Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead Rán Àwọn Míṣọ́nnárì Lọ sí “Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé”
ÓTI lé ní àádọ́ta ọdún báyìí tí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ti ń rán míṣọ́nnárì jáde. Kíláàsì kẹtàdínláàádọ́fà ti ilé ẹ̀kọ́ yìí kẹ́kọ̀ọ́ yege ní September 11, 1999. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìdínláàádọ́ta tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè mọ́kànlá ló wà ní kíláàsì náà, a sì rán wọn lọ láti sìn ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn wọ̀nyí yóò dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn míṣọ́nnárì mìíràn, tí wọ́n ti kó ipa pàtàkì nínú mímú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kẹ́yìn kí ó tó gòkè lọ sọ́run ṣẹ. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun yóò “jẹ́ ẹlẹ́rìí [òun] . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà, tó wáyé ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ní Patterson, New York, jẹ́ ayẹyẹ kan tó kọ yọyọ ní àyíká ẹlẹ́wà náà. Inú àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà dùn gan-an láti rí àwọn ìbátan, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, àti àwọn àlejò níbẹ̀. Gbogbo àwọn tó pésẹ̀ títí kan àwọn tó ń gbélé gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lórí rédíò àtàwọn tó ń wò ó nínú fídíò tí a so pọ̀ mọ́ Brooklyn àti Wallkill jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó dín mẹ́jọ.
Fi Òtítọ́ Sin Jèhófà àti Aládùúgbò Rẹ
“Ta Ló Ń Ṣe Ti Jèhófà?” Ìyẹn ni àkòrí ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀ tí Carey Barber sọ, ẹni tó jẹ́ ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tó sì tún jẹ́ alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà. Ó ṣàlàyé pé kókó yìí ló dojú kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè. Ó rán àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege àtàwọn tó wà níbẹ̀ létí pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló pàdánù ìwàláàyè wọn nínú aginjù nítorí pé wọn ò ṣe ti Jèhófà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣubú sínú ìbọ̀rìṣà, wọ́n “jókòó láti jẹ àti láti mu. Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde láti gbádùn ara wọn.” (Ẹ́kísódù 32:1-29) Jésù kìlọ̀ nípa ewu kan náà fún àwọn Kristẹni, ó ní: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn.”—Lúùkù 21:34-36.
Ẹni tí ó sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e, ìyẹn Gene Smalley tó wà ní Ẹ̀ka Ìkọ̀wé, bi àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà pé: “Ṣé Ẹ Óò Jẹ́ Atura?” Ó ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, pa·re·go·riʹa jẹ́ èyí tí a gbà sínú èdè Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí orúkọ oògùn kan tó ń dín ìrora kù. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí nínú Kólósè 4:11, láti ṣàpèjúwe àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, a túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “àrànṣe afúnnilókun.”
Àwọn míṣọ́nnárì tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà lè di atura tòde òní lọ́nà kan tó gbéṣẹ́ gidigidi nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ di àrànṣe afúnnilókun fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ládùúgbò tí a yàn wọ́n sí, àti nípa fífi ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìfẹ́ hàn nínú ìbákẹ́gbẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wọn.
Daniel Sydlik, ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ló sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e, lórí kókó náà: “Òfin Oníwúrà Tó Yẹ Ká Máa Fi Gbé Ìgbésí Ayé.” Ó ṣàlàyé pé ìlànà gíga tí Jésù gbé kalẹ̀ nínú Mátíù 7:12, tó sọ pé, “gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn,” wé mọ́ híhùwà rere sí àwọn ẹlòmíràn, kì í ṣe pé kí a wulẹ̀ máa yẹra fún ohun tó lè pa wọ́n lára.
Láti ṣe èyí láṣeyọrí, ohun mẹ́ta la nílò: ojú tó lè tètè rí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, ọkàn tó lè báni kẹ́dùn, àti ọwọ́ tó ṣe tán láti ranni lọ́wọ́. Ní àkótán ó sọ pé: “Tí ọkàn wa bá sọ pé ká ran ẹnì kan lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe é ní kíámọ́sá. A gbọ́dọ̀ máa tiraka láti ṣe fún àwọn ẹlòmíràn bí a ti fẹ́ kí wọ́n ṣe fún wa.” Pàápàá jù lọ, èyí ṣe pàtàkì fún àwọn míṣọ́nnárì tó ń lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn láti lọ ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di Kristẹni tòótọ́.
