ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/05 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 9/05 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Àkíyèsí: Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, a ó ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan nígbà Àpéjọ Àgbègbè. Kí àwọn ìjọ ṣe àyípadà tó bá yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run.” Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, kí ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ẹ ó ṣe kẹ́yìn kẹ́ ẹ tó lọ sí àpéjọ náà láti tún sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìmọ̀ràn pàtàkì tó kan ìjọ yín nínú àkìbọnú ti oṣù yìí. Lẹ́yìn oṣù kan tàbí méjì tẹ́ ẹ bá ti ṣe àpéjọ àgbègbè yín, kẹ́ ẹ ya ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ìṣẹ́jú sọ́tọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn (ẹ sì lè lo apá tó jẹ́ ti àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ) láti fi ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú àpéjọ náà táwọn ará ti rí i pé ó wúlò fáwọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Apá àkànṣe tí yóò máa wáyé nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn wa yìí á máa fún wa láǹfààní láti ṣàlàyé bá a ṣe ń lo àwọn ohun tá a kọ́ ní àpéjọ àti bí wọ́n ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́nà tó túbọ̀ múná dóko.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 12

Orin 29

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù September sílẹ̀. Ẹ lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ September 15 àti Jí! October 8. (Lo àbá kẹta fún Jí! October 8.) Ẹ tún lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà. Jẹ́ kí alàgbà kan ṣe ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, kí ọ̀dọ́ kan sì ṣe ìkejì. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, pe àfiyèsí àwọn ará sí díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n lè rí kọ́ nínú ẹ̀.

15 min: “Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ.”a Ní kí àwùjọ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń ya àkókò sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ kí wọ́n bàa lè ka Bíbélì. Gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n lo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2005 lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé láti fi ṣètò ìgbòkègbodò tẹ̀mí wọn.

20 min: “Gbogbo Onírúurú Èèyàn La Ó Gbà Là.”b Jẹ́ kí àwọn ará rí bí wọ́n ṣe lè fi àwọn kókó náà sílò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín.

Orin 110 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 19

Orin 168

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì látinú lẹ́tà ẹ̀ka ọ́fíìsì, èyí tó wà lójú ìwé àkọ́kọ́ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.

20 min: Lílo Àwọn Ìwé Ìròyìn Láti Wàásù Ìhìn Rere. Lóṣù October, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Tó o bá bẹ̀rẹ̀ àsọyé náà, jíròrò àwọn àbá tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2005, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 3 sí 6. Àwọn àbá náà rèé: (1) Fi ìwé ìròyìn méjèèjì lọni pa pọ̀. (2) Máa ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí wàá fi máa lọ́wọ́ nínú pípín ìwé ìròyìn. (3) Pinnu iye ìwé ìròyìn tí wàá máa fi sóde lóṣooṣù. (4) Máa lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti fi àwọn ìwé ìròyìn lọni. (5) Máa lo àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́nà tó múná dóko. Jẹ́ kí àwọn ará rí bí wọ́n ṣe lè fi àwọn àbá wọ̀nyí sílò. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù yìí (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín) láti ṣàṣefihàn bá a ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ bá a bá ń lo Ilé Ìṣọ́ October 1 àti Jí! October 8. (Lo àbá kẹrin fún Jí! October 8.) Ẹ tún lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn bẹ́ ẹ bá fẹ́ lo àwọn ìwé ìròyìn náà. Láfikún sí ìyẹn, ẹ fojú dá àwọn àpilẹ̀kọ míì nínú ìwé ìròyìn náà, èyí táwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín, kẹ́ ẹ sì ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó bá ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ náà mu. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn apá tó gbámúṣé nínú ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà.

15 min: “Ẹ Máa Gbé Ara Yín Ró.”c Jẹ́ kí àwùjọ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe jàǹfààní nínú báwọn ẹlòmíì ṣe ń ṣàníyàn nípa wọn.

Orin 199 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 26

Orin 122

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ọrẹ tá à ń ṣe. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù September sílẹ̀.

30 min: “Ẹ Máa Gbé Jèhófà Lárugẹ Nínú Ìjọ Ńlá.”d Akọ̀wé ìjọ ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ní kí ìjọ yín lọ. Fi ìbéèrè àti ìdáhùn darí àwọn ìpínrọ̀ tá a kọ nọ́ńbà sí bá a ṣe máa ń ṣe nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ní kí arákùnrin kan tẹ́ ẹ ti sọ fún tẹ́lẹ̀ ka àwọn ìpínrọ̀ náà. Ṣàtúnyẹ̀wò àpótí tá a pè ní, “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè.”

Orin 8 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 3

Orin 54

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

18 min: “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jẹ́ ‘Onígbọràn Látọkànwá.’”e Bí àkókò bá ṣe wà sí, jẹ́ kí àwùjọ ṣàlàyé lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

22 min: “Ìsinsìnyí Ló Yẹ Ká Wàásù!”f Sọ fún aṣáájú ọ̀nà kan tàbí méjì pé kí wọ́n ṣàlàyé lórí àtúnṣe tí wọ́n ti ṣe kí wọ́n bàa lè ṣe aṣáájú ọ̀nà àtàwọn ìbùkún tí wọ́n ti rí gbà.

Orin 197 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́