ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/05 ojú ìwé 3-6
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2006

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2006
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Ìtọ́ni
  • ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 10/05 ojú ìwé 3-6

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2006

Ìtọ́ni

Ní ọdún 2006, ìtọ́ni tó tẹ̀ lé e yìí la ó lò bá a bá ń darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 2006.

IBI TÁ A TI MÚṢẸ́ JÁDE: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run [be-YR] àti Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè -Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ [yp-YR].

Kí ilé ẹ̀kọ́ yìí máa bẹ̀rẹ̀ LÁKÒÓKÒ pẹ̀lú orin, àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀, ká sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tó tẹ̀ lé e yìí:

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn tàbí alàgbà mìíràn tó tóótun ni kó máa sọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, èyí tá a mú látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Láwọn ìjọ tí alàgbà ò bá ti pọ̀ tó, a lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun.)

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí, kó sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú Ilé Ìṣọ́ tàbí ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kó fi ìṣẹ́jú mẹ́wàá sọ ọ̀rọ̀ ìtọ́ni yìí láìsí pé ó ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwùjọ. Kì í ṣe pé kí asọ̀rọ̀ náà kàn sọ̀rọ̀ lórí ibi tá a yàn fún un nìkan ni, ṣùgbọ́n ní pàtàkì, ó yẹ kó sọ ìwúlò kókó tó ń sọ̀rọ̀ lé lórí, kó sì tẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ni kó lò. A retí pé káwọn arákùnrin tó bá máa ṣe iṣẹ́ yìí rí i dájú pé àwọn kò kọjá àkókò tó yẹ kí wọ́n lò. A lè fún wọn nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́ bó bá yẹ.

ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTINÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Fún ìṣẹ́jú márùn-ún àkọ́kọ́, kí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ títóótun, tó máa ṣiṣẹ́ náà, ṣàlàyé bí Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ náà ṣe wúlò sí fún ìjọ. Ó lè sọ̀rọ̀ lórí apá èyíkéyìí lára Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ náà. Kì í wulẹ̀ ṣe pé kó kàn ṣe àkópọ̀ ibi tá a ní kó kà o. Ohun tí iṣẹ́ yìí wà fún ni láti jẹ́ kí àwùjọ lóye ìdí tí ọ̀rọ̀ tó ń sọ fi wúlò àti bó ṣe wúlò sí fún wọn. Kí asọ̀rọ̀ náà rí i dájú pé àlàyé òun kò kọjá ìṣẹ́jú márùn-ún. Kí ó wá lo ìṣẹ́jú márùn-ún tó kù láti fi gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwùjọ. Kí ó sọ pé kí àwùjọ sọ̀rọ̀ ṣókí (ní ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀) lórí ohun tí wọ́n gbádùn nínú Bíbélì kíkà náà àtàwọn àǹfààní rẹ̀. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ pé káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a yàn sí kíláàsì mìíràn máa lọ síbẹ̀.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KEJÌ: Ìṣẹ́jú mẹ́rin tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Arákùnrin ni ká máa jẹ́ kó ka ìwé náà. Kí akẹ́kọ̀ọ́ ka ibi tá a yàn fún un láìsí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ àsọparí. Bí ó bá ń ka ìwé Sáàmù, ó gbọ́dọ̀ ka àkọlé tó sábà máa ń wà níbẹ̀rẹ̀ orí kọ̀ọ̀kan, tó bá wà níbẹ̀rẹ̀ orí tá a yàn fún un. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lógún jù lọ ni bó ṣe máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kàwé dáadáa nípa ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí: kíkàwé lọ́nà tó yéni yékéyéké, jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ni lẹ́nu, títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dídánudúró bó ṣe yẹ àti sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dáni.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸTA: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Arábìnrin ni ká máa yan iṣẹ́ yìí fún. A lè yan ìgbékalẹ̀ kan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a fún ní iṣẹ́ yìí tàbí kí wọ́n fúnra wọn yan ọ̀kan lára ìgbékalẹ̀ tá a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 82 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a yàn fún un. Bí a kò bá kọ inú ìwé tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa láti lè mọ ohun tó máa sọ. Àwọn iṣẹ́ tá a kọ ibi tá a ti mú wọn jáde sí ni kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lógún jù lọ ni ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, bó ṣe mú kí onílé ronú lórí Ìwé Mímọ́ àti bó ṣe mú kó lóye àwọn kókó pàtàkì inú iṣẹ́ rẹ̀. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yan olùrànlọ́wọ́ kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸRIN: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Kí akẹ́kọ̀ọ́ tá a yan iṣẹ́ yìí fún sọ̀rọ̀ lórí kókó tá a yàn fún un. Bí a kò bá kọ ibi tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye pèsè láti lè mọ ohun tó máa sọ. Bá a bá yàn án fún arákùnrin, kó sọ ọ́ bí àsọyé nípa dídarí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó bá jẹ́ arábìnrin ni yóò bójú tó o, kí ó tẹ̀ lé ìtọ́ni tá a pèsè fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè gbé Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin fún arákùnrin nígbàkigbà tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé, bí a bá sàmì yìí (*) síwájú ẹṣin ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, àwọn arákùnrin ni ká yàn án fún kí wọ́n lè sọ ọ́ bí àsọyé.

