó o sì ń fi ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ hàn sí wọn.—Róòmù 12:10. w24.02 17-18 ¶11, 13