Inututu
Ẹmi tutupẹlẹ, laisi irera tabi ẹmi igberaga. Itẹsi ero-ori ti o jẹ ki ẹnikan ni agbara lati farada ipalara pẹlu suuru ati laisi isunnibinu, irunu, tabi fifi buburu san buburu lọna igbẹsan. O jẹ alabaakẹgbẹ timọtimọ a si maa nrii lẹẹkọọkan ti o dayatọ si awọn iwa miiran iru bii ẹmi irẹlẹ, ero-inu rirẹlẹ, ati iwa jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́. Ọrọ Heberu naa ti a tumọ si “oninututu” (‛a·nawʹ) wa lati inu gbongbo naa ‛a·nahʹ, eyi ti o tumọ si “pọnloju, rẹsilẹ, tẹlogo.”
Ninu Bibeli, inututu ni a tẹnumọ gẹgẹbi ibi ti ero-ori ẹnikan tẹ̀ si lakọọkọ nipa Ọlọrun, lẹhin naa nipa awọn ẹda eniyan. Fun apẹẹrẹ, a ti kọ ọ́ pe: “Awọn ẹni oninututu yoo mu ayọ wọn pọ sii ninu Jehofa funraarẹ.” (Aisa. 29:19, NW) Awọn eniyan oninututu ṣeé kọ—Jehofa “yoo kọ awọn ẹni oninututu ni ọna rẹ̀” (Saamu 25:9, NW)—wọn si muratan lati farada ibawi lati ọwọ Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ pe iru ibawi bẹẹ nbani ninu jẹ ni akoko naa. (Heb. 12:4-11) Inututu nmu ki ẹnikan duro de Jehofa lati ṣe atunṣe awọn aitọ ati ipalara ti o jiya lọna aiṣedajọ ododo, dipo didi ẹni ti a ru soke pẹlu ibinu. (Saamu 37:8-11) Iru awọn eniyan bẹẹ ni a ko jakulẹ, nitori ẹni ti Jehofa yàn, “èèkàn lati inu kukute Jese,” yoo funni ni ibawitọsọna ni ododo “nitori awọn ẹni oninututu ilẹ-aye.”—Aisa. 11:1-4, NW.
Mose
Mose jẹ iru eniyan bẹẹ gan an, “ti o jẹ oninututu julọ ninu gbogbo eniyan ti o wa lori ilẹ,” ẹnikan ti o le gba iṣofintoto laini imọlara irunu. (Num. 12:3, NW) Ohun ti o ṣẹlẹ nigba ọrọ yii lori inututu rẹ ni akoko naa nigba ti Miriamu ati Aaroni kùn lodisi Mose. Niti gidi, o jẹ ifisun ti ko yẹ lodisi Jehofa eyi ti oun tete kiyesi ti o si bawi.—Numeri 12:1-15.
Awọn alalaye ọrọ kan fẹsun kan pe fun Mose lati ṣakọsilẹ itọka yii si inututu tirẹ̀ fúnraarẹ̀ jẹ iyinra ẹni ti a ko dalare. Awọn alameyitọ miiran sọ pe gbolohun ọrọ naa ni a fikun un lẹhin naa lati ọwọ ẹnikan nigba ti awọn miiran ẹwẹ funni ni eyi gẹgẹ bi ẹri pe o ṣetan Mose ko kọ Iwe Marun Akọkọ naa. Bi o ti wu ki o ri, Alaye-ọrọ Cook sọ nipa awọn ọrọ wọnyi pe: “Nigba ti a ba ka wọn si eyi ti Mose sọ ti kì í ṣe ‘ti idanuṣe tirẹ funraarẹ,’ ṣugbọn labẹ idari Ẹmi Mimọ eyi ti o wa lori rẹ (fiwe xi. 17), wọn fi ‘àìgbè si ara ẹni lẹhin’ han, eyi ti o jẹ ẹri ojú-ẹsẹ̀ naa si ìjójúlówó wọn ati pẹlu sí imisi wọn. Nipa awọn ọrọ wọnyi ati nipa awọn ayọka naa nibi ti Mose ti ṣakọsilẹ ti o ṣe kedere bakan naa nipa awọn aṣiṣe oun tikaraarẹ, (fiwe xx. 12 sqq.; Ẹks. iv. 24 sqq.; Deut. i. 37), otitọ inu ti ẹni ti o jẹrii nipa araarẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe si araarẹ̀ nbẹ nibẹ (fiwe St Mat. xi 28, 29). Awọn ọrọ naa ni a fi kun un lati ṣalaye bi o ti jẹ pe Mose ko gbe awọn igbesẹ lati da araarẹ lare, ati idi ti Oluwa ṣe dasi i ni kia bẹẹ ni asẹhinwa asẹhinbọ.”