ÀKÓKÒ: Kí akẹ́kọ̀ọ́ kankan má ṣe kọjá àkókò, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà má sì ṣe sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Ká fi ọgbọ́n dá Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì sí Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin dúró bí àkókò wọn bá ti pé. Bí àwọn arákùnrin tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ níbẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́, ìyẹn ọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní tàbí àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà bá kọjá àkókò, ká fún wọn nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́. Kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ rí i dájú pé àwọn kò kọjá àkókò. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ yìí látòkèdélẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta láìka orin àti àdúrà mọ́ ọn.

ÌMỌ̀RÀN: Ìṣẹ́jú kan. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ kò ní lò ju ìṣẹ́jú kan lọ lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan láti fi sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró lórí ohun kan nínú iṣẹ́ náà tó kíyè sí pé ó dára gan-an. Kì í ṣe pé kó kàn kí akẹ́kọ̀ọ́ pé “ó ṣeun,” kàkà bẹ́ẹ̀, kó ṣàlàyé àwọn ìdí pàtó tí ohun tó kíyè sí nínú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà fi wúlò. Bó bá kíyè sí i pé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan kù síbì kan, lẹ́yìn ìpàdé tàbí nígbà mìíràn, ó tún lè fún un nímọ̀ràn táá mú kó tẹ̀ síwájú.

OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN: Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè yan alàgbà kan tó tóótun, bó bá wà, láfikún sí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Bí àwọn alàgbà bá pọ̀ nínú ìjọ, a lè máa lo alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó tóótun lọ́dọọdún láti ṣe iṣẹ́ yìí. Ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn ni láti máa fún àwọn arákùnrin tó ń bójú tó Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní àti kókó pàtàkì látinú Bíbélì nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kó jẹ́ pé gbogbo ìgbà táwọn alàgbà bíi tiẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá bójú tó àwọn iṣẹ́ yìí ni yóò máa gbà wọ́n nímọ̀ràn.

ÌWÉ ÌMỌ̀RÀN Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Èyí wà nínú ìwé tá à ń lò fún ilé ẹ̀kọ́.

ÀTÚNYẸ̀WÒ ALÁFẸNUSỌ: Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Ní oṣù méjì-méjì, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò máa darí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ṣáájú èyí, a óò gbọ́ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà, bá a ṣe ṣàlàyé lókè. Àwọn kókó tá a jíròrò nínú ilé ẹ̀kọ́ láàárín oṣù méjì tó ṣáájú, títí kan ti ọ̀sẹ̀ yẹn gan-an ni àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ náà yóò dá lé lórí. Bí àpéjọ àyíká yín bá bọ́ sí ọ̀sẹ̀ àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ, ẹ sún àtúnyẹ̀wò náà (àti ìyókù nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sẹ̀ yẹn) sí ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé àpéjọ àyíká yín. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọ̀sẹ̀ yẹn ni kẹ́ ẹ sì lò ní àpéjọ àyíká. Bí alábòójútó àyíká yóò bá bẹ ìjọ yín wò ní ọ̀sẹ̀ tí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ bọ́ sí, orin, ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì tó wà fún ọ̀sẹ̀ yẹn ni kẹ́ ẹ lò. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìtọ́ni (tó máa tẹ̀ lé ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ) tó wà fún ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e ni kẹ́ ẹ sọ. Ní ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò yẹn, ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì tó wà fún ọ̀sẹ̀ yẹn lẹ máa gbọ́, lẹ́yìn náà lẹ ó wá ṣe àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ.

ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ

Jan. 2 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 29 sí 32 Orin 91

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jàǹfààní Lẹ́kùn-ún Rẹ́rẹ́ Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Ní Inú Dídùn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 2: 2 Kíróníkà 30:1-12

No. 3: Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Sọ̀rọ̀ Àlùfààṣá

No. 4: Báwo Lo Ṣe Lè Fi Hàn Pé O ‘Bọ̀wọ̀ Fáwọn Òbí Rẹ’ (yp-YR orí 1)

Jan. 9 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 33 sí 36 Orin 144

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Kíkàwé Lọ́nà Tó Tọ́ (be-YR ojú ìwé 83 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 1: 2 Kíróníkà—Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ẹ̀ (w85-YR 11/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: 2 Kíróníkà 34:1-11

No. 3: Ohun Tàwọn Òbí Àtàwọn Ọ̀dọ́ Lè Ṣe Kí Wọ́n Bàa Lè Gbọ́ra Wọn Yé (yp-YR orí 2 ojú ìwé 18 sí 19 àti 22 sí 25)

No. 4: Má Ṣe Tijú Láé Bó O Ṣe Ń Tẹ̀lé Ìlànà Bíbélì Lórí Ìwà Rere

Jan. 16 Bíbélì kíkà: Ẹ́sírà 1 sí 5 Orin 137

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bó O Ṣe Lè Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́ (be-YR ojú ìwé 84 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 85 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Jèhófà Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ!—Apá 1 (w86-YR 2/15 ojú ìwé 29)

