ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 6/1 ojú ìwé 27-30
  • Lẹhin Buchenwald Mo Ri Otitọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lẹhin Buchenwald Mo Ri Otitọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Faṣẹ Ọba Mu Mi
  • Loju Ọna Si Ilẹ Germany
  • Igbesi-Aye Ojoojumọ
  • Awujọ Yiyatọ Kan
  • Ọkọ̀ Oju-Irin Iku
  • Igbesẹ Titun Kan
  • Jèhófà Gbà Wá Lọ́wọ́ Àwọn Ìjọba Bóofẹ́bóokọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kò Sí Ohun Tí Ó Dára Bí Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìgbọ́kànlé Tí Mo Ní Nínú Ọlọ́run Ló Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró
    Jí!—2002
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 6/1 ojú ìwé 27-30

Lẹhin Buchenwald Mo Ri Otitọ

ILU Grenoble, France, ni mo gbé dàgbà, ni awọn ọdun 1930. Olukọ ti ń kọ mi ni ede German, ọmọ ilẹ̀ France kan, jẹ́ onigboonara ẹhànnà fun eto ijọba Nazi. Oun maa ń figba gbogbo tẹnumọ ọn ni ile-ẹkọ pe German “ń bọ̀ wa wulo” ni ọjọ kan. Bi o ti wu ki o ri, eyi ti o pọju ninu awọn olukọ wa, ti wọn ni iriri Ogun Agbaye I, ni wọn ń daamu nipa idagbasoke eto ijọba Nazi ni Germany. Emi paapaa nimọlara idaamu bi o ṣe tubọ ń ṣe kedere siwaju ati siwaju sii pe ogun ń bọ̀.

Ni ọdun 1940, ni ibẹrẹ Ogun Agbaye II, mo padanu arakunrin obi mi ololufẹ kan ninu ìjà kan ti o kira lori odò Somme. Mo ni imọlara ìkorò ọkàn gidigidi ṣugbọn mo ṣì kere lati forukọ silẹ ninu Ẹgbẹ Ọmọ-Ogun ti ilẹ̀ France. Bi o ti wu ki o ri, ni ọdun mẹta lẹhin naa, nigba ti awọn ara German gba ilẹ France a fun mi ni anfaani lati lo òye-iṣẹ́ mi gẹgẹ bi oluyaworan fun Ẹgbẹ Oṣiṣẹ Abẹ́lẹ̀ fun ilẹ̀ France fun ete didoju ijọba ilẹ Germany bolẹ̀. Mo tayọ ninu ṣiṣe àdàkọ awọn àmì ìfọwọ́sí-nǹkan ti mo si tun ń ṣiṣẹ ṣiṣe ẹ̀dà òǹtẹ̀ awọn ara Germany. Mo ri itẹlọrun pupọ tobẹẹ ninu biba awọn ọmọ-ogun ọ̀tá tí wọn gba ilẹ wa jà lọna yii ti o fi jẹ pe ero nipa eto ijọba Kọmunist tí awọn alabaakẹgbẹ mi ní kò jamọ nnkankan loju mi ni ìgbà naa.

A Faṣẹ Ọba Mu Mi

Ni November 11, 1943, Ẹgbẹ Oṣiṣẹ Abẹ́lẹ̀ ti adugbo pe ìpè fun ṣiṣe ìwọ́de kan lati fi ṣeranti adehun ìdá-ogun-dúró ranpẹ ti Ogun Agbaye I. Ṣugbọn awọn ẹ̀ṣọ́ ilẹ France ti ń fi ọkọ̀ rìn kiri ti tò dí oju-ọna afárá ti o lọ si ibi iranti ogun, ti wọn si fun wa niṣiiri pe ki a pada lọ si ile. Ẹgbẹ oníwọ̀ọ́de tiwa pinnu lati lọ si ibi ìṣèrántí ogun miiran ninu ìlú. Ṣugbọn a ti gbagbe ohun kan. Ibi ìṣèrántí naa kò jìnnà si ọfiisi awọn ọlọpaa Gestapo.

