Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù July
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 5
Orin 6
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá oṣù April lórílẹ̀-èdè yìí àti níjọ àdúgbò. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
20 min: “Máa Gbàdúrà fún Ìrànlọ́wọ́ Jèhófà.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì mú kí ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn tẹ̀ lé e. Ṣàlàyé bí onírúurú àdúrà àtọkànwá ṣe ń kó ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kẹ́sẹ járí. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìrírí tó fi hàn pé àdúrà tó bákòókò mu ti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.—Wo Ilé Ìṣọ́ October 15, 1996, ojú ìwé 32.
15 min: Lo Àwọn Àkànṣe Ìwé Ìfilọni Lọ́nà Rere. Àsọyé àti àwọn àṣefihàn. Ṣàlàyé ìdí táwọn ìtẹ̀jáde náà fi jẹ́ irinṣẹ́ tó ṣeyebíye nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Wọ́n ṣe àlàyé tó gbámúṣé nípa ọ̀kan-kò-jọ̀kan kókó tó fani mọ́ra, wọ́n sì ṣe àlàyé àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ lọ́nà rírọrùn. Fi èyí tí ẹ ní lọ́wọ́ hàn. Ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ráńpẹ́ méjì tàbí mẹ́ta táa gbé ka àwọn ìdámọ̀ràn tó wà lábẹ́ àkọlé náà “Presentations” [Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀] nínú Watch Tower Publications Index.
Orin 181 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 12
Orin 103
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: “Ìmúrasílẹ̀ Ń Máyọ̀ Wá.” Àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Ṣàlàyé ìdí tí ìmúrasílẹ̀ fi ṣe kókó fún iṣẹ́ ìsìn pápá àti bí ó ti ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ayọ̀ ńláǹlà nínú ohun tí à ń ṣe. (Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 39, ìpínrọ̀ 1 sí 3.) Fọ̀rọ̀ wá akéde méjì tàbí mẹ́ta tó dáńgájíá lẹ́nu wò, kí wọ́n sọ bí wọ́n ti ń múra sílẹ̀ kí wọ́n tó jáde iṣẹ́ ìsìn àti bí èyí ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Sọ ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́nà April 15, 1993, ojú ìwé 30, tó fi hàn pé ìwé Reasoning gbéṣẹ́ ní mímúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.
20 min: “Tètè Sọ Ohun Tóo Ní Í Sọ!” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti àwọn àṣefihàn. Ṣàyẹ̀wò ìdámọ̀ràn kọ̀ọ̀kan nípa ohun tí a ó sọ kí onílé lè fẹ́ láti gbọ́ wa. Kí àwọn akéde onírìírí ṣe àṣefihàn àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ mélòó kan tó gbéṣẹ́. Ké sí àwùjọ láti pèsè àfikún ìdámọ̀ràn, kí wọ́n sì sọ àwọn ìrírí tí ń fúnni níṣìírí, tó fi ohun tó gbéṣẹ́ ládùúgbò hàn.
Orin 183 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 19
Orin 31
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Fífi Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Kọ́ Àwọn Ọmọdé. Àsọyé látẹnu alàgbà. Láti àárọ̀ ọjọ́ ló ti yẹ káwọn ọmọ wa ti jẹ́ ògbóṣáṣá pẹ̀lú wa nínú iṣẹ́ ìsìn. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìrírí tí wọ́n bá ní yóò di ìpìlẹ̀ tó dúró sán-ún fún ìgbàgbọ́ àti ìtara wọn láwọn ọdún ẹ̀yìnwá ọ̀la. Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n fọwọ́ dan-in dan-in mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, kí wọ́n sì mọ̀wàáhù. Àwọn ọmọdé gbọ́dọ̀ yàgò fún ṣíṣe wọ́nranwọ̀nran; àkókò iṣẹ́ ìsìn kì í ṣàkókò eré ṣíṣe. Ohun tó dáa jù ni pé kí wọ́n bá àwọn àgbàlagbà ṣiṣẹ́. A ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti nípìn-ín nínú gbígbọ́rọ̀kalẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òye wọn. Ojúṣe àwọn òbí ni láti pèsè àbójútó; wọ́n gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti kọ́kọ́ ṣètò ẹni tí yóò bá wọn ṣiṣẹ́. Gbóríyìn fáwọn ọmọdé nígbà tí wọ́n bá ṣe dáadáa. Bàbá kan ṣe àṣefihàn bí ó ti ń múra ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá.
20 min: Ṣé Dandan Ni Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ètò Àjọ Kan? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka ìwé Reasoning, ojú ìwé 280 sí 284. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ṣalábàápàdé àwọn èèyàn tó tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ṣùgbọ́n tí wọ́n kórìíra “dídarapọ̀ mọ́” ètò ẹ̀sìn kan. Ṣàyẹ̀wò ìtumọ̀ “organization” [ètò àjọ], àti àwọn ànímọ́ méje táa lè fi dá ètò àjọ Jèhófà tó ṣeé fojú rí mọ̀. Ṣàlàyé ìdí tó fi yàtọ̀ sáwọn yòókù àti bí dídarapọ̀ mọ́ ọn ti ń mú àwọn ìbùkún tòótọ́ wá.
Orin 189 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 26
Orin 184
15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo àwọn ará létí pé kí wọ́n ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún oṣù July. Ṣe àgbéyẹ̀wò “Ṣé Wàá Lọ?”
10 min: Àpótí Ìbéèrè.
20 min: Ǹjẹ́ À Ń Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn jíròrò àwọn kókó kan látinú Ilé Ìṣọ́nà February 15, 1996, ojú ìwé 19 sí 22, pẹ̀lú ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tàbí méjì. Tẹnu mọ́ àwọn ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí a fi ní láti wá àwọn ẹni yíyẹ kàn nínú ìpínlẹ̀ wa, kí a sì sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 10:11) Àwọn wọ̀nyí ló ń mí ìmí ẹ̀dùn nítorí gbogbo ipò búburú tó lòdì sọ́nà Ọlọ́run, tí wọ́n ń rí láyìíká wọn, wọ́n sì fẹ́ wá Jèhófà kí ọjọ́ ìbínú rẹ̀ tó wọlé dé. (Ìsík. 9:4; Sef. 2:2, 3) Lára wọn ni ‘àwọn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.’ (Ìṣe 13:48) Iṣẹ́ táa gbé lé wa lọ́wọ́ ni láti máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn, ká máa kọ́ àwọn èèyàn ní gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ru ìfẹ́ àwọn táa ń bá pàdé sókè lẹ́nu iṣẹ́ ilé-dé-ilé, tàbí nígbà táa bá ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà, àti nínú ìjẹ́rìí lójú pópó, síbẹ̀síbẹ̀, ìgbà táa bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tẹ̀ lé e—ìyẹn, ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—là ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Tọ́ka sáwọn ìdámọ̀ràn tó gbéṣẹ́ nípa báa ṣe lè ṣe èyí.
Orin 14 àti àdúrà ìparí.