No. 2: Ẹ́sírà 1:1-11

No. 3: Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Ní Ẹ̀rí Ọkàn Tó Dáa

No. 4: Ìdí Táwọn Ọ̀dọ́ Fi Gbọ́dọ̀ Máa Finú Han Àwọn Òbí Wọn (yp-YR orí 2 ìpínrọ̀ 20 sí 21)

Jan. 23 Bíbélì kíkà: Ẹ́sírà 6 sí 10 Orin 106

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Ketekete (be-YR ojú ìwé 86 ìpínrọ̀ 1 sí 6)

No. 1: Jèhófà Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ!—Apá 2 (w86-YR 2/15 ojú ìwé 30)

No. 2: Ẹ́sírà 6:1-12

No. 3: Ìdí Táwọn Òbí Kì Í Fi Í Fún Àwọn Ọmọ Wọn Lómìnira Pátápátá (yp-YR orí 3)

No. 4: aOjú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìgbéyàwó

Jan. 30 Bíbélì kíkà: Nehemáyà 1 sí 4 Orin 161

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Béèyàn Ṣe Lè Sọ̀rọ̀ Sókè Ketekete (be-YR ojú ìwé 87, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 88 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Ìjọsìn Tòótọ́ Yọ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun (Nehemáyà 1 sí 6) (w86-YR 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí 19)

No. 2: Nehemáyà 2:1-10

No. 3: Oríṣi Ààbò Tó Ṣe Pàtàkì Jù

No. 4: Béèyàn Ṣe Lè Wà ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ọmọ Ìyá Èèyàn (yp-YR orí 6)

Feb. 6 Bíbélì kíkà: Nehemáyà 5 sí 8 Orin 40

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Pípe Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Tọ́—Àwọn Kókó Tó Yẹ Kí O Gbé Yẹ̀ Wò (be-YR ojú ìwé 89 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 90 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́ (be-YR ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Nehemáyà 5:1-13

No. 3: Ìdí Tí Fífi Ilé Sílẹ̀ Ò Fi Lè Yanjú Ìṣòro (yp-YR orí 7)

No. 4: “Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-Àyà Rẹ” (Òwe 4:23)

Feb. 13 Bíbélì kíkà: Nehemáyà 9 sí 11 Orin 159

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Jáfáfá Sí I Nínú Bó O Ṣe Ń Pe Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 90 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 92)

No. 1: Wọ́n Ń Kọ́ Àlàáfíà Dípò Ogun (w04-YR 1/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 8 sí ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 6)

No. 2: Nehemáyà 10:28-37

No. 3: Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa

No. 4: Bó O Ṣe Lè Yan Ọ̀rẹ́ Tòótọ́ (yp-YR orí 8 ojú ìwé 65 sí 67 àti 70 sí 72)

Feb. 20 Bíbélì kíkà: Nehemáyà 12 sí 13 Orin 118

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Kí Ọ̀rọ̀ Yọ̀ Mọ́ni Lẹ́nu (be-YR ojú ìwé 93 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: A Fún Ìjọsìn Tòótọ́ Ní Okun Agbára Padà (Nehemáyà 7 sí 13) (w86-YR 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 20 sí ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 20)

No. 2: Nehemáyà 13:1-14

No. 3: Bó O Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọ̀rẹ́ Rẹ Tó Kó sí Ìṣòro (yp-YR orí 8 ojú ìwé 68 sí 69)

No. 4: bÀwọn Kristẹni Ò Gbọ́dọ̀ Lọ́wọ́ sí Eré Kọ̀ǹpútà Oníwà-Ipá

Feb. 27 Bíbélì kíkà: Ẹ́sítérì 1 sí 5 Orin 215

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àwọn Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Ọ̀rọ̀ Á Fi Máa Yọ̀ Mọ́ Ẹ Lẹ́nu (be-YR ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 96 ìpínrọ̀ 3, yàtọ̀ sí àpótí tó wà ní ojú ìwé 95)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Mar. 6 Bíbélì kíkà: Ẹ́sítérì 6 sí 10 Orin 74

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ohun Tó O Lè Ṣe Bó O Bá Ń Kólòlò (be-YR ojú ìwé 95, àpótí)

No. 1: cÌdáǹdè Àtọ̀runwá Kúrò Lọ́wọ́ Ìparun-Àpatán (w87-YR 2/15 ojú ìwé 26 sí 27)

No. 2: Ẹ́sítérì 6:1-10

No. 3: Ìdáhùn Pẹ̀lẹ́ Máa Ń Yí Ìhónú Padà

No. 4: Ìdí Táwọn Èwe Fi Ń Ṣe Ohun Táwọn Ojúgbà Wọn Ń Ṣe (yp-YR orí 9 ojú ìwé 73 sí 76)

Mar. 13 Bíbélì kíkà: Jóòbù 1 sí 5 Orin 160

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Dídánudúró Níbi Àmì Ìpíngbólóhùn àti Dídánudúró Láti Yí Èrò Padà (be-YR ojú ìwé 97 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 98 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: dJóòbù Lo Ìfaradà—Àwa Pẹ̀lú Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀! (w94-YR 11/15 ojú ìwé 10 sí 14)