Kíámọ́sá ni awọn ọmọ-ogun ti wọn dihamọra yí agbo wa po, ti wọn si tò wa jọ ni kikọju wa si ogiri. Nigba ti awọn ọmọ-ogun naa mú ki a sún siwaju, wọn rí awọn ibọn ìléwọ́ melookan lori ilẹ̀. Bi kò ti si ẹni ti o fẹ lati jẹwọ pe oun lo ni wọn, awọn ọmọ-ogun dá kiki awọn obinrin ati awọn ewe lati ọjọ-ori 16 sisalẹ silẹ. Nipa bayii, lati ọmọ ọdun 18, ni a ti sọ mi sẹwọn, papọ pẹlu awọn 450 ẹlẹwọn miiran. Ni ọjọ melookan lẹhin naa, a gbe wa lọ si àgọ́ ti a gbé fun ìgbà diẹ lẹ́bàá ilu Compiègne, ni ariwa ilẹ̀ France.

Loju Ọna Si Ilẹ Germany

Ni January 17, 1944, mo ni ifarakanra akọkọ—ṣugbọn lọna ti o ṣeni laanu ki i ṣe eyi ti o pẹ lọ titi—pẹlu awọn ọmọ ogun Germany ti wọn ni àṣíborí ti a fi àmì swastika ṣelọsọọ lapa òsì ati lẹta ibẹrẹ orukọ naa SS (Schutzstaffel) ni apa ọ̀tún. Wọn kó ọgọrọọrun awọn ẹlẹwọn jọpọ, ti a si nilati rìn lọ si ibudokọ oju irin ti ilu Compiègne. Nṣe ni a ń gbá wa ni ìpá wọnu awọn ọkọ apoti ẹrù ọkọ reluwe naa niti gidi. Ninu ọkọ apoti ẹrù temi nikan, 125 awọn ẹlẹwọn ni wọn wà nibẹ. Fun ọjọ mẹta ati òru meji, a kò ni ohunkohun lati jẹ tabi lati mu. Laaarin wakati melookan, awọn wọnni ti wọn ṣe alailera julọ ti ṣubú lulẹ̀ ti a sì bẹrẹ sii tẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Ọjọ meji lẹhin naa a de ilu Buchenwald, nitosi ilu Weimar, ni àárín gbùngbùn ilẹ̀ Germany lọhun-un.

Lẹhin ti a ti fi oògùn apakòkòrò wẹ̀ mi mọ́ ti a sì gẹ irun ori mi, a fun mi ni nọmba iforukọsilẹ naa 41,101 a sì kà mi sí “Akópayàbáni ti Ẹgbẹ Kọmunist.” Ni ìgbà ìṣémọ́ kan nitori àrùn, mo ṣalabaapade alufaa ti ẹgbẹ Dominic naa Michel Riquet, ti ó wá pada di olokiki lẹhin ogun nitori awọn iwaasu rẹ̀ ni Katẹdirali ti Notre Dame, ni ilu Paris. Papọ pẹlu awọn ọdọkunrin miiran ti a jumọ jẹ irọ̀, mo beere idi ti Ọlọrun fi fayegba iru awọn ìpayà bẹẹ lọwọ rẹ̀. O dahun pe: “Iwọ gbọdọ la ijiya pupọ gan an kọja lati lè yẹ fun lilọ si ọrun.”

