Ka Ìyè Tòótọ́ Gidi Sí Ìṣúra
ÌGBÉSÍ-AYÉ yìí ha ni gbogbo ohun tí ó wà bí? Nípa fífún wa ní ìṣírí láti “di ìyè tòótọ́ gidi mú gírígírí,” Bibeli ń fihàn pé púpọ̀ síi wà. (1 Timoteu 6:17-19, NW) Bí ìwàláàyè wa ti ìsinsìnyí kì í bá ṣe ìyè tòótọ́ gidi, èwo wá ni?
Àyíká ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí a mẹ́nukàn lókè yìí fihàn pé “ìyè àìnípẹ̀kun” ni ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun níláti dì mú gírígírí. (1 Timoteu 6:12, NW) Fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rẹpẹtẹ, èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀-ayé. Adamu, ọkùnrin àkọ́kọ́, ní ìrètí gbígbé títí láé nínú paradise lórí ilẹ̀-ayé. (Genesisi 1:26, 27) Òun yóò kú kìkì bí ó bá jẹ nínú “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” (Genesisi 2:17) Ṣùgbọ́n nítorí pé Adamu àti aya rẹ̀, Efa, fi àìgbọràn jẹ nínú igi náà, Ọlọrun kéde ìdájọ́ ikú. ‘Ní ọjọ́ tí wọ́n jẹ nínú rẹ̀,’ wọ́n kú ní ojú-ìwòye Ọlọrun wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìṣubú wọn sínú ikú ti ara. Ìgbésí-ayé wọn kò tún jẹ́ ojúlówó mọ́ bí irú èyí tí wọ́n ti kọ́kọ́ gbádùn.
Ọ̀nà sí “Ìyè Tòótọ́ Gidi”
Nítorí àtilè mú kí “ìyè tòótọ́ gidi” ṣeé ṣe, Jehofa Ọlọrun ṣètò láti gba aráyé là. Láti ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìṣètò yìí, ẹ jẹ́ kí a ronú nípa ilé-iṣẹ́ kékeré kan. Gbogbo ẹ̀rọ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ti yọnu wọ́n sì ń fa ìṣòro fún àwọn tí ń lò wọ́n nítorí pé òṣìṣẹ́ tí ó kọ́kọ́ lo ẹ̀rọ náà ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kò náání ìwé atọ́nà ẹni tí ó ṣe ẹ̀rọ náà ó sì ba gbogbo ẹ̀rọ náà jẹ́. Gbogbo ohun tí àwọn tí yóò máa lo àwọn ẹ̀rọ náà lónìí lè ṣe kò ju pé kí wọ́n sa gbogbo agbára wọn láti lo ohun tí ó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn. Ẹni tí ó ni ilé-iṣẹ́ náà fẹ́ láti tún àwọn ẹ̀rọ náà ṣe láti ran àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì ń ya owó-àkànlò tí ó pọndandan fún ète yẹn sọ́tọ̀.
Ẹni àkọ́kọ́ ‘tí ó lo ẹ̀rọ náà,’ Adamu, kò ka ìwàláàyè tí a fifún un sí ìṣúra. Nítorí náà, ó ta àtaré ìwàláàyè aláìpé sí àwọn ọmọ rẹ̀, èyí tí ó dọ́gba pẹ̀lú ẹ̀rọ kan tí kò ṣiṣẹ́ dáradára. (Romu 5:12) Bíi ti àwọn tí wọ́n fi ẹ̀rọ tí ń bẹ nínú ilé-iṣẹ́ náà ṣiṣẹ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tí wọn kò lè rí ojútùú sí ipò ọ̀ràn náà, kò ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Adamu láti jèrè ìyè tòótọ́ gidi fún ara wọn. (Orin Dafidi 49:7) Láti ṣàtúnṣe ipò tí ó dàbí èyí tí ń múni sọ̀rètínù yìí, Jehofa rán Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo wá sórí ilẹ̀-ayé láti ra ìyè àìnípẹ̀kun padà fún aráyé. (Luku 1:35; 1 Peteru 1:18, 19) Nípa kíkú ikú ìrúbọ nítorí aráyé, Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo ti Ọlọrun, Jesu Kristi, pèsè owó náà—ìwàláàyè tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí tí Adamu sọnù. (Matteu 20:28; 1 Peteru 2:22) Pẹ̀lú ẹbọ ṣíṣeyebíye yìí, Jehofa ní ìdí fún pípèsè ìyè tòótọ́ gidi náà.