No. 2: Jóòbù 2:1-13

No. 3: Béèyàn Ṣe Lè Borí Ẹ̀mí Ṣohun Tẹ́gbẹ́ Ń Ṣe (yp-YR orí 9 ojú ìwé 77 sí 80)

No. 4: Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Káwọn Kristẹni Tòótọ́ Máa Ráhùn

Mar. 20 Bíbélì kíkà: Jóòbù 6 sí 10 Orin 214

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Dídánudúró Láti Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀ àti Dídánudúró Nígbà Tí Ipò Nǹkan Bá Mú Kó Yẹ Bẹ́ẹ̀ (be-YR ojú ìwé 99 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 100 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Ọ̀nà Tí Nǹkan Tẹ̀mí Gbà Dára Ju Nǹkan Tara Lọ (w04-YR 10/15 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: Jóòbù 7:1-21

No. 3: Kí Ló Túmọ̀ sí Láti Jẹ́ Ẹni Mímọ́ Gaara ní Ọkàn-Àyà

No. 4: Báwo Ni Ìrísí Ti Ṣe Pàtàkì Tó? (yp-YR orí 10)

Mar. 27 Bíbélì kíkà: Jóòbù 11 sí 15 Orin 8

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Títẹnumọ́ Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Yẹ (be-YR ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 102 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: “Ẹ Máa Fiyè sí Bí Ẹ Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀” (be-YR ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: Jóòbù 12:1-25

No. 3: Kí Ló Yẹ Kí Kristẹni Kan Fi Sọ́kàn Tó Bá Dọ̀rọ̀ Aṣọ Wíwọ̀? (yp-YR orí 11 ojú ìwé 90 sí ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 1)

No. 4: Ohun Tó Ń Jẹ́ Ká Máa Láyọ̀ Nídìí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa

Apr. 3 Bíbélì kíkà: Jóòbù 16 sí 20 Orin 50

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bó O Ṣe Lè Ṣàtúnṣe Lórí Títẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 102 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 104 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Bí A Ṣe Ń Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run (w04-YR 3/1 ojú ìwé 19 sí 21)

No. 2: Jóòbù 16:1-22

No. 3: Bí Jèhófà Ṣe Ń Fa Àwọn Èèyàn Láti Wá Sin Òun

No. 4: Àwọn Àǹfààní Wíwọṣọ ‘Tó Mọ Níwọ̀n Tá A sì Ṣètò Dáradára’ (yp-YR orí 11 ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 96)

Apr. 10 Bíbélì kíkà: Jóòbù 21 sí 27 Orin 119

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Títẹnumọ́ Àwọn Kókó Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Èrè Pọ̀ Nínú Lílépa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí (w04-YR 10/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Jóòbù 24:1-20

No. 3: Jèhófà Ń Fún Wa Ní Agbára Tó Ju Ìwọ̀n Ti Ẹ̀dá Lọ

No. 4: Béèyàn Ṣe Lè Ní Ọ̀wọ̀ Ara Ẹni (yp-YR orí 12 ojú ìwé 98 sí ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 2)

Apr. 17 Bíbélì kíkà: Jóòbù 28 sí 32 Orin 100

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ohùn Lọ́nà Tó Máa Bá Àwọn Tó Ò Ń Bá Sọ̀rọ̀ Mu (be-YR ojú ìwé 107 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 108 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Fífetísílẹ̀ ní Ìpàdé Ìjọ àti Láwọn Àpéjọ (be-YR ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 5)

No. 2: Jóòbù 29:1-25

No. 3: Ṣọ́ra Kó O Má Bàa Dá Ara Ẹ Lójú Jù (yp-YR orí 12 ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 103)

No. 4: Ìdí Tí Ẹnu Fi Ya Ogunlọ́gọ̀ sí Ọ̀nà Tí Jésù Gbà Ń Kọ́ni

Apr. 24 Bíbélì kíkà: Jóòbù 33 sí 37 Orin 94

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Máa Lo Ohùn Rẹ Lọ́nà Tó Túbọ̀ Dára Sí I (be-YR ojú ìwé 108 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 110 ìpínrọ̀ 2)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

May 1 Bíbélì kíkà: Jóòbù 38 sí 42 Orin 154

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ—Ṣe Ìyípadà Nínú Bí O Ṣe Ń Gbóhùn Sókè Tàbí Bí O Ṣe Ń Rẹ Ohùn Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: eÈrè Jóòbù—Orísun Kan fún Ìrètí (w94-YR 11/15 ojú ìwé 15 sí 20)

No. 2: Jóòbù 38:1-24

No. 3: Ọ̀nà Wo Ni Aísáyà 60:22 Gbà Ń Nímùúṣẹ Lóde Òní?