Àwọn Olùkọ́ Sọ Ọ̀rọ̀ Ìránnilétí Tó Gbé Wọn Ró
Karl Adams, tó jẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gilead, fún àwọn míṣọ́nnárì tó ń ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà níṣìírí láti “Máa Dàgbà Sí I.” Lọ́nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ní láti dàgbà nínú ìmọ̀, kí wọ́n sì tún máa dàgbà sí i nínú mímọ bí wọn yóò ṣe lò ó dáadáa. Ní Gilead, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti kọ́ bí a ṣe ń ṣe ìwádìí láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì àti ohun tó fà á tí wọ́n fi wáyé. A ti rọ̀ wọ́n láti máa ronú lórí bó ṣe yẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan nípa lórí ìgbésí ayé wọn. A rọ̀ wọ́n láti máa ṣe èyí lọ.
“Èkejì, kí wọn máa dàgbà nínú ìfẹ́. Ìfẹ́ máa ń dàgbà sí i nígbà tí a bá ṣìkẹ́ rẹ̀. Tí a bá sì pa á tì, ó lè kú,” Arákùnrin Adams ló sọ bẹ́ẹ̀. (Fílípì 1:9) Wàyí o, gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, wọn ní láti dàgbà nínú ìfẹ́ lábẹ́ onírúurú ipò tó bá yọjú. Ẹ̀kẹ́ta: “Ẹ máa bá a lọ ní dídàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (2 Pétérù 3:18) Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Èyí ni àgbàyanu inú rere tí Jèhófà fi hàn nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. Bí ìmọrírì tí a ní fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yẹn ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni inú wa yóò túbọ̀ máa dùn láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àti ohun tí ó yàn fún wa láti ṣe.”
Ẹlòmíràn tó jẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gilead, Mark Noumair, sọ̀rọ̀ lórí àkòrí náà, “Bóo Bá Fìfẹ́ Gbà Á, Wàá Rí I Pé Ẹ̀mí Rẹ Gbé E.” Ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ kọ́ bí a ṣe ń fi ìfẹ́ kojú àwọn ipò tí ń peni níjà nínú ìgbésí ayé míṣọ́nnárì, yóò sì ṣeé ṣe fún yín láti fara dà á. Kìkì àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí. Kódà bí o bá rí i pé àwọn ìmọ̀ràn mú ẹ̀tanú lọ́wọ́, bóyá tó jọ pé a dójú sọni, tàbí tó ní ojúsàájú nínú, ìfẹ́ fún Jèhófà àti ìbátan rẹ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara mọ́ ọn.”
Arákùnrin Noumair là á mọ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ nínú. “Àmọ́ bíbójútó ẹrù iṣẹ́ kan láìsí ìfẹ́ kò ní fún ọ láyọ̀. Bí o kò bá fẹ́ràn àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́—bíi gbígbọ́únjẹ, rírajà, fífọ èso, síse omi—iṣẹ́ wọ̀nyí lè tètè sú ẹ. O lè sinmẹ̀dọ̀, kí o sì bi ara rẹ pé, ‘Èé ṣe tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Tóo bá wá sọ fún ara rẹ pé, ‘Ohun tí mo ń ṣe ń ṣàlékún ìlera àti ayọ̀ àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ mi,’ wàá rí i pé kò ní ṣòro fún ọ láti máa ṣe é lọ.” Ní àkópọ̀, ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Yálà ó jẹ́ ọ̀rọ̀ lórí gbígba ìbáwí ni o, bóyá lórí mímú ẹ̀jẹ́ míṣọ́nnárì rẹ ṣẹ ni o, tàbí bíbójútó àwọn èdè àìyedè, fífi ìfẹ́ gbà á yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ tí a yàn fún ọ nìṣó. ‘Ìfẹ́ kì í kùnà láé.’”—1 Kọ́ríńtì 13:8.
Wallace Liverance, tó jẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gilead ló bójú tó apá tó tẹ̀ lé e tó ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣe àṣefihàn àwọn ìrírí amárayágágá bíi mélòó kan tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn nígbà tí wọ́n bá àwọn ìjọ tó wà ládùúgbò ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ sí lílọ láti ilé dé ilé, wọ́n tún lo ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbà níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nnárì tí wọ́n wà láti wá àwọn ènìyàn lọ sí ibùdókọ̀, ibi tí wọ́n ti ń fọṣọ, ibùdó ọkọ̀ ojú irin, àti ibòmíràn gbogbo.
Àwọn Míṣọ́nnárì Tó Nírìírí Fi Wọ́n Lọ́kàn Balẹ̀
Nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì tuntun bá lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ kí wọ́n máa ṣàníyàn? Ṣé wọ́n lè kojú ìpèníjà ṣíṣe iṣẹ́ ní ilẹ́ òkèèrè? Kí ni a máa ń ṣe láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì láti ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí lọ́wọ́, kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí? Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àti àwọn mìíràn, Steven Lett, tó wà ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, àti David Splane, tó wà ní Ẹ̀ka Ìkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ wá àwọn arákùnrin tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn ìgbìmọ̀ ẹ̀ka tó ń lọ lọ́wọ́ ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower nígbà yẹn lẹ́nu wò. Àwọn arákùnrin náà tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ń sìn gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ ẹ̀ka ní Sípéènì, Hong Kong, Liberia, Benin, Madagascar, Brazil, àti Japan.