Jesu Kristi
Jesu ṣaṣefihan inututu nipa fifarada gbogbo iru èṣe ti a fi ṣe e laisi ọrọ irahun kan, o tilẹ jẹ ki a sin oun funraarẹ lọ si ibùpa gẹgẹbi ọdọ-agutan kan ti ko ya ẹnu rẹ̀ ni ilodisi. (Filip. 2:5-8; Heb. 12:2; Iṣe 8:32-35; Aisa. 53:7) Ẹni ti o Tobiju Mose lọ yi tun sọrọ rere nipa araarẹ fun awọn ẹlomiran gẹgẹ bi oninututu kan tabi ọlọ́kàn rirẹlẹ eniyan. (Mat. 11:28, 29, AS, KJ, ED, NW, Ro) Gẹgẹ bi Aisaya 61:1 (NW) ti sọtẹlẹ, a fami ororo yan an pẹlu ẹmi Jehofa “lati sọ ihinrere naa fun awọn ẹni oninututu.” Lẹhin kika asọtẹlẹ yii ninu Sinagọgu ilu ibilẹ rẹ ti Nasarẹti, Jesu polongo pe: “Lonii yii, iwe mimọ ti ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ yii ni imuṣẹ.” (Luuku 4:16-21, NW) Ni titipa bayii rán Ọmọkunrin rẹ aayo-olufẹ lati kọ́ awọn oninututu nipa igbala, Ọlọrun nitootọ nfi ojurere akanṣe gan an hàn si wọn.—Saamu 149:4; Owe 3:34.
O Nmu Èrè Wá
Ikesini naa ti wolii Sẹfanaya sọ jade ni a ṣi nnawọ rẹ̀ si awọn eniyan oninututu ilẹ-aye: “Ẹ wa Jehofa, gbogbo ẹyin oninututu ilẹ-aye, ti o ti sọ ipinnu idajọ Rẹ funraarẹ dàṣà. Ẹ wa ododo, ẹ wa inututu [tabi, ẹmi irẹlẹ; irẹlẹ ọkan]. Boya a o tọju yin pamọ ni ọjọ ibinu Jehofa.” (Sẹfanaya 2:3, alaye ẹsẹ iwe NW) Lékè ati rekọja iyẹn ni awọn ileri agbayanu miiran wa ti a nawọ rẹ̀ si iru awọn ẹni bẹẹ. Fun apẹẹrẹ: “Awọn oninututu funraawọn yoo ní ilẹ-aye ní ìní wọn yoo si ri inu didun wọn ti o kọyọyọ ninu ọpọ alaafia.” (Saamu 37:11, NW) Ni itumọ tẹmi ati ni ti gidi, “awọn oninututu yoo jẹun wọn yoo si ni itẹlọrun.”—Saamu 22:26, NW.
Nitori naa, ni iyatọ si awọn ẹni buburu ti wọn nṣi awọn oninututu lọna ti wọn si nwa ọ̀nà lati pa wọn run (Amosi 2:7; 8:4), Jehofa nfetisi awọn ifẹ atọkanwa wọn nipa didahun awọn adura wọn; ireti wọn ninu Jehofa ni a ko mu jakulẹ. (Saamu 10:17; 9:18) Owe tootọ ni o jẹ, “O san lati jẹ onirẹlẹ ọkan pẹlu awọn oninututu ju lati pin ikogun pẹlu awọn ti wọn gbe araawọn ga.” —Owe 16:19.