No. 4: Kí Ló Ń Fa Ìsoríkọ́? (yp-YR orí 13 ojú ìwé 104 sí ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 2)

May 8 Bíbélì kíkà: Sáàmù 1 sí 10 Orin 168

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ—Máa Yí Ìwọ̀n Ìyárasọ̀rọ̀ Rẹ Padà (be-YR ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 3 sí 113 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: fOnísáàmù Náà Kọrin Ìyìn Jèhófà (w86-YR 8/15 ojú ìwé 19 sí 20)

No. 2: Sáàmù 4:1-5:12

No. 3: Ohun Tó Ń Fa Ìsoríkọ́ àti Bá A Ṣe Lè Borí Rẹ̀ (yp-YR orí 13 ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 2)

No. 4: Máa Di Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rọ̀ Afúnni-nílera Mú

May 15 Bíbélì kíkà: Sáàmù 11sí 18 Orin 217

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ—Lo Onírúuru Ìró Ohùn (be-YR ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 114 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: gDúró Ti Jèhófà (w86-YR 10/15 ojú ìwé 28 sí 29)

No. 2: Sáàmù 14:1-16:6

No. 3: Láwọn Ọ̀nà Wo Ni Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì í Fi Í Ṣe Apá Kan Ayé?

No. 4: Bí A Ṣe Lè Kojú Ìsoríkọ́ (yp-YR orí 13 ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 114)

May 22 Bíbélì kíkà: Sáàmù 19 sí 25 Orin 23

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Hàn Nínú Ohùn Rẹ (be-YR ojú ìwé 115 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 116 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Ìjìnlẹ̀ Òye Rere Ń Múni Rí Ojú Rere (w04-YR 7/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: Sáàmù 22:1-22

No. 3: Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Dá Wà Ṣùgbọ́n Tí Kò Ní Dá Nìkan Wà (yp-YR orí 14 ojú ìwé 115 sí 117)

No. 4: hKí Ni Àwọn Ìránnilétí Ọlọ́run, Kí sì Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Fiyè sí Wọn?

May 29 Bíbélì kíkà: Sáàmù 26 sí 33 Orin 203

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìtara Bá Ohun Tí À Ń Sọ Mu (be-YR ojú ìwé 116 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 117 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Túbọ̀ Jáfáfá (be-YR ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: Sáàmù 30:1-31:8

No. 3: Láwọn Ọ̀nà Wo Ni Òtítọ́ Gbà Ń Dá Ẹnì Kan Sílẹ̀ Lómìnira?

No. 4: Ojútùú sí Ìdánìkanwà (yp-YR orí 14 ojú ìwé 118 sí 120)

June 5 Bíbélì kíkà: Sáàmù 34 sí 37 Orin 167

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Ọ̀yàyà Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 118 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: Agbára Tí Àdúrà Ní (w04-YR 8/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 10)

No. 2: Sáàmù 34:1-22

No. 3: Kí Ló Ń Mú Kéèyàn Máa Tijú (yp-YR orí 15 ojú ìwé 121 sí 122)

No. 4: Irú Àwọn Ìbọ̀rìṣà Wo La Gbọ́dọ̀ Sá Fún?

June 12 Bíbélì kíkà: Sáàmù 38 sí 44 Orin 216

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Ẹni Hàn (be-YR ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: Ipa Tí Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Kó Láti Mú Kí Agbára Ìrántí Ṣiṣẹ́ (be-YR ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Sáàmù 40:1-17

No. 3: Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tòótọ́ Kò Tako Bíbélì

No. 4: Béèyàn Ṣe Lè Borí Ìtìjú (yp-YR orí 15 ojú ìwé 123 sí 126)

June 19 Bíbélì kíkà: Sáàmù 45 sí 51 Orin 104

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìfaraṣàpèjúwe àti Ìrísí Ojú Ṣe Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 121 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Ìgbà Wo Ni Jésù Dé? (w04-YR 3/1 ojú ìwé 16, àpótí)

No. 2: Sáàmù 46:1-47:9

No. 3: Dídojúkọ Ẹ̀dùn Ọkàn (yp-YR orí 16)

No. 4: Báwo Ni Kristẹni Kan Ṣe Lè Jẹ́ Aláìlera, Síbẹ̀ Kó Lágbára? (2 Kọ́r. 12:10)

June 26 Bíbélì kíkà: Sáàmù 52 sí 59 Orin 103

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bó O Ṣe Lè Máa Lo Ìfaraṣàpèjúwe àti Ìrísí Ojú (be-YR ojú ìwé 122 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 123 ìpínrọ̀ 3)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

July 3 Bíbélì kíkà: Sáàmù 60 sí 68 Orin 45

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Wíwo Ojú Àwùjọ Nígbà Tó O Bá Wà Lóde Ẹ̀rí (be-YR ojú ìwé 124 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Bí Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ (w04-YR 11/1 ojú ìwé 29 sí 30)

No. 2: Sáàmù 60:1-61:8

No. 3: Ṣó Yẹ Ká Máa Rú Òfin Ọlọ́run Nítorí Pé Gbogbo Ìgbòkègbodò Kristẹni Là Ń Lọ́wọ́ Sí?

