ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 12/15 ojú ìwé 30
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Dídáríji Ara Yín Lẹ́nì Kíní Kejì’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • O Lè Jèrè Arákùnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 12/15 ojú ìwé 30

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ǹjẹ́ o ti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ dídùn inú rẹ láti rántí àwọn ohun tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:

◻ Kí ni àwọn ìbéèrè díẹ̀ tí àwọn Kristẹni méjì lè béèrè lọ́wọ́ ara wọn kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ronú fífẹ́ ara wọn sọ́nà?

Ǹjẹ́ ipò tẹ̀mí ẹni yìí àti ìfọkànsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run dá mi lójú? Ǹjẹ́ mo rò pé èmi àti ẹni yìí lè jọ máa sin Ọlọ́run títí ayé? Ǹjẹ́ a ti mọ ìwà ara wa dáadáa? Ǹjẹ́ ó dá mi lójú pé a ó lè gbé pa pọ̀ títí gbére? Ǹjẹ́ a mọ̀ nípa ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ti ṣe sẹ́yìn àti ipò tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa wà báyìí?—8/15, ojú ìwé 31.

◻ Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ilẹ̀ ayé”? (Mátíù 5:13)

Ohun tí Jésù ń sọ ni pé bí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run, yóò pa ìwàláàyè àwọn tó bá tẹ́tí sí wọn mọ́, tàbí kó gbà wọ́n là. Lóòótọ́, àwọn tó ń fi ọ̀rọ̀ Jésù sílò yóò rí ààbò kúrò nínú ìwà àti ipò tẹ̀mí tó ń dómùkẹ̀ nínú ayé.— 8/15, ojú ìwé 32.

◻ Báwo ni àwọn tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà ṣe lè yẹra fún ìdẹkùn ìṣekúṣe?

Bóo bá ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, ó dáa tóo bá lè yẹra fún dídá wà pẹ̀lú àfẹ́sọ́nà rẹ ní àwọn ipò tí kò yẹ. Ó dáa jù tí ẹ̀yin méjèèjì bá wà láàárín àwọn ẹlòmíràn tàbí ibi tí ojú ti lè tóo yín. Ẹ ṣọ́ra fún ọ̀nà tí ẹ gbà ń fi ìfẹ́ hàn sí ara yín, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan yín bọ̀wọ̀ fún ìmọ̀lára àti ẹ̀rí ọkàn ẹnì kejì rẹ̀.—9/1, ojú ìwé 17, 18.

◻ Kí ni òye?

Òye ni agbára àtiyẹ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn wò, kí a sì mọ bó ṣe rí nípa wíwo gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọn, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ lóye kókó náà. (Òwe 4:1)—9/15, ojú ìwé 13.

◻ Kí ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa lónìí?

Ká má fọ̀rọ̀ gùn, ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa ni pé ká fetí sí Ọmọ Rẹ̀, ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Mátíù 16:24; 1 Pétérù 2:21)—9/15, ojú ìwé 22.

◻ Kìkì àwọn wo ló lè ní àlàáfíà?

Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà,” kìkì àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ìlànà òdodo rẹ̀, ló lè ní àlàáfíà. (Róòmù 15:33)—10/1, ojú ìwé 11.

◻ Báwo ni Jósẹ́fù ṣe ní agbára láti hùwà rere, tó fi lè sọ fún ìyàwó Pọ́tífárì lójoojúmọ́ pé, òun ò ṣe?

Jósẹ́fù ka ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà sí pàtàkì ju ìgbádùn ìgbà díẹ̀ tí òun yóò rí. Ní àfikún sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò sí lábẹ́ òfin àtọ̀runwá, Jósẹ́fù lóye ìlànà ìwà rere dáadáa. (Jẹ́nẹ́sísì 39:9)—10/1, ojú ìwé 29.

◻ Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká múra tán láti dárí ji arákùnrin wa?

Báa ṣe ń retí pé kí Ọlọ́run máa dárí jì wá, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ṣe tán láti máa dárí ji àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 6:12, 14; Lúùkù 11:4)—10/15, ojú ìwé 17.

◻ Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Mátíù 18:15-17 ń tọ́ka sí, kí ló sì fi èyí hàn?

Ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù ní lọ́kàn jẹ́ èyí tó wúwo débi tó ti lè yọrí sí kíka oníwà àìtọ́ náà sí “ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Àwọn Júù kò jẹ́ bá àwọn Kèfèrí ṣe wọléwọ̀de, wọ́n sì máa ń yẹra fáwọn agbowó orí. Nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni Mátíù 18:15-17 ń ṣàlàyé nípa rẹ̀, kì í ṣe aáwọ̀ lásán láàárín ẹnì kan sẹ́nì kan tàbí ìwà àfojúdi tẹ́nì kan hù sí ọ tó mú ọkàn rẹ gbọgbẹ́, tóo lè dárí jì í, tàbí tóo lè gbàgbé ẹ̀. (Mátíù 18:21, 22)—10/15, ojú ìwé 19.

◻ Kí ni nínífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tòótọ́ ń béèrè?

Nínífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sún ẹnì kan láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó béèrè. (Sáàmù 119:97, 101, 105) Èyí ń béèrè ṣíṣàtúnṣe èrò àti ọ̀nà ìgbésí ayé ẹni ní gbogbo ìgbà.—11/1, ojú ìwé 14.

◻ Nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan táa ti rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà, kí la wá lè fi ta Ọba tó lọ́lá jù lọ, tó tún jẹ́ Afúnni-Ní-Ǹkan lọ́nà gíga lọ́lá náà lọ́rẹ?

Bíbélì fi hàn pé ẹ̀bùn dídára jù lọ tí a lè fún Jèhófà ni “ẹbọ ìyìn.” (Hébérù 13:15) Èé ṣe? Nítorí pé ẹbọ yìí ní í ṣe ní tààràtà pẹ̀lú gbígba ẹ̀mí là, èyí ló sì jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún Jèhófà ní àkókò òpin yìí. (Ìsíkíẹ́lì 18:23)—11/1, ojú ìwé 21.

◻ Kí ni Sólómọ́nì ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́ṣẹ́ màlúù”? (Oníwàásù 12:11)

Ọ̀rọ̀ àwọn ẹni tó ní ọgbọ́n Ọlọ́run máa ń gún ọkàn òǹkàwé tàbí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ ní kẹ́ṣẹ́, kó lè tẹ̀ síwájú ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tó ń kà tàbí tó ń gbọ́.—11/15, ojú ìwé 21.

◻ Kí ni ìfòyemọ̀ tí Ọlọ́run ń fúnni?

Ó jẹ́ agbára láti dá ohun tó tọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́, ká sì wá yan ọ̀nà tó tọ́. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífi í sílò ló ń fúnni ní ìfòyemọ̀.—11/15, ojú ìwé 25.

◻ Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní nígbà táa bá ń tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́? (2 Tímótì 3:1)

A gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kì í ṣe pé kí ẹnì kan wá gba ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀ sọ́wọ́ débi tí kò ní láyọ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lóòótọ́ la gbóríyìn fún ẹ̀mí tó múra tán láti ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ìmúratán tún gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti “ìyèkooro èrò inú” hàn. (Títù 2:12; Ìṣípayá 3:15, 16)—12/1, ojú ìwé 28.

◻ Báwo la ṣe lè kojú ìpèníjà títọ́ ọmọ?

Ọlọ́run fún àwọn òbí nímọ̀ràn láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere, alábàákẹ́gbẹ́, olùbánisọ̀rọ̀, àti olùkọ́. (Diutarónómì 6:6, 7)—12/1, ojú ìwé 32.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́