Igbesi-Aye Ojoojumọ

Awọn olugbe apapọ ojule ti o jẹ 61 ni ibudo awọn ọmọ-ogun gbọdọ jí dide ni nǹkan bi 4:30 òwúrọ̀. A o jade sode pẹlu aṣọ ni kiki ìbàdí a sì nilati fọ́ yinyin ti o ti dì sinu omi ìwẹ̀ wa lọpọ ìgbà lati lè fi wẹ̀. Yala araarẹ lekoko tabi kò lè, olukuluku gbọdọ ṣegbọran. Tẹle eyi ni burẹdi pinpin funni—burẹdi alailadun ti o jẹ lati iwọn ounce 7 si 11 lọjọ kọọkan, papọ pẹlu iwọnba bọ́tà fẹẹrẹfẹ ati ohun ti o farajọ eso igi ti a ti sè (jam). Ni 5:30 òwúrọ̀, a o kó gbogbo eniyan jọ fun orukọ pípè. Iru iriri bibanilẹru gidigidi wo ni o jẹ́ lati fi ẹhin wa gbé awọn ti wọn ti ku loru jade! Òórùn eefin buruku ti awọn oku ti ń jó ń rán wa leti awọn ẹlẹgbẹ wa. Imọlara ti ìríra, anireti, ati ikoriira bò wa mọlẹ, nitori ti a mọ̀ pe awa pẹlu lè pari ayé tiwa lọna kan-naa.

Iṣẹ mi ní BAU II Kommando (ẹgbẹ́ awọn akọ́lé ipin keji) ní ninu gbígbẹ́ awọn kòtò ti a kò nilo fun ete eyikeyii. Ni gbàrà ti a bá ti gbẹ́ ẹ jìn tó ẹṣẹ bàtà meje sisalẹ ni a tun nilati dí i rẹ́mú pada tiṣọratiṣọra. Iṣẹ maa ń bẹrẹ ni 6:00 òwúrọ̀, pẹlu isinmi ranpẹ alaabọ wakati ni ọjọkanri, lẹhin eyi ti a o maa bá iṣẹ lọ titi di 7:00 alẹ́. Pipe orukọ ni alẹ́ saba maa ń dabi eyi ti kì yoo pari mọ́. Nigbakigba ti awọn ọmọ-ogun ilẹ̀ Germany bá ti padanu ọpọlọpọ awọn ọmọ-ogun loju ija pẹlu awọn ara Russia, o lè maa ba a lọ titi di ọganjọ òru.

Awujọ Yiyatọ Kan

Ẹnikẹni ti o ba gbiyanju lati salọ kuro ninu àgọ́ naa ni o rọrun lati dá mọ̀ nitori pe gbogbo wa ní ọ̀nà ìgbà gẹrun ti kò baramu. Irun ori wa ni a ń gẹ̀ lọna onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ tabi ki wọn gé e mọ́lẹ̀ gan an laaarin tabi lẹgbẹẹgbẹ. Bi o ti wu ki o ri, awọn ẹlẹwọn kan ni a wulẹ ń gẹrun wọn lasan. Ta ni wọn? Olori ojule ti wa tẹ́ ìfẹ́ ìtọpinpin wa lọrun. “Bibelforscher (Awọn Akẹkọọ Bibeli) ni wọn,” ni o wi. ‘Ṣugbọn ki ni Awọn Akẹkọọ Bibeli ń ṣe ninu àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́?’ ni mo ń ṣe kayeefi. “Wọn wà nihin in nitori pe wọn ń jọsin Jehofa,” ni o sọ fun mi. Jehofa! Iyẹn ni ìgbà akọkọ ti mo tíì gbọ́ orukọ Ọlọrun rí.

Mo wa mọ̀ diẹ nipa Awọn Akẹkọọ Bibeli naa nigba ti o ya. Ọpọ julọ ninu wọn jẹ́ ara Germany. Pupọ ninu wọn ti wà ninu àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lati aarin awọn ọdun 1930 nitori kíkọ̀ lati ṣegbọran si Hitler. Wọn ìbá ti lọ lọfẹẹ, ṣugbọn wọn kọ̀ lati juwọsilẹ. Awọn ẹ̀sọ́ SS ń lò wọn gẹgẹ bi onigbàjámọ̀ tiwọn funraawọn, a sì ń fun wọn ni awọn akanṣe iṣẹ òpò ti o ń beere fun oṣiṣẹ ti o ṣee fọkantẹ, iru bii awọn iṣẹ ni ọfiisi ti a ti ń ṣe abojuto. Ohun ti o fa wa lọkan mọra julọ ni ìbàlẹ̀ ọkàn wọn, aisi ikoriira patapata tabi ẹmi ìfàtakò hàn ati ti igbẹsan. Emi kò loye rẹ̀. Lọna ti o ṣenilaaanu, emi kò le sọ ede German pupọ tó lati fi jumọsọrọpọ pẹlu wọn ni ìgbà naa.

