Ki ni O Nfa Idaamu Idile?
BOB kigbe pe, ‘Ọlẹ ni! Atunleṣe buruku gbáà ni!’
Jean fesi pada pe, ‘Iyẹn kìí ṣe otitọ rara!’ Oun kii fimọriri han fun ohunkohun ti mo bá gbiyanju lati ṣe. O jẹ okunrin alariiwisi julọ ti mo tii bá pade ri.’
Ki ni o ṣaitọ ninu igbesi-aye Bob ati Jean?a Igbeyawo aṣẹṣẹṣe wọn jẹ kiki oṣu mẹrin, ṣugbọn o ti fẹrẹẹ fori ṣápọ́n. Bi o ti wu ki o ri, ọran wọn kii ṣe àrà ọ̀tọ̀, nitori àkójọ isọfunni oniṣiro fihan pe aisirẹpọ ninu igbeyawo jẹ ohun ti o wọpọ. Awọn ogbogi nsọ nisinsinyi pe idaji ninu gbogbo awọn igbeyawo titun ni United States ni yoo yọri si ikọsilẹ. Awọn àkójọ isọfunni oniṣiro ti nbani ninu jẹ lọna ti o farajọra nwa lati ọpọ awọn ilu miiran. Sibẹ, ikọsilẹ wulẹ jẹ ọkan lara rẹ ni. Ni iye ti ko lẹgbẹ ati fun oniruuru awọn idi, awọn idile wà ninu idaamu.
Awọn Idi Diẹ fun Idaamu Idile
Awọn ọmọde ni a nipa lé lori lọna ti o ga nigba ti awọn ipo onidaamu ba wà ninu idile. Iwe irohin Newsweek rohin pe: “Idamẹta ninu gbogbo awọn ọmọ ti a bi ni ọdun mẹwaa ti o kọja sẹhin [ni United States] ni o ṣeeṣe ki wọn gbé ninu idile onigbeyawo atunṣe kan ki wọn to pe ọmọ ọdun mejidinlogun. Ọkan ninu gbogbo ọmọ mẹrin lonii ni a ntọ́ dagba lati ọwọ obi kanṣoṣo. Nǹkan bii 22 ipin ninu ọgọrun awọn ọmọ lonii ni a bi lẹhin ode igbeyawo; ninu awọn wọnni, nǹkan bi idamẹta ni a bi fun iya ti ko tii pe ọmọ ogun ọdun.”
Ni mimẹnukan okunfa ti o tan mọ́ idaamu idile, J. Patrick Gannon, onimọ nipa ilokulo ọmọde wipe: “Iwadii lọ́ọ́lọ́ọ fihan pe araadọta ọkẹ mẹwaa mẹwaa awọn eniyan dagba ninu awọn idile ti ko tòrò nibi ti iwa ipa, ibalopọ laaarin ibatan ti o sunmọra tabi híhan ero imọlara léèmọ̀ tí imukumu ọti nṣokunfa jẹ ohun ti nṣẹlẹ gidi lojoojumọ.” Ko ya nilẹnu pe ọpọ awọn ọmọ ti a mu dojulumọ iru awọn nǹkan bẹẹ le ma mọ bi wọn ṣe le yẹra fun idaamu idile gẹgẹ bi awọn agbalagba.
Awọn oluṣakiyesi kan le di ẹbi idaamu idile ru awọn iyipada ọrọ aje, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ati iwa rere ti o tàn ka awọn ilẹ ti wọn ni ile iṣẹ ẹrọ ńláńlá. Fun apẹẹrẹ, awọn obinrin ti wọn ńkówọnu iṣẹ bóojí-o-jími lọna pupọ jaburata ti taná ran àtúntò awọn ipa iṣẹ ati ẹru-iṣẹ ile ti o saba maa nfa idarudapọ. Awọn ìyá nfi aniyan sọ òye iṣẹ ti wọn ti patì nigba kan rí jí lẹẹkan sii, ti awọn baba si nfi ìlọ́tìkọ̀ jijakadi pẹlu awọn iṣẹ ile nigba ti awọn ọmọ nfi ẹkun mu araara wọn ba igbesi-aye ile itọju awọn ọmọ wẹ́wẹ́ mu.
Ọpọlọpọ awọn idile wa labẹ ikimọlẹ lile koko ni awọn ilẹ yika aye. Obi kan ti nṣiṣẹ fi eyi we “gbigbe ninu ipo pajawiri nigba gbogbo.” Ko yani lẹnu pe eyi ti o fẹrẹ to idaji ninu awọn ti a fọrọ wá lẹnu wò ninu Iwadii Gallup ti aipẹ yii sọ pe ‘idile awọn ara America ni o burú jáì lonii ju bi o ti ri ni ọdun mẹwaa sẹhin lọ,’ awọn diẹ ni wọn si gbagbọ pe ipo naa yoo sunwọn si.
Nitori naa idaamu idile jẹ akori ọrọ fun ijiroro atigbà dégbà lori tẹlifisọn ati redio. Awọn awujọ nka gbogbo awọn iwe ti wọn npese iranlọwọ ara-ẹni lori ọran idile, ti awọn diẹ si npese iwọn imọran ti o gbeṣẹ ti o si ṣee mulo. Bi o tilẹ jẹ pe iṣileti lati ‘jumọ sọrọ pọ ni falala’ tabi lati ‘sọ ero ara ẹni jade’ le ṣe iranlọwọ, ṣugbọn eyi ko tíì yanju awọn iṣoro inu ile. Ọrọ ẹkọ ti o tẹle yoo ṣe bẹẹ yoo si fi bi a o ṣe yanju awọn idaamu idile han.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Awọn iyipada orukọ ni a lo lati pa aṣiiri mọ.