Fún aráyé onígbọràn, ẹbọ ìràpadà Jesu yóò túmọ̀ sí ìyè ayérayé nínú paradise orí ilẹ̀-ayé. (Orin Dafidi 37:29) Ìrètí yìí ní a nasẹ̀ rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n bá la “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olódùmarè,” tí a pè ní Har–Magedoni já. (Ìṣípayá 16:14-16, NW) Yóò pa gbogbo ìwà burúkú rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀-ayé. (Orin Dafidi 37:9-11) Àwọn tí Ọlọrun pa mọ́ sínú iyè-ìrántí rẹ̀ tí wọ́n kú ṣáájú àkókò yẹn ni a óò jí dìde sínú Paradise tí a mú padàbọ̀sípò lórí ilẹ̀-ayé wọn yóò sì ní ìrètí gbígbádùn ìyè tòótọ́ gidi tí ó wà ní ìpamọ́ fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Ọlọrun.—Johannu 5:28, 29.
Ó Yẹ Kí A Ṣìkẹ́ Ìwàláàyè Wa ti Ìsinsìnyí
Èyí kò túmọ̀ sí pé a lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ṣàìka ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè wa ti ìsinsìnyí sí. Ẹni tí ó ni ilé-iṣẹ́ náà yóò ha lo àkókò àti owó láti tún ẹ̀rọ náà ṣe fún òṣìṣẹ́ kan tí kò bójútó o bí? Kàkà bẹ́ẹ̀, agbanisíṣẹ́ náà kì yóò ha fi ẹ̀rọ tí a túnṣe náà sí ìkáwọ́ ẹnì kan tí ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti lo ẹ̀rọ ti àkọ́kọ́ dáradára bí?
Ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́mìí ìṣoore tí ẹ̀bùn náà ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, ó fẹ́ kí a ṣìkẹ́ rẹ̀. (Orin Dafidi 36:9; Jakọbu 1:17) Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa àníyàn tí Jehofa ní fún àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé, Jesu wí pé: “Awọn irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn.” (Luku 12:7, NW) Jehofa pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israeli láti máṣe pànìyàn, èyí tí a lè retí pé ó wémọ́ ṣíṣàì fi ọwọ́ ara-ẹni pa ara-ẹni. (Eksodu 20:13) Èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún wíwo ìfọwọ́ ara-ẹni pa ara-ẹni gẹ́gẹ́ bíi yíyàn kan.
Bí wọ́n ti mọ̀ pé Jehofa lọ́kàn-ìfẹ́ sí ire wa, àwọn olùbẹ̀rù Ọlọrun ń lo àwọn ìlànà Bibeli láti díwọ̀n àwọn àṣà òde-ìwòyí. Fún àpẹẹrẹ, nítorí pé a béèrè pé kí àwọn Kristian tòótọ́ ‘wẹ ara wọn mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran-ara ati ti ẹ̀mí, kí wọ́n sì máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé ninu ìbẹ̀rù Ọlọrun,’ wọ́n yẹra fún tábà àti àwọn oògùn tí ń yínilọ́kànpadà tí ó lè di bárakú.—2 Korinti 7:1, NW.
Ọkàn-ìfẹ́ Ọlọrun nínú ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn ni a tún rí síwájú síi nínú ìmọ̀ràn rẹ̀ pé kí a pa “àyà tí ó yè korokoro” mọ́ kí a sì yẹra fún ìwà pálapàla. (Owe 14:30; Galatia 5:19-21) Nípa dídìrọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga wọ̀nyí, a ń pa wá mọ́ kúrò nínú àwọn nǹkan bí ìhónú tí ń ṣàkóbá fún ìlera àti àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré.
