Òpó-igi Idaloro
Ohun eelo kan iru eyi ti a pa Jesu lori rẹ̀ nipasẹ ìkànmọ́gi. (Mat. 27:32-40; Maaku 15:21-30; Luuku 23:26; Joh. 19:17-19, 25) Ni ibamu pẹlu èdè Giriiki igbaani ọ̀rọ̀ naa (stau·rosʹ) ti a tumọsi “òpó-igi idaloro” ninu New World Translation ni pataki duro fun òpó-igi kan ti o wà lóòró, tabi igi gbọọrọ gigun, ko si si ẹ̀rí kankan pe awọn onkọwe Iwe Mimọ Kristian lede Giriiki lò ó lati tọkasi òpó-igi kan ti o ni igi àgbédábùú.
Iwe naa The Non-Christian Cross, lati ọwọ John Denham Parsons, wipe: “Ninu Giriiki apilẹkọ, ko si gbolohun ọ̀rọ̀ kanṣoṣo eyikeyii ninu ọgọọrọ awọn iwe kikọ ti wọn papọ di Majẹmu Titun, ti o fi ẹ̀rí ti ko ṣe taarata paapaa han niti pe stauros ti a lò ninu ọran ti Jesu yatọ si stauros gidi kan; dajudaju kii ṣe pẹlu itumọ pe kii ṣe ìtí igi gẹdú kan, ṣugbọn pe o papọ jẹ ìtí igi meji ti a kàn papọ ni irisi àgbélébùú. . . . Kii ṣe iṣina kekere ni o jẹ lati ọ̀dọ̀ awọn olukọ wa lati tumọ ọ̀rọ̀ naa stauros gẹgẹ bi ‘àgbélébùú’ nigba ti wọn nṣetumọ iwe akọsilẹ Ṣọọṣi ti èdè Giriiki si èdè ibilẹ wa, ati lati ti igbesẹ yẹn lẹhin nipa fifi ‘àgbélébùú’ sinu awọn iwe atumọ èdè wa gẹgẹ bi itumọ stauros laifi tiṣọratiṣọra ṣalaye pe lọna eyikeyii iyẹn kii ṣe itumọ ipilẹṣẹ ọ̀rọ̀ naa ni ọjọ awọn Apọsteli, ati pe ko di itumọ rẹ̀ ipilẹṣẹ titi di akoko pipẹ lẹhin naa, o si dì bẹẹ nigba naa, bi o ba tilẹ ri bẹẹ rara, kiki nitori pe, laika aisi ẹ̀rí itilẹhin si, o jẹ fun idi kan tabi ki awọn ẹlomiran lero pe stauros naa gan-an lori eyi ti a ti pa Jesu ní irú irisi yẹn.”—London, 1896, oju-iwe 23, 24.
Idi Ti Jesu Fi Nilati Ku Lori Òpó-igi
Ni akoko ti Jehofa Ọlọrun fi ofin rẹ̀ fun awọn ọmọ Israẹli, wọn fi araawọn si abẹ aigbọdọmaṣe lati gbe ni ibamu pẹlu awọn itumọ rẹ̀. (Ẹks. 24:3) Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi àtìrandíran ọmọ Adamu ẹlẹṣẹ, ko ṣeeṣe fun wọn lati ṣe bẹẹ lọna pipe. Fun idi yii wọn wa sabẹ ifibu Ofin naa. Lati mu akanṣe ifibu yii kuro lori wọn, Jesu ni a nilati fikọ sori òpó-igi gẹgẹ bi ọdaran kan ti a fibú. Nipa eyi apọsteli Pọọlu kọwe pe: “Iye awọn ti nbẹ ni ipa iṣẹ ofin nbẹ labẹ ègún: nitori ti a ti kọ ọ pe, Ìfibú ni olukuluku ẹni ti kò duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati maa ṣe wọn. . . . Kristi ti rà wa pada kuro lọwọ ègún ofin, ẹni ti a fi ṣe ègún fun wa: nitori ti a ti kọ ọ pe, Ìfibú ni olukuluku ẹni ti a fi kọ́ sori igi.”—Gal. 3:10-13.