Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 12
Orin 218
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù June sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ June 15 àti Jí! April-June. Nínú ọ̀kan lára ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo àwọn ìwé ìròyìn nígbà tá a ò bá sí lóde ẹ̀rí.
20 min: “Iṣẹ́ Ìyọ́nú Ni Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa.”a Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ.
15 min: Fọkàn Tán “Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 3.
Orin 47 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 19
Orin 21
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
20 min: Ọ̀rọ̀ Tó Bọ́ Sákòókò Mà Dára O! Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ January 1, 2006, ojú ìwé 16 sí 19. Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, sọ̀rọ̀ lórí àǹfààní mẹ́rin tó wà nínú kéèyàn máa gbóríyìn fáwọn ẹlòmíì bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àkòrí náà, “Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Rẹ̀.” Kó o wá ní kí àwùjọ fèsì àwọn ìbéèrè yìí: Ta lẹnì kan tá ò gbọ́dọ̀ má yìn? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn lọ́nà títọ́ fáwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni? Kí làwọn nǹkan tá a lè gbóríyìn fáwọn tá a jọ wà nínú ìjọ lé lórí? Àǹfààní wo ló wà nínú gbígbóríyìn fáwọn tá a jọ wà nínú ìdílé, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe é? Ọ̀nà wo ni bí ẹnì kan ṣe gbóríyìn fún ọ gbà fún ọ ní ìṣírí tàbí okun?
15 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Gbígbóríyìn fún Wọn.”b Fi àṣefihàn kan kún un nínú èyí tí akéde ti fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí onílé sọ, tó sì gbóríyìn fún un látọkànwá, tó tún wá lo ohun tí onílé sọ yẹn bí àtẹ̀gùn láti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó bá kókó yẹn mu.
Orin 96 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 26
Orin 63
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! April-June. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí akéde náà béèrè ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ tó lè fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni dáhùn nígbà tó bá padà ṣèbẹ̀wò.
15 min: Bá A Ṣe Lè Mọwọ́ Irin Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Wa Tuntun. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní kí àwùjọ sọ àwọn nǹkan tó fà wọ́n mọ́ra nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, àwọn nǹkan bí, àwọn ìbéèrè tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àti àpótí àtúnyẹ̀wò tó tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì tó wà lábẹ́ orí kọ̀ọ̀kan (ojú ìwé 106, 114); àwọn àwòrán (ojú ìwé 122 sí 123, 147, 198); àtàwọn àfikún (ojú ìwé 197, ìpínrọ̀ 1 àti 2). Ọ̀nà tá a gbà gbé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ dùn létí ó sì tuni lára (ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 12). Àlàyé rẹ̀ rọrùn láti lóye, ó sì ṣe kedere (ojú ìwé 58, ìpínrọ̀ 5) àwọn àkàwé rẹ̀ bá ẹ̀kọ́ ibẹ̀ mu (ojú ìwé 159, ìpínrọ̀ 12). Ṣe la mú kí ọ̀rọ̀ àkọ́sọ inú rẹ̀ mú kó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (ojú ìwé 3 sí 7). Sọ àwọn ìrírí táwọn ará ti gbádùn látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé tuntun náà.
15 min: Bá A Ṣe Máa Wàásù Ìhìn Rere Lóṣù July. Kókó wo làwọn èèyàn máa ń fẹ́ jíròrò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín? Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tó ṣàṣeyọrí nínú lílo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni bóyá tí wọ́n tiẹ̀ ti fi ìwé náà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kó o wá ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé náà nínú ìwàásù ilé-dé-ilé nípa lílo àwọn àbá tó máa ń wọ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín lọ́kàn.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January 2005, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 5.
Orin 208 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 3
Orin 111
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù June sílẹ̀ bí wọn ò bá tíì fi sílẹ̀ tẹ́lẹ̀.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: “Bọ́wọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run.”c Ní káwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn àfojúsùn wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kí wọ́n sì sọ ohun tí wọ́n ń ṣe kí ọwọ́ wọn lè tẹ̀ ẹ́. O lè ti ní kẹ́nì kan tàbí méjì múra sílẹ̀ ṣáájú láti sọ̀rọ̀.
Orin 30 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.