Bí Jehofa ṣe ń ṣàníyàn tó nípa ìwàláàyè àwọn ènìyàn rẹ̀ tún ṣe kedere nínú ìṣílétí rẹ̀ pé kí wọ́n yẹra fún àjẹjù àti àmujù. (Deuteronomi 21:18-21; Owe 23:20, 21) A kìlọ̀ fún àwọn Kristian pé àwọn oníwọra àti ọ̀mùtípara kì yóò jogún Ìjọba Ọlọrun, ìyẹn ni pé, wọn kì yóò gbádùn ìyè tòótọ́ gidi náà láé. (1 Korinti 6:9, 10; 1 Peteru 4:3) Nípa fífúnni ní ìṣírí láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, Jehofa ń kọ́ wa láti ṣe ara wa ní àǹfààní.—Isaiah 48:17.
Nígbà tí a bá ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun, a ń fihàn pé a ka ìwàláàyè wa ti ìsinsìnyí sí ìṣúra. Àmọ́ ṣáá o, ìyè tòótọ́ gidi ni ó tilẹ̀ ṣe pàtàkì jù. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ àìnípẹ̀kun, àwọn Kristian tòótọ́ so ìjẹ́pàtàkì púpọ̀ mọ́ ọn ju ìwàláàyè wọn ti ìsinsìnyí lọ. Nígbà tí Jesu Kristi fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ, ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ṣíṣe ìfẹ́-inú Jehofa. Ìgbọràn sí Bàbá rẹ̀ ṣe pàtàkì fún un lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé níhìn-ín lọ. Ọ̀nà tí Jesu tọ̀ yọrí sí àjíǹde rẹ̀ àti gbígbà tí ó gba ìwàláàyè àìlèkú nínú ọ̀run. (Romu 6:9) Ikú rẹ̀ tún túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun fún aráyé onígbọràn tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀.—Heberu 5:8, 9; 12:2.
Òfin Ṣíṣekókó Lórí Ẹ̀jẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè lóye, àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu fi ọ̀nà ìrònú rẹ̀ hàn. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn nínú ohun gbogbo, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe. Ohun kan ni pé, èyí ṣàlàyé ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi kọ ìfàjẹ̀sínilára, èyí tí àwọn dókítà kan pè ní agbẹ̀mílà. Ẹ jẹ́ kí a wo bí ẹnì kan ṣe lè fihàn pé òun ka ìyè tòótọ́ gidi sí ìṣúra nípa kíkọ ìfàjẹ̀sínilára.
Bíi ti Jesu Kristi, àwọn Kristian tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ ọkàn láti wàláàyè lójú Ọlọrun, ìyẹn sì béèrè fún ìgbọràn pátápátá sí I. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi pé: ‘Ẹ máa takété sí awọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà ati sí ẹ̀jẹ̀ ati sí ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa ati sí àgbèrè.’ (Iṣe 15:28, 29, NW) Èéṣe tí òfin nípa ẹ̀jẹ̀ yìí fi wà lára àwọn àṣẹ tí àwọn Kristian gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí?
Òfin tí a fifún àwọn ọmọ Israeli béèrè fún títakété sí ẹ̀jẹ̀. (Lefitiku 17:13, 14) Àwọn Kristian kò sí lábẹ́ Òfin Mose. Ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé àṣẹ náà láti máṣe jẹ ẹ̀jẹ̀ ti wà ṣáájú Òfin; a ti kọ́kọ́ fifún Noa lẹ́yìn Àkúnya náà. (Genesisi 9:3, 4; Kolosse 2:13, 14) Àṣẹ yìí kan gbogbo àwọn ọmọ Noa, àwọn ẹni tí gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀-ayé ti ọ̀dọ̀ wọn ṣẹ̀ wá. (Genesisi 10:32) Ní àfikún, Òfin Mose ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìdí tí Ọlọrun fi tẹpẹlẹ mọ́ ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀. Lẹ́yìn kíkà á léèwọ̀ fún àwọn ọmọ Israeli láti máṣe jẹ irú ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí, Ọlọrun wí pé: “Ẹ̀mí ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀: èmi sì ti fi í fún yín láti máa fi ṣètùtù fún ọkàn yín lórí pẹpẹ nì: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ní í ṣe ètùtù fún ọkàn.” (Lefitiku 17:11) Ọlọrun ya ẹ̀jẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìrúbọ lórí pẹpẹ. Òfin rẹ̀ lórí ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ ṣípayá ọlá-àṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé pátá. (Esekieli 18:4; Ìṣípayá 4:11) Bí a bá fi ojú-ìwòye Jehofa wo ìwàláàyè wa, a óò rí i pé kì í ṣe tiwa ṣùgbọ́n pé Ọlọrun wulẹ̀ fi í sí ìkáwọ́ wa ni.
Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ẹni tí ń lo ẹ̀rọ nínú àkàwé wa ní ẹ̀rọ kan ní ìkáwọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a fi ìwàláàyè wa ti ìsinsìnyí sí ìkáwọ́ wa. Kí ni ìwọ yóò ṣe bí ẹ̀rọ rẹ bá nílò àtúnṣe tí atẹ́rọṣe sì dámọ̀ràn pé kí o tún un ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà ara ẹ̀rọ tí a dìídì kàléèwọ̀ nínú ìwé atọ́nà fún lílo ẹ̀rọ náà? Ìwọ kì yóò ha tọ àwọn atẹ́rọṣe mìíràn lọ láti rí i bí wọ́n bá lè tún ẹ̀rọ náà ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìtọ́ni inú ìwé atọ́nà fún títún ẹ̀rọ náà ṣe bí? Ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀ ó sì díjú ju ẹ̀rọ kan lọ. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a mísí, ìwé atọ́nà fún mímú kí àwọn ènìyàn máa wàláàyè nìṣó, Olùṣẹ̀dá wa ka lílo ẹ̀jẹ̀ láti gbé ìwàláàyè ró léèwọ̀. (Deuteronomi 32:46, 47; Filippi 2:16) Kò ha bọ́gbọ́nmu láti faramọ́ àwọn ohun tí ìwé atọ́nà náà béèrè fún bí?
Nítòótọ́, kì í ṣe pé àwọn Kristian tí ń ṣàìsàn, tí wọ́n béèrè pé kí a bójútó ọ̀ràn tiwọn láìlo ẹ̀jẹ̀ ń kọ gbogbo ìtọ́jú ìṣègùn. Wọ́n wulẹ̀ ń béèrè fún ìtọ́jú tí yóò fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìwàláàyè wọn—ti ìsinsìnyí àti ti ọjọ́-iwájú ni. Àwọn dókítà tí wọ́n fi tìgboyà-tìgboyà bọ̀wọ̀ fún ìdúró tí àwọn Kristian mú ń jẹ́rìí sí àwọn àǹfààní títọ́jú wọn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n bá béèrè fún. Oníṣẹ́-abẹ kan tí ń fa ẹ̀jẹ̀ síni lára lọ́pọ̀ ìgbà sọ pé: “Bíbá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pàdé ti sún mi láti ní ọ̀wọ́ àwọn ìlànà titun.” Ní báyìí ó ti ń gbìyànjú láti ṣètọ́jú àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí pàápàá láìlo ẹ̀jẹ̀.
Kíka Ìyè Tòótọ́ Gidi Sí Ìṣúra
Kí ni ọ̀wọ́ àwọn ìlànà titun tí oníṣẹ́-abẹ yìí rí nípasẹ̀ títọ́jú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? Ó ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé ohun tí ó wémọ́ títọ́jú aláìsàn kan kò níí ṣe pẹ̀lú apá ibi tí ń ṣàìsàn nínú ara nìkan bíkòṣe pẹ̀lú ẹni náà látòkèdélẹ̀. Kì yóò ha jẹ́ ohun yíyẹ pé kí a yọ̀ọ̀da fún aláìsàn kan láti béèrè fún ìtọ́jú tí ó dára jùlọ fún ire ara rẹ̀ níti ara ìyára, nípa tẹ̀mí, àti nípa ti èrò ìmọ̀lára?
