ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 7/1 ojú ìwé 3-4
  • “Kí Ni Òtítọ́?”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Kí Ni Òtítọ́?”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbu Ẹnu Àtẹ́ Lu Òtítọ́
  • Àṣà Ojú-Ìwòye Èyí-Wù-Mí-Ò-Wù-Ọ́
  • Ta Ni Pọ́ńtíù Pílátù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Èéṣe Tí A Fi Ń Wá Òtítọ́ Kiri?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Lati Ọ̀dọ̀ Pilatu Sọdọ Hẹrọdu A sì Tún Rán an Pada
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Pílátù àti Hẹ́rọ́dù Rí I Pé Jésù Ò Jẹ̀bi
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 7/1 ojú ìwé 3-4

“Kí Ni Òtítọ́?”

ÀWỌN ọkùnrin méjì tí wọ́n dojúkọ ara wọn yàtọ̀ gédégbé sí ara wọn. Ọ̀kan jẹ́ òṣèlú tí ó jẹ́ afòfíntótó ṣàríwísí, olùlépa àṣeyọrí, ọlọ́rọ̀, ẹni tí ó ṣetán láti ṣe ohunkóhun láti mú ìtẹ̀síwájú bá iṣẹ́ ìgbésí-ayé rẹ̀. Èkejì jẹ́ olùkọ́ni tí ó kọ ọrọ̀ àti ipò-ọlá sílẹ̀ tẹ̀gàntẹ̀gàn tí ó sì múratán láti fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ láti lè gba ẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn là. A kò ṣẹ̀ṣẹ̀ níláti máa sọ pé, ojú-ìwòye àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí kò dọ́gba! Lórí ọ̀ràn kan ní pàtàkì, wọ́n takora délẹ̀délẹ̀—ọ̀ràn òtítọ́.

Pontiu Pilatu àti Jesu Kristi ni àwọn ọkùnrin náà. Jesu dúró níwájú Pilatu gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn tí a dá lẹ́bi. Èéṣe? Jesu ṣàlàyé ìdí fún èyí—ní tòótọ́, ìdí náà gan-an tí òun fi wá sí orí ilẹ̀-ayé tí ó sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀—jálẹ̀ sí ohun kan: òtítọ́. Ó wí pé: “Nitori èyí ni a ṣe bí mi, nitori èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.”—Johannu 18:37.

Ìbéèrè tí ó yẹ fún àfiyèsí ni èsì Pilatu jẹ́: “Kí ni òtítọ́?” (Johannu 18:38) Ó ha fẹ́ ìdáhùn níti gidi bí? Bóyá ni. Jesu jẹ́ ẹnì kan tí ó lè dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí tí a bá fi òtítọ́-inú béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n kò dá Pilatu lóhùn. Bibeli sì sọ pé lẹ́yìn bíbéèrè ìbéèrè rẹ̀, Pilatu jáde kúrò nínú àkòdì àwọn àwùjọ láìjáfara. Ó ṣeé ṣe kí gómìnà Romu náà ti béèrè ìbéèrè náà pẹ̀lú ẹ̀mí àìgbàgbọ́ afòfíntótó ṣàríwísí, bíi ní sísọ pé, “Òtítọ́ kẹ̀? Kí ni ń jẹ́ bẹ́ẹ̀? Kò sí ohunkóhun tí ń jẹ́ bẹ́ẹ̀!”a

Ojú-ìwòye tàbítàbí tí Pilatu ní nípa òtítọ́ kò ṣàjèjì lónìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ pé èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ni òtítọ́ jẹ́—ní èdè mìíràn, ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ lójú ẹnì kan lè má jẹ́ òtítọ́ lójú ẹlòmíràn, kí méjèèjì baà lè “tọ̀nà.” Èrò-ìgbàgbọ́ yìí ti tànkálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan wà fún un—“ojú-ìwòye èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́.” Ojú tí o fi wo ọ̀ràn òtítọ́ ha nìyẹn bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó ha ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé o ti tẹ́wọ́gba ojú-ìwòye yìí láì gbé e yẹ̀wò dáradára bí? Àní bí o kò bá tí ì ṣe bẹ́ẹ̀, o ha mọ bí ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn yìí ti ṣe nípa ìdarí lórí ìgbésí-ayé rẹ tó bí?

Bíbu Ẹnu Àtẹ́ Lu Òtítọ́

Kò dájú pé Pontiu Pilatu ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó gbé ìbéèrè dìde sí èrò òtítọ́ pọ́ńbélé. Àwọn ọlọ́gbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn Griki kan nígbàanì sọ ẹ̀kọ́ irú àwọn iyèméjì bẹ́ẹ̀ di ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ìgbésí-ayé wọn! Ọ̀rúndún márùn-ún ṣáájú Pilatu, Parmenides (ẹni tí a ti kà sí baba-ìsàlẹ̀ fún ẹ̀kọ́ nípa ìrònú ti Europe) gbàgbọ́ pé ọwọ́ kò lè tó ìmọ̀ tòótọ́. Democritus, tí a kansáárá sí gẹ́gẹ́ bí “ẹni títóbi lọ́lá jùlọ nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn nígbàanì,” fi ìtẹnumọ́ kéde pé: “Òtítọ́ jinlẹ̀. . . . A kò mọ ohunkóhun dájú.” Ó ṣeé ṣe kí ẹni tí a bọ̀wọ̀ fún jùlọ nínú gbogbo wọn, Socrates, ti sọ pé gbogbo ohun tí òun mọ̀ dájú ni pé òun kò mọ ohunkóhun.

