Báwo Ni Ìwàláàyè Ṣe Ṣeyebíye fún Ọ Tó?
Ọ̀DỌ́MỌDÉKÙNRIN kan ṣekúpa ara rẹ̀ nígbà tí ó bẹ́ sílẹ̀ láti àjà kẹjọ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì nínú ilé kan tí ó ní àwọn ibùgbé àdáni. Ó ti ka ìwé tí ó ṣàpèjúwe pé bíbẹ́ sílẹ̀ láti ibi gíga “kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìrora tàbí àìfararọ tàbí ìbẹ̀rù; kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń gbádùnmọ́ni.” Ẹni tí ó kọ ìwé tí a tẹ̀jáde ní Japan yìí, sọ pé òun wulẹ̀ ń dábàá “ìfọwọ́ ara-ẹni pa ara-ẹni gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn yíyàn tí ń bẹ nínú ìgbésí-ayé ni.”
Kì í ṣe kìkì àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn pa ara wọn ni wọ́n ṣàìka ìwàláàyè sí lónìí. Àwọn tí ń wakọ̀ níwàkiwà pẹ̀lú ń fi ọ̀wọ̀ tí kò tó nǹkan hàn fún ìwàláàyè. Àwọn kan tilẹ̀ ń mutí wakọ̀, ọ̀pọ̀ ń ṣínábolẹ̀ lójú títì tí wọ́n sì ń ṣekúpa ara wọn.
Àwọn mìíràn ń fi bí wọ́n ṣe kó iyán ìwàláàyè wọn kéré tó hàn nípa ìtẹnumọ́ tí wọ́n gbékarí ìgbádùn. Àwọn amusìgá kọ̀ láti dáwọ́ sìgá mímu dúró, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé sìgá mímu lè fa ikú tí a sì ti pè é ní ikú ayọ́kẹ́lẹ́ pani. Kàkà tí wọn ìbá fi pa ìwà-ní-mímọ́ mọ́ nínú ayé tí ìbálòpọ̀ ń sínníwín yìí, ọ̀pọ̀ ń lépa àti máa ṣe ìṣekúṣe tí ó sábà máa ń yọrísí ikú.
Láìtilẹ̀ mọ̀ rárá, àwọn kan ń fi ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè du ara wọn nípa àjẹjù, àmujù, eré ìmárale tí kò tó, àti wíwá ìgbádùn. Òǹkọ̀wé ilẹ̀ Japan náà Shinya Nishimaru kìlọ̀ pé: “Àṣà oúnjẹ jíjẹ tí kò ní ìdiwọ̀n kì í jẹ́ kí ètò-inú ara ṣiṣẹ́ déédéé, bẹ́ẹ̀ sì ni ìlépa ìrọ̀rùn àti ìgbádùn nìkan ṣáá ń sọ àwọn ènìyàn di aláìlókun nínú.” Àwọn kan ní ojú-ìwòye kan náà pẹ̀lú àwọn ará ìgbàanì tí wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu; nítorí ọ̀la ni àwa óò kú.”—Isaiah 22:13; 1 Korinti 15:32, NW.
Bẹ́ẹ̀ni, àìka ìwàláàyè sí ti gbilẹ̀ káàkiri lónìí. Nítorí náà, ó yẹ láti béèrè pé, Báwo ni ìwàláàyè ṣe ṣeyebíye fún ọ tó? Ó ha yẹ kí a pa ìwàláàyè mọ́ ní àforí-àfọrùn bí? Ohunkóhun ha sì wà tí ó ṣeyebíye ju ìwàláàyè wa ìsinsìnyí lọ bí?