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti nírìírí wọ̀nyí, tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, fi ọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà balẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún fi àwọn òbí àti àwọn ìbátan tó wà níbẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀lú. Láti inú ìrírí tiwọn fúnra wọn àti ti àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n fi hàn pé kò sí bí ìṣòrò àti àníyàn ti lè pọ̀ tó, a ó borí ẹ̀. Raimo Kuokkanen, míṣọ́nnárì kan láti Madagascar, sọ pé, àwọn ìṣòro tí wọ́n lè dojú kọ lè pọ̀, “àmọ́ wọ́n ṣeé yanjú, Society ṣì máa ń ṣèrànwọ́.” Östen Gustavsson, tó ń sìn ní Brazil báyìí sọ pé: “A ò yan iṣẹ́ náà, ńṣe la gbà á. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti fara mọ́ ọn.” James Linton tó ń sìn ní Japan, sọ pé ohun tó ran òun lọ́wọ́ ni “àwọn arákùnrin tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ìyẹn ni àwọn tó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì níbi tí a yàn wọ́n sí.” Iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì jẹ́ ọ̀nà táa lè gbà sin Jèhófà, kí a sì tún bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀, iṣẹ́ ìsìn tó lè fún wa ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ni.
Yẹra fún Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Ń Pa Ipò Tẹ̀mí
Theodore Jaracz, ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tí òun fúnra rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege ni kíláàsì keje ti Gilead ní ọdún 1946, ló sọ ọ̀rọ̀ àsọparí, lórí kókó náà: “Ìpèníjà Náà Láti Máa Wà Láàyè Nípa Tẹ̀mí.” Lẹ́yìn tó kọ́kọ́ mẹ́nu kan ìwà ìkà bíburú jáì tó ń lọ láwọn ibi púpọ̀ lágbàáyé, ó wá tọ́ka sí i pé ní tòótọ́, lójoojúmọ́ ni àjálù burúkú ń já lu ìran ènìyàn.
Nígbà tí Arákùnrin Jaracz ń ṣàlàyé lé Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún lórí, ó sọ nípa “àjàkálẹ̀ àrùn” àti “ìparun” tó ti sọ ipò tẹ̀mí àwọn èèyàn dìdàkudà, tó sì ti pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ láyìíká wa. Èṣù àti ètò búburú rẹ̀ ti lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí táa lè fi wé àjàkálẹ̀ àrùn, ó gbé àwọn ọgbọ́n wọ̀nyí ka kíkó ìmọ̀ jọ àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, kí ó lè sọ ipò tẹ̀mí di ahẹrẹpẹ, kó sì pa á kú pátápátá, ṣùgbọ́n Jèhófà mú un dá wa lójú pé àwọn àrùn wọ̀nyí kò ní ran “ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ.”—Sáàmù 91:1-7.
Arákùnrin Jaracz sọ pé: “Ìpèníjà náà ni pé kí á máa jẹ́ onílera nínú ìgbàgbọ́ nígbà gbogbo, kí a rí i pé a wà níbi ààbò ní gbogbo ìgbà. A kò lè dà bí àwọn ẹlẹ́gàn ‘àwọn tí kò ní ohun tẹ̀mí.’ Ìṣòro kan lèyí jẹ́ lónìí. Ó jẹ́ ìṣòro kan tó dojú kọ gbogbo àwa táa wà nínú ètò yìí. Ó sì lè dojú kọ ìwọ náà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì rẹ.” (Júúdà 18, 19) Àmọ́, ó jẹ́ kó yé àwọn míṣọ́nnárì tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà pé wọ́n lè ṣàṣeyọrí nínú dídi ipò tẹ̀mí wọn mú lẹ́nu iṣẹ́ tí a yàn fún wọn. Fún àpẹẹrẹ, ó rọ̀ wọ́n láti ronú lórí bí àwọn ará wa ṣe ń fara dà á ní Rọ́ṣíà, ní Éṣíà, àti ní àwọn ilẹ̀ Áfíríkà—bó tilẹ̀ jẹ́ pé a fòfin dè wọ́n, tí à ń ṣe àtakò líle koko sí wọn, tí à ń fi wọ́n ṣẹ̀sín, tí àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ ń gbékèé yíde, táwọn kan sì ń fi ẹ̀sùn èké kàn wọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, àwọn ìṣòro táa lè rí kòrókòró máa ń pẹ̀lú rẹ̀, ìyẹn èyí tí ìjà láàárín ẹ̀yà kan sí èkejì àti àìtó àwọn ohun kòṣeémánìí máa ń fà.