Níti Kumiko ẹni ọdún 15, fífi ìfàjẹ̀sínilára ṣètọ́jú àrùn leukemia rẹ̀ tí ó lè ṣekú pa á ni yíyàn bíburú jùlọ kanṣoṣo tí ó wà. Gbígbìyànjú láti mú ẹ̀mí rẹ̀ gùn síi lọ́nà yìí fún ìwọ̀nba ọ̀sẹ̀, oṣù, tàbí ọdún mélòókan síi pàápàá kò tó ohun tí yóò ná an lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Níwọ̀n bí ó ti ya ìgbésí-ayé rẹ̀ ti ìsinsìnyí sí mímọ́ fún Jehofa Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, ó bọ̀wọ̀ fún ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá rẹ̀ àti àwọn ìbátan mìíràn tako ìdúró rẹ̀ gidigidi, Kumiko dúró gbọnyin-gbọnyin. Dókítà rẹ̀ bi í nígbà kan rí pé: “Bí Ọlọrun rẹ bá ń dárí ìkùnà jini, òun kì yóò ha dáríjì ọ́ bí o bá tilẹ̀ gba ẹ̀jẹ̀ sára?” Kumiko kọ̀ láti juwọ́sílẹ̀ kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí a gbékarí Bibeli sílẹ̀. Ó mú ìdúró rẹ̀, ‘nípa dídi ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.’ (Filippi 2:16, NW) Gẹ́gẹ́ bí ìyá bàbá rẹ̀ tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ti sọ, “Kumiko kò jẹ́ pa ìgbàgbọ́ rẹ̀ tì.” Láìpẹ́ ìṣarasíhùwà bàbá àti ìyá bàbá rẹ̀ àti ti dókítà tí ń tọ́jú rẹ̀ yípadà.
Ìgbàgbọ́ lílágbára tí Kumiko ní nínú Jehofa Ọlọrun, tí ó lè jí i dìde nínú ikú, ru ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn sókè. Nígbà tí ó ṣì wàláàyè, ó pàrọwà fún bàbá rẹ̀ pé: “Àní bí mo ba tilẹ̀ kú, a óò jí mi dìde nínú Paradise. Ṣùgbọ́n bí ẹ ba parun ní Har–Magedoni, èmi kì yóò rí yín. Nítorí náà ẹ jọ̀wọ́ ẹ kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.” Bàbá rẹ̀ ṣáà ń sọ pé: “Nígbà tí ara rẹ bá yá, èmi yóò ṣe bẹ́ẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí Kumiko kú nítorí àmódi rẹ̀ tí kò mọ́wọ́dúró, bàbá rẹ̀ fi àkọsílẹ̀ kúkúrú kan sínú pósí rẹ̀ tí ó kà pé: “Èmi yóò rí ọ ní Paradise, Kumiko.” Lẹ́yìn ètò ìsìnkú náà, ó bá àwọn tí wọ́n wá síbi ìsìnkú náà sọ̀rọ̀ ó sì wí pé: “Mo ṣèlérí fún Kumiko pé èmi yóò rí i ní Paradise. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tì í gbà á gbọ́ nítorí pé èmi kò tí ì kẹ́kọ̀ọ́ tó, mo sì ti pinnu láti farabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ràn mí lọ́wọ́.” Àwọn mìíràn pẹ̀lú nínú ìdílé rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
Kumiko ní ọ̀wọ̀ tòótọ́ fún ìwàláàyè ó sì fẹ́ láti wàláàyè. Ó mọrírì gbogbo ohun tí àwọn dókítà rẹ̀ ṣe láti gba ìwàláàyè rẹ̀ ti ìsinsìnyí là. Bí ó ti wù kí ó rí, nípa ṣíṣègbọràn sí ìwé atọ́nà tí ó jẹ́ ti Ẹlẹ́dàá, ó fi ẹ̀rí hàn pé òun ka ìyè tòótọ́ gidi sí ìṣúra. Fún àràádọ́ta-ọ̀kẹ́, ìyẹn yóò túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú paradise orí ilẹ̀-ayé. Ìwọ yóò ha wà lára wọn bí?