Ìbẹnu àtẹ́ lu èrò yìí pé a lè mọ òtítọ́ ti ń bá a nìṣó títí di ọjọ́ wa. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́gbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn kan sọ pé níwọ̀n bí ìmọ̀ ti ń dé ọ̀dọ̀ wa nípasẹ̀ òye ìmọ̀lára wa, èyí tí a lè tàn jẹ, kò sí ìmọ̀ tí a lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ó jẹ́ òtítọ́. René Descartes ọlọ́gbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn ọmọ ilẹ̀ France tí ó sì tún jẹ́ onímọ̀ ìṣirò pinnu láti ṣàyẹ̀wò gbogbo ohun tí òun rò pé òun mọ̀ dájúdájú. Ó pa gbogbo rẹ̀ tì àyàfi òtítọ́ kanṣoṣo tí òun rò pé a kò lè gbé ìbéèrè dìde sí ti: “Cogito ergo sum,” tàbí, “Mò ń ronú, nítorí náà mo wà.”

Àṣà Ojú-Ìwòye Èyí-Wù-Mí-Ò-Wù-Ọ́

Ojú-ìwòye èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ kò mọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn nìkan. Àwọn aṣáájú ìsìn ń fi kọ́ni, wọ́n ń gbìn ín síni lọ́kàn ní ilé-ẹ̀kọ́, àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn sì ń tàn án kálẹ̀. Bíṣọ́ọ̀bù Episcopal John S. Spong sọ ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn pé: “A gbọ́dọ̀ . . . kúrò lórí ríronú pé a ní òtítọ́ àti pé àwọn mìíràn gbọdọ̀ tẹ́wọ́gba ojú-ìwòye wa láti lè mọ̀ pé òtítọ́ pọ́ńbélé rékọjá ohun tí gbogbo wa lè lóye.” Ojú-ìwòye èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ti Spong, bíi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlùfáà lónìí, máa ń tètè pa àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli lórí ìwàhíhù tì láti lè fàyègba ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn ti “kóńkó jabele.” Fún àpẹẹrẹ, nínú ìsapá láti fi àwọn abẹ́yà kan náà lòpọ̀ “lọ́kàn balẹ̀” nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Episcopal, Spong kọ̀wé kan tí ó sọ pé aposteli Paulu jẹ́ abẹ́yà kan náà lòpọ̀!

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ ó dàbí ẹni pé ètò ilé-ẹ̀kọ́ ń mú irú ìrònú kan náà jáde. Allan Bloom kọ nínú ìwé rẹ̀ The Closing of the American Mind pé: “Ohun kan wà tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan lè mọ̀ dájú dáradára: ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ tí ń wọ yunifásítì ni ó gbàgbọ́ pé, tàbí ni ó sọ pé òun gbàgbọ́ pé, èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ni òtítọ́ jẹ́.” Bloom rí i pé bí òun bá pe ìgbàgbọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òun lórí ọ̀ràn yìí níjà, wọn yóò hùwàpadà pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, “bí ẹni pé òun ń gbé ìbéèrè dìde sí ìṣirò náà pè 2 + 2 = 4.”

Ìrònú kan náà ni a ń gbé lárugẹ ní àwọn ọ̀nà mìíràn tí kò lóǹkà. Fún àpẹẹrẹ, ó dàbí ẹni pé àwọn oníròyìn orí tẹlifíṣọ̀n àti ìwé agbéròyìnjáde máa ń ní ọkàn-ìfẹ́ sí pípa àwọn olùgbọ́ wọn lẹ́rìn-ín ju gbígbé òtítọ́ inú ìtàn kan kalẹ̀ lọ. Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n kan ni a ti túnṣe tàbí tún fíìmù rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti lè mú kí ó baà lè túbọ̀ di àrímáleèlọ. Ogun lílágbára síi ni a sì gbé dìde sí òtítọ́ nínú eré-ìnàjú. Ọ̀pá ìdiwọ̀n àti òtítọ́ ìwàhíhù tí àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn ni a ń wò ní gbogbogbòò gẹ́gẹ́ bí aláìbágbàmu mọ́ tí a sì máa ń fi ṣe ẹlẹ́yà ní tààràtà.

Àmọ́ ṣáá o, àwọn kan lè jiyàn pé púpọ̀ lára ojú-ìwòye èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ yìí ṣojú fún ọkàn tí ó ṣípayá ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ìyọrísí tí ó dára lórí ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Ṣùgbọ́n, ó ha rí bẹ́ẹ̀ níti tòótọ́ bí? Kí sì ni nípa ìyọrísí rẹ̀ lórí rẹ? O ha gbàgbọ́ pé èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ni òtítọ́ tàbí pé kò tilẹ̀ sí rárá? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, wíwá a lè dàbí fífi àkókò ṣòfò lójú tìrẹ. Irú ojú-ìwòye bẹ́ẹ̀ yóò ní ipa ìdarí lórí ọjọ́ ọ̀la rẹ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bibeli R. C. H. Lenski ti sọ, “ohùn tí” Pilatu “fi sọ̀rọ̀ jọ ti ẹni ayé kan tí ń fi ọ̀rọ̀ dágunlá tí ó sì tipa ìbéèrè rẹ̀ ní in lọ́kàn láti sọ pé ohunkóhun tí ó bá jẹmọ́ ti òtítọ́ ìsìn jẹ́ ìméfò tí kò níláárí.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́