Nígbà tí ìfàsẹ́yìn bá ti ń bá ipò tẹ̀mí ẹnì kan, “ó pọndandan láti wá ohun tó fa ìṣòro náà, kí a sì wá ọ̀nà láti yanjú ẹ̀ nípa lílo ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ó fún wọn ní àwọn àpẹẹrẹ láti inú Bíbélì. A rọ Jóṣúà láti máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka ẹ̀dà ìwé Òfin náà lójoojúmọ́. (Jóṣúà 1:8) Nígbà tí wọ́n rí ìwé òfin náà nígbà ayé Jòsáyà, inú Jèhófà sì dùn sí bí wọ́n ṣe tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nínú rẹ̀ délẹ̀délẹ̀. (2 Àwọn Ọba 23:2, 3) Àtìgbà ọmọdé jòjòló ni Tímótì ti mọ Ìwé Mímọ́. (2 Tímótì 3:14, 15) Kì í ṣe pé àwọn ará Bèróà ń fetí sílẹ̀ dáadáa nìkan ni; a tún kà wọ́n sí ‘ọlọ́kàn rere’ nítorí pé wọ́n ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́. (Ìṣe 17:10, 11) Táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa tó sì tẹ̀ lé e, Jésù Kristi lọ̀gá.—Mátíù 4:1-11.
Lákòótán, Arákùnrin Jaracz fìtara gba àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà níyànjú pé: “Ní báyìí, ẹ ti múra tán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì yín. Ẹ óò sì lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, ká sọ ọ́ ní ṣáńgílítí, ẹ̀ ń lọ sí ọ̀pọ̀ ibi tó yàtọ̀ síra lórí ilẹ̀ ayé. Bí a bá sì kojú ìpèníjà tó ní í ṣe pẹ̀lú wíwà láàyè nípa tẹ̀mí, nígbà náà a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun gba àfiyèsí wa kúrò nínú ohun tí a ti pinnu láti ṣe. Ẹ óò fi ìtara wàásù, ẹ óò sún àwọn mìíràn láti fara wé ìgbàgbọ́ yín, a ó sì máa bá yín gbàdúrà pé kí Jèhófà mú kí àwọn tí ẹ bá kọ́ mọ ìjẹ́pàtàkì ohun tí ẹ kọ́ wọn, bí ó ti mú kí àwa náà mọ̀ ọ́n. Nípa bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ ni àwọn tó ṣì máa bọ́ lọ́wọ́ àjálù nípa tẹ̀mí tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí jákèjádò ayé. Wọn ó dara pọ̀ mọ́ wa ní mímú kí iye àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà pọ̀ sí i. Kí Jèhófà sì ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.”
Lẹ́yìn tí alága ka àwọn ìkíni tó wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé, àkókò wá tó láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà ní ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà wọn. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n ka lẹ́tà ìwúrí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kọ láti fi ìmọrírì wọn hàn. Wọ́n mà fi ìmoore wọn hàn sí Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ o, fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n gbà, àti fún iṣẹ́ tí a yàn wọ́n sí gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì tó ń lọ sí “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé”!—Ìṣe 1:8.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Ìsọfúnni Nípa Kíláàsì
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 11
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 24
Iye akẹ́kọ̀ọ́: 48
Iye tọkọtaya: 24
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 34
Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 17
Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kíláàsì Kẹtàdínláàádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead
Ní ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí, a fi nọ́ńbà sí ìlà láti iwájú lọ sí ẹ̀yìn, a sì kọ orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan.
1. Peralta, C.; Hollenbeck, B.; Shaw, R.; Hassan, N.; Martin, D.; Hutchinson, A. 2. Edwards, L.; Vezer, T.; Ceruti, Q.; Entzminger, G.; D’Aloise, L.; Baglieri, L. 3. Knight, P.; Krause, A.; Kasuske, D.; Rose, M.; Friedl, K.; Nieto, R. 4. Rose, E.; Backus, T.; Talley, S.; Humbert, D.; Bernhardt, A.; Peralta, M. 5. D’Aloise, A.; Humbert, D.; Dunn, H.; Gatling, G.; Shaw, J.; Ceruti, M. 6. Baglieri, S.; Krause, J.; Hollenbeck, T.; Martin, M.; Bernhardt, J.; Hutchinson, M. 7. Backus, A.; Dunn, O.; Gatling, T.; Vezer, R.; Knight, P.; Hassan, O. 8. Nieto, C.; Talley, M.; Friedl, D.; Kasuske, A.; Edwards, J.; Entzminger, M.