Ọkọ̀ Oju-Irin Iku

Bi awọn Apawọ́pọ̀jagun ti ń sunmọ wa sii, awọn ẹlẹwọn ni a ń fi ranṣẹ si awọn àgọ́ ti wọn jinna wọnu orilẹ-ede naa, ṣugbọn awọn wọnyi wá ń di eyi ti o kun àkúnjù lọna ti o banilẹru. Ni April 6, 1945, awọn ẹ̀ṣọ́ SS kó awa 5,000, ti wọn sì fipa mu wa bọ si oju-ọna lati rin ìrìn ibùsọ̀ mẹfa lọ sí ilu Weimar. Awọn wọnni ti kò lè rin ni igbesẹ kan-naa ni a ń fi iwa òṣìkà yìnbọnlù ni ọrùn. Nigba ti a de ibudokọ oju-irin ni ilu Weimar nikẹhin, a goke wọnu awọn ọkọ apoti ẹrù ti reluwe alainilelori, tí ọkọ oju-irin naa si gbera lọ. Fun 20 ọjọ ni o fi ń lọ lati ibudokọ reluwe kan si omiran la aarin ilẹ̀ Germany kọja ati lẹhin naa wọnu orilẹ-ede Czechoslovakia.

Ni owurọ ọjọ kan, apakan ọkọ oju-irin wa ni a gbe yà si oju irin miiran lẹgbẹẹ kan. Awọn ọmọ-ogun ṣı ẹnu awọn ibọn arọjo ọta, wọn ṣı awọn ẹnu ọna ọkọ akẹru kan, wọn si bẹẹrẹ si pa awọn ẹlẹwọn ara Russia ti o wa ninu rẹ̀ lápalù. Ki ni ohun ti o fa a? Awọn ẹlẹwọn mejila ti pa awọn ẹ̀ṣọ́ wọn ti wọn si salọ ni òru. Ani di oni olonii mo ṣì lè ri ẹ̀jẹ̀ ti ń dà ṣooro silẹ gba ti ẹnu ọna ọkọ naa bọ si oju-ọna reluwe naa.

Nikẹhin, ọkọ oju-irin naa de ilu Dachau, nibi ti awọn Ọmọ-ogun America ti dá wa silẹ lominira ni ọjọ meji lẹhin naa. Ni akoko ìrìn ọlọjọ 20 naa, kiki ohun agbẹmiiro ti a rí jẹ ni kúkúǹdùkú tutu melookan ati iwọnba omi diẹ. Iye awa ti o bẹrẹ jẹ 5,000, ṣugbọn kiki 800 ni o laaja. Ọpọ awọn miiran ni wọn ku ni awọn ọjọ diẹ lẹhin naa. Ni temi, mo lo eyi ti o pọju ninu ìrìn naa ni jijokoo sori oku kan.

Igbesẹ Titun Kan

Lẹhin idasilẹ lominira mi kò si ohun ti o dabii pe o ba iwa ẹda mu fun mi ju pe ki ń fi akitiyan ṣetilẹhin fun Ẹgbẹ́ Oṣelu Kọmunist ti French, niwọn bi mo ti bá ọpọ ninu awọn mẹmba rẹ̀—papọ pẹlu awọn ti o gbajumọ—kẹgbẹ tẹlẹ ni Buchenwald. Mo di oluranlọwọ akọwe ẹgbẹ Kọmunist kekere kan ni ilu Grenoble a si fun mi niṣiiri lati lọ gba idanilẹkọọ ti o wà fun awọn olóyè ni ilu Paris.