No. 4: Ojú Táwọn Kristẹni Fi Ń Wo Ẹ̀kọ́ Ìwé (yp-YR orí 17)

July 10 Bíbélì kíkà: Sáàmù 69 sí 73 Orin 225

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Wíwo Ojú Àwùjọ Nígbà Tó O Bá Ń Sọ Àsọyé (be-YR ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Kí Nìdí Tó O Fi Gbọ́dọ̀ Fi Ara Rẹ̀ fún Ìwé Kíkà? (be-YR ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Sáàmù 71:1-18

No. 3: Béèyàn Ṣe Lè Mú Kí Èsì Ìdánwò Rẹ̀ Sunwọ̀n Sí I (yp-YR orí 18)

No. 4: iÌdí Táwọn Kristẹni Ò Fi Gbọ́dọ̀ Máa Ṣojúsàájú

July 17 Bíbélì kíkà: Sáàmù 74 sí 78 Orin 28

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ Lóde Ẹ̀rí (be-YR ojú ìwé 128 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 129 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Ète Tí Ó Tọ́ Ni Kí Ó Sún Ọ Kàwé (be-YR ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: Sáàmù 75:1-76:12

No. 3: Kí Ni Wíwá Jèhófà Túmọ̀ Sí? (Sef. 2:3)

No. 4: Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Máa Yọ Ọ́ Lẹ́nu Nílé Ìwé (yp-orí 19)

July 24 Bíbélì kíkà: Sáàmù 79 sí 86 Orin 112

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ Lórí Pèpéle (be-YR ojú ìwé 129 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 130 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: “Àgọ́ Àwọn Adúróṣánṣán Yóò Gbilẹ̀” (w04-YR 11/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 2)

No. 2: Sáàmù 82:1-83:18

No. 3: Béèyàn Ṣe Lè Bá Olùkọ́ Rẹ́ (yp-orí 20)

No. 4: Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Kí Ẹ̀dá Èèyàn Aláìpé Múnú Ọlọ́run Dùn?

July 31 Bíbélì kíkà: Sáàmù 87 sí 91 Orin 57

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ Nígbà Tó O Bá Ń Kàwé fún Àwùjọ (be-YR orí 130 ìpínrọ̀ 2 sí 4)

No. 1: “Bí Ìmọ̀ Ṣe Jẹ́ Ohun Rírọrùn,” Tí Ọgbọ́n sì Máa Ń Ṣọ́ Wa (w04-YR 11/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 7)

No. 2: Sáàmù 89:1-21

No. 3: Apá Kan Ìjọsìn Wa Ni Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Jẹ́

No. 4: Bá A Ṣe Lè Rí Iṣẹ́ Tí Iṣẹ́ Náà Ò sì Ní Bọ́ (yp-YR orí 21)

Aug. 7 Bíbélì kíkà: Sáàmù 92 sí 101 Orin 190

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìrísí Tó Dára Ń Buyì Kún Ìhìn Rere (be-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Bá A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ (be-YR ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2)

No. 2: Sáàmù 92:1-93:5

No. 3: Yan Iṣẹ́ Ìgbésí Ayé Tó Dáa Jù (yp-YR orí 22)

No. 4: Bí Ìwà Títọ́ Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó

Aug. 14 Bíbélì kíkà: Sáàmù 102 sí 105 Orin 1

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Báwo Ni Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti Ìyèkooro Èrò Inú Ṣe Tan Mọ́ Wíwọṣọ àti Mímúra (be-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: “Àwọn Iṣẹ́ Rẹ Mà Pọ̀ O, Jèhófà!” (w04-YR 11/15 ojú ìwé 8 sí 9)

No. 2: Sáàmù 104:1-24

No. 3: Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Máa Ṣọ́nà

No. 4: Kí Nìdí Tí Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó Fi Burú (yp-YR orí 23)

Aug. 21 Bíbélì kíkà: Sáàmù 106 sí 109 Orin 201

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àǹfààní Tó Wà Nínú Kí Ìmúra Èèyàn Wà Létòlétò (be-YR ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Ohun Táwọn Ojúgbà Yín Ń Ṣe Láìkọ́kọ́ Ronú Lé E Lórí Dáadáa (w04-YR 10/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 5)

No. 2: Sáàmù 107:20-43

No. 3: Bó O Ṣe Ní Lọ́wọ́ sí Ìṣekúṣe (yp-YR orí 24)

No. 4: Àwọn Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Fara Wé Ọlọ́run?

Aug. 28 Bíbélì kíkà: Sáàmù 110 sí 118 Orin 125

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Níní Ìrísí Tó Dára Kò Ní Mú Àwọn Èèyàn Kọsẹ̀ (be-YR ojú ìwé 133, ìpínrọ̀ 2 sí 4)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Sept. 4 Bíbélì kíkà: Sáàmù 119 Orin 59

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìdúró Ara àti Ohun Èlò Tó Wà ní Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lérè (be-YR ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: Sáàmù 119:25-48

No. 3: Ohun Tó Ń Mú Ká Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ Ìjọba

No. 4: Ṣé Bẹ́ẹ̀ Náà Ni Ìdánìkanhùwà Ìbálòpọ̀ Ṣe Burú Tó Ni? (yp-YR orí 25)

Sept. 11 Bíbélì kíkà: Sáàmù 120 sí 134 Orin 65

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Dín Àyà Jíjá Kù Bó O Bá Ń Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 135 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 137 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìwádìí (be-YR ojú ìwé 33 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: Sáàmù 121:1-123:4

No. 3: Bó Ò Ṣe Ní Kó Sínú Ìdẹkùn Ìdánìkanhùwà Ìbálòpọ̀ (yp-YR orí 26)

No. 4: Kí Ni Àbùmọ́, Báwo Ni Jésù sì Ṣe Lò Ó?

