Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 28
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 6 ìpínrọ̀ 19 sí 25 àti àpótí tó wà lójú ìwé 65
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 3-6
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù July. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Lẹ́yìn náà, yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o sì ní kí àwùjọ sọ àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan. Ní ìparí iṣẹ́ rẹ, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà ìpadàbẹ̀wò.—Wo km 8/07 ojú ìwé 3.
15 min: Wọ́n Kọ́ Ọ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Àwọn èèyàn mọ Tímótì gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere tó nítara tó sì já fáfá. (Fílí. 2:20-22) Dé ìwọ̀n àyè kan, ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà kọ́ ọ ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. (2 Tím. 1:5; 3:15) Àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí, tá a gbé ka Ìwé Mímọ́ máa ṣèrànwọ́ fún àwọn òbí kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti di ajíhìnrere tó já fáfá. (1) Má ṣe jẹ́ kó pẹ́ rárá kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í mú ọmọ rẹ lọ sóde ẹ̀rí; dá a lẹ́kọ̀ọ́ láti máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ débi tí ọjọ́ orí àti agbára rẹ̀ bá gbé e dé. (Òwe 22:6) (2) Fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa fífi iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe ohun àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ. (Fílí. 1:9, 10) (3) Nígbà Ìjọsìn Ìdílé tàbí láwọn ìgbà míì, máa gbin ìfẹ́ àti ìmọrírì fún iṣẹ́ ìwàásù sí ọmọ rẹ lọ́kàn. (Diu. 6: 6, 7) (4) Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ fi hàn pé o lẹ́mìí tó dáa nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Fílí. 3:8; 4:8; 1 Tím. 1:12) (5) Ẹ sọ ọ́ dàṣà láti máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù gẹ́gẹ́ bí ìdílé. (Ìṣe 5:41, 42) (6) Àwọn òjíṣẹ́ tó ní ìtara fún iṣẹ́ ìsìn ni kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́. (Òwe 13:20) Ní kí àwọn ará sọ ohun táwọn òbí wọn ti ṣe ní pàtó tó mú kí wọ́n lè máa gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì já fáfá lẹ́nu rẹ̀.