Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 28, 2010. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ May 3 sí June 28, 2010, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
1. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí Dáfídì ṣe ṣọ̀fọ̀ nígbà tí Ábínérì kú? (2 Sám. 3:31-34) [w05 5/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 6; w06 7/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 9 sí 10]
2. Kí la lè rí kọ́ látinú 2 Sámúẹ́lì 5:12? [w05 5/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 7]
3. Ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé èrò tó dára ló wà lọ́kàn wa, ǹjẹ́ ìyẹn sọ pé ká yí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe pa dà? (2 Sám. 6:1-7) [w05 5/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 8]
4. Báwo ni ohun tí Dáfídì ṣe fún Mefibóṣẹ́tì ṣe fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí? (2 Sám. 9:7) [w02 5/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 5]
5. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àjọṣe Ítítáì ará Gátì àti Dáfídì Ọba? (2 Sám. 15:19-22) [w09 5/15 ojú ìwé 27 sí 28]
6. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, kí nìdí tá a fi lè sọ pé irọ́ ni Síbà pa mọ́ Mefibóṣẹ́tì? (2 Sám. 16:1-4) [w02 2/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
7. Nígbà tí Dáfídì ní kí Básíláì ẹni ọgọ́rin ọdún wá máa gbé ní àgbàlá ọba, kí nìdí tí Básíláì fi dábàá pé kí Kímúhámù gbádùn àǹfààní yẹn? (2 Sám. 19:33-37) [w07 6/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 13]
8. Báwo ni jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ṣe sọ Dáfídì di ẹni ńlá? (2 Sám. 22:36) [w07 11/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1; w04 11/1 ojú ìwé 29]
9. Kí nìdí tí Ádóníjà fi gbìyànjú láti gba ìjọba nígbà tí Dáfídì kò tíì kú? (1 Ọba 1:5) [w05 7/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 5]
10. Kí nìdí tí Jèhófà fi dáhùn àdúrà tí Sólómọ́nì gbà pé kí Jèhófà fún òun ní ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀? (1 Ọba 3:9) [w05 7/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2]