Sept. 18 Bíbélì kíkà: Sáàmù 135 sí 141 Orin 97

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Di Ẹni Tí Ọkàn Rẹ̀ Máa Ń Balẹ̀ (be-YR ojú ìwé 137 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 138 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: j‘Fi Ìbùkún fún Jèhófà’—Èé Ṣe? (w86-YR 12/15 ojú ìwé 30 sí 31)

No. 2: Sáàmù 136:1-26

No. 3: Kí Nìdí Tí Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi Fi Jẹ́ Oúnjẹ Àjọjẹ?

No. 4: Ìdí Tí Àìlábòsí Fi Jẹ́ Ìlànà Dídára Jù Lọ (yp-YR orí 27)

Sept. 25 Bíbélì kíkà: Sáàmù 142 sí 150 Orin 5

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìdí Tí Lílo Makirofóònù Fi Ṣe Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 139 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 140 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: kỌlọ́run Aláyọ̀, Àwọn Èèyàn Aláyọ̀! (w87-YR 3/15 ojú ìwé 21 sí 22)

No. 2: Sáàmù 142:1-143:12

No. 3: Bó O Ṣe Lè Borí Ìfẹ́ Aláìnírònú (yp-YR orí 28)

No. 4: Àwọn Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Máa Ro Tàwọn Ẹlòmíì Mọ́ Tiwa?

Oct. 2 Bíbélì kíkà: Òwe 1 sí 6 Orin 111

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Máa Lo Makirofóònù Lọ́nà Tó Yẹ (be-YR ojú ìwé 140 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 142 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Fetí sí Ọgbọ́n Kó O sì Fojú Ìníyelórí Wò Ọgbọ́n (Òwe 1 sí 4) (w87-YR 5/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1 sí 11)

No. 2: Òwe 5:1-23

No. 3: Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá O Ti Tó Ẹni Tó Ń Dá Ọjọ́ Àjọròde (yp-YR orí 29 ojú ìwé 225 sí 231 àti 234 sí 235)

No. 4: lMá Ṣe Máa Tan Ìtàn Èké Kálẹ̀ (2 Tím. 4:4)

Oct. 9 Bíbélì kíkà: Òwe 7 sí 11 Orin 73

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Bíbélì Láti Fi Dáhùn Ìbéèrè (be-YR ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Àwọn Ọ̀nà Láti Gbà Fi Ọgbọ́n Hàn Sóde (Òwe 5 sí 15) (w87-YR 5/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 12 sí ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 10)

No. 2: Òwe 7:1-27

No. 3: Àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni Ń Mú Kí Ẹgbẹ́ Ará Wa Túbọ̀ Wà Níṣọ̀kan

No. 4: Ǹjẹ́ Ewu Wà Nínú Kí Ọkùnrin àti Obìnrin Máa Ṣọ̀rẹ́? (yp-YR orí 29 ojú ìwé 232 sí 233)

Oct. 16 Bíbélì kíkà: Òwe 12 sí 16 Orin 180

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Béèyàn Ṣe Lè Túbọ̀ Jáfáfá Nínú Lílo Bíbélì (be-YR ojú ìwé 144 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Kíkọ́ Láti Lo Àwọn Ohun Èlò Ìṣèwádìí Yòókù (be-YR ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 38 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: Òwe 14:1-21

No. 3: Pípinnu Ìgbà Tó Yẹ Láti Ṣègbéyàwó (yp-YR orí 30)

No. 4: Kí Ló Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Túbọ̀ Máa Pọkàn Pọ̀ Nígbà Tá A Bá Wà Nípàdé?

Oct. 23 Bíbélì kíkà: Òwe 17 sí 21 Orin 131

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fúnni Níṣìírí Láti Lo Bíbélì (be-YR ojú ìwé 145 sí 146)

No. 1: Bẹ̀rù Jèhófà, Ìwọ Yóò sì Láyọ̀—Apá 1 (Òwe 16 sí 24) (w87-YR 5/15 ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 11 sí 20)

No. 2: Òwe 17:1-20

No. 3: Ojú Wo Làwọn Kristẹni Fi Ń Wo Àwọn Àgbàlagbà

No. 4: Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bó Bá Jẹ́ Ojúlówó Ìfẹ́ Ni (yp-YR orí 31 ojú ìwé 242 sí 247 àti 250 sí 251)

Oct. 30 Bíbélì kíkà: Òwe 22 sí 26 Orin 9

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Láti Máa Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Máa Yé Ẹni Tó Ń Gbọ́ Wa (be-YR ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 2)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Nov. 6 Bíbélì kíkà: Òwe 27 sí 31 Orin 51