Bi o ti wu ki o ri, a mu ijakulẹ ba mi laipẹ. Ni November 11, 1945, a kesi wa lati kopa ninu ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọrìn kan ni ilu Paris. Ẹlẹgbẹ (camarade) wa naa tí awujọ wa wà nikaawọ rẹ̀ gba iye owo kan fun sisanwo ibugbe wa ṣugbọn kò dabi pe oun fẹ lati lò ó nitori tiwa. O wa di dandan pe ki a maa rán an leti awọn ilana ipilẹ alailabosi ati ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ti o yẹ ki o so wa pọ̀ ṣọkan. Mo tun mọ̀ pe pupọ awọn gbajumọ eniyan ti mo ti mọ̀ kò wulẹ ni ojutuu si awọn iṣoro ayé. Ṣugbọn, fun eyi ti o pọjulọ, wọn jẹ alaigba-Ọlọrun-gbọ, emi si gbagbọ ninu Ọlọrun.

Mo ṣípò pada lọ si ilu Lyons lẹhin naa, nibi ti mo ti ń baa lọ lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi ayaworan ile. Ni ọdun 1954, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa meji ṣe ibẹwo sọdọ mi, mo si san asansilẹ owo fun iwe irohin Ji! Ni ọjọ meji lẹhin naa, ọkunrin kan ṣebẹwo sọdọ mi pẹlu ọ̀kan lara awọn obinrin ti o ti kan ilẹkun mi ṣaaju. Iyawo mi ati emi wá mọ̀ lojiji pe awa mejeeji nifẹẹ si awọn nǹkan tẹmi.

Nigba awọn ijiroro ti o tẹ̀lé e, mo ranti awọn Bibelforscher ni Buchenwald ti wọn jẹ oloootọ si ìgbàgbọ́ wọn tobẹẹ gẹẹ. Kiki ìgbà naa ni mo to wá mọ̀ pe ọ̀kan-náà ni awọn Bibelforscher wọnyii ati Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ọpẹlọpẹ ikẹkọọ Bibeli kan, emi ati aya mi mu iduro wa fun Jehofa a sì baptisi wa ni April 1955.

Awọn isọyeranti mi ṣe kedere bi ẹnipe ni àná ni gbogbo rẹ̀ ṣẹlẹ. Emi kò kabaamọ awọn iriri lilekoko mi ti atẹhinwa. Wọn ti fun mi lokun wọn si ti ran mi lọwọ lati ri pe awọn ijọba ayé yii kò ni ohun pupọ lati fifunni. Bi o tilẹ jẹ pe awọn iriri ti ara-ẹni kàn wulẹ lè ṣeranwọ fun awọn ẹlomiiran de aye ipo kan ni, emi yoo layọ bi temi bá kàn lè ṣeranwọ fun awọn ọ̀dọ́ eniyan lonii lati riran rí imulẹmofo ti ayé yii ati ni iyọrisi eyi ki wọn wá awọn ilana iwa hihu rere, ti o jẹ aduroṣanṣan ninu isin Kristian tootọ, gẹgẹ bi Jesu ti fi kọni.

Lonii, ijiya ati aisi idajọ ododo jẹ apakan igbesi-aye ojoojumọ. Gẹgẹ bii ti awọn Bibelforscher ninu awọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, emi pẹlu ń wọ̀nà fun dide ayé ti o sanju, nibi ti ifẹ arakunrin ati idajọ ododo yoo ti gbodekan dipo iwa ipa ati ilepa onigboonara ẹhànnà. Ṣaaju ìgbà naa, mo ń gbiyanju lati ṣiṣẹsin Ọlọrun ati Kristi bi mo ti lè ṣe to gẹgẹ bi alagba kan ninu ijọ Kristian, papọ pẹlu aya mi, awọn ọmọ mi, ati awọn ọmọ-ọmọ mi.—Orin Dafidi 112:7, 8.—Bi René Séglat ti ṣe sọ ọ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Loke: Orukọ pípè ninu àgọ́ naa

Lapa òsì: Ẹnu ọna abawọle si Buchenwald. Akọle naa kà pe: “Fun olukuluku bi o ti tọ́ si i”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Loke: Ibi ìfiná sun oku ni Buchenwald

Lapa òsì: Ẹlẹwọn 16 fun ìpín kọọkan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́