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ọ̀rọ̀ Yíyẹ Láti Fi Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 149 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Bẹ̀rù Jèhófà, Ìwọ Yóò sì Láyọ̀—Apá 2 (Òwe 25 sí 31) (w87-YR 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí 19)

No. 2: Òwe 28:1-18

No. 3: Bó O Ṣe Lè Gbọ́kàn Kúrò Lórí Ìjákulẹ̀ (yp-YR orí 31 ìpínrọ̀ 248 sí 249)

No. 4: Ìdí Tá Ò Fi Gbọ́dọ̀ Ṣèdájọ́ Àwọn Tá À Ń Bá Pàdé Lóde Ẹ̀rí Látàrí Ìrísí Wọn

Nov. 13 Bíbélì kíkà: Oníwàásù 1 sí 6 Orin 25

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìtẹnumọ́ Yíyẹ Kan Fífi Bí Ọ̀rọ̀ Ṣe Rí Lára Hàn (be-YR ojú ìwé 150 ìpínrọ̀ 1 sí 2)

No. 1: Ìjọsìn Tòótọ́ Ń Tẹ́ni Lọ́rùn (w87-YR 9/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: Oníwàásù 5:1-15

No. 3: Ọ̀nà Wo Ni Ọlọ́run Gbà Fi Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Pa Mọ́ Fáwọn Ọlọgbọ́n Àtàwọn Amòye? (Mát. 11:25)

No. 4: Bó O Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ìfẹ́sọ́nà (yp-YR orí 32)

Nov. 20 Bíbélì kíkà: Oníwàásù 7 sí 12 Orin 37

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Tẹnu Mọ́ Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Yẹ (be-YR ojú ìwé 150 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 151 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n (Oníwàásù 7 sí 12) (w87-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí 20)

No. 2: Oníwàásù 9:1-12

No. 3: Ewu Tó Wà Nínú Káwọn Ọ̀dọ́ Máa Mutí (yp-YR orí 33)

No. 4: Kí Nìdí Tí Ò Fi Dáa Kéèyàn Máa Jowú?

Nov. 27 Bíbélì kíkà: Orin Sólómọ́nì 1 sí 8 Orin 11

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Onírúurú Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 151 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 152 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: Ìfẹ́ Tòótọ́ Máa Ń Yọ Ayọ̀-Ìṣẹ́gun! (w87-YR 11/15 ojú ìwé 24 sí 25)

No. 2: Orin Sólómọ́nì 7:1-8:4

No. 3: Kí Nìdí Tí Aṣọ Kristẹni Fi Gbọ́dọ̀ Mọ́ Tónítóní Kó sì Bójú Mu?

No. 4: Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kéèyàn Lo Oògùn Olóró (yp-YR orí 34)

Dec. 4 Bíbélì kíkà: Aísáyà 1 sí 5 Orin 90

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìwé Mímọ́ Bí O Ti Yẹ (be-YR ojú ìwé 153 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 154 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: aAyọ̀ Yíyọ̀ Fáwọn Tí Ń Rìn Nínú Ìmọ́lẹ̀ (w01-YR 3/1 ojú ìwé 12 sí 17)

No. 2: Aísáyà 3:1-15

No. 3: Ṣe Àṣàyàn Ohun Tí Wàá Máa Kà (yp-YR orí 35)

No. 4: bKí Nìdí Táwọn Kristẹni Fi Gbọ́dọ̀ “Lọ́ra Nípa Ìrunú” (Ják. 1:19)

Dec. 11 Bíbélì kíkà: Aísáyà 6 sí 10 Orin 204

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Ìlò Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere (be-YR ojú ìwé 154 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 155 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Ṣíṣe Ìlapa Èrò (be-YR ojú ìwé 39 sí 42)

No. 2: Aísáyà 10:1-14

No. 3: Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Dárí Ji Ẹni Tó Bá Ṣẹ̀ Wá?

No. 4: Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Tẹlifíṣọ̀n Wíwò Kó Bá Ẹ (yp-YR orí 36)

Dec. 18 Bíbélì kíkà: Aísáyà 11 sí 16 Orin 47

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Máa Fèrò Wérò Látinú Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 155 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 156 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Jẹ́ Káwọn Òbí Yín Ràn Yín Lọ́wọ́ Kẹ́ Ẹ Lè Dáàbò Bo Ọkàn Yín (w04-YR 10/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Aísáyà 11:1-12

No. 3: Ojú Tó Yẹ Ká Máa Fi Wo Eré Ìnàjú (yp-YR orí 37)

No. 4: Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kò Ní Kópa Nínú Ogun Amágẹ́dọ́nì

Dec. 25 Bíbélì kíkà: Aísáyà 17 sí 23 Orin 53

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò (be-YR ojú ìwé 157 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mú látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

b Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mú látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

c Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

d Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

e Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

f Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

g Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

h Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mú látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

i Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mú látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

j Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

k Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

l Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mú látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

a Àwọn arákùnrin nìkan ni kí a yàn án fún.

b Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mú látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́